A Máa Pín Ìròyìn Ìjọba No. 38 Lóṣù January!
1. Àwọn ìbéèrè wo ló máa ń ṣe àwọn èèyàn ní kàyéfì nípa àwọn tó ti kú, báwo la sì ṣe máa dáhùn àwọn ìbéèrè náà lóṣù January?
1 Láìka ohun tí kálukú gbà gbọ́, ikú jẹ́ ọ̀tá gbogbo èèyàn. (1 Kọ́r. 15:26) Ọ̀pọ̀ máa ń ṣe kàyéfì nípa àwọn ìbéèrè bí, ibo ni àwọn òkú wà? Ǹjẹ́ a ṣì lè pa dà rí àwọn tó ti kú? Nítorí náà, oṣù kan gbáko ni gbogbo ìjọ kárí ayé fi máa kópa nínú pípín Ìròyìn Ìjọba No. 38 káàkiri. Àkòrí ìwé náà ni, Ǹjẹ́ Àwọn Tó Ti Kú Lè Jíǹde? Ọjọ́ kìíní oṣù January ni àkànṣe ìpínkiri yìí máa bẹ̀rẹ̀. Lẹ́yìn tá a bá ti pín in tán, a máa bẹ̀rẹ̀ sí í lo Ìròyìn Ìjọba No. 38 yìí lóde ẹ̀rí bí a ṣe máa ń lo àwọn ìwé àṣàrò kúkúrú wa yòókù.
2. Kí ló wà nínú Ìròyìn Ìjọba No. 38?
2 Ohun Tó Wà Nínú Ìwé Náà: A ṣe Ìròyìn Ìjọba No. 38 kó lè ṣeé ká sí méjì lọ́nà tí àkòrí rẹ̀ tó fani mọ́ra yóò fi hàn dáadáa, kí wọ́n sì lè rí ìbéèrè yìí: Kí ni ìdáhùn rẹ? . . . Bẹ́ẹ̀ ni. Bẹ́ẹ̀ kọ́. Kò dá mi lójú.” Lẹ́yìn tí ẹni tá a fún ní Ìròyìn Ìjọba náà bá ṣí i, ó máa rí ìdáhùn Bíbélì sí ìbéèrè tá a fi ṣe àkòrí rẹ̀ àti àǹfààní tí àwọn ìlérí tó wà nínú Bíbélì lè ṣe fún un. Ó tún máa rí ìdí tó fi yẹ kó gba ohun tí Bíbélì sọ gbọ́. Ìbéèrè kan wà lẹ́yìn ìwé náà tó máa mú onítọ̀hún ronú jinlẹ̀, kó sì kẹ́kọ̀ọ́ púpọ̀ sí i.
3. Báwo la ṣe máa pín Ìròyìn Ìjọba No. 38?
3 Bá A Ṣe Máa Pín In Fáwọn Èèyàn: Bí a ṣe máa ń pín ìwé ìkésíni sí Ìrántí Ikú Kristi àti ti àpéjọ àgbègbè náà la ṣe máa pín Ìròyìn Ìjọba yìí. Àwọn alàgbà máa fún ìjọ ní ìtọ́ni nípa bí wọ́n ṣe máa kárí ìpínlẹ̀ ìwàásù, bí a ṣe ṣàlàyé fún wọn nínú lẹ́tà April 1, 2013 tá a kọ sí ìgbìmọ̀ àwọn alàgbà. Àwọn ìjọ tí ìpínlẹ̀ ìwàásù wọn kò tóbi lè ṣèrànwọ́ fún àwọn ìjọ tó sún mọ́ wọn tí ìpínlẹ̀ tiwọn tóbi. Má ṣe gbàgbé pé iye ẹ̀dà Ìròyìn Ìjọba No. 38 tó o bá nílò fún ọ̀sẹ̀ kan ló yẹ kó o gbà. Tẹ́ ẹ bá ti kárí ìpínlẹ̀ ìwàásù yín lẹ́nu iṣẹ́ ilé-dé-ilé, ẹ lè máa fún àwọn èèyàn níbikíbi tẹ́ ẹ bá ti rí wọn. Tí ẹ bá pín gbogbo ẹ̀dà tí ẹ ní lọ́wọ́ tán kí oṣù tó parí, ẹ bẹ̀rẹ̀ sí í fún àwọn èèyàn ní ìtẹ̀jáde tàbí ìwé tá a máa lò lóṣù yẹn. Bí a ṣe máa pín Ìròyìn Ìjọba yìí kiri la máa gbájú mọ́ ní Sátidé àkọ́kọ́, kì í ṣe bá a ṣe máa bẹ̀rẹ̀ ìkẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì. Lópin ọ̀sẹ̀, a lè fún àwọn èèyàn ní ìwé ìròyìn níbi tá a bá ti rí i pé ó yẹ bẹ́ẹ̀. Ṣé o ti bẹ̀rẹ̀ sí í múra sílẹ̀ kó o lè ráyè kópa dáadáa nínú àkànṣe pípín Ìròyìn Ìjọba náà kiri?