Ìtòlẹ́sẹẹsẹ fún Ọ̀sẹ̀ February 18
Ọ̀SẸ̀ TÓ BẸ̀RẸ̀ NÍ FEBRUARY 18
Orin 52 àti Àdúrà
□ Ìkẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì Ìjọ:
jr orí 5 ìpínrọ̀ 13 sí 18 (30 min.)
□ Ilé Ẹ̀kọ́ Ìjọba Ọlọ́run:
Bíbélì kíkà: Máàkù 1-4 (10 min.)
No. 1: Máàkù 2:18–3:6 (4 min. tàbí kó máà tó bẹ́ẹ̀)
No. 2: Ìdí Tí Gbogbo Èèyàn Fi Ń Jìyà Ẹ̀ṣẹ̀ Ádámù—td 15B (5 min.)
No. 3: Kí Ni Ìtúmọ̀ Ọ̀rọ̀ Tí Pọ́ọ̀lù Sọ Nínú 1 Kọ́ríńtì 7:29-31? (5 min.)
□ Ìpàdé Iṣẹ́ Ìsìn:
15 min: Máa Wàásù Ọ̀rọ̀ Náà Ní Àsìkò Tí Ó Kún Fún Ìdààmú. (2 Tím. 4:2) Ìjíròrò tá a gbé ka Ilé Ìṣọ́ September 15, 2008, ojú ìwé 7, ìpínrọ̀ 3 sí 6 àti Ilé Ìṣọ́ May 1, 2001, ojú ìwé 16, ìpínrọ̀ 10 àti 11. Ní kí àwọn ará sọ ẹ̀kọ́ tí wọ́n rí kọ́.
15 min: “A Máa Bẹ̀rẹ̀ Sí Í Pín Ìwé Ìkésíni Síbi Ìrántí Ikú Kristi Ní March 1.” Ìbéèrè àti ìdáhùn. Fún àwọn ará ní ẹ̀dà kọ̀ọ̀kan ìwé ìkésíni náà, kó o sì jíròrò ohun tó wà nínú rẹ̀. Tẹ́ ẹ bá ń jíròrò ìpínrọ̀ 2, ní kí alábòójútó iṣẹ́ ìsìn sọ ètò tí ìjọ ti ṣe láti kárí ìpínlẹ̀ ìwàásù yín. Tẹ́ ẹ bá ń jíròrò ìpínrọ̀ 3, ẹ lo ọ̀nà ìgbọ́rọ̀kalẹ̀ tó wà lójú ìwé 4 láti ṣe àṣefihàn bá a ṣe lè fún àwọn èèyàn ní ìwé ìkésíni náà.
Orin 8 àti Àdúrà