Wọ́n Ń Fi Ìyọ́nú Ṣolùṣọ́ Àwọn Àgùtàn Kékeré Náà
NÍNÚ gbogbo ẹranko agbéléjẹ̀, kò sí èyì tí ó fi bẹ́ẹ̀ dàbí àgùtàn. Ọ̀pọ̀ jùlọ nínú àwọn ẹranko ní okun àti ọgbọ́n-àdánidá tí a nílò láti wá oúnjẹ kí wọ́n sì sá mọ́ àwọn ẹranko tí ń fi wọ́n ṣe ìjẹ lọ́wọ́, ṣùgbọ́n àgùtàn yàtọ̀. Ó rọrùn fún àwọn adọdẹfiṣèjẹ láti gbéjàkò ó, láìní agbára tí ó pọ̀ tó láti gbèjà araarẹ̀. Láìsí olùṣọ́, àgùtàn kan jẹ́ oníbẹ̀rù àti aláìlónígbèjà. Tí ó bá kúrò lára agbo, ó tètè máa ń sọnù. Àwọn àgùtàn tí wọ́n rọrùn láti kọ́ nígbà náà ní àwọn ìdí títayọ́ láti ní ìmọ̀lára ìsúnmọ́ra pẹ́kípẹ́kí pẹ̀lú olùṣọ́ wọn. Láìsí i àǹfààní lílàájá wọn kò tó nǹkan. Nítorí àwọn ànímọ́ wọ̀nyí, Bibeli lo àgùtàn lọ́nà ìṣàpẹẹrẹ láti dúró fún àwọn ènìyàn aláìmọwọ́mẹsẹ̀, tí a ń fìyà jẹ, tàbí tí wọn kò ní ààbò.
A gbọ́dọ̀ gbà pé, olùṣọ́-àgùtàn kan ń ṣiṣẹ́ dáradára láti gba èrè rẹ̀. Ìgbésí-ayé rẹ̀ kìí ṣe ọ̀kan tí ó rọrùn. Òun ni a ṣí kalẹ̀ sí ooru àti òtútù, ó sì ń ṣàìsùn. Òun níláti dáàbòbo agbo àgùtàn kúrò lọ́wọ́ àwọn adọdẹfiṣèjẹ, ní fífi araarẹ̀ sínú ewu nígbà púpọ̀. Níwọ̀n bí ó ti jẹ́ pé olùṣọ́-àgùtàn kan níláti jẹ́ kí agbo àgùtàn wà papọ̀, púpọ̀ nínú àkókò rẹ̀ ni ó ń lò ní wíwá àwọn àgùtàn tí wọ́n ti ṣáko tàbí tí wọ́n sọnù kiri. Ó níláti ṣètọ́jú èyí tí ń ṣàìsàn àti èyí tí ó ṣèṣe. Àwọn ọ̀dọ́-àgùtàn tí kò lágbára àti àwọn tí ó ti rẹ̀ ni ó níláti gbé. Àníyàn àtìgbàdégbà wà nípa rírí ìpèsè oúnjẹ àti omi tí ó tó. Kò ṣàìwọ́pọ̀ fún olùṣọ́-àgùtàn láti sùn mọ́jú níta nínú pápá kí ó baà lè ríi pé ààbò dájú fún agbo náà. Nípa bẹ́ẹ̀, ṣíṣe olùṣọ́-àgùtàn jẹ́ ìgbésí-ayé oníṣòro-mímúná tí ó ń béèrè iṣẹ́-ìsìn ọkùnrin kan tí ó jẹ́ alákíkanjú, aláápọn, àti ẹni tí ó lè fi ọgbọ́n yanjú ọ̀ràn. Ju gbogbo rẹ̀ lọ, ó níláti ní agbára náà láti fi ojúlówó àníyàn hàn fún agbo àgùtàn tí a fi sí ìkáwọ́ rẹ̀.
Ṣíṣolùṣọ́-Àgùtàn Agbo Ọlọrun
Bibeli ṣàpèjúwe àwọn ènìyàn Ọlọrun gẹ́gẹ́ bí àgùtàn tí ó rọrùn láti darí àti àwọn tí wọ́n ń bójútó wọn gẹ́gẹ́ bí olùṣọ́-àgùtàn. Jehofa fúnraarẹ̀ ni ‘olùṣọ́-àgùtàn àti alábòójútó ọkàn wa.’ (1 Peteru 2:25) Jesu Kristi, “olùṣọ́-àgùtàn rere náà,” sọ ìdàníyàn rẹ̀ jáde pé kí àwọn àgùtàn náà gba àbójútó oníyọ̀ọ́nú nígbà tí ó sọ fún aposteli Peteru pé: ‘Máa bọ́ àwọn ọ̀dọ́-àgùtàn mi, máa ṣolùṣọ́ àwọn àgùtàn kékeré mi, máa bọ́ àwọn àgùtàn mi.’ (Johannu 10:11; 21:15-17, NW) Àwọn Kristian alábòójútó ni a ti fi ìrònújinlẹ̀ gbé ‘ṣíṣolùṣọ́-àgùtàn ìjọ Ọlọrun’ lé lọ́wọ́. (Iṣe 20:28) Iṣẹ́ wọn gẹ́gẹ́ bí alábòójútó nípa tẹ̀mí sì béèrè fún àwọn ànímọ́ olùṣọ́-àgùtàn dáradára gidi kan—ìgboyà, aápọn, jíjẹ́ ẹni tí ó lè fi ọgbọ́n yanjú ọ̀ràn, àti ní pàtàkì, àníyàn àtọkànwá fun ire-áásìkí agbo.
Ní àwọn ọjọ́ Esekieli wòlíì Ọlọrun, ọ̀pọ̀ jùlọ nínú àwọn olùṣọ́-àgùtàn tí a yànsípò láti bójútó àìní àwọn ènìyàn Jehofa ní Israeli kùnà láti ṣe ojúṣe wọn. Agbo Ọlọrun jìyà gidigidi, tí púpọ̀ nínú àwọn àgùtàn náà sì ń fi ìjọsìn tòótọ́ sílẹ̀. (Esekieli 34:1-10) Lónìí, àwọn àlùfáà Kristẹndọm fi araawọn hàn gẹ́gẹ́ bí olùṣọ́-àgùtàn ìjọ Kristian tí a fẹnu lásán pè bẹ́ẹ̀, ṣùgbọ́n ipò àìsàn rẹ̀ nípa tẹ̀mí fi ẹ̀rí hàn pé àwọn àlùfáà náà dàbí àwọn afàwọ̀rajà tí wọ́n kọ àwọn ènìyàn sílẹ̀ tí wọ́n sì lò wọ́n nílòkulò nígbà tí Jesu wà lórí ilẹ̀-ayé. Àwọn olórí ìsìn Kristẹndọm dàbí àwọn “alágbàṣe,” tí wọn “kò sì náání àwọn àgùtàn.” (Johannu 10:12, 13) Kò sí ọ̀nà kan tí wọ́n gbà múratán, lágbára-ìṣe, tàbí tóótun láti ṣolùṣọ́-àgùtàn agbo Ọlọrun.
Àwọn Olùṣọ́-Àgùtàn tí Wọ́n Bìkítà Níti Tòótọ́
Jesu fi àpẹẹrẹ pípé lélẹ̀ fún gbogbo àwọn tí wọn yóò fẹ́ láti ṣolùṣọ́-àgùtàn agbo Jehofa. Ní gbogbo ọ̀nà ni òun gbà jẹ́ onífẹ̀ẹ́, onínúure, oníyọ̀ọ́nú, tí ó sì ń ṣèrànwọ́ fún àwọn ọmọ-ẹ̀yìn rẹ̀. Ó gbé ìgbésẹ̀ náà láti wá àwọn tí wọ́n ṣe aláìní kiri. Bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé ọwọ́ Jesu dí tí ó sì máa ń rẹ̀ ẹ́ níye ìgbà, ó máa ń fi ààyè sílẹ̀ nígbà gbogbo láti fetísílẹ̀ sí àwọn ìṣòro wọn àti láti fún wọn ní ìṣírí. Ìmúratán rẹ̀ láti jọ̀wọ́ ẹ̀mí rẹ̀ sílẹ̀ nítìtorí wọ́n jẹ́ ìfihàn ìfẹ́ tí ó dé góńgó.—Johannu 15:13.
Lónìí, gbogbo àwọn alàgbà ìjọ tí a yànsípò, àti àwọn ìránṣẹ́ iṣẹ́-òjíṣẹ́ pẹ̀lú, ń ṣàjọpín ẹrù-iṣẹ́ yìí síhà agbo náà. Nípa báyìí, àní àwọn àǹfààní nípa ti ara tí ó ṣeéṣe kí wọ́n rí ní orílẹ̀-èdè mìíràn kò yí èyí tí ó pọ̀jù lára àwọn ọkùnrin tí ó ṣeé fi ẹrù-iṣẹ́ lé lọ́wọ́ wọ̀nyí lọ́kàn padà láti ṣí lọ sí orílẹ̀-èdè mìíràn kí wọ́n sì tipa báyìí fi àwọn ìjọ sílẹ̀ láìsí ìrànlọ́wọ́ àti àbójútó tí ó tó. Bí a ti ń gbé ní “ìgbà ewu,” àwọn agbo nílò ìṣírí àti ìtọ́sọ́nà. (2 Timoteu 3:1-5) Ewu kan tí ó ti wà tipẹ́tipẹ́ náà ni pé àwọn kan yóò di ẹran-ìjẹ fun Satani, ẹni tí “bíi kìnnìún tí ń ké ramúramù . . . ń wá ẹni tí yóò pajẹ kiri.” (1 Peteru 5:8) Nísinsìnyí ju ti ìgbàkigbà rí lọ, o ṣekókó pé kí àwọn Kristian olùṣọ́-àgùtàn “máa kìlọ̀ fun àwọn tíí ṣe aláìgbọràn, ẹ máa tu àwọn aláìlọ́kàn nínú, ẹ máa ran àwọn aláìlera lọ́wọ́.” (1 Tessalonika 5:14) Wíwà lójúfò déédéé ṣe pàtàkì bí wọ́n bá níláti ṣèdíwọ́ fun àwọn aláìfẹsẹ̀múlẹ̀ kúrò nínú fífi agbo sílẹ̀.—1 Timoteu 4:1.
Báwo ni olùṣọ́-àgùtàn ṣe lè pinnu ìgbà tí àgùtàn kan bá nílò ìrànlọ́wọ́? Díẹ̀ lára àwọn àmì tí wọ́n túbọ̀ máa ń farahàn ni kíkùnà láti wá sí àwọn ìpàdé Kristian, àìkópa déédéé nínú iṣẹ́-ìsìn pápá, àti ìtẹ̀sí láti yẹra fún ìbákẹ́gbẹ́ tímọ́tímọ́ pẹ̀lú àwọn ẹlòmíràn. Àìlera ni a tún lè rí nípa fífi tìṣọ́ratìṣọ́ra ṣàkíyèsí ìṣesí àwọn àgùtàn àti irú ìtẹ̀sí tí ń farahàn nínú ìjíròrò wọn. Wọ́n lè ní ìtẹ̀sí láti ṣọ̀fintótó nípa àwọn ẹlòmíràn, bóyá kí wọ́n máa gbé àwọn ìmọ̀lára ìfìbínúhàn yọ. Àwọn ìjíròrò wọn lè dálórí àwọn ìlépa nípa ti ara lọ́nà àṣerégèé dípò lórí àwọn ìlépa ti ẹ̀mí. Àìní ìtara, àìní ẹ̀mí pé nǹkan yóò dára, àti ayọ̀ lápapọ̀ lè túmọ̀sí pe ìgbàgbọ́ wọn ti di aláìlera. Ojú tí ó rẹ̀wẹ̀sì lè jẹ́ àmì kan pé wọ́n ti ní ìkìmọ́lẹ̀ láti ọ̀dọ̀ àwọn ìbátan alátakò tàbí àwọn ọ̀rẹ́ inú ayé. Ní ṣíṣàkíyèsí àwọn àmì wọ̀nyí, olùṣọ́-àgùtàn lè ṣiṣẹ́ síhà pípinnu irú ìrànlọ́wọ́ tí a nílò.
Nígbà tí wọ́n bá ń ṣèbẹ̀wò láti ran onígbàgbọ́ ẹlẹgbẹ́ wọn kan lọ́wọ́, àwọn olùṣọ́-àgùtàn Kristian níláti fi pàtàkì ète wọn sọ́kàn. Kìí wulẹ̀ ṣe kìkì ìkésíni ẹgbẹ́-òun-ọ̀gbà pẹ̀lú ìjíròrò nípa àwọn ohun tí kò níláárí. Ète aposteli Paulu ní ṣíṣe ìbẹ̀wò sọ́dọ̀ àwọn ará rẹ̀ jẹ́ láti ‘lè fún wọn ní ẹ̀bùn ẹ̀mí díẹ̀, kí á lè fi ẹsẹ̀ wọn múlẹ̀ àti pé kí wọ́n lè jùmọ̀ ní ìtùnú nípa ìgbàgbọ́ àwọn méjèèjì.’ (Romu 1:11, 12) Láti ṣàṣepé èyí, ìmúrasílẹ̀ ṣáájú ni a nílò.
Lákọ̀ọ́kọ́, wo ẹni náà kínníkínní, kí o sì gbìyànjú láti fòyemọ bí ipò tẹ̀mí rẹ̀ ti rí. Bí ìyẹn bá ti fìdí múlẹ̀, ronú lórí irú àwọn ìtọ́sọ́nà, ìṣírí, tàbí ìṣítí tí yóò ṣàǹfààní jùlọ. Bibeli, Ọ̀rọ̀ Ọlọrun, gbọ́dọ̀ jẹ́ orísun ìsọfúnni àkọ́kọ́ nítorí pé ó “ní agbára.” (Heberu 4:12) Àwọn ìwé-ìròyìn Ilé-ìṣọ́nà àti Jí! ni a lè yẹ̀wò fún àwọn ọ̀rọ̀-ẹ̀kọ́ tí wọ́n nííṣe pẹ̀lú àwọn àìní pàtó ti àgùtàn náà tí ó kojú àwọn àkànṣe ìṣòro. Àwọn ìrírí amúnilárayá gágá àti atunilára ni a lè rí nínú ìwé Yearbook of Jehovah’s Witnesses. Góńgó-ìlépa náà jẹ́ láti tẹ ohun tẹ̀mí kan mọ́nilọ́kàn èyí tí yóò ‘dára fun ìgbéró ẹni náà.’—Romu 15:2.
Ṣíṣolùṣọ́-Àgùtàn tí Ń Gbéniró
Olùṣọ́-àgùtàn agbo àgùtàn gidi kan mọ̀ pé àwọn àgùtàn gbáralé òun fún ààbò àti ìtọ́jú. Ewu tí ó wọ́pọ̀ jùlọ ń wá láti inú ṣíṣáko lọ, àìsàn, àárẹ̀, ìfaragbọgbẹ́, àti láti ọ̀dọ̀ àwọn adọdẹfiṣèjẹ. Ní irú ọ̀nà kan-náà àwọn olùṣọ́-àgùtàn nípa tẹ̀mí gbọ́dọ̀ mọ̀ kí wọ́n sì kojú irú àwọn ewu kan-náà tí ó ń wu ire-áásìkí agbo. Èyí tí ó tẹ̀lé e yìí ni irú àwọn ìṣòrò àti àwọn àmọ̀ràn díẹ̀ lórí ohun tí a lè sọ láti gbin àwọn ìsọfúnni tí ń gbéniró nípa tẹ̀mí síni lọ́kàn.
(1) Bí àgùtàn tí kò wà lójúfò, àwọn Kristian kan ń ṣáko lọ kúrò nínú agbo Ọlọrun nítorí pé a ré wọn lọ nípasẹ̀ ohun tí ó dàbí òòfà aláìlèpanilára tí ó gbádùnmọ́ni. Wọ́n lè di ẹni tí a pínníyà wọ́n sì tilẹ̀ lè súlọ nítorí lílépa àwọn góńgó tí ó tanmọ́ ohun-ìní ti ara, eré-ìtura, tàbí eré-ìnàjú. (Heberu 2:1) Irú àwọn ẹni bẹ́ẹ̀ ni a lè rán létí ìjẹ́kánjúkánjú àwọn àkókò, nípa àìní náà láti fàsúnmọ́ ètò-àjọ Jehofa, àti nípa ìjẹ́pàtàkì fífi ire Ìjọba sí ipò kìn-ín-ní nínú ìgbésí-ayé. (Matteu 6:25-33; Luku 21:34-36; 1 Timoteu 6:8-10) Àmọ̀ràn tí ń ṣèrànwọ́ ni a rí nínú ọ̀rọ̀-ẹ̀kọ́ náà “Pa Iduro-deede Rẹ Mọ́—Báwo?” nínu Ilé-Ìṣọ́nà November 15, 1984, ojú-ìwé 8 sí 11.
(2) Olùṣọ́-àgùtàn kan níláti pèsè ìtọ́jú fún àgùtàn tí ó dùbúlẹ̀ àìsàn. Bákan náà, àwọn olùṣọ́-àgùtàn nípa tẹ̀mí gbọ́dọ̀ ran àwọn Kristian tí wọ́n di aláìsàn nípa tẹ̀mí nítorí àwọn ipò òdì nínú ìgbésí-ayé wọn lọ́wọ́. (Jakọbu 5:14, 15) Wọ́n lè jẹ́ aláìníṣẹ́lọ́wọ́, wọ́n lè ní ìṣòro àìlera lílekoko kan, tàbí wọ́n lè máa ní ìrírí àwọn ìṣòro nínú ìgbésí-ayé ìdílé wọn. Irú àwọn ènìyàn bẹ́ẹ̀ lè ní ìyánhànhàn tí kò tó nǹkan fún oúnjẹ tẹ̀mí tàbí ìpéjọpọ̀ pẹ̀lú àwọn ènìyàn Ọlọrun. Èyi ní òdìkejì a máa yọrísí ìyara-ẹni láṣo àti ìrẹ̀wẹ̀sì. A níláti mú un dá wọn lójú pé Jehofa bìkítà fún wọn òun yóò sì mú wọn dúró la àwọn àkókò lílekoko já. (Orin Dafidi 55:22; Matteu 18:12-14; 2 Korinti 4:16-18; 1 Peteru 1:6, 7; 5:6, 7) Ó tún lè ṣèrànwọ́ láti ṣàtúnyẹ̀wò ọ̀rọ̀-ẹ̀kọ́ náà “Maa Wo Ọkankan Gan-an Gẹgẹ Bi Kristian,” tí a rí nínú Ilé-Ìṣọ́nà December 1, 1980, ojú-ìwé 12 sí 15.
(3) Olùṣọ́-àgùtàn níláti máa ṣàkíyèsí àgùtàn tí ó bá ń ṣàárẹ̀. Àwọn díẹ̀ ti forítì í pẹ̀lú ìṣòtítọ́ nínú iṣẹ́-ìsìn Jehofa la àwọn ọdún púpọ̀ kọjá. Wọ́n ti jà fitafita la ọ̀pọ̀ ìdánwò àti àdánwò já. Nísinsìnyí wọ́n ń fi àwọn àmì dídi aláàárẹ̀ nínú ṣíṣe dáradára hàn wọ́n sì tún lè fi iyèméjì hàn nípa àìní náà fún ìgbòkègbodò ìwàásù tí a fi gbogbo ọkàn ṣe. Ó pọndandan láti mú ẹ̀mí wọn jígìrì, ní sísọ ìmọrírí wọn dọ̀tun fún ayọ̀ àti ìbùkún tí ń wá láti inú iṣẹ́-ìsìn àtọkànwá sí Ọlọrun ní àfarawé Jesu Kristi. (Galatia 6:9, 10; Heberu 12:1-3) Bóyá a lè ràn wọ́n lọ́wọ́ láti ríi pé Jehofa mọrírì iṣẹ́-ìsìn adúróṣinṣin wọn ó sì lè fún wọn lókun fún àwọn ìgbòkègbodò ọjọ́-iwájú sí ìyìn rẹ̀. (Isaiah 40:29, 30; Heberu 6:10-12) Ó lè ṣàǹfààní láti ṣàjọpín àwọn èrò láti inú ọ̀rọ̀-ẹ̀kọ́ náà “Máṣe Juwọ́sílẹ̀ nínú Ṣíṣe Ohun Tí Ó Jẹ́ Rere,” tí ó farahàn nínú Ilé-Ìṣọ́nà July 15, 1988, ojú-ìwé 9 si 14.
(4) Bí àgùtàn tí ó ṣèṣe, àwọn Kristian kan ni a ti mú ara kan nípa ohun tí wọ́n wòye pé ó jẹ́ ìwà láìfí. Síbẹ̀, bí a bá ń dáríji àwọn ẹlòmíràn, Baba wa ọ̀run yóò fi ìdáríjì tí a nílò jíǹkí wa. (Kolosse 3:12-14; 1 Peteru 4:8) Àwọn arákùnrin tàbí arábìnrin kan lè ti gba àmọ̀ràn tàbí ìbáwí tí wọ́n lérò pé kò tọ̀nà. Bí ó ti wù kí ó rí, gbogbo wa lè jàǹfààní láti inú àmọ̀ràn àti ìbáwí nípa tẹ̀mí, ó sì ń fúnni ní ìtùnú láti mọ̀ pé Jehofa ń bá àwọn tí òun ní ìfẹ́ sí wí. (Heberu 12:4-11) Nítorí pé a kò tíì fún wọn ní àwọn àǹfààní iṣẹ́-ìsìn tí wọ́n lérò pé wọ́n tóótun fún, àwọn mìíràn ti fààyègba ìfìbínúhàn láti dá ọ̀gbun sílẹ̀ láàárín wọn àti ìjọ. Ṣùgbọ́n bí a bá níláti mú araawa takété sí ètò-àjọ Jehofa, kì yóò sí ibìkankan mọ́ láti lọ fún ìgbàlà àti ayọ̀ tòótọ́. (Fiwé Johannu 6:66-69.) Àwọn ìsọfúnni tí ń ṣèrànwọ́ ní ọ̀nà yìí ni a lè rí nínú ọ̀rọ̀-ẹ̀kọ́ náà “Títọ́júdi Ìṣọ̀kanṣoṣo Kristian Wa Mú,” tí ó wà nínú Ilé-Ìṣọ́nà August 15, 1988, ojú-ìwé 28 sí 30.
(5) A níláti dáàbòbo àwọn àgùtàn kúrò lọ́wọ́ àwọn adọdẹfiṣèjẹ. Ní ìfiwéra, àwọn kan ni a lè takò kí á sì dáyàfò nípasẹ̀ àwọn ìbátan aláìgbàgbọ́ tàbí àwọn alájọṣiṣẹ́. Ìwàtítọ́ wọn lè wá sábẹ́ ìkọlù nígbà tí a bá dojú àwọn ìkìmọ́lẹ̀ kọ wọ́n láti mú wọn dín iṣẹ́-ìsìn wọn sí Ọlọrun kù tàbí dáwọ́ níní ìpín nínú iṣẹ́-òjíṣẹ́ Kristian dúró. Bí ó ti wù kí ó rí, a fún wọn lókun, nígbà tí a bá ràn wọ́n lọ́wọ́ láti mọ̀ pé àtakò ni wọ́n níláti retí ó sì jẹ́ ọ̀kan lára àwọn ẹ̀rí pé àwa jẹ́ ojúlówó ọmọlẹ́yìn Jesu Kristi. (Matteu 5:11, 12; 10:32-39; 24:9; 2 Timoteu 3:12) Ó lè ṣàǹfààní láti ṣàlàyé pé bí wọ́n bá jẹ́ olùṣòtítọ́, Jehofa kì yóò fi wọ́n sílẹ̀ láé yóò sì sẹ̀san fún ìforítì wọn. (2 Korinti 4:7-9; Jakọbu 1:2-4, 12; 1 Peteru 5:8-10) Ọ̀rọ̀-ẹ̀kọ́ náà tí àkọlé rẹ̀ jẹ́ “Fifara Da A Tayọtayọ Laika Inunibini Si” nínú Ilé-Ìsọ́nà October 15, 1982, ojú-ìwé 19 sí 25, pèsè ìṣírí síwájú síi.
Ẹ̀yin Olùṣọ́-Àgùtàn —Ẹ Mú Ẹrù-Iṣẹ́ Yín Ṣẹ
Àìní agbo Ọlọrun pọ̀, àbójútó-onítọ̀ọ́jú gidi sì jẹ́ iṣẹ́ agbàkókò kan. Nítorí náà awọn Kristian olùṣọ́-àgùtàn gbọ́dọ̀ jẹ́ oníyọ̀ọ́nú, adàníyàn látọkànwá, kí wọ́n sì lọ́kàn-ìfẹ́ nínú jíjẹ́ olùrannilọ́wọ́. Sùúrù àti ìwòyeronú ṣe pàtàkì. Nígbà tí àwọn kan wà tí wọ́n nílò àmọ̀ràn àti ìṣítí, àwọn mìíràn ń jàǹfààní jùlọ láti inú ìṣírí. Lílọ ṣèbẹ̀wò ráńpẹ́ lè ti tó nínú àwọn ọ̀ràn kan, nígbà tí ó sì jẹ́ pé nínú àwọn ọ̀ràn mìíràn ìkẹ́kọ̀ọ́ Bibeli déédéé ni a lè nílò. Nínú gbogbo ọ̀ràn góńgó àkọ́kọ́ jẹ́ láti gbin ìtọ́sọ́nà tí ń gbéniró nípa tẹ̀mí sí wọn lọ́kàn tàbí àmọ̀ràn onífẹ̀ẹ́ tí yóò sún ẹni náà láti dá àṣà ìkẹ́kọ̀ọ́ dáradára sílẹ̀, kí ó di ẹni tí ń lọ tàbí tí ń báa lọ nínú lílọ sí àwọn ìpàdé ìjọ déédéé, kí ó sì gbádùn ìkópa tí ó gbéṣẹ́ nínú iṣẹ́-òjíṣẹ́ Kristian. Ìwọ̀nyí jẹ́ àwọn ọ̀nà pàtàkì tí a lè gbà fún àwọn onígbàgbọ́ ẹlẹgbẹ́ wa ní ìtìlẹ́yìn kí á sì ràn wọ́n lọwọ́ láti ṣí ọ̀nà sílẹ̀ fún ìṣiṣẹ́ ẹ̀mí mímọ́ Jehofa ní fàlàlà.
Àwọn olùṣọ́-àgùtàn tí wọ́n pèsè irú ìtìlẹ́yìn bẹ́ẹ̀ ṣe iṣẹ́-ìsìn tí ó níyelórí jùlọ fún agbo Ọlọrun. (Wo Ilé-Ìṣọ́nà July 15, 1986, ojú-ìwé 27 sí 31.) Ohun tí àwọn olùṣọ́-àgùtàn nípa tẹ̀mí ń ṣe ni àwọn àgùtàn mọrírì gan-an. Lẹ́yìn gbígba irú ìrànlọ́wọ́ bẹ́ẹ̀, olórí ìdílé kan sọ pé: ‘Lẹ́yìn tí a ti wà nínú òtítọ́ fún ọdún méjìlélógún, ìfẹ́ fún ọrọ̀-àlùmọ́nì fà wá lọ sínú ayé. A sábà máa ń fẹ́ láti lọ sí àwọn ìpàdé, ṣùgbọ́n ó wulẹ̀ dàbí ẹni pé kò lè ṣeéṣe fún wa ni. A kò bá ètò-ìgbékalẹ̀ Satani mú rárá, nítorí náà a pín wa níyà pátápátá, a wà ní àdádó. Èyí fi wá sínu ìjákulẹ̀ àti ìsoríkọ́. A nílò àwọn ọ̀rọ̀ ìṣírí. Nígbà tí alàgbà kan bẹ̀ wá wò, a fi tayọ̀tayọ̀ gba ìpèsè ìkẹ́kọ̀ọ́ Bibeli kan nínú ilé wa. Ní báyìí gbogbo wa ti padà sínú ètò-àjọ Jehofa tí ó láàbò. Èmi kò lè sọ bí ayọ̀ tí mo nímọ̀lára rẹ̀ ti ga tó!’
Ìdí fún ìdùnnú púpọ̀ wà nígbà tí àwọn arákùnrin tàbí arábìnrin wa tí wọ́n ṣákolọ tàbí tí wọ́n ní ìrẹ̀wẹ̀sì bá di ẹni tí a mú sọjí tí a sì tún sọ di alákitiyan-iṣẹ́ nípa tẹ̀mí. (Luku 15:4-7) Ète Jehofa fún àwọn ènìyàn rẹ̀ ní a múṣẹ nígbà tí wọ́n bá wà ní ìṣọ̀kan “gẹ́gẹ́ bí ọ̀wọ́ ẹran nínú agbo wọn.” (Mika 2:12) Nínú èbúté aláàbò yìí, wọ́n ‘rí ìsinmi fún ọkàn wọn’ pẹ̀lú ìrànlọ́wọ́ Olùṣọ́-Àgùtàn Rere náà, Jesu Kristi. (Matteu 11:28-30) Àwọn àgùtàn jákèjádò ayé tí wọ́n wà ní ìṣọ̀kan ń gba ìtọ́sọ́nà, ìtùnú, àti ààbò papọ̀ pẹ̀lú ọ̀pọ̀ yanturu oúnjẹ́ tẹ̀mí.
Lónìí, nípasẹ̀ ìgbòkègbodò olùṣọ́-àgùtàn yìí, Jehofa ń ríi pé a ń ṣe iṣẹ́ onífẹ̀ẹ́ kan tí ó wà ní ìṣọ̀kan pẹ̀lú ìlérí rẹ̀ àtijọ́ pé: “Àní èmi, ó béèrè àwọn àgùtàn mi, èmi ó sì wá wọ́n rí. . . . Èmi ó sì gbá wọn jọ níbi gbogbo tí wọ́n ti fọ́nká sí . . . Èmi óò bọ́ wọn ní pápá oko dáradára . . . Èmi óò wá èyí tí ó sọnù lọ, . . . èmi ó sì di èyí tí a ṣá lọ́gbẹ́, èmi óò mú èyí tí ó ṣàìsàn ní ara le.” (Esekieli 34:11-16) Ẹ wo irú ìtùnú tí ó wà nínú mímọ̀ pé Jehofa ni Olùṣọ́-Àgùtàn wa!—Orin Dafidi 23:1-4.
Nítorí àwọn ìpèsè àtọ̀runwá fún ṣíṣolùṣọ́-àgùtàn agbo Ọlọrun, gẹ́gẹ́ bí ìránṣẹ́ Jehofa àwa lè ṣàjọpín àwọn èrò-ìmọ̀lára Dafidi, ẹni tí ó wí pé: “Èmi ó dùbúlẹ̀ pẹ̀lú ní àlàáfíà, èmi ó sì sùn; nítorí ìwọ, Oluwa, nìkanṣoṣo ni o ń mú mi jókòó ní àìléwu.” (Orin Dafidi 4:8) Bẹẹni, àwọn ènìyàn Jehofa nímọ̀lára ààbò nínú ìtọ́jú onífẹ̀ẹ́ rẹ̀ wọ́n sì kún fún ọpẹ́ pé àwọn alàgbà Kristian ń fi ìyọ́nú ṣolùṣọ́-àgùtàn àwọn àgùtàn kékeré náà.
[Àwòrán Credit Line tó wà ní ojú ìwés 20, 21]
Potter’s Complete Bible Encyclopedia