A Máa Bẹ̀rẹ̀ Sí Í Pín Ìwé Ìkésíni Síbi Ìrántí Ikú Kristi Ní March 1
1. Ìgbà wo la máa bẹ̀rẹ̀ sí í pín ìwé ìkésíni síbi Ìrántí Ikú Kristi? Kí nìdí tí ọjọ́ tá a máa fi pín in fi pọ̀ ju ti tẹ́lẹ̀ lọ?
1 Ní ọjọ́ Friday, March 1, a máa bẹ̀rẹ̀ sí í pín ìwé ìkésíni síbi Ìrántí Ikú Kristi tá a máa ń ṣe lọ́dọọdún. Ọjọ́ Tuesday, March 26, la máa ṣe Ìrántí Ikú Kristi lọ́dún yìí. Èyí túmọ̀ sí pé iye ọjọ́ tá a máa fi pín ìwé ìkésíni náà lọ́dún yìí máa pọ̀ ju ti tẹ́lẹ̀ lọ. Ká lè fún àwọn èèyàn púpọ̀ sí i láǹfààní láti gba ìwé ìkésíni, pàápàá àwọn tó ń gbé láwọn ibi tí ìjọ ti ní ìpínlẹ̀ ìwàásù tó pọ̀.
2. Àwọn ètò wo ló wà fún gbígba ìwé ìkésíni àti bá a ṣe máa pín in kárí àwọn ìpínlẹ̀ wa?
2 Bá A Ṣe Máa Pín In: Àwọn alàgbà máa fún yín ní ìtọ́ni nípa bẹ́ ẹ ṣe máa kárí ìpínlẹ̀ ìwàásù yín. Wọ́n á sì sọ fún yín bóyá ẹ lè fi ìwé ìkésíni sí ẹnu ọ̀nà àwọn tí kò bá sí nílé. Tí ìwé ìkésíni bá ṣẹ́ kù sí yín lọ́wọ́ lẹ́yìn tẹ́ ẹ parí iṣẹ́ ìwáàsù ilé-dé-ilé ní ìpínlẹ̀ ìwàásù yín, ẹ lè máa pín in fún àwọn tẹ́ ẹ bá tún bá pàdé. Alábòójútó iṣẹ́ ìsìn máa rí i dájú pé ìwé ìkésíni tẹ́ ẹ ti kọ àdírẹ́sì ibi tẹ́ ẹ máa lò àti aago tẹ́ ẹ máa ṣe é sí wà lórí káńtà tí ẹ̀ ń kó àwọn ìwé ìkẹ́kọ̀ọ́ tàbí ìwé ìròyìn sí kí àwọn ará lè mú iye tí wọ́n bá fẹ́. Àmọ́ kì í ṣe gbogbo ìwé ìkésíni tí ìjọ bá ní lọ́wọ́ lẹ máa kó jáde lẹ́ẹ̀kan náà. Tá a bá fẹ́ gba ìwé ìkésíni, ká má ṣe mú ju iye tá a máa lò ní ọ̀sẹ̀ yẹn lọ.
3. Kí ló yẹ ká fi sọ́kàn tá a bá ń pín ìwé ìkésíni?
3 Ohun Tá A Máa Sọ: Ó yẹ ká jẹ́ kí ọ̀rọ̀ wa ṣe ṣókí. Ìyẹn á jẹ́ ká lè fún àwọn èèyàn tó pọ̀ dáadáa ní ìwé ìkésíni náà. Àpẹẹrẹ ohun tẹ́ ẹ lè sọ wà lójú ìwé 4 nínú Iṣẹ́ Òjíṣẹ́ Ìjọba Wa yìí. Ẹ lè tún un ṣe lọ́nà tó máa bá ìpínlẹ̀ ìwàásù yín mu. Àmọ́ kò yẹ ká wá kánjú kúrò lọ́dọ̀ àwọn onílé tó bá nífẹ̀ẹ́ sí ọ̀rọ̀ wa tàbí tí wọ́n bi wá ní ìbéèrè. Tá a bá ń pín ìwé ìkésíni láwọn òpin ọ̀sẹ̀, ó yẹ ká tún máa pín àwọn ìwé ìròyìn wa nígbà tá a bá rí i pé ó yẹ. Tó bá di ọjọ́ Sátidé, March 2, ìwé ìkésíni la máa pín dípò ká fi ọjọ́ yẹn bẹ̀rẹ̀ ìkẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì.
4. Kí nìdí tó fi yẹ ká fi ìtara pín ìwé ìkésíni yìí?
4 A nírètí pé ọ̀pọ̀ èèyàn ló máa dara pọ̀ mọ́ wa láti ṣe Ìrántí Ikú Kristi. A máa gbọ́ àsọyé tó ṣàlàyé ẹni tí Jésù jẹ́ gan-an. (1 Kọ́r. 11:26) Àsọyé náà máa jẹ́ ká mọ àǹfààní tí ikú Jésù ṣe fún wa. (Róòmù 6:23) Ó sì tún máa jẹ́ ká mọ ìdí tó fi ṣe pàtàkì pé ká máa rántí Jésù. (Jòh. 17:3) Torí náà, ẹ jẹ́ ká fi ìtara pín ìwé ìkésíni náà!