Fifi Jẹlẹnkẹ Bojuto Awọn Agutan Ṣiṣeyebiye Ti Jehofa
AWỌN alagba fetisilẹ pẹlu iparọrọ. Wọn ti rinrin-ajo fun nǹkan bii 30 ibusọ (50 kilomita) lati Efesu si Miletu lati gba itọni lati ọ̀dọ̀ aposteli Paulu. Nisinsinyi ọkàn wọn bajẹ lati gbọ́ pe eyi yoo jẹ́ akoko ti o kẹhin ti wọn yoo ri i. Nitori naa wọn mọ̀ pe awọn ọ̀rọ̀ ti yoo tẹlee yoo jẹ́ eyi ti o ṣe pataki gan-an: “Ẹ kiyesi ara yin ati gbogbo agbo, laaarin eyi ti ẹmi mimọ ti yàn yin ṣe alaboojuto, lati ṣe oluṣọ-agutan ijọ Ọlọrun, eyi ti o fi ẹjẹ Ọmọkunrin oun funraarẹ rà.”—Iṣe 20:25, 28, 38, NW.
Itọka ranpẹ ti Paulu ṣe si awọn oluṣọ-agutan dajudaju fun awọn alagba Efesu wọnyẹn ni isọfunni ńláǹlà. Wọn ti mọ̀ nipa iṣẹ dída agutan ni agbegbe ti o wà láyìíká. Wọn tun jẹ ojulumọ pẹlu ọpọlọpọ awọn itọka si awọn oluṣọ-agutan ninu Iwe Mimọ Lede Heberu. Wọn si mọ̀ pe Jehofa fi araarẹ̀ wé Oluṣọagutan awọn eniyan rẹ̀.—Isaiah 40:10, 11.
Paulu sọrọ nipa wọn gẹgẹ bi “alaboojuto” laaarin “agbo,” ati gẹgẹ bi ‘oluṣọagutan ijọ.’ Nigba ti o jẹ́ pe ede-isọrọ naa “alaboojuto” tọkasi ohun ti o jẹ́ iṣẹ́ wọn, ọ̀rọ̀ naa “ṣe oluṣọ-agutan” ṣapejuwe bí wọn ṣe nilati ṣe abojuto yẹn. Bẹẹni, awọn alaboojuto nilati ṣetọju mẹmba ijọ kọọkan ní ọ̀nà onifẹẹ kan-naa ti oluṣọ-agutan kan yoo gbà bojuto agbo agutan rẹ̀.
Lonii, iwọnba awọn alagba diẹ ni wọn ti lè ni ìrírí tààràtà nipa dída awọn agutan gidi. Ṣugbọn Bibeli ṣe ọpọlọpọ itọka si agutan ati awọn oluṣọ-agutan, ni pataki ni ọ̀nà iṣapẹẹrẹ, debi pe awọn ọ̀rọ̀ Paulu wọnyẹn ní ipa ti kò lopin. Pupọ ni a sì lè kẹkọọ rẹ̀ lati inu awọn akọsilẹ nipa awọn oluṣọ-agutan ti Ọlọrun ṣojurere si ni awọn ìgbà atijọ. Awọn apẹẹrẹ agbafiyesi wọn lè ran awọn alagba ode-oni lọwọ lati rí awọn animọ ti wọn nilati mú dagba lati lè ṣabojuto ijọ Ọlọrun.
Dafidi Oluṣọ-Agutan ti Kò Bẹ̀rù
Nigba ti a ba ronu nipa awọn oluṣọ-agutan akoko ti a kọ Bibeli, o ṣeeṣe julọ pe ki a ranti Dafidi, nitori pe o bẹrẹ gẹgẹ bi ẹni ti ń da agutan. Ọ̀kan ninu awọn ẹkọ ti a kọ́kọ́ kọ́ ninu igbesi-aye Dafidi ni pe jíjẹ́ oluṣọ-agutan kìí ṣe ipò ìyọrí-ọlá. Lotiitọ, nigba ti wolii Samueli dé lati fi òróró yan ọmọkunrin Jesse kan gẹgẹ bi ọba Israeli ọjọ-iwaju, Dafidi ọdọmọde ni a gbojufoda patapata lakọọkọ. Ó jẹ́ kiki lẹhin ti Jehofa ti kọ awọn ẹ̀gbọ́n rẹ̀ meje ni a tó mẹnukan Dafidi, ẹni ti o wà ninu pápá ti “ó ń ṣọ́ agutan.” (1 Samueli 16:10, 11) Bi o tilẹ ri bẹẹ, awọn ọdun ti Dafidi lò gẹgẹ bi oluṣọ-agutan mura rẹ̀ silẹ fun iṣẹ ti ń gba afiyesi ati isapa naa ti ṣiṣe oluṣọ-agutan orilẹ-ede Israeli. “[Jehofa] sì yan Dafidi iranṣẹ rẹ̀, o sì mu un kuro lati inu agbo-agutan wá . . . lati maa bọ́ Jakọbu, eniyan rẹ̀,” ni Orin Dafidi 78:70, 71 sọ. Lọna ti o baa mu, Dafidi kọ Orin kẹtalelogun didun ti a sì mọ daradara, ti o bẹrẹ pẹlu awọn ọ̀rọ̀ naa: “OLUWA ni Oluṣọ-agutan mi.”
Bii ti Dafidi, awọn alagba ninu ijọ Kristian gbọdọ ṣiṣẹsin gẹgẹ bi oluṣọ-agutan ọmọ-abẹ onirẹlẹ ki wọn maṣe wá ìyọrí-ọlá ti kò tọ́. Gẹgẹ bi aposteli Paulu ti kọwe si Timoteu, awọn ti wọn ń nàgà fun ẹru-iṣẹ ṣiṣe oluṣọ-agutan yii ‘ń fẹ́ iṣẹ rere,’ kìí ṣe ìyọrí-ọlá.—1 Timoteu 3:1.
Bi o tilẹ jẹ pe iṣẹ Dafidi gẹgẹ bi oluṣọ-agutan gidi jẹ́ eyi ti o rẹlẹ̀, ni ìgbà miiran o maa ń beere fun igboya nla. Fun apẹẹrẹ, ni ìgbà kan ti kinniun kan gbé awọn agutan lati inu agbo-ẹran baba rẹ̀ lọ ati ni ìgbà miiran beari kan, Dafidi fi pẹlu aibẹru koju o sì pa awọn adọdẹpẹranjẹ naa. (1 Samueli 17:34-36) Ìfìgboyà hàn lọna pípẹtẹrí kan ni eyi jẹ́ nigba ti ẹnikan bá ronu pe kinniun kan lè pa awọn ẹranko tí ó tobi pupọ ju oun funraarẹ. Beari ilẹ Siria ti o maa ń gbe Palestine, ti o tẹ̀wọ̀n pupọ tó 140 kilogram, lè pa àgbọ̀nrín pẹlu àbàrá eleekanna lilagbara rẹ̀ kan.
Aniyan onigboya Dafidi fun awọn agutan baba rẹ̀ jẹ́ apẹẹrẹ rere fun awọn oluṣọ-agutan ninu ijọ Kristian. Aposteli Paulu kilọ fun awọn alagba Efesu nipa awọn “ìkookò buburu” ti wọn kì yoo “dá agbo sí.” (Iṣe 20:29) Ní awọn akoko ode-oni pẹlu, awọn ìgbà kan yoo wà ti awọn Kristian oluṣọ-agutan yoo nilati fi igboya hàn lati lè ṣabojuto ìwàdéédéé awọn agutan Jehofa.
Bi o tilẹ jẹ pe a nilati fi igboya daabobo awọn agutan naa, a tun nilati fi jẹlẹnkẹ patapata bá wọn lò, ni afarawe oluṣọ-agutan onifẹẹ naa, Dafidi ati Oluṣọ-agutan Rere naa, Jesu Kristi. (Johannu 10:11) Ní mímọ̀ pe agbo naa jẹ́ ti Jehofa, awọn alagba kò gbọdọ fi ọwọ́ lile mú awọn agutan naa, ‘ní fifi ipá mu awọn ti wọn jẹ́ ajogun Ọlọrun.’—1 Peteru 5:2, 3; Matteu 11:28-30; 20:25-27.
Ṣiṣe Iṣiro
Baba awọn Heberu naa Jakọbu jẹ́ oluṣọ-agutan kan ti a mọ̀ dunju miiran. Ó ka araarẹ̀ si ẹni ti yoo dahun fun agutan kọọkan ti a fi sabẹ itọju rẹ̀. Ó fi pẹlu iṣotitọ pupọ tobẹẹ bojuto awọn agbo-ẹran àna rẹ̀, Labani, debi pe lẹhin 20 ọdun ninu iṣẹ-isin rẹ̀, Jakọbu lè sọ pe: “Agutan rẹ ati ewurẹ rẹ ko ṣẹ́nú, agbo ọ̀wọ̀-ẹran rẹ ni emi kò si pajẹ. Eyi ti ẹran fàya, emi kò mú un fun ọ wá; emi ni o sì gba òfò rẹ̀; ni ọwọ́ mi ni iwọ beere rẹ̀, a báà jí i ni ọ̀sán, a báà jí i ni oru.”—Genesisi 31:38, 39.
Awọn Kristian alaboojuto fi aniyan kan ti o tilẹ tobi ju hàn fun awọn agutan tí Oluṣọ-agutan ọkàn wa, Jehofa Ọlọrun, ‘fi ẹ̀jẹ̀ Ọmọkunrin rẹ̀ rà.’ (Iṣe 20:28; 1 Peteru 2:25; 5:4) Paulu tẹnumọ ẹru-iṣẹ pataki yii nigba ti o rán awọn Kristian Heberu létí pe awọn ọkunrin ti wọn ń mu ipo iwaju ninu ijọ “ń ṣọ́ ẹ̀ṣọ́ nitori ọkàn yin, bi awọn ti yoo ṣe iṣiro.”—Heberu 13:17.
Apẹẹrẹ ti Jakọbu tun fihàn pẹlu pe iṣẹ oluṣọ-agutan kan kò ni ààlà akoko. Ó jẹ́ iṣẹ tọ̀sán-tòru ti o sì sábà maa ń beere fun ifara-ẹni-rubọ. Ó wi fun Labani pe: “Bayii ni mo wà; ongbẹ ń gbẹ mi ni ọ̀sán, otutu si ń mú mi ni òru: oorun mi sì dá kuro ni oju mi.”—Genesisi 31:40.
Dajudaju otitọ ni eyi jẹ́ nipa pupọ awọn Kristian alagba ti wọn jẹ́ onifẹẹ lonii, gẹgẹ bi iriri ti o tẹlee yii ti ṣapejuwe rẹ̀. A dá arakunrin kan duro si ibi itọju loju mejeeji ní ile-iwosan kan lẹhin ti fifa awọn ṣẹẹli kókó-ọlọ́yún inu ọpọlọ lati mọ okunfa aisan rẹ̀ ti lọjupọ. Awọn idile rẹ̀ ṣeto lati wà ni itosi rẹ̀ ni ile-iwosan lọ́sàn-án ati lóru. Lati pese itilẹhin ati iṣiri ti ó nilo, ọ̀kan lara awọn alagba adugbo ṣatunṣe igbokegbodo rẹ̀ kíkúnfọ́fọ́ ki o baa lè bẹ ọkunrin alaisan naa ati awọn idile rẹ̀ wò lojoojumọ. Bi o ti wu ki o ri, nitori igbokegbodo itọju loju mejeeji ti ile-iwosan naa, kò fi ìgbà gbogbo ṣeeṣe fun un lati ṣebẹwo ni ojumọmọ. Eyi tumọsi pe alagba naa niye ìgbà nilati wà ní ile-iwosan naa ni alẹ́ patapata. Ṣugbọn o ń fi tayọtayọ lọ si ibẹ lálaalẹ́. “Mo mọ̀ pe mo nilati lọ ṣe ibẹwo ni akoko kan ti o rọrun fun alaisan naa, kìí ṣe ni akoko kan ti o rọrun fun mi,” ni alagba naa wi. Nigba ti arakunrin naa ti gbadun tó fun gbigbe lọ si apa ibomiran ní ile-iwosan naa, alagba naa ń baa lọ pẹlu awọn ibẹwo oníṣìírí rẹ̀ ojoojumọ.
Ohun ti Mose Kẹkọọ Gẹgẹ Bi Oluṣọ-Agutan Kan
Bibeli ṣapejuwe Mose gẹgẹ bi “ọlọ́kàn tútù ju gbogbo eniyan lọ ti ń bẹ lori ilẹ.” (Numeri 12:3) Bi o ti wu ki o ri, akọsilẹ naa fihàn pe eyi kìí sábà jẹ́ bi ọ̀ràn ti ri nigba gbogbo. Gẹgẹ bii ọdọmọkunrin kan, ó ti pa ọmọ Egipti kan nitori pe o lu arakunrin rẹ̀ ọmọ Israeli. (Eksodu 2:11, 12) Dajudaju eyi kìí ṣe iwa eniyan onirẹlẹ kan! Sibẹ, Ọlọrun yoo ṣì lo Mose lati dari orilẹ-ede kan ti o ni araadọta-ọkẹ ninu la aginju kọja lọ si Ilẹ Ileri. Ni kedere, nigba naa, Mose nilo idanilẹkọọ siwaju sii.
Bi o tilẹ jẹ pe Mose ti gba idanilẹkọọ ninu “gbogbo ọgbọ́n ará Egipti,” pupọ sii ni o ṣì nilo ki oun baa lè ṣabojuto agbo Jehofa. (Iṣe 7:22) Bawo ni o ti ṣeeṣe ki iru afikun idanilẹkọọ yii ri? Ó dara, fun 40 ọdun, Ọlọrun faayegba Mose lati ṣiṣẹsin gẹgẹ bi oluṣọ-agutan rirẹlẹ kan ni ilẹ Midiani. Bi o ti ń bojuto awọn agbo ẹran àna rẹ̀, Jetro, Mose mu iru awọn animọ rere bii suuru, iwatutu, irẹlẹ, ipamọra, ọkàn tútù, ati ikora-ẹni-nijaanu dagba. Ó tun kọ́ lati duro de Jehofa. Bẹẹni, bibojuto agutan gidi mú Mose dé oju iwọn lati jẹ́ oluṣọ-agutan orilẹ-ede Israeli.—Eksodu 2:15–3:1; Iṣe 7:29, 30.
Iwọnyi ha kọ́ ni awọn animọ naa gan-an ti alagba kan nilo ki o baa lè bojuto awọn eniyan Ọlọrun lonii bi? Bẹẹni, nitori Paulu rán Timoteu leti pe “iranṣẹ Oluwa . . . gbọdọ . . . jẹ́ ẹni pẹlẹ si eniyan gbogbo, ẹni ti o lè kọ́ni, onisuuru, ẹni ti yoo ma kọ́ awọn aṣodi pẹlu iwatutu.”—2 Timoteu 2:24, 25.
Awọn akoko lè wà nigba ti alagba kan lè nimọlara ijakulẹ nitori pe ó ni iṣoro ninu mímú awọn animọ wọnyi dagba dé ẹkunrẹrẹ. Bi o tilẹ ri bẹẹ, oun kò gbọdọ jọ̀gọ̀nù. Gẹgẹ bi o ti ri pẹlu Mose, ó lè gba akoko gigun lati gbé awọn animọ ti ẹnikan nilo lati jẹ́ oluṣọ-agutan rere ró lẹkun-un-rẹrẹ. Bi o ti wu ki o ri, bi akoko ti ń lọ, iru isapa alaapọn bẹẹ ni a o san èrè fun.—Fiwe 1 Peteru 5:10.
Gẹgẹ bi alagba kan, boya a kò lò ọ́ lẹkun-un-rẹrẹ bii ti awọn yooku. Ó ha lè jẹ́ pe, gẹgẹ bii ti Mose, Jehofa ń yọọda fun ọ lati mú awọn animọ ṣiṣepataki kan dagba lẹkun-un-rẹrẹ ni bi? Maṣe gbagbe lae pe Jehofa ‘bikita nipa rẹ.’ Bi o ti wu ki o ri, a tun gbọdọ fi aini naa sọkan lati ‘fi irẹlẹ wọ araawa laṣọ, nitori pe Ọlọrun kọ oju ija si awọn agberaga ṣugbọn ó ń fi oore-ọfẹ fun awọn onirẹlẹ.’ (1 Peteru 5:5-7) Bi o ba lo araarẹ ti o sì gba idanilẹkọọ ti Jehofa yọọda fun, iwọ lè tubọ wulo fun un, gan-an gẹgẹ bi Mose ti ṣe.
Gbogbo Agutan Jehofa Ni O Ṣeyebiye
Awọn oluṣọ-gutan onifẹẹ, aṣeegbarale ti akoko ti a kọ Bibeli nimọlara níní ẹru-iṣẹ sipa agutan kọọkan. Ohun kan-naa ni o gbọdọ jẹ́ otitọ nipa awọn oluṣọ-agutan nipa tẹmi. Eyi ṣe kedere lati inu ọ̀rọ̀ Paulu: “Ẹ kiyesi . . . gbogbo agbo.” (Iṣe 20:28) Awọn wo ni “gbogbo agbo” yoo ní ninu?
Jesu ṣe apejuwe nipa ọkunrin kan ti o ni ọgọrun-un agutan ṣugbọn ti o fi pẹlu imuratan wá ọ̀kan ti o ṣako lọ ki o baa lè mu un pada wa sinu agbo naa. (Matteu 18:12-14; Luku 15:3-7) Ni ọ̀nà kan-naa alaboojuto kan gbọdọ ni aniyan fun ọkọọkan mẹmba ijọ. Aiṣiṣẹmọ ninu iṣẹ-isin tabi ní lilọ si awọn ipade Kristian kò tumọsi pe agutan naa kìí tun ṣe ara agbo naa mọ́. O ṣì jẹ́ ara “gbogbo agbo” ti awọn alagba gbọdọ ‘dahun fun’ lọdọ Jehofa.
Ẹgbẹ́ awọn alagba kan bẹrẹ sii daniyan gidigidi pe awọn kan ti wọn ti ń darapọ pẹlu ijọ ti ṣako lọ́ sinu aiṣiṣẹmọ. A ṣe akọsilẹ awọn eniyan wọnyi, a sì ṣe akanṣe isapa lati bẹ̀ wọn wò ati lati ràn wọn lọ́wọ́ lati pada sinu agbo-agutan Jehofa. Ẹ wo bi awọn alagba wọnyi ti kún fun ọpẹ si Ọlọrun tó pe laaarin ọdun meji ati aabọ, o ṣeeṣe fun wọn lati ran iye awọn eniyan ti o ju 30 lọ lọwọ lati di ogboṣaṣa ninu iṣẹ-isin Jehofa lẹẹkan sii. Ọ̀kan lara awọn ti a tipa bayii ranlọwọ ti jẹ́ alaiṣiṣẹmọ fun nǹkan bi ọdun 17 sẹhin!
Iwuwo ẹru-iṣẹ yii ni a tẹ̀ mọ́ awọn alaboojuto lọkan siwaju sii nipa otitọ naa pe awọn agutan naa ni ‘a rà pẹlu ẹ̀jẹ̀ Ọmọkunrin [Ọlọrun] tikaraarẹ.’ (Iṣe 20:28) Kò si iye-owo ti o ga ju eyi lọ ti a kì bá ti san fun awọn agutan ṣiṣeyebiye wọnyi. Sì ronu nipa gbogbo akoko ati isapa ti a lò ninu iṣẹ-isin lati ṣalabaapade ki a sì ṣeranwọ fun ẹni-bi-agutan kọọkan! Kò ha yẹ ki a ṣe iru isapa kan-naa lati pa gbogbo wọn mọ́ sinu agbo-agutan Ọlọrun bi? Dajudaju, gbogbo agutan kọọkan ninu ijọ ṣeyebiye.
Koda nigba ti mẹmba kan ninu agbo bá lọwọ ninu aṣiṣe wiwuwo kan, ẹru-iṣẹ awọn alagba kò yipada. Wọn ń baa lọ lati jẹ́ oluṣọ-agutan ti o bikita, ti ń fi jẹlẹnkẹ ati iwatutu sapa lati daabobo ẹlẹṣẹ naa bi o bá ṣeeṣe rara. (Galatia 6:1, 2) O banininujẹ pe, ninu iru awọn ọ̀ràn kan o hàn gbangba pe mẹmba ijọ kan ṣaini ibanujẹ oniwa-bi-Ọlọrun fun ẹṣẹ wiwuwo ti o ti dá. Awọn oluṣọ-agutan onifẹẹ nigba naa ní ẹru-iṣẹ ti o bá Iwe Mimọ mu lati daabobo iyoku agbo naa lodisi ipa akodọtibani yii.—1 Korinti 5:3-7, 11-13.
Bi o tilẹ ri bẹẹ, Jehofa Ọlọrun fi apẹẹrẹ pipe ti ninawọ aanu si awọn agutan ti ń rìn régberègbe. Oluṣọ-agutan wa oníyọ̀ọ́nú sọ pe: “Emi o wá eyi ti o sọnu lọ, emi o sì mu eyi ti a lé lọ pada bọ̀, emi o sì di eyi ti a ṣá lọ́gbẹ́, emi o mu eyi ti o ṣaisan ni ara le.” (Esekieli 34:15, 16; Jeremiah 31:10) Ní afarawe apẹẹrẹ didara gan-an yii, a ti ṣe eto onifẹẹ kan fun awọn oluṣọ-agutan nipa tẹmi lode-oni lati bẹ awọn eniyan ti a ti yọlẹgbẹ wò, awọn ti wọn lè dahunpada nisinsinyi si iranlọwọ wọn. Isapa alaaanu yii lati jere iru awọn agutan tí ó nù bẹẹ ti so eso rere. Arabinrin kan ti a gbà pada sọ pe: “Nigba ti awọn alagba késí mi, iṣiri ti mo nilo lati pada wá ni ó jẹ́.”
Laisi iyemeji, awọn ọ̀rọ̀ Paulu si awọn alagba Efesu ní Miletu kun fun itumọ—fun wọn ati fun awọn alaboojuto lonii. Itọka rẹ̀ si awọn oluṣọ-agutan jẹ́ irannileti nipa awọn animọ fifanimọra ti o gbọdọ hàn ninu awọn alaboojuto—awọn animọ bi irẹlẹ ati igboya, gẹgẹ bi ọba oluṣọ-agutan naa Dafidi ti fi apẹẹrẹ rẹ̀ lelẹ; imọlara ẹru-iṣẹ funra-ẹni ati aájò aláàbò, eyi ti o hàn gbangba ninu iṣẹ-isin Jakọbu tọ̀sán-tòru; ati imuratan lati gba idanilẹkọọ siwaju sii pẹlu suuru, gẹgẹ bi Mose ṣe fihàn. Niti gidi, awọn apẹẹrẹ inu Bibeli wọnyi yoo ran awọn alagba ijọ lọwọ lati mú awọn animọ ti wọn nilo dagba ki wọn si ṣagbeyọ wọn ki wọn baa lè fi owọ́ jẹlẹnkẹ ‘dari ijọ Ọlọrun, ti o fi ẹ̀jẹ̀ Ọmọkunrin rẹ̀ rà.’