Àwọn Ọ̀nà Ìgbọ́rọ̀kalẹ̀ Tá A Lè Lò
Láti Bẹ̀rẹ̀ Ìkẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì Ní Sátidé Àkọ́kọ́ Lóṣù December
“Ọ̀pọ̀ èèyàn ló ń retí pé kí Jésù pa dà wá. Tó bá pa dà wá, kí lohun kan tó o máa fẹ́ kó ṣe?” Jẹ́ kó fèsì. Fi ẹ̀yìn Ilé Ìṣọ́ December 1 han onílé, kẹ́ ẹ sì jọ jíròrò àlàyé tó wà lábẹ́ ìbéèrè àkọ́kọ́ àti ó kéré tán, ọ̀kan lára àwọn ẹsẹ Ìwé Mímọ́ tó wà níbẹ̀. Fún un ní ìwé ìròyìn náà, kó o sì ṣètò láti pa dà lọ jíròrò ìdáhùn sí ìbéèrè tó kàn.
Ilé Ìṣọ́ December 1
“Ọwọ́ àwọn èèyàn máa ń dí gan-an lóde òní débi pé ó ti wá ṣòro gan-an fún wọn láti ronú nípa Ọlọ́run. Ǹjẹ́ o rò pé ó ṣe pàtàkì pé ká máa fi ti Ọlọ́run ṣáájú nínú gbogbo ohun tá a bá ń ṣe? [Jẹ́ kó fèsì.] Nínú Ìwàásù Lórí Òkè, èyí táwọn èèyàn mọ̀ dáadáa, Jésù sọ pé ká tó lè ní ojúlówó ayọ̀, a gbọ́dọ̀ máa ṣe àwọn nǹkan tí Ọlọ́run fẹ́. [Ka Mátíù 5:3.] Ìwé ìròyìn yìí sọ ìdí mẹ́ta tá a fi nílò Ọlọ́run.”
Ji! November–December
“Ìdààmú ti bá ọ̀pọ̀ èèyàn lónìí. Ṣé o rò pé Ọlọ́run bìkítà nípa àwọn tí ìdààmú ò jẹ́ kí wọ́n gbádùn? [Jẹ́ kó fèsì. Kó o wá ka Sáàmù 34:18.] Ìwé ìròyìn yìí ṣàlàyé bí àwọn tí ìdààmú bá ṣe lè rí ìrànlọ́wọ́ gbà látọ̀dọ̀ Ọlọ́run, kódà bí ó bá pọn dandan pé kí wọ́n tún gba ìtọ́jú ìṣègùn. Ó tún ṣàlàyé bí sísọ ìṣòro wọn fún ọ̀rẹ́ tímọ́tímọ́ kan ṣe lè jẹ́ kí wọ́n fara dà á.” Fi àpilẹ̀kọ tó wà lójú ìwé 10 sí 11 hàn án.