Ìtòlẹ́sẹẹsẹ fún Ọ̀sẹ̀ March 21
Ọ̀SẸ̀ TÓ BẸ̀RẸ̀ NÍ MARCH 21
Orin 47 àti Àdúrà
□ Ìkẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì Ìjọ:
bt orí 1 ìpínrọ̀ 10 sí 15, àti àtẹ tó wà lójú ìwé 12 (25 min.)
□ Ilé Ẹ̀kọ́ Ìjọba Ọlọ́run:
Bíbélì kíkà: Jóòbù 6-10 (10 min.)
No. 1: Jóòbù 8:1-22 (4 min. tàbí kó máà tó bẹ́ẹ̀)
No. 2: Ìdí Tí Ọlọ́run Kò Fi Fàyè Gba Jíjọ́sìn Àwọn Baba Ńlá—td 22A (5 min.)
No. 3: Báwo La Ṣe Lè Fi Ìtọ́ni Tó Wà Nínú Mátíù 10:16 Sílò? (5 min.)
□ Ìpàdé Iṣẹ́ Ìsìn:
5 min: Àwọn ìfilọ̀.
15 min: Máa Lo Bíbélì Nígbà Tó O Bá Ń Dáhùn Ìbéèrè. Ìjíròrò tó dá lórí ìwé Ilé Ẹ̀kọ́ Ìjọba Ọlọ́run, ojú ìwé 143 sí 144. Ṣe àṣefihàn méjì níbi tí ẹnì kan ti ń béèrè ìbéèrè tó lè jẹ yọ ní ìpínlẹ̀ ìwàásù ìjọ yín lọ́wọ́ akéde kan. Nínú àṣefihàn àkọ́kọ́, ó fún onílé ní ìdáhùn tó tọ́, àmọ́ kò tọ́ka sí ẹsẹ Bíbélì kankan. Nínú àṣefihàn kejì, ó fi Bíbélì dáhùn ìbéèrè náà. Ní kí àwùjọ sọ ìdí tí ọ̀nà kejì yẹn fi dára ju ti àkọ́kọ́ lọ.
15 min: “A Máa Pín Ìwé Ìkésíni Síbi Ìrántí Ikú Kristi Bẹ̀rẹ̀ Láti April 2.” Ìbéèrè àti ìdáhùn. Fún àwùjọ ní ìwé ìkésíni kọ̀ọ̀kan, kó o sì ṣàgbéyẹ̀wò àwọn ohun tó wà nínú rẹ̀. Sọ ètò tí ìjọ ṣe nípa bẹ́ ẹ ṣe máa kárí ìpínlẹ̀ ìwàásù ìjọ yín. Ṣàṣefihàn ọ̀nà ìgbọ́rọ̀kalẹ̀ kan.
Orin 109 àti Àdúrà