ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍNTÁNẸ́Ẹ̀TÌ ti Watchtower
ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍŃTÁNẸ́Ẹ̀TÌ
ti Watchtower
Yorùbá
ọ́
  • ẹ
  • ọ
  • ṣ
  • ń
  • ẹ́
  • ẹ̀
  • ọ́
  • ọ̀
  • BÍBÉLÌ
  • ÌTẸ̀JÁDE
  • ÌPÀDÉ
  • jr orí 11 ojú ìwé 128-139
  • ‘Àwọn Olùṣọ́ Àgùntàn Ní Ìbámu Pẹ̀lú Ọkàn-àyà Mi’

Kò sí fídíò kankan ní apá yìí.

Má bínú, fídíò yìí kò jáde.

  • ‘Àwọn Olùṣọ́ Àgùntàn Ní Ìbámu Pẹ̀lú Ọkàn-àyà Mi’
  • Ọ̀rọ̀ Tí Ọlọ́run Bá Wa Sọ Nípasẹ̀ Jeremáyà
  • Ìsọ̀rí
  • Àpilẹ̀kọ Míì Tó Jọ ọ́
  • BÍ WỌ́N ṢE Ń BÓJÚ TÓ AGBO ỌLỌ́RUN
  • ‘WỌN YÓÒ BỌ́ YÍN DÁJÚDÁJÚ’
  • “ÈYÍ NI OHUN TÍ JÈHÓFÀ WÍ”
  • BÁNI WÍ “DÉ ÌWỌ̀N TÍ Ó BẸ́TỌ̀Ọ́ MU”
  • Ẹ̀yin Olùṣọ́ Àgùntàn, Ẹ Tẹ̀ Lé Àpẹẹrẹ Àwọn Olùṣọ́ Àgùntàn Ńlá Náà
    Ilé Ìṣọ́ Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—2013
  • Fifi Jẹlẹnkẹ Bojuto Awọn Agutan Ṣiṣeyebiye Ti Jehofa
    Ilé-Ìṣọ́nà Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—1993
  • Àwọn Olùṣọ́ Àgùntàn Tí Wọ́n Jẹ́ “Àpẹẹrẹ Fún Agbo”
    Ilé Ìṣọ́ Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—2006
  • Ẹ̀yin Kristẹni Olùṣọ́ Àgùntàn,—‘Ẹ Jẹ́ Kí Ọkàn-Àyà Yín Gbòòrò’!
    Ilé Ìṣọ́ Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—2000
Àwọn Míì
Ọ̀rọ̀ Tí Ọlọ́run Bá Wa Sọ Nípasẹ̀ Jeremáyà
jr orí 11 ojú ìwé 128-139

Orí Kọkànlá

‘Àwọn Olùṣọ́ Àgùntàn Ní Ìbámu Pẹ̀lú Ọkàn-àyà Mi’

1, 2. (a) Kí ló lè ṣẹlẹ̀ tí kò bá sẹ́ni tó ń dáàbò bo agbo àgùntàn kan? (b) Láyé ìgbà tí wọ́n ń kọ Bíbélì, kí ni iṣẹ́ àwọn olùṣọ́ àgùntàn?

NÍGBÀ tí Hiroyasu wà lọ́mọdé ní orílẹ̀-èdè Japan, ìyá rẹ̀ ra àgbò kan àti abo àgùntàn kan fún un kó máa sìn wọ́n. Abo àgùntàn náà ń bí ọmọ méjì-méjì lọ́dún, àgùntàn rẹ̀ wá ń pọ̀ sí i. Nígbà tó fi máa di ọmọ ọdún méjìlá, àgùntàn rẹ̀ ti tó méjìlá sí mẹ́tàlá. Hiroyasu wá sọ ohun kan tó ṣẹlẹ̀, ó ní: “Láàárọ̀ kùtù ọjọ́ kan, mo ń gbọ́ igbe àwọn àgùntàn náà látorí ibùsùn mi, àmọ́ mi ò dìde lọ yọjú sí wọn lẹ́sẹ̀kẹsẹ̀. Nígbà tí mo fi máa débẹ̀, mo rí i pé àwọn ajá igbó kan sá kúrò níbi táwọn ọ̀dọ́ àgùntàn mi wà. Wọ́n ti fa ikùn wọn ya. Mo bá sáré ń wá ìyá àwọn àgùntàn náà. Nígbà tí mo máa rí i, ó ṣì ń mí, àmọ́ inú ọ̀gbàrá ẹ̀jẹ̀ ló wà. Ó wá jẹ́ pé èyí àgbò nìkan ló yè bọ́. Inú mi bà jẹ́ gan-an. Ǹ bá ti jáde lọ wò wọ́n ní gbàrà tí mo kọ́kọ́ gbọ́ igbe wọn, nítorí pé wọn ò lè gba ara wọn lọ́wọ́ àwọn ajá igbó wọ̀nyẹn.”

2 Láyé ìgbà tí wọ́n ń kọ Bíbélì, ó fẹ́rẹ̀ẹ́ jẹ́ pé gbogbo èèyàn ló mọ bí iṣẹ́ olùṣọ́ àgùntàn ṣe rí. Iṣẹ́ rẹ̀ ni láti da àwọn ẹran ọ̀sìn tó wà níkàáwọ́ rẹ̀ lọ síbi tí koríko tútù wà kó sì rí i pé wọ́n rí oúnjẹ jẹ dáadáa. Ó tún máa ń dáàbò bò wọ́n lọ́wọ́ àwọn nǹkan tó lè pa wọ́n jẹ, á sì tún wá àwọn tó bá sọ nù. (1 Sám. 17:34-36) Ó máa ń rí i pé àwọn àgùntàn òun dùbúlẹ̀ jẹ́ẹ́jẹ́ẹ́ láìséwu. Ó sì tún máa ń ṣèrànwọ́ fún èyí tó bá fẹ́ bímọ, á sì tọ́jú ọmọ tí wọ́n ṣẹ̀ṣẹ̀ bí. Ọ̀pọ̀ nínú àwọn tó kọ Bíbélì, títí kan Jeremáyà, ló lo olùṣọ́ àgùntàn láti fi ṣàkàwé ẹnì kan tí wọ́n fa àwọn èèyàn lé lọ́wọ́ pé kó máa bójú tó wọn, ì báà jẹ́ ọba wọn tàbí alábòójútó wọn nípa tẹ̀mí.

3. Nígbà tí Jeremáyà lo èdè ọ̀rọ̀ náà, “olùṣọ́ àgùntàn” àti “ṣe olùṣọ́ àgùntàn,” kí ló fi tọ́ka sí?

3 Ìgbà táwọn kan nínú ìjọ máa ń rò pé àwọn alàgbà ń ṣe iṣẹ́ olùṣọ́ àgùntàn ni ìgbà tí wọ́n bá rí i pé wọ́n lọ sọ́dọ̀ àwọn ará ìjọ láti ṣèrànwọ́ fún wọn tàbí láti gbà wọ́n níyànjú. Àmọ́ tá a bá wo bí Jeremáyà ṣe lo ọ̀rọ̀ náà “olùṣọ́ àgùntàn” àti ọ̀rọ̀ náà “ṣe olùṣọ́ àgùntàn,” a ó rí i pé ṣe ló fi tọ́ka sí gbogbo ojúṣe tí àwọn tó ń ṣàbójútó ní Júdà gbọ́dọ̀ máa ṣe sáwọn èèyàn Júdà. Ọlọ́run máa ń bá àwọn ọmọ aládé, àwọn wòlíì àtàwọn àlùfáà Júdà wí, pé olùṣọ́ àgùntàn burúkú ni wọ́n torí pé ire àwọn aráàlú ò jẹ wọ́n lógún. (Jer. 2:8) Nítorí pé kálukú wọn ń lépa ire tara wọn, wọ́n ń fìyà jẹ àwọn “àgùntàn” wọn, ìyẹn àwọn aráàlú, wọ́n ń ṣì wọ́n lọ́nà, wọ́n sì ń pa wọ́n tì. Àní ó burú débi pé wọn ò tiẹ̀ yà sí ọ̀rọ̀ ìjọsìn àwọn èèyàn Ọlọ́run rárá. Jèhófà ké “ègbé” sórí àwọn olùṣọ́ àgùntàn burúkú yẹn, ó sì fi dá àwọn èèyàn rẹ̀ lójú pé òun máa fún wọn láwọn olùṣọ́ àgùntàn tó lójú àánú táá máa gbọ́ tiwọn táá sì máa dáàbò bò wọ́n.—Ka Jeremáyà 3:15; 23:1-4.

4. Àwọn wo ló ń bójú tó àwọn àgùntàn Ọlọ́run lóde òní, irú ẹ̀mí wo ló sì yẹ kí wọ́n máa fi bójú tó wọn?

4 Jésù Olórí Olùṣọ́ Àgùntàn Jèhófà, ẹni tó di Orí ìjọ Kristẹni, ló mú ìlérí Ọlọ́run yìí ṣẹ ní pàtàkì. Ó lóun ni “olùṣọ́ àgùntàn àtàtà” tó ń fi ìyọ́nú bójú tó àwọn tó wà níkàáwọ́ rẹ̀. (Jòh. 10:11-15) Lóde òní, àwọn tí Jèhófà ń lò láti bójú tó àwọn àgùntàn rẹ̀ tó wà lórí ilẹ̀ ayé ni àwọn olùṣọ́ àgùntàn tó ń sìn lábẹ́ Kristi, yálà àwọn ẹni àmì òróró ti ẹgbẹ́ ẹrú olóòótọ́ àti olóye ni o tàbí àwọn alàgbà tó mọṣẹ́ wọn níṣẹ́ látinú “ogunlọ́gọ̀ ńlá.” (Ìṣí. 7:9) Bí Jésù ṣe fi gbogbo ara jin iṣẹ́ yìí làwọn náà ṣe máa ń gbìyànjú láti fi gbogbo ara wọn jin iṣẹ́ náà. Wọ́n ń sa gbogbo ipá wọn láti bọ́ ìjọ, kí wọ́n sì ṣìkẹ́ rẹ̀ bíi ti Kristi. Èyíkéyìí lára wọn tó bá pa àwọn arákùnrin rẹ̀ tì tàbí ó jẹ olúwa lé wọn lórí tàbí ó le koko mọ́ wọn tàbí ó ń fẹlá lé wọn lórí, gbé! (Mát. 20:25-27; 1 Pét. 5:2, 3) Kí ni Jèhófà ń fẹ́ káwọn olùṣọ́ àgùntàn inú ìjọ máa ṣe lóde òní? Nínú àwọn ìwé tí Jeremáyà kọ, kí la rí kọ́ nípa irú ìwà àti ẹ̀mí tó yẹ káwọn alàgbà ní bí wọ́n ṣe ń bójú tó àwọn iṣẹ́ wọn? Ẹ jẹ́ ká ṣàyẹ̀wò ojúṣe wọn gẹ́gẹ́ bí alábòójútó àti olùpèsè ìrànwọ́, gẹ́gẹ́ bí olùkọ́ nínú ìjọ àti láwọn ibòmíì àti gẹ́gẹ́ bí onídàájọ́.

BÍ WỌ́N ṢE Ń BÓJÚ TÓ AGBO ỌLỌ́RUN

5-7. (a) Ọ̀nà wo ni Jèhófà ń fẹ́ káwọn alàgbà máa gbà bójú tó àwọn àgùntàn rẹ̀, kí sì nìdí rẹ̀? (b) Báwo làwọn alàgbà ṣe máa fi hàn pé àwọn nífẹ̀ẹ́ àwọn ará gan-an, títí kan àwọn tó ṣáko lọ?

5 Àpọ́sítélì Pétérù sọ pé Jèhófà ni “olùṣọ́ àgùntàn àti alábòójútó ọkàn” wa. (1 Pét. 2:25) Irú ọwọ́ wo ni Ọlọ́run fi mú “àwọn àgùntàn” rẹ̀? A ó rí ìdáhùn rẹ̀ tá a bá wo ohun tó ṣẹlẹ̀ nígbà ayé Jeremáyà. Lẹ́yìn tí Jèhófà ti sọ̀rọ̀ sí àwọn olùṣọ́ àgùntàn burúkú tí wọ́n fọ́n agbo Ọlọ́run ká, tí wọn ò sì bìkítà nípa wọn, ó sọ pé òun máa “kó” àwọn àgùntàn òun “jọpọ̀,” òun á sì kó wọn pa dà wá sílẹ̀ ìjẹko wọn. Ó wá ṣèlérí pé òun máa yan àwọn olùṣọ́ àgùntàn rere fún wọn, tí wọ́n máa “ṣe olùṣọ́ àgùntàn wọn ní ti gidi,” tí wọ́n á sì dáàbò bò wọ́n kúrò lọ́wọ́ àwọn ọ̀tá oníwà bí ìkookò. (Jer. 23:3, 4) Dájúdájú, àwọn àgùntàn Jèhófà yẹn ṣe pàtàkì gan-an lójú rẹ̀. Bẹ́ẹ̀ náà làwọn àgùntàn rẹ̀ tòde òní. Ohun iyebíye ló ná an kó lè ṣeé ṣe fún wọn láti jèrè ìyè àìnípẹ̀kun.—1 Pét. 1:18, 19.

6 Bíi tàwọn olùṣọ́ àgùntàn agbo ẹran náà lọ̀rọ̀ àwọn alábòójútó ìjọ Kristẹni ṣe rí, wọn ò gbọ́dọ̀ fọwọ́ dẹngbẹrẹ mú àbójútó ìjọ. Tó o bá jẹ́ alàgbà, ǹjẹ́ o máa ń wà lójúfò kó o lè rí àmì èyíkéyìí tó bá fi hàn pé ìnira ń bá àwọn ará kan, ṣé ó sì máa ń yá ọ lára láti tètè ràn wọ́n lọ́wọ́? Sólómọ́nì ọlọ́gbọ́n ọba sọ pé: “Ó yẹ kí o mọ ìrísí agbo ẹran rẹ ní àmọ̀dunjú. Fi ọkàn-àyà rẹ sí àwọn agbo ẹran ọ̀sìn rẹ.” (Òwe 27:23) Lóòótọ́, ṣe ni ẹsẹ yìí ń fi hàn pé ó dára gan-an kí olùṣọ́ àgùntàn jẹ́ aláápọn; síbẹ̀, a lè fi ṣàlàyé ọ̀nà tó yẹ kí àwọn olùṣọ́ àgùntàn nípa tẹ̀mí tó wà nínú ìjọ máa gbà ṣe àbójútó ìjọ. Tó o bá jẹ́ alàgbà, ǹjẹ́ o ń sa gbogbo ipá rẹ láti rí i pé ò ń yàgò fún ẹ̀mí jíjẹ gàba lórí àwọn ará? Níwọ̀n bí Pétérù ti sọ̀rọ̀ nípa ‘jíjẹ olúwa lé àwọn tí í ṣe ogún Ọlọ́run lórí,’ ìyẹn fi hàn pé ó ṣeé ṣe dáadáa kí alàgbà kan fẹ́ jẹ olúwa lé wọn lórí. Báwo lo ṣe máa wá ṣe ipa tìrẹ láti mú kí ohun tí Jeremáyà 33:12 sọ̀rọ̀ nípa rẹ̀ ṣeé ṣe? (Kà á.) Nígbà míì, òbí anìkantọ́mọ, opó, àwọn àgbàlagbà, ìdílé tí ọkọ tàbí aya ti lọ́mọ tẹ́lẹ̀ kí wọ́n tó fẹ́ra, tàbí àwọn ọ̀dọ́, máa ń nílò àbójútó àti ìrànlọ́wọ́ àrà ọ̀tọ̀.

Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 130

7 Bí olùṣọ́ àgùntàn ṣe máa ní láti wá àgùntàn rẹ̀ nígbà míì, bẹ́ẹ̀ náà làwọn olùṣọ́ àgùntàn inú ìjọ ṣe máa ní láti wá àwọn akéde míì tó ti sú lọ kúrò nínú agbo Ọlọ́run nítorí ìdí kan tàbí òmíràn, kí wọ́n sì ràn wọ́n lọ́wọ́. Ó máa gba ẹ̀mí ìfara-ẹni-rúbọ àti ìrẹ̀lẹ̀ kí alàgbà kan tó lè ṣe èyí. Ṣe ló sì yẹ kó máa fẹ̀sọ̀ gbọ́ tàwọn tí Jèhófà fi sábẹ́ àbójútó rẹ̀. Nítorí náà, á dáa káwọn alàgbà ìjọ bi ara wọn léèrè láìtan ara wọn jẹ, pé: ‘Báwo ni mo ṣe ń gbìyànjú tó láti fún àwọn ará níṣìírí àti láti gbé wọn ró dípò kí n máa bẹnu àtẹ́ lù wọ́n tàbí kí n máa ṣàríwísí wọn? Ǹjẹ́ mo ṣe tán tinútinú láti rí i pé mò ń ṣe dáadáa ju tàtẹ̀yìnwá lọ?’ Nígbà míì, ó lè gba ìsapá léraléra kéèyàn tó lè fi ojú tí Ọlọ́run fi ń wo ohun kan wò ó. Nítorí náà, tí arábìnrin tàbí arákùnrin kan bá ń lọ́ tìkọ̀ láti tẹ̀ lé ìmọ̀ràn kan tá a fún un látinú Ìwé Mímọ́ (kì í ṣe èrò tara ẹni là ń sọ o), ńṣe ni ká rántí Jèhófà, Olùṣọ́ Àgùntàn àti Alábòójútó Gíga Jù. Ṣe ló ń fi sùúrù bá àwọn èèyàn rẹ̀ oníwàkiwà “sọ̀rọ̀ ṣáá,” tó ń gbìyànjú láti ràn wọ́n lọ́wọ́. (Jer. 25:3-6) Èyí tó pọ̀ jù lára àwọn èèyàn Ọlọ́run lóde òní ló ń yàgò fún ìwàkiwà, àmọ́ tó bá wá ṣẹlẹ̀ pé ó yẹ kí alàgbà báni wí, kí alàgbà náà ṣe é bíi ti Jèhófà yìí.

8. Ọ̀nà wo làwọn olùṣọ́ àgùntàn inú ìjọ lè gbà tẹ̀ lé àpẹẹrẹ Jeremáyà?

8 Jeremáyà gbàdúrà fáwọn Júù nígbà tí ìrètí wà pé wọ́n ṣì lè pa dà sọ́dọ̀ Jèhófà. Ó sọ fún Ọlọ́run pé: “Rántí ìdúró mi níwájú rẹ láti sọ ohun rere àní nípa wọn, láti yí ìhónú rẹ padà kúrò lórí wọn.” (Jer. 18:20) Ẹ lè rí i látinú ọ̀rọ̀ yìí pé ṣe ni Jeremáyà ń wá ibi táwọn èèyàn rẹ̀ dáa sí, kò wá ìṣubú wọn. Lóde òní náà, irú ẹ̀mí tí Jeremáyà ní yìí ló yẹ kí àwọn alábòójútó ìjọ ní, títí táá fi hàn kedere pé ẹni tí wọ́n fẹ́ ṣèrànwọ́ fún kò ṣe tán láti yí pa dà kúrò nínú ọ̀nà búburú rẹ̀. Ohun tó dáa láti máa ṣe ni pé kí wọ́n máa yin àwọn èèyàn fún rere tí wọ́n ń ṣe, kí wọ́n máa gbàdúrà fún wọn, kí wọ́n sì máa gbàdúrà pa pọ̀ pẹ̀lú wọn.—Mát. 25:21.

Ìlérí wo ni Ọlọ́run gbẹnu Jeremáyà ṣe nípa àwọn olùṣọ́ àgùntàn tẹ̀mí? Báwo ló ṣe yẹ kí àwọn alábòójútó ìjọ máa bójú tó agbo Ọlọ́run?

‘WỌN YÓÒ BỌ́ YÍN DÁJÚDÁJÚ’

9, 10. Kí nìdí tó fi jẹ́ pé kéèyàn tó lè jẹ́ olùṣọ́ àgùntàn (alàgbà ìjọ) rere ó gba kéèyàn jẹ́ olùkọ́?

9 Ní ìbámu pẹ̀lú ohun tá a kà nínú Jeremáyà 3:15, àwọn olùṣọ́ àgùntàn inú ìjọ ní láti máa “fi ìmọ̀ àti ìjìnlẹ̀ òye bọ́” àwọn ará, ìyẹn ni pé kí wọ́n jẹ́ olùkọ́. (1 Tím. 3:2; 5:17) Jèhófà sọ fún àwọn èèyàn rẹ̀ pé ohun táwọn olùṣọ́ àgùntàn rere tóun ṣèlérí á máa ṣe nìyẹn. Ó sì rọ àwọn Júù pé kí wọ́n gba ẹ̀kọ́ tó ń tọ́ni sọ́nà tí Jeremáyà wòlíì òun ń kọ́ wọn. (Ka Jeremáyà 6:8.) Kí àgùntàn kan tó lè máa ta pọ́n-ún pọ́n-ún, ó gbọ́dọ̀ rí oúnjẹ aṣaralóore jẹ. Bákan náà, kí àwọn èèyàn Ọlọ́run tó lè jẹ́ alágbára nípa tẹ̀mí, wọ́n nílò ọ̀rọ̀ àti ìtọ́ni látinú Ìwé Mímọ́.

10 Iṣẹ́ àwọn alàgbà pín sí ọ̀nà méjì tó bá dọ̀rọ̀ kíkọ́ni. Ọ̀kan ni pé kí wọ́n máa kọ́ni nínú ìjọ, èkejì sì ni pé kí wọ́n máa kọ́ àwọn tí kò tíì di Ẹlẹ́rìí. Ní ti kíkọ́ àwọn tí kò tíì di Ẹlẹ́rìí, ẹ jẹ́ ká rántí pé ọ̀kan lára ìdí pàtàkì tí ìjọ Kristẹni fi wà ni pé kí wọ́n lè máa wàásù ìhìn rere Ìjọba Ọlọ́run. Nítorí náà, àwọn alàgbà gbọ́dọ̀ jẹ́ ajíhìnrere onítara. (Jer. 1:7-10) Ìyẹn láá jẹ́ kí wọ́n lè máa ṣe ojúṣe wọn níwájú Ọlọ́run, kí wọ́n sì tún fàpẹẹrẹ rere lélẹ̀ fáwọn ará ìjọ. Tó o bá jẹ́ alàgbà, ǹjẹ́ o kò rí i pé bíbá àwọn ará lọ́kùnrin lóbìnrin ṣiṣẹ́ pọ̀ lóde ẹ̀rí ń jẹ́ kó o lè ṣèrànwọ́ fún wọn kí ọ̀nà ìgbàkọ́ni wọn lè túbọ̀ dáa sí i, kí tìrẹ náà sì sunwọ̀n sí i? Tó o bá sì ń fìtara mú ipò iwájú nínú iṣẹ́ ìwàásù, ńṣe lò ń tipa bẹ́ẹ̀ fún àwọn ará níṣìírí tó ṣe kókó, èyí táá mú ìtẹ̀síwájú bá ìjọ náà lódindi.

11, 12. Kí ni alàgbà tó bá fẹ́ jẹ́ olùṣọ́ àgùntàn rere gbọ́dọ̀ rí i pé òun ń ṣe?

11 Bí àwọn alàgbà ṣe ń kópa nínú bíbọ́ ìjọ, ohun tí wọ́n ń kọ́ni gbọ́dọ̀ jẹ́ látinú Bíbélì; ìgbà yẹn ni yóò tó jẹ́ oúnjẹ tẹ̀mí tó ń ṣara lóore. Èyí fi hàn pé kí àwọn olùṣọ́ àgùntàn ìjọ tó lè jẹ́ olùkọ́ tó pegedé, wọ́n gbọ́dọ̀ jẹ́ni tó ń kẹ́kọ̀ọ́ Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run lójú méjèèjì. Ohun tí Jeremáyà sọ pé àwọn aṣáájú Júdà kò ṣe nìyẹn tí wọ́n fi dẹni tí kò wúlò rárá. Ó ní: “Àwọn olùṣọ́ àgùntàn ti hùwà àìnírònú, wọn kò sì wá Jèhófà pàápàá. Ìdí nìyẹn tí wọn kò fi fi ìjìnlẹ̀ òye hùwà, gbogbo ẹran wọn tí ń jẹko sì ni a ti tú ká.” (Jer. 10:21) Àwọn aṣáájú Júdà yìí, tó yẹ kó jẹ́ olùkọ́, kò tẹ̀ lé ìlànà Ìwé Mímọ́, wọn ò sì wá Ọlọ́run. Abájọ tí wọn ò fi hùwà ọlọgbọ́n. Ìyẹn ló fà á tí Jeremáyà fi kéde ìdájọ́ tó gbóná janjan sórí àwọn aṣáájú Júdà tó pera wọn ní wòlíì yẹn.—Ka Jeremáyà 14:14, 15.

12 Àwọn alábòójútó ìjọ Kristẹni kò dà bí àwọn olùṣọ́ àgùntàn èké yẹn ní tiwọn. Ṣe ni wọ́n máa ń fara balẹ̀ wo àpẹẹrẹ tí Jésù fi lélẹ̀, wọ́n á sì tẹ̀ lé e. Ìyẹn ló ń sọ wọ́n di olùṣọ́ àgùntàn ọlọgbọ́n tó ń bójú tó agbo Ọlọ́run. Tá a bá wo ti iṣẹ́ tó pọ̀ lọ́rùn wọn àtàwọn ohun tí wọ́n gbọ́dọ̀ bójú tó, ó lè má fi bẹ́ẹ̀ rọrùn fún wọn láti ní àkókò kan pàtó tí wọ́n á fi máa dá kẹ́kọ̀ọ́ déédéé. Àmọ́ tó o bá jẹ́ alàgbà, ǹjẹ́ ó dá ọ lójú gbangba pé ọ̀nà kan ṣoṣo tí ẹ̀kọ́ tó ò ń kọ́ni lè gbà ṣàǹfààní, kó jóòótọ́, kó sì kún fún ìmọ̀ àti ìjìnlẹ̀ òye, ni pé kó o gbé e kárí Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run àti ìtọ́ni ẹgbẹ́ ẹrú olóòótọ́ àti olóye? Tó o bá rí i pé o kì í ráyè dá kẹ́kọ̀ọ́ mọ́ bíi ti tẹ́lẹ̀, kí lo máa ṣe kí tìrẹ má lọ dà bí tàwọn olùṣọ́ àgùntàn èké ti ìgbà ayé Jeremáyà?

Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 135

13. Kí ni Jeremáyà ń ṣe tó mú kó jẹ́ olùkọ́ tó pegedé, ẹ̀kọ́ wo sì ni àwọn olùṣọ́ àgùntàn inú ìjọ lónìí lè rí kọ́ lára rẹ̀?

13 Ohun kan tó mú kí Jeremáyà túbọ̀ jẹ́ olùkọ́ tó pegedé ni bó ṣe máa ń lo àpèjúwe. Èyí ò ṣàjèjì ṣá o, torí Jèhófà ló ní kó ṣe bẹ́ẹ̀. Ẹ ò rí i pé àwọn èèyàn ò ní gbàgbé ohun tó sọ nígbà tó fọ́ ìkòkò amọ̀ mọ́lẹ̀ lójú wọn, tó sì kéde pé bí wọ́n ṣe máa fọ́ Jerúsálẹ́mù àtàwọn èèyàn rẹ̀ túútúú gan-an nìyẹn! (Jer. 19:1, 10, 11) Jeremáyà tún ṣe àjàgà onígi ó sí gbé e sọ́rùn láti fi sọ bí ìyà àwọn Júù ṣe máa pọ̀ tó nígbà tí wọ́n bá ń sìnrú lábẹ́ Bábílónì. (Jeremáyà orí 27 àti 28) Lóòótọ́ Ọlọ́run kò sọ pé káwọn alàgbà ìjọ rẹ máa ṣe irú àwọn nǹkan bẹ́ẹ̀ láti fi ṣàlàyé ọ̀rọ̀ tí wọ́n ń sọ. Síbẹ̀, tí wọ́n bá lo àwọn àpèjúwe àti ìrírí tó bá a mu nígbà tí wọ́n bá ń kọ́ni, ǹjẹ́ o kì í gbádùn rẹ̀? Àwọn àfiwé àti àpẹẹrẹ téèyàn ti ronú jinlẹ̀ lé dáadáa kó tó lò ó, tó sì bá ọ̀rọ̀ mu, máa ń wọni lọ́kàn gan-an ni, ó sì máa ń mú káwọn èèyàn lè ṣe ohun tó tọ́.

14. (a) Kí ni Jeremáyà ní lọ́kàn nígbà tó ń béèrè nípa ‘básámù ní Gílíádì’? (b) Kí làwọn alàgbà ìjọ lè ṣe tó máa mú kí àwọn ará ìjọ lè túbọ̀ máa ṣe dáadáa nípa tẹ̀mí?

14 A dúpẹ́ gan-an o fún iṣẹ́ olùkọ́ tí àwọn olùṣọ́ àgùntàn inú ìjọ ń ṣe! Nígbà ayé rẹ̀, Jeremáyà rí i pé àwọn èèyàn òun nílò ìwòsàn nípa tẹ̀mí. Ó wá béèrè pé: “Ṣé básámù kò sí ní Gílíádì ni? Ṣé kò sí amúniláradá níbẹ̀ ni?” (Jer. 8:22) Òróró básámù kúkú wà ní Gílíádì, ìyẹn àgbègbè kan lápá ìlà oòrùn Jọ́dánì nílẹ̀ Ísírẹ́lì. Àwọn èèyàn mọ̀ pé oògùn gidi ni oje igi olóòrùn dídùn yìí, wọ́n sì máa ń fi sí ojú ọgbẹ́ kára lè tuni kó sì tètè jinná. Àmọ́ àwọn Júù yẹn ò rí ìwòsàn gbà nípa tẹ̀mí. Kí nìdí tó fi rí bẹ́ẹ̀? Jeremáyà sọ pé: “Àwọn wòlíì pàápàá ń sọ àsọtẹ́lẹ̀ èké ní ti gidi; àti ní ti àwọn àlùfáà, wọ́n ń tẹni lórí ba ní ìbámu pẹ̀lú agbára wọn. Àwọn ènìyàn mi sì nífẹ̀ẹ́ rẹ̀ bẹ́ẹ̀.” (Jer. 5:31) Lóde òní náà ńkọ́? Ó dájú pé wàá gbà pé “básámù” wà “ní Gílíádì,” ìyẹn nínú ìjọ yín. Ohun tó dà bí òróró básámù atunilára ni ìtùnú táwọn olùṣọ́ àgùntàn inú ìjọ tó láájò máa ń fúnni bí wọ́n ṣe ń fi tìfẹ́tìfẹ́ tọ́ka àwọn ará sí àwọn ìlànà Ìwé Mímọ́, bí wọ́n ṣe ń gbé wọn ró àti bí wọ́n ṣe ń gbàdúrà fún wọn tí wọ́n sì ń báwọn gbàdúrà pa pọ̀.—Ják. 5:14, 15.

Kí ló wù ọ́ jù nínú bí àwọn alàgbà ìjọ rẹ ṣe ń kọ́ni? Kí ló mú kí ọ̀nà tí wọ́n ń gbà kọ́ni dára gan-an?

“ÈYÍ NI OHUN TÍ JÈHÓFÀ WÍ”

15, 16. Kí nìdí tí agbo àgùntàn gidi àti agbo àgùntàn tẹ̀mí fi nílò àfiyèsí?

15 Fojú inú wo bínú olùṣọ́ àgùntàn kan ṣe máa dùn tó lẹ́yìn tó ti ṣe òpò àti akitiyan púpọ̀, tí àgùntàn rẹ̀ wá bí àwọn ọmọ tó ń tọ pọ́n-ún pọ́n-ún! Àmọ́, olùṣọ́ àgùntàn yìí mọ̀ pé táwọn ọmọ àgùntàn náà bá máa dàgbà dáadáa, wọ́n nílò àfiyèsí. Nítorí náà, ó gbọ́dọ̀ rí i pé wọ́n rí oúnjẹ gidi jẹ tó bó ṣe yẹ. Ìrù ọmọ oríṣi àwọn àgùntàn kan sábà máa ń gùn tí wọ́n bá ṣẹ̀ṣẹ̀ bí i, ó sì lè máa fi kó ìgbẹ́ àti ìdọ̀tí. Níwọ̀n bí olùṣọ́ àgùntàn sì ti máa ń fẹ́ káwọn ẹran ọ̀sìn rẹ̀ máa wà ní mímọ́, kára wọn sì le, ó lè gé ìrù ọmọ àgùntàn náà kúrú, àmọ́ yóò fọgbọ́n ṣe é kó má bàa dùn ún jù. Bí àwọn olùṣọ́ àgùntàn tẹ̀mí ṣe máa ń fún àwọn ará ìjọ wọn láfiyèsí tìfẹ́tìfẹ́ náà nìyẹn. (Jòh. 21:16, 17) Inú àwọn alàgbà máa ń dùn gan-an tí wọ́n bá rí olùfìfẹ́hàn tó ń tẹ̀ síwájú kó lè di Kristẹni tòótọ́. Wọ́n máa ń fẹ́ kí ara gbogbo àgùntàn Ọlọ́run, lọ́mọdé lágbà le koko, kí wọ́n sì jẹun kánú nípa tẹ̀mí. Nítorí náà, gbogbo ìgbà ni wọ́n máa ń kíyè sí wọn láti lè ṣèrànlọ́wọ́ fún wọn nígbà tó bá yẹ. Ó sì dájú pé iṣẹ́ wọn yìí tún kan rírán àwọn ará létí “ohun tí Jèhófà wí,” ìyẹn ohun tí Ìwé Mímọ́ kọ́ni.—Jer. 2:2, 5; 7:5-7; 10:2; Títù 1:9.

16 Jeremáyà nílò ìgboyà láti lè kéde iṣẹ́ Ọlọ́run. Bẹ́ẹ̀ náà làwọn alábòójútó ìjọ ṣe nílò ìgboyà, pàápàá níbi tó bá ti pọn dandan kí wọ́n sọ̀rọ̀ láti lè dáàbò bo àwọn ará ìjọ. Bí àpẹẹrẹ, olùṣọ́ àgùntàn inú ìjọ lè rí i pé ó yẹ kóun ṣèrànlọ́wọ́ kí ‘àṣẹ̀ṣẹ̀bí ọmọ àgùntàn,’ ìyẹn àwọn ẹni tuntun, àti àwọn tó dà bí “àgùntàn” tó ti dàgbà pàápàá, má bàa fara kó èérí ayé Sátánì. Ẹni tó fẹ́ kó sí ewu yìí lè ṣàì béèrè ìmọ̀ràn rárá. Síbẹ̀, ṣé olùṣọ́ àgùntàn tó mọṣẹ́ rẹ̀ níṣẹ́ yóò kàn fọwọ́ lẹ́rán máa wo ọ̀kan nínú àgùntàn rẹ̀ bó ṣe ń rìn lọ síbi ewu? Rárá o! Bákan náà, kò ní fọwọ́ yẹpẹrẹ mú ipò tẹ́ni yẹn wà, kó wá ṣe bíi pé kò séwu rárá, nígbà tó ṣe kedere pé ewu wà, bóyá tó tiẹ̀ lè mú kí ìránṣẹ́ Ọlọ́run yẹn pàdánù àlàáfíà tó ní pẹ̀lú Jèhófà.—Jer. 8:11.

17. Ìgbà wo ni olùṣọ́ àgùntàn kan máa ní láti pàfiyèsí àrà ọ̀tọ̀ sí àgùntàn inú agbo lọ́kọ̀ọ̀kan, báwo ló sì ṣe máa ṣe é?

17 Bí ohunkóhun bá ń mú kí àgùntàn tí kò fura rìn gbéregbère lọ kúrò láàárín agbo, olùṣọ́ àgùntàn tó wà lójúfò á tètè dá a pa dà sínú agbo. (Ka Jeremáyà 50:6, 7.) Bákan náà, nígbà míì, alábòójútó kan máa ní láti sojú abẹ níkòó fún àwọn tó bá ń rìn gbéregbère ní bèbè ewu, àmọ́ yóò sọ ọ́ tìfẹ́tìfẹ́ ni o. Bí àpẹẹrẹ, ó lè ṣàkíyèsí pé àwọn àfẹ́sọ́nà méjì tí wọ́n máa tó fẹ́ra sílé ń dá wà láwọn nìkan ní àwọn ibi tí ìfẹ́kúfẹ̀ẹ́ ti lè ru bò wọ́n lójú. Alàgbà onínúure àti olóye kan yóò ràn wọ́n lọ́wọ́ kí wọ́n lè yẹra fún irú nǹkan tó lè kó wọn sínú ewu bẹ́ẹ̀. Bó tilẹ̀ jẹ́ pé alàgbà náà máa ṣọ́ra kó má lọ máa fẹ̀sùn kàn wọ́n, yóò jẹ́ kí wọ́n rí àwọn ohun tó lè sún wọn ṣe ohun tí Jèhófà kórìíra. Ṣe làwọn alàgbà olóòótọ́ máa ń ṣe bíi ti Jeremáyà, tí wọ́n á fi hàn kedere pé ohun tí Ọlọ́run ní kò dáa, kò dáa lóòótọ́. Jèhófà ni wọ́n sì fìwà jọ tí wọ́n bá ń ṣe bẹ́ẹ̀, torí ó gbẹnu wòlíì rẹ̀ rọ àwọn èèyàn rẹ̀ pẹ̀lẹ́pẹ̀lẹ́ pé: “Ẹ jọ̀wọ́, ẹ má ṣe irú ohun ìṣe-họ́ọ̀-sí yìí tí mo kórìíra.” (Jer. 5:7; 25:4, 5; 35:15; 44:4) Ǹjẹ́ o mọyì aájò àwọn olùṣọ́ àgùntàn onífẹ̀ẹ́ lórí agbo Ọlọ́run lóòótọ́?

18. Àbájáde rere wo ni ìsapá àwọn olùṣọ́ àgùntàn inú ìjọ lè ní?

18 Gbogbo àwọn tí Jeremáyà gbà nímọ̀ràn kọ́ ló gba ìmọ̀ràn rẹ̀. Àmọ́ àwọn kan gba ìmọ̀ràn ṣá o. Bí àpẹẹrẹ, nígbà tí ìbáwí tọ́ sí Bárúkù, ọ̀rẹ́ Jeremáyà tó tún jẹ́ akọ̀wé rẹ̀, Jeremáyà ò lọ́ tìkọ̀ láti bá a wí. (Jer. 45:5) Kí ló wá yọrí sí? Bárúkù dẹni tó rí ojú rere Ọlọ́run, ó sì la ìparun Jerúsálẹ́mù já. Bákan náà lónìí, báwọn alàgbà ìjọ ṣe ń rí i pé ìrànlọ́wọ́ tí wọ́n ń ṣe fún Ẹlẹ́rìí bíi tiwọn ń yọrí sí rere, ìyẹn á máa fún wọn níṣìírí láti túbọ̀ ‘máa bá a lọ ní fífi ara wọn fún ìgbani-níyànjú, àti fún kíkọ́ni’ èyí tó ń gbẹ̀mí là.—1 Tím. 4:13, 16.

BÁNI WÍ “DÉ ÌWỌ̀N TÍ Ó BẸ́TỌ̀Ọ́ MU”

Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 138

19, 20. Kí ni ojúṣe àwọn alàgbà tó bá kan ọ̀rọ̀ àwọn oníwà àìtọ́?

19 Ipa míì táwọn alábòójútó òde òní ń kó ni pé wọ́n máa ń ṣe iṣẹ́ onídàájọ́ nínú ìjọ. Lẹ́ẹ̀kọ̀ọ̀kan, àwọn alàgbà máa ń bójú tó ọ̀rọ̀ àwọn tó mọ̀ọ́mọ̀ dẹ́ṣẹ̀, tí wọ́n á máa gbìyànjú láti mú kí ẹlẹ́ṣẹ̀ náà lè ronú pìwà dà. Jèhófà fi inúure gba àwọn tó ṣàìtọ́ níyànjú, síbẹ̀ ó sojú abẹ níkòó, pé kí wọ́n kọ ọ̀nà búburú wọn sílẹ̀. (Jer. 4:14) Tẹ́nì kan nínú ìjọ bá wá kọ̀ láti fi ìwà ẹ̀ṣẹ̀ rẹ̀ sílẹ̀, àwọn alábòójútó gbọ́dọ̀ gbégbèésẹ̀ láti dáàbò bo agbo lọ́wọ́ ipa búburú tírú ẹni bẹ́ẹ̀ lè ní lórí ìjọ. Ó lè jẹ́ pé ṣe ni wọ́n máa yọ irú ẹni bẹ́ẹ̀ kúrò nínú ìjọ bí Ìwé Mímọ́ ṣe sọ. Ohun tí Jèhófà ń retí ni pé káwọn alàgbà ṣe ohun tó bá ìdájọ́ òdodo mu láwọn ipò bẹ́ẹ̀. Àpẹẹrẹ dáadáa tí Jòsáyà ọba rere sì fi lélẹ̀ nìyẹn. Bíbélì sọ pé: “Ó gba ìbéèrè ẹ̀tọ́ lábẹ́ òfin ti àwọn tí ìṣẹ́ ń ṣẹ́ àti àwọn òtòṣì rò.” Ńṣe ló fìwà jọ Ọlọ́run tó fẹ́ràn ìdájọ́ òdodo. Ìdí nìyẹn tí Jèhófà fi lè sọ nípa ìwà Jòsáyà, pé: “Ìyẹn kì í ha ṣe ọ̀ràn mímọ̀ mí bí?” Nítorí pé Jòsáyà mú ìdájọ́ òdodo àti òdodo ṣẹ, “nǹkan lọ dáadáa fún un.” Ǹjẹ́ ọkàn rẹ kì í túbọ̀ balẹ̀ nígbà táwọn alàgbà ìjọ rẹ bá ń sa gbogbo ipá wọn láti tẹ̀ lé àpẹẹrẹ Jòsáyà?—Jer. 22:11, 15, 16.

20 Mọ̀ dájú pé ńṣe ni Jèhófà máa ń bá oníwà àìtọ́ wí dé “ìwọ̀n tí ó bẹ́tọ̀ọ́ mu.” (Jer. 46:28) Nípa bẹ́ẹ̀, ìṣarasíhùwà oníwà àìtọ́ kan àti ohun tó mú un hu ìwà tó hù làwọn alàgbà fi ń mọ̀ bóyá wọ́n á kàn fún un nímọ̀ràn tàbí kí wọ́n kàn gbà á níyànjú tàbí kí wọ́n fi ìbáwí fà á létí. Ó tiẹ̀ sì lè gba pé kí wọ́n yọ oníwà àìtọ́ tí kò bá ronú pìwà dà lẹ́gbẹ́. Nírú ipò bẹ́ẹ̀, àwọn alàgbà kì í gbàdúrà láàárín ìjọ fún irú ẹni tí wọ́n yọ lẹ́gbẹ́ bẹ́ẹ̀ tí kò jáwọ́ nínú ẹ̀ṣẹ̀; torí pé bí ẹní gbàdúrà sínú afẹ́fẹ́ lásán ni yóò jẹ́.a (Jer. 7:9, 16) Àmọ́ ṣá, wọ́n máa ń tẹ̀ lé àpẹẹrẹ Ọlọ́run nípa jíjẹ́ kí ẹni tí wọ́n yọ lẹ́gbẹ́ náà mọ bó ṣe lè pa dà rí ojú rere Ọlọ́run. (Ka Jeremáyà 33:6-8.) Lóòótọ́, ó lè dunni pé ẹnì kan dẹni tá a ní láti yọ lẹ́gbẹ́, ó dá wa lójú pé òdodo làwọn ìlànà Ọlọ́run, ó sì tọ́, òun ló sì tún dára jù.—Ìdárò 1:18.

21. Ipò wo ló yẹ kí agbo Ọlọ́run wà, báwo lo sì ṣe máa sa ipa tìrẹ kí ìyẹn lè ṣeé ṣe?

21 Tí àwọn olùṣọ́ àgùntàn ìjọ bá ń wá àwọn ìlànà Ọlọ́run nípa ọ̀ràn tó bá jẹ yọ tí wọ́n sì ń tẹ̀ lé e, agbo Ọlọ́run yóò máa rí oúnjẹ aṣaralóore jẹ, ara wọn á le, ààbò tó péye á sì wà fún wọn. (Sm. 23:1-6) Ohun tí Jeremáyà ti jẹ́ ká mọ̀ nípa ìwà àti ẹ̀mí tó bójú mu àti èyí tí kò bójú mu, máa ṣèrànwọ́ fáwọn alábòójútó inú ìjọ bí wọ́n ṣe ń ṣe ojúṣe wọn tó ṣe pàtàkì, ìyẹn láti máa bójú tó àwọn àgùntàn Ọlọ́run. Nítorí náà, olúkúlùkù wa lè bi ara rẹ̀ pé, ‘Ṣé màá máa bá a lọ láti mọyì ètò tí Jèhófà ṣe fún kíkọ́ àwa èèyàn rẹ̀, fún títọ́ wa sọ́nà àti dídáàbò bò wá, nípa rírí i dájú pé mo ń kọ́wọ́ ti àwọn alábòójútó tó ń ṣe “olùṣọ́ àgùntàn . . . ní ti gidi” pẹ̀lú “ìmọ̀ àti ìjìnlẹ̀ òye”?’—Jer. 3:15; 23:4.

Àwọn ipò wo ló máa gba pé káwọn alábòójútó fi ìgboyà gbé ìgbésẹ̀? Kí ni Jèhófà ń retí pé káwọn alàgbà ìjọ ṣe nígbà tí wọ́n bá ń ṣe ìdájọ́?

a Wo Ilé Ìṣọ́ December 1, 2001, ojú ìwé 30 àti 31.

    Yorùbá Publications (1987-2025)
    Jáde
    Wọlé
    • Yorùbá
    • Fi Ráńṣẹ́
    • Èyí tí mo fẹ́ràn jù
    • Copyright © 2025 Watch Tower Bible and Tract Society of Pennsylvania
    • Àdéhùn Nípa Lílò
    • Òfin
    • Ètò Nípa Ìsọfúnni Rẹ
    • JW.ORG
    • Wọlé
    Fi Ráńṣẹ́