A Máa Pín Ìwé Ìkésíni Síbi Ìrántí Ikú Kristi Bẹ̀rẹ̀ Láti April 2
1. Ìgbà wo la máa pín ìwé ìkésíni síbi Ìrántí Ikú Kristi lọ́dún yìí, àǹfààní wo ló sì wà nínú ìpolongo ọdọọdún yìí?
1 Láti April 2 sí April 17, a máa pín ìwé ìkésíni síbi ìṣẹ̀lẹ̀ tó ṣe pàtàkì jù lọ nínú ọdún, ìyẹn Ìrántí Ikú Kristi. Látẹ̀yìnwá, ọ̀pọ̀ àwọn tó gba ìwé ìkésíni náà ló wá síbi Ìrántí Ikú Kristi. Bí àpẹẹrẹ, lọ́jọ́ Ìrántí Ikú Kristi kan, obìnrin kan pe ẹ̀ka ọ́fíìsì, ó sọ pé: “Mo ṣẹ̀ṣẹ̀ wọlé ni, mo sì bá ìwé ìkésíni kàn lábẹ́ ilẹ̀kùn mi. Ó wù mí láti lọ, àmọ́ mi ò mọ aago tó má bẹ̀rẹ̀.” Arákùnrin tó dáhùn ìpè rẹ̀ sọ ibi tó ti lè rí àkókò tí wọ́n máa bẹ̀rẹ̀ nínú ìwé ìkésíni náà. Obìnrin náà wá ṣèlérí pé: “Màá rí i pé mo débẹ̀ lálẹ́ yìí!”
2. Kí la lè sọ nígbà tá a bá fẹ́ fún àwọn èèyàn ní ìwé ìkésíni náà?
2 Bá A Ṣe Máa Ṣé E: Níwọ̀n bó ti jẹ́ pé àkókò díẹ̀ la ní láti kárí ìpínlẹ̀ ìwàásù wa, á dáa ká jẹ́ kí ọ̀rọ̀ wa ṣe ṣókí. Lẹ́yìn tá a bá ti kí onílé, a lè sọ pé: “A fẹ́ fún ìdílé yín ní ìwé ìkésíni síbi ohun kan tá a máa ń ṣe lọ́dọọdún, èyí tó máa wáyé jákèjádò ayé lọ́jọ́ Sunday April 17. [Mú ìwé ìkésíni náà fún onílé.] Ọjọ́ Ìrántí Ikú Kristi lọjọ́ yìí. Wọ́n máa sọ àsọyé Bíbélì kan tó dá lórí bá a ṣe lè jàǹfààní látinú ìràpadà Kristi, ọ̀fẹ́ ni o. Ọjọ́ tá a máa ṣe é àti àkókò tó máa bẹ̀rẹ̀ ní àdúgbò wa níbí wà nínú ìwé ìkésíni yìí.”
3. Báwo la ṣe lè pe gbogbo èèyàn bó bá ṣe lè ṣeé ṣe fún wa tó?
3 Bí ìpínlẹ̀ ìwàásù ìjọ yín bá tóbi, àwọn alàgbà lè ní kẹ́ ẹ fi ìwé ìkésíni náà sílẹ̀ fún àwọn tí kò sí nílé, tẹ́ ẹ bá máa lè fi sí ibi tí àwọn tó ń kọjá lọ kò ti ní rí i. Má gbàgbé láti pe àwọn ìpadàbẹ̀wò rẹ, mọ̀lẹ́bí rẹ, àwọn tẹ́ ẹ jọ ń ṣiṣẹ́, ọmọléèwé àtàwọn míì tó o bá mọ̀. Tẹ́ ẹ bá ń pín ìwé ìkésíni náà lópin ọ̀sẹ̀, ẹ fún àwọn èèyàn ní ìwé ìròyìn nígbà tó bá yẹ bẹ́ẹ̀. Ǹjẹ́ o lè ṣe aṣáájú-ọ̀nà olùrànlọ́wọ́ lóṣù April, kó o sì kó ipa tó pọ̀ nínú ìpolongo tó ń gbádùn mọ́ni yìí?
4. Kí nìdí tá a fi fẹ́ kí àwọn olùfìfẹ́hàn wá síbi Ìrántí Ikú Kristi?
4 Ìjẹ́rìí tó lágbára ni àwọn olùfìfẹ́hàn tó bá wá síbẹ̀ máa rí gbà. Wọ́n máa gbọ́ nípa ìfẹ́ àrà-ọ̀tọ̀ tí Jèhófà lò láti pèsè ìràpadà fún wa. (Jòh. 3:16) Wọ́n máa kẹ́kọ̀ọ́ nípa bí Ìjọba Ọlọ́run ṣe máa ṣe aráyé láǹfààní. (Aísá. 65:21-23) A tún máa sọ fún wọn pé kí wọ́n bá àwọn olùtọ́jú èrò sọ̀rọ̀ bí wọ́n bá fẹ́ ká wá máa kọ́ wọn lẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì, kí wọ́n lè kẹ́kọ̀ọ́ sí i. Àdúrà wa ni pé kí ọ̀pọ̀ èèyàn tí wọ́n jẹ́ olóòótọ́ ọkàn dáhùn pa dà sí ìkésíni yìí, kí wọ́n sì dara pọ̀ mọ́ wa láti ṣe Ìrántí Ikú Kristi!