Fífi Ìfaradà Wàásù ní Ilẹ̀ Yìnyín àti Iná
ICELAND wà ní Àríwá Atlantic ní nǹkan bí agbedeméjì-ọ̀nà láàárín Àríwá America àti Europe. Bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé ó wà ní ìsàlẹ̀ Arctic Circle, ipò ojú-ọjọ́ rẹ̀ tura ju bí a ṣe lè retí lọ, nítorí ìyọrísí ìlọ́wọ́ọ́wọ́ Ìṣẹ́tí Òkun. Iceland ni a ti pè ní ilẹ̀ yìnyín àti iná nítorí pé ó ní ìṣàn-òkìtì-yìnyín títóbi jùlọ́ ní Europe ó sì tún jẹ́ ọ̀kan lára àwọn àgbègbè òkè-ayọnáyèéfín tí ń bú jáde lóòrèkóòrè ní ayé. Ohun tí a mọ̀ dáradára ni ọ̀pọ̀ ìsun-omi gbígbóná àti èéfín iná púpọ̀ tí ó wà níbẹ̀, àgbègbè òkè-ayọnáyèéfín tí ń rú ooru gbígbóná àti àwọn afẹ́fẹ́ onísúlfúrù jáde.
Àwọn ọ̀kẹ́mẹ́tàlá olùgbé erékùṣù títóbi jùlọ ṣìkejì ti Europe yìí jẹ́ ìran-àtẹ̀lé àwọn Viking, tí wọ́n tẹ̀dó síhìn-ín ní nǹkan tí ó ju ẹ̀ẹ́dẹ́gbẹ̀fà ọdún lọ sẹ́yìn. Èdè Iceland ní pàtàkì jẹ́ ọ̀kan náà bí ti Old Norse, èdè àwọn ará Scandinavia ti ọjọ́ àwọn Viking. Ó ti wà ní ohun tí ó fẹ́rẹ̀ẹ́ má yípadà nítorí pé àwọn ará Iceland kúndùn kíka àwọn ìtàn àtọdúnmọ́dún wọn, tí a kọ ní pàtàkì jùlọ ní ọ̀rúndún kẹtàlá.
Nígbà tí ó fi máa di ọ̀rúndún kẹrìndínlógún, Bibeli ni a bẹ̀rẹ̀ síí túmọ̀ sí èdè Iceland. “Májẹ̀mú Titun” kan farahàn ní 1540 àti odindi Bibeli ní 1584. Iye tí ó ju ìpín àádọ́rùn-ún nínú ọgọ́rùn-ún àwọn ènìyàn náà jẹ́ ti Ṣọọṣi Evangelical Lutheran, ìsìn tí Ìjọba fàṣẹ sí. Bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé a rí Bibeli ní ohun tí ó fẹ́rẹ̀ẹ́ jẹ́ gbogbo ilé, àwọn díẹ̀ ni wọ́n gbàgbọ́ pé Ọ̀rọ̀ Ọlọrun ni. Ọ̀pọ̀ jùlọ àwọn ará Iceland a máa gba ojú-ìwòye ẹlòmíràn yẹ̀wò nípa ìsìn àti, ní gbogbogbòò, wọ́n jẹ́ adáronú.
Ìhìnrere Dé Iceland
Àwọn ọmọ ilẹ̀ Iceland tí wọ́n kọ́kọ́ gbọ́ ìhìnrere Ìjọba náà ń gbé ní Canada nígbà yẹn. Ọ̀kan nínú wọn ni Georg Fjölnir Lindal. Àwọn òbí rẹ̀ wá láti Iceland, ó sì ń sọ èdè Iceland. Láìpẹ́ lẹ́yìn tí ó ya ìgbésí-ayé rẹ̀ sí mímọ́ fún Jehofa Ọlọrun, ó di oníwàásù ìhìnrere alákòókò kíkún. Ní 1929, nígbà tí ó jẹ́ ẹni ogójì ọdún, ó mú ìhìnrere náà tọ àwọn ènìyàn lọ ní ilẹ̀ yìnyín àti iná yẹn.
Iṣẹ́ takuntakun wo ni èyí jẹ́ fún ẹyọ ẹnìkan! Iceland jẹ́ nǹkan bíi 320 kìlómítà láti àríwá sí gúúsù àti ohun tí ó tó 500 kìlómítà láti ìlà-oòrùn sí ìwọ̀-oòrùn. Ààlà ilẹ̀-ẹ̀bá etíkun, tí ó fi mọ́ itọ́ omi kékeré àti ńlá, jẹ́ nǹkan bíi ọ̀kẹ́ mẹ́ta lé ní irínwó kìlómítà ní gígùn. Ní àkókò yẹn, kò sí ọ̀nà gidi kan kí a kúkú sọ pé kò sí ọkọ̀-ìrìnnà kankan tàbí ọ̀nà tí a gbà ń rìnrìn-àjò yíká èyíkéyìí lóde-òní. Síbẹ̀, Arákùnrin Lindal kárí gbogbo erékùṣù náà láàárín ọdún mẹ́wàá ó sì pín ẹgbẹẹgbẹ̀rún ìwé. Ó rìnrìn-àjò gba etíkun náà nínú ọkọ̀ ojú-omi ọlọ́pọ́n, nígbà tí ó bá sì ṣèbẹ̀wò sí àwọn inú oko, ó ń lo ẹṣin méjì, ọ̀kan láti gbé e àti èkejì láti gbé ìwe àti àwọn ohun-ìní rẹ̀.
Fún ohun tí ó fẹ́rẹ̀ẹ́ tó ọdún méjìdílógún, Arákùnrin Lindal ni Ẹlẹ́rìí kanṣoṣo tí ó wà ní Iceland. Láìka iṣẹ́ àṣekára rẹ̀ sí, òun kò rí ẹnìkankan tí ó mú ìdúró rẹ̀ fún Ìjọba náà ní àkókò yẹn. Ìdánìkanwà alákòókò gígùn rẹ̀ parí ní March 25, 1947, nígbà tí àwọn akẹ́kọ̀ọ́yege àkọ́kọ́ ti Watchtower Bible School of Gilead dé. Ìwọ lè ronúwòye ayọ̀ rẹ̀ nígbà tí Jehofa dáhùn àdúrà rẹ̀ fún àwọn òṣìṣẹ́ púpọ̀ síi fún ìkórè náà ní ìkẹyìn. (Matteu 9:37, 38) Arákùnrin Lindal ń bá iṣẹ́-ìsìn rẹ̀ lọ ní Iceland títí fi di ìgbà tí ó padà sí Canada ní 1953.
Àwọn Òṣìṣẹ́ Púpọ̀ síi fún Ìkórè Náà
Àwọn miṣọ́nnárì tí wọ́n dé ní 1947 jẹ́ àwọn arákùnrin méjì láti Denmark. Àwọn miṣọ́nnárì méjì dé síi ní ọdún méjì lẹ́yìn náà. Bí wọ́n ti ń bá iṣẹ́ ìwàásù náà lọ papọ̀ pẹ̀lú àwọn ọ̀rẹ́ díẹ̀ tí wọ́n ti ṣí wá sí Iceland, ẹgbẹẹgbẹ̀rún ìtẹ̀jáde ni a pínkiri. Ọ̀pọ̀ jùlọ àwọn ará Iceland jẹ́ ọ̀jẹ̀wé, ṣùgbọ́n àwọn tí ó dáhùnpadà sí ìhìnrere náà kò pọ̀. Lẹ́yìn ọdún mẹ́tàdínlọ́gbọ̀n ti gbígbìn àti bíbomirin, àwọn arákùnrin onísùúrù náà bẹ̀rẹ̀ síí rí èso làálàá wọn. Ní 1956 àwọn ẹni titun méje mú ìdúró wọn fún Ìjọba náà wọ́n sì ya ìgbésí-ayé wọn sí mímọ́ fún Jehofa.
Láàárín ọdún mẹ́wàá tí ó kọjá, iye àwọn olùpòkìkí Ìjọba ti rékọjá ìlọ́po méjì. Nísinsìnyí, ìjọ méje àti àwùjọ àdádó kan, àròpọ̀ 280 àwọn olùpòkìkí ìhìnrere ni ó wà. Ẹ jẹ́ kí a rin ìrìn-àjò ráńpẹ́ yíká erékùṣù náà láti bẹ àwọn ìjọ wọ̀nyí wò.
Yíká Olú-Ìlú
Àwọn arákùnrin àti arábìnrin tí wọ́n farada gbogbo àwọn ọdún wọ̀nyẹn ni a ti bùkún fún lọ́pọ̀ jaburata. Ìjọ méjì tí ń gbèrú ni ó wà ní Reykjavík, olú-ìlú ńlá náà. Wọ́n ń pàdé nínú Gbọ̀ngàn Ìjọba mèremère tí ó wà nínú ilé kan-náà tí ẹ̀ka ọfíìsì wà, èyí tí a yàsímímọ́ ní 1975.
Friðrik àti Ada wà lára àwọn méje tí a baptisi nígbà náà lọ́hùn-ún ní 1956. “Mo padà rántí pé a máa ń ṣe àwọn ìpàdé nínú iyàrá kékeré kan nínú yàrá òkè-ilé níbi tí àwọn miṣọ́nnárì ń gbé,” ni Friðrik sọ. “Ààyè wà fún àga méjìlá, ṣùgbọ́n nígbà mìíràn, nígbà tí àwọn tí ó pọ̀ ju iye tí ó máa ń wá déédéé bá yọjú, a ń ṣí ilẹ̀kùn tí ó kángun sí yàrá kékeré náà. Ẹ wo irú ìyàtọ̀ tí ó jẹ́ lónìí nígbà tí ìjọ méjì ń kún Gbọngan Ijọba!”
Friðrik ni ó ń bójútó Ẹ̀ka Ìpèsè Oúnjẹ nígbà tí a ṣe àpéjọ àkọ́kọ́. “Mo ṣe ọ̀pọ̀ jùlọ nínú iṣẹ́ náà fúnraàmi, àti ní àkókò kan-náà, kò ṣàjèjì fún mi láti ní apá mẹ́ta tàbí mẹ́rin lórí ìtòlẹ́sẹẹsẹ náà lójoojúmọ́. Nígbà tí mo ń ṣiṣẹ́ nínú ilé-ìdáná, mo so aṣọ ìseńjẹ kan kọ́rùn. Nígbà tí àkókò tó láti sọ ọ̀rọ̀-àsọyé, mo gbé jákẹ́ẹ̀tì mi wọ̀ mo sì yára wọnú gbọ̀ngàn lọ. Ní ìgbà mélòókan àwọn ará níláti rán mi létí láti tú aṣọ-ìseńjẹ kúrò lọ́rùn. Nísinsìnyí a ní irínwó sí ẹ̀ẹ́dẹ́gbẹ̀ta tí ń pésẹ̀ sí àwọn àpéjọ, papọ̀ pẹ̀lú àwọn alàgbà rere tí ń ṣàjọpín nínú bíbójútó àwọn apá lórí ìtòlẹ́sẹẹsẹ. Ọ̀pọ̀lọpọ̀ àwọn tí wọ́n múratán láti ṣèrànlọ́wọ́ ni wọ́n tún wà ní Ẹ̀ka Ìpèsè Oúnjẹ.”
Ìjọ tí ó súnmọ́ Reykjavík jùlọ ni Keflavík, nǹkan bíi àádọ́ta kìlómítà sí ìwọ̀-oòrùn. Ọkọ̀ náà gbé wa la àwọn pápá ẹrẹ̀ tí ó ń di àpáta kọjá. Ìpín mẹ́wàá nínú ọgọ́rùn-ún Iceland ni ó kún fún ẹrẹ̀ tí ó ń di àpáta. Ewéko tí ó kọ́kọ́ farahàn nínú àwọn pápá wọ̀nyí papọ̀ jẹ́ àwọn lichen àti àwọn èpò éléwé wẹ́rẹ́wẹ́rẹ́, ṣùgbọ́n ní àwọn pápá tí ẹrẹ̀ tí ó ń di àpáta ti gbẹ mọ́ tipẹ́, ìwọ yóò rí àwọn èso wild berry àti koríko kékeré tí kò ga púpọ̀.
Ìjọ tí ó wà ní Keflavík ní àwọn akéde mọ́kàndínlógún a sì dá a sílẹ̀ ni 1965. Nítòsí ni pápá ọkọ̀ òfuurufú jákèjádò àwọn orílẹ̀-èdè wà, ibùdó ológun ti United States sì tún wà níbẹ̀ pẹ̀lú. Bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé kò tíì ṣeéṣe fún àwọn Ẹlẹ́rìí náà láti lè ṣiṣẹ́ láti ilé dé ilé nínú ibùdó náà fúnraarẹ̀, ọ̀pọ̀ àwọn ìkẹ́kọ̀ọ́ Bibeli ni a ti darí níbẹ̀, iye ènìyàn kéréjé kan sì ti kẹ́kọ̀ọ́ òtítọ́.
Ìjọ mìíràn wà ní Selfoss, kìlómítà márùndínlọ́gọ́ta níhà ìlà-oòrùn Reykjavík. Níhìn-ín ni a rí orílẹ̀-èdè oníṣẹ́-àgbẹ̀ irúgbìn pẹ̀lú ọ̀sìn màlúù àti àgùtàn, papọ̀ pẹ̀lú ilé-iṣẹ́ wàrà ṣíṣe títóbi jùlọ ti Iceland. Lójú ọ̀nà, a kọjá Hveragerði, ìlú kékeré kan tí ó wà nínú àfonífojì ẹlẹ́wà kan. Láti òkèèrè a ṣàkíyèsí ọwọ̀n ooru láti inú àwọn ìṣàn-omi gbígbóná ní gbogbo àfonífojì náà. Èyí ni ọ̀kan lára àwọn àgbègbè gbígbóná jùlọ ní orílẹ̀-èdè náà, ọ̀pọ̀lọpọ̀ ilé-ewéko ni a sì ti kọ́ láti lè ṣàmúlò àwọn ohun àmúṣọrọ̀ wọ̀nyí kí á sì pèsè àwọn tòmátì, kùkúḿbà, àti onírúurú òdòdó láti inú ilé-olóoru wá.
Ní àgbègbè yìí ìjọ kékeré kan ṣùgbọ́n tí ń gbékánkán ṣiṣẹ́ ti àwọn akéde Ìjọba mọ́kàndínlógún wà. Sigurður àti Guðrún Svava ṣí wá láti Reykjavík láti ṣètìlẹ́yìn fún àwùjọ kékeré yìí ní déédéé ìgbà tí ìjọ àkọ́kọ́ fìdímúlẹ̀ ní 1988. Sigurður ni alàgbà kanṣoṣo tí ó wà níbẹ̀. Kí ó tó di ọ̀kan lára àwọn Ẹlẹ́rìí Jehofa ní nǹkan bí ọdún mẹ́wàá sẹ́yìn, ó jẹ́ olórin kan tí ó gbajúmọ̀, tí ń lu onírúurú ìlù. Lónìí, fèrèsé ni ó ń nù láti fi gbọ́ bùkátà, ó sì tún ń kọ́ni ní orin. Ọ̀nà ìgbàgbé ìgbésí-ayé rẹ̀ gẹ́gẹ́ bíi adánilárayá kan mú ọ̀pọ̀lọpọ̀ ìṣòro wá fún un, irú bí ìlòkulò oògùn, àmujù ọtí, àti ìgbéyàwó tí ó ti foríṣánpọ́n. Ó ti nítẹ̀ẹ́lọ́rùn tó nísinsìnyí, bí ó ti ní ète nínú ìgbésí-ayé tí ó sì ń ṣiṣẹ́sin Jehofa!
Lọ sí Ìpẹ̀kun Ìlà-Oòrùn
Bí a ti ń fi Selfoss sílẹ̀, a bọ́ sẹ́nu ìrìn ọ̀rìnlélẹ́gbẹ̀ta kìlómítà, tí èyí tí ó pọ̀ jùlọ nínú rẹ̀ jẹ́ lórí ọ̀nà tóóró tí a da òkúta wẹ́wẹ́ sí. A forílé ìjọ tí ó kàn, ní ìlú Reyðarfjörður, ní ìlà-oòrùn etíkun. Láàárín ààbọ̀ wákàtí, a bẹ̀rẹ̀ síí rí Hekla, òkè ayọnáyèéfín tí ó lókìkí jùlọ ti Iceland. Ó ti bú jáde lẹ́ẹ̀mẹrin ní ọ̀rúndún yìí.
Ní 1973 ìbújáde òkè ayọnáyèéfín amúnijígìrì wáyé lórí Vestmannaeyjar (Àwọn Erékùṣù Westmann). Àpapọ̀ nǹkan bíi ọ́dúnrún lé lẹ́gbẹ̀ẹ́dọ́gbọ̀n olùgbé níbẹ̀ ni a ṣí nípò kúrò láìséwu lọ sí àárín ilẹ̀ láàárín àwọn wákàtí díẹ̀. Lẹ́yìn ìmúpadàbọ̀sípò ìlú náà, ọ̀pọ̀ jùlọ lára àwọn olùgbé náà padà ní kẹ̀rẹ̀kẹ̀rẹ̀. Àwọn Ẹlẹ́rìí méjì ń gbé níbẹ̀ nísinsìnyí wọ́n sì ń wàásù ìhìnrere fún àwọn ènìyàn nínú àwùjọ kékeré yìí. Ní wíwakọ̀ fún wákàtí méjì mìíràn, a mú wa gbádùn ìran mèremère ti Vatnajökull títóbilọ́lá, tí ó tóbi jùlọ fíìfíì nínú àwọn ìṣàn-òkìtì-yìnyín Iceland, pẹ̀lú àròpọ̀ ọ̀ọ́dúnrún lé lẹ́gbàá mẹ́rin kìlómítà níbùú-lóòró. Ní ojú ọ̀nà, a tún kọjá ọ̀pọ̀lọpọ̀ àwọn ìtàkìtì-omi mèremère àti àwọn odò.
Bí a ti lo wákàtí mẹ́wàá lójú ọ̀nà, a dé ibi tí a ń rè. Ní Reyðarfjörður a pàdé àwọn akéde méjìlá nínú ìjọ tí a dá sílẹ̀ gbẹ̀yìn ní Iceland. Kò sí àwọn Ẹlẹ́rìí kankan tí ń gbé ní àgbègbè yìí títí fi di ìgbà tí a dá ilé miṣọ́nnárì sílẹ̀ ní apá tí ó kẹ́yìn 1988. Kjell àti Iiris, tọkọtaya miṣọ́nnárì láti Sweden tí wọn ti ń ṣiṣẹ́sìn ní Iceland láti 1963, ni a yànṣẹ́ fún láti ṣiṣẹ́ láàárín àwọn ẹ̀ẹ́dẹ́gbàájọ ènìyàn ní àgbègbè ìgbèríko yìí. Ọ̀pọ̀lọpọ̀ gbé nínú abúlé ẹja pípa kékeré lẹ́bàá ààlà ilẹ̀ etíkun, tí ó gbòòrò tó nǹkan bíi ẹ̀ẹ́dẹ́gbẹ̀ta kìlómítà.
Kjell ròyìn pé: “Kò sí iyèméjì pé Jehofa ti bùkún iṣẹ́ Ìjọba náà ní jìngbìnnì ní apá ibí yìí ní Iceland. Ní January 1, 1993, ìjọ kan ni a dá sílẹ̀, a sì ń darí ọ̀pọ̀lọpọ̀ àwọn ìkẹ́kọ̀ọ́ Bibeli dídára pẹ̀lú àwọn ẹnìkọ̀ọ̀kan tí wọ́n ń ní ìtẹ̀síwájú rere. Bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé ọ̀nà ìrìnnà ti yípadà láti ìgbà tí Arákùnrin Lindal ti ń gẹṣin rìn, kìí fìgbà gbogbo rọrùn láti wakọ̀ kọjá àwọn gẹ̀rẹ́gẹ̀rẹ́ òkè lórí àwọn ojú-ọ̀nà oníyìnyín nígbà tí ojú ọjọ́ máa ń dágúdẹ̀ nínú oṣù lákòókò òjò, àní pẹ̀lú ọkọ̀ jeep ẹlẹ́sẹ̀-mẹ́rin pàápàá. Lẹ́ẹ̀kan rí, ẹ̀fúùfù gbá a dànù lójú-ọ̀nà oníyìnyín tí ó sì tàkìtí lẹ́ẹ̀mejì tàbí lẹ́ẹ̀mẹta lọ sísàlẹ̀ gẹ̀rẹ́gẹ̀rẹ́ kan. Inú wa ti dùn tó láti yèbọ́ láìfarapa!”
Lẹ́yìn ọgbọ̀n ọdún ní Iceland, Iiris sọ pé: “La ọ̀pọ̀ ọdún já ọ̀pọ̀lọpọ̀ ti wá láti àwọn orílẹ̀-èdè mìíràn láti ṣèrànwọ́. Bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé ọ̀pọ̀ jùlọ níláti lọ fún onírúurú ìdí, wọ́n ti ní ìpín ńláǹlà dájúdájú nínú iṣẹ́ gbígbìn àti bíbomirin. A láyọ̀ pé ó ṣeéṣe fún wa láti dúró, níwọ̀n bí a ti wá ní àǹfààní rírí ìkórè náà tí ń wọlé wá. Jehofa ń mú iṣẹ́ náà yára kánkán níhìn-ín pẹ̀lú.”
Ọ̀pọ̀ jùlọ nínú ìbísí náà ti wá nítorí pé àwọn ẹni titun ń jẹ́rìí fún àwọn òṣìṣẹ́ ẹlẹgbẹ́ wọn. Atli kẹ́kọ̀ọ́ òtítọ́ lọ́dọ̀ àwọn miṣọ́nnárì ó sì bẹ̀rẹ̀ síí bá àwọn ẹlòmíràn sọ̀rọ̀ ní ilé-iṣẹ́ ìkọ́lé tí ó ti ń ṣiṣẹ́. Méjì nínú àwọn òṣìṣẹ́ ẹlẹgbẹ́ rẹ̀ ń ṣàjọpín nínú iṣẹ́ ìwàásù náà nísinsìnyí, a sì baptisi ọ̀kan àti ìyàwó rẹ̀ ní November 1992. Òṣìṣẹ́ ẹlẹgbẹ́ rẹ̀ kẹta ti ń kẹ́kọ̀ọ́ Bibeli pẹ̀lú àwọn Ẹlẹ́rìí.
Fíforílé Ojú-Ọ̀nà Ìhà-Àríwá
Ní fífi Reyðarfjörður sílẹ̀, a forílé ìwọ̀-oòrùn. Ìjọ tí ó kàn jìnnà tó ọ̀ọ́dúnrún kìlómítà, ní ìlú Akureyri. Àwọn àkànṣe oníwàásù alákòókò kíkún ni a yàn láti ṣiṣẹ́ níbẹ̀ ní ìbẹ̀rẹ̀ àwọn ọdún 1950. Láti ìbẹ̀rẹ̀ gan-an, iṣẹ́ náà bá àtakò lílekoko pàdé láti ọ̀dọ̀ àwọn àlùfáà-ṣọ́ọ̀ṣì kan. Àwọn ọ̀rọ̀-ẹ̀kọ́ ni a tẹ̀jáde nínú ìwé-ìròyìn àdúgbò láti kìlọ̀ lòdìsí àwọn Ẹlẹ́rìí Jehofa. Ọ̀pọ̀lọpọ̀ nínú àwọn ènìyàn ìlú ni wọ́n tún ń lọ́wọ́ nínú ìbẹ́mìílò. Ṣùgbọn nítorí ìfaradà àti sùúrù àwọn onírúurú aṣáájú-ọ̀nà àti àwọn miṣọ́nnárì, lónìí ìjọ tí ń gbékánkánṣiṣẹ́ àti onífẹ̀ẹ́ kan tí ó ní àwọn oníwàásù Ìjọba márùndínlógójì ni ó wà.
Friðrik, ọ̀kan lára àwọn alàgbà níhìn-ín, jẹ́ apẹja. Lẹ́yìn lílọ sí àpéjọpọ̀ àgbègbè ní 1982, ó dá á lójú pé òtítọ́ ni òun ń kẹ́kọ̀ọ́ rẹ̀. Ó padà sí Akureyri pẹ̀lú ìpinnu láti jẹ́rìí fún ìdílé, àwọn ọ̀rẹ́, àti òṣìṣẹ́ ẹlẹgbẹ́ rẹ̀. Friðrik ṣètò láti fi iṣẹ́ rẹ̀ gẹ́gẹ́ bí apẹja sílẹ̀ kí ó baà lè ní àkókò púpọ̀ síi pẹ̀lú ìjọ. Ó sọ fún ọ̀rẹ́bìnrin rẹ̀, Helga, pé àwọn kò lè máa gbé papọ̀ mọ́ títí di ìgbà tí àwọn bá jọ ṣègbéyàwó, níwọ̀n bí òun yóò ti di ọ̀kan lára àwọn Ẹlẹ́rìí Jehofa. Friðrik tún fẹ́ kí ó kẹ́kọ̀ọ́ Bibeli nítorí pé òun kò ní ‘gbé aláìgbàgbọ́ níyàwó.’ (1 Korinti 7:39) Sí ìyàlẹ́nu rẹ̀ Helga bẹ̀rẹ̀ síi kẹ́kọ̀ọ́. Wọn ṣègbéyàwó ní February 1983 a sì baptisi wọn láìpẹ́ lẹ́yìn ìgbà náà. Bí àkókò ti ń lọ ìyá àti arábìnrin Friðrik tún tẹ́wọ́gba òtítọ́.
A fi àdàgbá ìrìn-àjò rọ̀ sí Akranes, tí ó jẹ́ 350 kìlómítà láti Akureyri, rékọjá àwọn òkè gíga mẹ́ta àti ọ̀pọ̀lọpọ̀ àwọn àfonífojì mèremère. Níhìn-ìn a fi òkúta tẹ́ ojú-ọnà, ní mímú kí lílọ yíká náà gbádùnmọ́ni ní ìfiwéra pẹ̀lú àwọn ojú-ọ̀nà gbágungbàgun àti ojú-ọ̀nà olókùúta tóóró tí a ti rìn lórí rẹ̀ níbi púpọ̀ lójú ọ̀nà náà. Ní Akranes ìjọ tí ó kéré jùlọ wà ní Iceland—akéde márùn-ún, tí méjì nínú wọn ń sìn gẹ́gẹ́ bí alàgbà. Wọ́n parapọ̀ jẹ́ ìdílé méjì tí ó dáhùnpadà sí ìkésíni ará Makedonia náà, wọ́n fi ọ̀kan lára àwọn ìjọ títóbi jù ní Reykjavík sílẹ̀, wọ́n sì fìdíkalẹ̀ sí ìlú kékeré yìí láti ṣiṣẹ́sìn níbi tí àìní gbé pọ̀ jù. (Iṣe 16:9, 10) Fún ohun tí ó ju ọdún méjì lọ nísinsìnyí, wọ́n ti fi sùúrù wàásù ìhìnrere ní ìpínlẹ̀ yìí, pẹ̀lú ìgbọ́kànlé pé Jehofa yóò mú kí àwọn nǹkan dàgbà.—1 Korinti 3:6.
Ìfojúsọ́nà Dídányanran fún Ìbísí
Pẹ̀lú àwọn ilé-ewéko tí a ń mú móoru nípasẹ̀ agbára ooru-inú-ilẹ̀ àti ìmọ́lẹ̀ àtọwọ́dá, ó ti ṣeéṣe fún àwọn àgbẹ̀ Iceland láti gbin ọ̀pọ̀ onírúurú àwọn èso, ewébẹ̀, àti àwọn ewéko mìíràn. Bákan náà, àwọn Ẹlẹ́rìí, tí a ti mú gbáradì nípasẹ̀ òtítọ́ tẹ̀mí, ìlọ́wọ́ọ́wọ́ ti ìfipẹ̀lẹ́tùù yíniléròpadà, àti ìbùkún ẹ̀mí mímọ́ Jehofa, ti ń nírìírí àwọn àgbàyanu ìyọrísí nínú pápá Iceland.
Ní ọdún yìí 542 ènìyàn ni ó pésẹ̀ síbi Ìṣe-Ìrántí ikú Kristi, iye tí ó sì súnmọ́ igba ìkẹ́kọ̀ọ́ Bibeli inú ilé ni a ń darí nísinsìnyí. Ní àfikún, ìdáhùnpadà ọlọ́kànrere sí ìṣírí náà láti ṣiṣẹ́sìn ní àwọn ìpínlẹ̀ tí a kò pín fúnni fún wa ní ìgbọ́kànlé pé gbogbo àwọn ènìyàn bí-àgùtàn ní erékùṣù gbígbòòrò yìí yóò gbọ́ ohùn Olùṣọ́-Àgùtan Rere náà, Jesu Kristi. (Johannu 10:14-16) Irú àbájáde aláyọ̀ wo ni ó jẹ́ fún àwọn olùpòkìkí Ìjọba olùṣòtítọ́ wọ̀nyẹn tí wọ́n ti fi ọ̀pọ̀ sùúrù àti ìfaradà púpọ̀ tóbẹ́ẹ̀ hàn nínú wíwàásù ìhìnrere ní ilẹ̀ yìnyín àti iná ni ọdún mẹ́rìnlélọ́gọ́ta tí ó ti kọja!
[Àwòrán ilẹ̀ tó wà ní ojú ìwé 24]
(Láti rí bá a ṣe to ọ̀rọ̀ sójú ìwé, wo ìtẹ̀jáde náà gan-an)
Akureyri
Akranes
Keflavík
Selfoss
Vestmannaeyjar
Reyðarfjörður
Hekla
Geysir
VATNAJÖKULL
REYKJAVÍK
[Credit Line]
A gbé e karí àwòrán-ilẹ̀ láti ọwọ́ Jean-Pierre Biard