Ìtòlẹ́sẹẹsẹ fún Ọ̀sẹ̀ March 28
Ọ̀SẸ̀ TÓ BẸ̀RẸ̀ NÍ MARCH 28
Orin 45 àti Àdúrà
□ Ìkẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì Ìjọ:
bt orí 1 ìpínrọ̀ 16 sí 21 (25 min.)
□ Ilé Ẹ̀kọ́ Ìjọba Ọlọ́run:
Bíbélì kíkà: Jóòbù 11-15 (10 min.)
No. 1: Jóòbù 13:1-28 (4 min. tàbí kó máà tó bẹ́ẹ̀)
No. 2: Ìdí Tí Jésù fi Jẹ́ “Olúwa Sábáàtì”—Mát. 12:8 (5 min.)
No. 3: A Lè Bọlá fún Ẹ̀dá Èèyàn, Àmọ́ Ọlọ́run Nìkan Ni A Gbọ́dọ̀ Jọ́sìn—td 22B (5 min.)
□ Ìpàdé Iṣẹ́ Ìsìn:
5 min: Àwọn ìfilọ̀. Sọ ìwé tá a máa lò lóde ẹ̀rí lóṣù April, kó o sì ṣe àṣefihàn kan nípa béèyàn ṣe lè bẹ̀rẹ̀ ìkẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì nígbà tó bá pa dà lọ bẹ ẹnì kan tó gba ìwé ìròyìn wò.
10 min: Máa Ṣètìlẹ́yìn fún Iṣẹ́ Ìwàásù Ní Ìjọ àti Káàkiri Àgbáyé. Àsọyé tó dá lórí ìwé A Ṣètò Wa, ojú ìwé 127 sí 129, ìpínrọ̀ 2.
10 min: Múra Sílẹ̀ Láti Lo Àwọn Ìwé Ìròyìn Lóṣù April. Ìjíròrò. Fi ìṣẹ́jú kan tàbí méjì sọ̀rọ̀ lórí ohun tó wà nínú àwọn ìwé ìròyìn náà. Lẹ́yìn náà, yan àpilẹ̀kọ méjì tàbí mẹ́ta, kó o sì ní kí àwùjọ sọ àwọn ìbéèrè àti ẹsẹ Ìwé Mímọ́ tí wọ́n lè fi gbé ọ̀rọ̀ wọn kalẹ̀. Ṣe àṣefihàn bá a ṣe lè lo ìtẹ̀jáde kọ̀ọ̀kan.
10 min: “Ǹjẹ́ O Ti Ṣe Aṣáájú-Ọ̀nà Rí?” Ìbéèrè àti ìdáhùn. O lè fọ̀rọ̀ wá ọ̀rọ̀ wò lẹ́nu ẹnì kan tó ti fi iṣẹ́ aṣáájú-ọ̀nà sílẹ̀ nígbà kan rí, tó sì tún gbà á nígbà tí ipò rẹ̀ yí pa dà, bí irú ẹni bẹ́ẹ̀ bá wà lárọ̀ọ́wọ́tó. Kí ló jẹ́ kó lè gba iṣẹ́ aṣáájú-ọ̀nà pa dà? Àwọn ìbùkún wo ló ti rí?
Orin 6 àti Àdúrà