ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍNTÁNẸ́Ẹ̀TÌ ti Watchtower
ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍŃTÁNẸ́Ẹ̀TÌ
ti Watchtower
Yorùbá
ọ́
  • ẹ
  • ọ
  • ṣ
  • ń
  • ẹ́
  • ẹ̀
  • ọ́
  • ọ̀
  • BÍBÉLÌ
  • ÌTẸ̀JÁDE
  • ÌPÀDÉ
  • km 12/13 ojú ìwé 1
  • Ìtòlẹ́sẹẹsẹ fún Ọ̀sẹ̀ December 9

Kò sí fídíò kankan ní apá yìí.

Má bínú, fídíò yìí kò jáde.

  • Ìtòlẹ́sẹẹsẹ fún Ọ̀sẹ̀ December 9
  • Iṣẹ́ Òjíṣẹ́ Ìjọba Wa—2013
  • Ìsọ̀rí
  • Ọ̀SẸ̀ TÓ BẸ̀RẸ̀ NÍ DECEMBER 9
Iṣẹ́ Òjíṣẹ́ Ìjọba Wa—2013
km 12/13 ojú ìwé 1

Ìtòlẹ́sẹẹsẹ fún Ọ̀sẹ̀ December 9

Ọ̀SẸ̀ TÓ BẸ̀RẸ̀ NÍ DECEMBER 9

Orin 84 àti Àdúrà

□ Ìkẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì Ìjọ:

jl Ẹ̀kọ́ 17 sí 19 (30 min.)

□ Ilé Ẹ̀kọ́ Ìjọba Ọlọ́run:

Bíbélì kíkà: 1 Jòhánù 1–-5; 2 Jòhánù 1-13; 3 Jòhánù 1-14–Júúdà 1-25 (10 min.)

No. 1: 1 Jòhánù 5:1-21 (4 min. tàbí kó máà tó bẹ́ẹ̀)

No. 2: Báwo Ló Ṣe Yẹ Ká Máa Rántí Jésù Kristi?—Lúùkù 1:32, 33; Jòh. 17:3 (5 min.)

No. 3: Ǹjẹ́ Èèyàn Lè Báwọn Mọ̀lẹ́bí Rẹ̀ Tó Ti Kú Sọ̀rọ̀?—td 24D (5 min.)

□ Ìpàdé Iṣẹ́ Ìsìn:

Orin 5

15 min: Ilé Ẹ̀kọ́ Ìjọba Ọlọ́run ti Ọdún 2014. Alábòójútó ilé ẹ̀kọ́ ni kó sọ àsọyé yìí. Lo ìtòlẹ́sẹẹsẹ Ilé Ẹ̀kọ́ Ìjọba Ọlọ́run ti ọdún 2014 láti fi jíròrò àwọn ohun tó yẹ kí ìjọ yín fún láfiyèsí. Sọ fún àwọn ará pé tí orí àkọ́kọ́ ìwé Bíbélì kan bá wà lára Bíbélì kíkà, arákùnrin tó máa bójú tó àwọn kókó pàtàkì látinú Bíbélì kíkà ọ̀sẹ̀ yẹn kò ní mú ọ̀rọ̀ jáde mọ́ látinú ọ̀wọ́ àwọn àpilẹ̀kọ “Ọ̀rọ̀ Jèhófà Yè” tí ó bẹ̀rẹ̀ sí í jáde nínú Ilé Ìṣọ́ láti January 1, 2004. Fún àwọn ará níṣìírí láti máa fọwọ́ pàtàkì mú iṣẹ́ tá a bá yàn fún wọn, kí wọ́n máa lóhùn sí ìpàdé nígbà Bíbélì kíkà ọ̀sọ̀ọ̀sẹ̀, kí wọ́n sì máa fi àwọn àbá tí wọ́n bá rí gbà lọ́sọ̀ọ̀sẹ̀ látinú ìwé Jàǹfààní Nínú Ilé Ẹ̀kọ́ Ìjọba Ọlọ́run sílò.

15 min: “A Máa Pín Ìròyìn Ìjọba No. 38 Lóṣù January!” Ìbéèrè àti ìdáhùn. Fún gbogbo àwọn tó wá sípàdé ní ẹ̀dà kọ̀ọ̀kan Ìròyìn Ìjọba No. 38. Ní kí alábòójútó iṣẹ́ ìsìn sọ ètò tí ìjọ ṣe láti kárí ìpínlẹ̀ ìwàásù yín. Ẹ lo ọ̀nà ìgbọ́rọ̀kalẹ̀ ṣókí tó wà lójú ìwé 8 láti ṣe àṣefihàn bí a ṣe máa fún àwọn èèyàn ní Ìròyìn Ìjọba náà.

Orin 60 àti Àdúrà

    Yorùbá Publications (1987-2025)
    Jáde
    Wọlé
    • Yorùbá
    • Fi Ráńṣẹ́
    • Èyí tí mo fẹ́ràn jù
    • Copyright © 2025 Watch Tower Bible and Tract Society of Pennsylvania
    • Àdéhùn Nípa Lílò
    • Òfin
    • Ètò Nípa Ìsọfúnni Rẹ
    • JW.ORG
    • Wọlé
    Fi Ráńṣẹ́