A Máa Bẹ̀rẹ̀ Sí Í Pín Ìwé Ìkésíni Síbi Ìrántí Ikú Kristi Ní March 22
Lọ́dún yìí, ọjọ́ Sátidé March 22, la máa bẹ̀rẹ̀ sí í pín ìwé ìkésíni sí Ìrántí Ikú Kristi. A gba gbogbo wa níyànjú pé ká kópa kíkún níbẹ̀. Tó bá di òpin ọ̀sẹ̀, a tún máa fún àwọn èèyàn ní ìwé ìròyìn tá à ń lò lóṣù yẹn níbi tá a bá ti rí i pé ó yẹ bẹ́ẹ̀. Ní Sátidé àkọ́kọ́ lóṣù April, ìwé ìkésíni síbi Ìrántí Ikú Kristi la máa pín, a ò ní bẹ̀rẹ̀ ìkẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì nígbà àkọ́kọ́. Àmọ́, tá a bá pàdé ẹnì kan tó nífẹ̀ẹ́ sí ìwàásù wa gan-an, a lè gbìyànjú láti bẹ̀rẹ̀ ìkẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì pẹ̀lú rẹ̀. Alábòójútó iṣẹ́ ìsìn máa pinnu ọ̀nà tó dáa jù láti pín ìwé ìkésíni náà kẹ́ ẹ lè dé ọ̀dọ̀ ọ̀pọ̀ èèyàn ní ìpínlẹ̀ ìwàásù yín. Kí àwọn mọ̀lẹ́bí rẹ, àwọn tẹ́ ẹ jọ ń ṣiṣẹ́, àwọn ọmọléèwé rẹ, àwọn ìpadàbẹ̀wò rẹ àtàwọn míì tó o mọ̀ lè wà níbẹ̀, ìsinsìnyí ni kó o bẹ̀rẹ̀ sí í kọ orúkọ àwọn tó o fẹ́ pè wá kó o lè fún wọn ní ìwé ìkésíni tí àkókò bá tó. Àdúrà wa ni pé kí ọ̀pọ̀ dara pọ̀ mọ́ wa nígbà tá a bá ń ṣe Ìrántí Ikú Kristi tó máa jẹ́ ká mọyì àwọn méjì tó nífẹ̀ẹ́ wa jù lọ.—Jòh. 3:16; 15:13.