ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍNTÁNẸ́Ẹ̀TÌ ti Watchtower
ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍŃTÁNẸ́Ẹ̀TÌ
ti Watchtower
Yorùbá
ọ́
  • ẹ
  • ọ
  • ṣ
  • ń
  • ẹ́
  • ẹ̀
  • ọ́
  • ọ̀
  • BÍBÉLÌ
  • ÌTẸ̀JÁDE
  • ÌPÀDÉ
  • km 2/14 ojú ìwé 4
  • Àwọn Ìfilọ̀

Kò sí fídíò kankan ní apá yìí.

Má bínú, fídíò yìí kò jáde.

  • Àwọn Ìfilọ̀
  • Iṣẹ́ Òjíṣẹ́ Ìjọba Wa—2014
Iṣẹ́ Òjíṣẹ́ Ìjọba Wa—2014
km 2/14 ojú ìwé 4

Àwọn Ìfilọ̀

  • Ìwé tá a máa lò ní February: Ìròyìn Ayọ̀ Látọ̀dọ̀ Ọlọ́run!, Tẹ́tí sí Ọlọ́run Kó O Lè Wà Láàyè Títí Láé, Tẹ́tí sí Ọlọ́run, Ọ̀nà Tó Lọ sí Ìyè Àìnípẹ̀kun—Ṣé O Ti Rí I? tàbí ìwé olójú ewé 32 èyíkéyìí tó bá wà lọ́wọ́. Ẹ lè fún àwọn Mùsùlùmí ní: Ìgbàgbọ́ Òdodo Ló Máa Mú Kó O Ní Ayọ̀ àti Ìtọ́sọ́nà Ọlọ́run Ló Máa Ṣamọ̀nà Ẹ̀dá Wọ Párádísè tàbí ọ̀kan nínú méjèèjì. March àti April: Ìwé ìròyìn Ilé Ìṣọ́ àti Jí! May: Kí Ni Bíbélì Fi Kọ́ni Gan-an? tàbí ìwé àṣàrò kúkúrú èyíkéyìí tí ìjọ bá ní lọ́wọ́, irú bíi, Ṣé Wàá Fẹ́ Mọ Òtítọ́? àti àwọn ìwé àṣàrò kúkúrú márùn-ún tó ṣẹ̀ṣẹ̀ jáde: Irú Ìwé Wo Ni Bíbélì Jẹ́?, Kí Ló Máa Ṣẹlẹ̀ Lọ́jọ́ Ọ̀la?, Kí Ló Lè Mú Kí Ìdílé Láyọ̀?, Ta Ló Ń Darí Ayé Yìí?, Ǹjẹ́ Ìyà Lè Dópin?

  • Ẹṣin ọ̀rọ̀ àkànṣe àsọyé fún gbogbo ènìyàn ní àkókò Ìrántí Ikú Kristi lọ́dún 2014 ni “Kí Nìdí Tí Ọlọ́run Onífẹ̀ẹ́ Fi Fàyè Gba Ibi?”

  • Ẹ má ṣe tẹ ìtòlẹ́sẹẹsẹ tàbí ṣe àkọlé èyíkéyìí fún Ìràntí Ikú Kristi. Ìwé ìkésíni sí Ìrántí Ikú Kristi tí èto Ọlọ́run ṣe nìkan lẹ gbọ́dọ̀ lò. Ìgbìmọ̀ àwọn alàgbà ni kó yan ẹni tó máa sọ àsọyé Ìrántí Ikú Kristi, ìtọ́ni tó wà nínú ìwé àsọyé fún Ìrántí Ikú Kristi ni kí wọ́n tẹ̀ lé tí wọ́n bá ń yan àwọn tó máa gbàdúrà. Ẹ má ṣe sọ àwọn ìrírí tẹ́ ẹ ní lóde ẹ̀rí, ẹ má sì ṣètò láti kọ àwọn orin kan lákànṣe lákòókò náà.

  • Tẹ́ ẹ bá ń lo tábìlì àtàwọn ohun tó ṣeé gbé kiri láti wàásù láwọn ibi tí èrò pọ̀ sí, ẹ má ṣe kó Bíbélì síta. Àmọ́, ẹ lè ní Bíbélì láròówọ́tó kí ẹ lè fún àwọn tó bá béèrè fún un tàbí àwọn tó ṣe kedere pé wọ́n fẹ́ mọ ohun tí Bíbélì fi kọ́ni.

    Yorùbá Publications (1987-2025)
    Jáde
    Wọlé
    • Yorùbá
    • Fi Ráńṣẹ́
    • Èyí tí mo fẹ́ràn jù
    • Copyright © 2025 Watch Tower Bible and Tract Society of Pennsylvania
    • Àdéhùn Nípa Lílò
    • Òfin
    • Ètò Nípa Ìsọfúnni Rẹ
    • JW.ORG
    • Wọlé
    Fi Ráńṣẹ́