Ìtòlẹ́sẹẹsẹ fún Ọ̀sẹ̀ March 3
Ọ̀SẸ̀ TÓ BẸ̀RẸ̀ NÍ MARCH 3
Orin 112 àti Àdúrà
Ìkẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì Ìjọ:
cl orí 3 ìpínrọ̀ 19 sí 21, àpótí tó wà lójú ìwé 34 (30 min.)
Ilé Ẹ̀kọ́ Ìjọba Ọlọ́run:
Bíbélì kíkà: Jẹ́nẹ́sísì 36-39 (10 min.)
No. 1: Jẹ́nẹ́sísì 37:1-17 (4 min. tàbí kó máà tó bẹ́ẹ̀)
No. 2: Ṣé Fífi Èdè Fọ̀ Jẹ́ Ẹ̀rí Pé Ọlọ́run Tẹ́wọ́gba Ẹnì Kan?—td 32E (5 min.)
No. 3: Àwọn Kan Wà Nípò Tó Ga Ju Tiwa Lọ—lr orí 8 (5 min.)
Ìpàdé Iṣẹ́ Ìsìn:
10 min: Fi Àwọn Ìwé Ìròyìn Lọni Lóṣù March. Ìjíròrò. Kọ́kọ́ fi àwọn ọ̀nà ìgbọ́rọ̀kalẹ̀ tó wà lójú ìwé yìí ṣe àṣefihàn bí a ṣe lè fi àwọn ìwé ìròyìn náà lọni. Lẹ́yìn náà, ẹ jíròrò àwọn ọ̀nà ìgbọ́rọ̀kalẹ̀ náà láti ìbẹ̀rẹ̀ dópin. Ní ìparí ọ̀rọ̀ rẹ, ní kí àwọn ará sọ àwọn ọ̀nà tí wọ́n lè gbà fi àwọn ìwé ìròyìn náà lọni pa pọ̀ pẹ̀lú ìwé ìkésíni sí Ìrántí Ikú Kristi ní àwọn òpin ọ̀sẹ̀ méjì tó kẹ́yìn oṣù yìí.
10 min: Ohun tó ń fẹ́ àbójútó nínú ìjọ.
10 min: Báwo La Ṣe Ṣe Sí? Ìjíròrò. Ní kí àwọn ará sọ bí wọ́n ṣe jàǹfààní nígbà tí wọ́n lo àwọn àbá tó wà nínú àpilẹ̀kọ náà, “Mú Kí Iṣẹ́ Òjíṣẹ́ Rẹ Sunwọ̀n Sí I—Máa Ṣàkọsílẹ̀ Àwọn Tó Fìfẹ́ Hàn.” Ní kí wọ́n sọ àwọn ìrírí tó gbádùn mọ́ni tí wọ́n ní.
Orin 95 àti Àdúrà