Ǹjẹ́ O Ti Ṣe Aṣáájú-Ọ̀nà Rí?
1. Àǹfààní wo ni ọ̀pọ̀ ti gbádùn, àmọ́ kí ló ti wá pọn dandan pé kí àwọn kan ṣe?
1 Láti ọ̀pọ̀ ọdún sẹ́yìn ni ẹgbẹẹgbẹ̀rún àwọn ará ti láǹfààní “kíkọ́ni àti pípolongo ìhìn rere” gẹ́gẹ́ bí òjíṣẹ́ alákòókò kíkún. (Ìṣe 5:42) Àmọ́, àwọn kan ní láti fi iṣẹ́ aṣáájú-ọ̀nà sílẹ̀ nítorí onírúurú ìdí. Tó o bá ti ṣe aṣáájú-ọ̀nà rí, ǹjẹ́ o ti ṣàyẹ̀wò ipò tó o wà báyìí láti mọ̀ bóyá o tún lè pa dà sẹ́nu iṣẹ́ aṣáájú-ọ̀nà?
2. Kí nìdí tó fi yẹ kí àwọn tó ti ṣe aṣáájú-ọ̀nà nígbà kan rí gbé ipò tí wọ́n wà báyìí yẹ̀ wò?
2 Ipò Téèyàn Wà Máa Ń Yí Pa Dà: Ó lè jẹ́ pé ìṣòro kan tó mú kó o fi iṣẹ́ aṣáájú-ọ̀nà sílẹ̀ ti yanjú báyìí. Bí àpẹẹrẹ, tó bá jẹ́ torí pé o kò lè ṣe àádọ́rùn-ún wákàtí lóṣù lo ṣe fi iṣẹ́ aṣáájú-ọ̀nà sílẹ̀, ṣé o lè bẹ̀rẹ̀ nísìnyí tá a ti dín in kù sí àádọ́rin wákàtí? Tó bá jẹ́ pé iṣẹ́ tàbí bùkátà ìdílé ló mú kó o fi iṣẹ́ aṣáájú-ọ̀nà sílẹ̀ nígbà kan, ṣé iṣẹ́ rẹ ti wá rọrùn díẹ̀ sí i, àbí bùkátà ìdílé ti wá fúyẹ́ báyìí? Arábìnrin kan tó fi iṣẹ́ aṣáájú-ọ̀nà sílẹ̀ nítorí àìlera tún pa dà sẹ́nu iṣẹ́ náà lẹ́ni ọdún mọ́kàndínláàádọ́rùn-ún [89]. Nígbà tó rí i pé òun kò lọ sílé ìwòsàn fún ohun tó lé lọ́dún kan, ó wò ó pé ìlera òun lè gbé e láti ṣe iṣẹ́ aṣáájú-ọ̀nà pa dà!
3. Báwo ni àwọn tó wà nínú ìdílé ṣe lè fọwọ́ sowọ́ pọ̀ láti ran ẹnì kan nínú ìdílé wọn lọ́wọ́ kó lè ṣe aṣáájú-ọ̀nà?
3 Ìwọ lè máà tíì ṣe aṣáájú-ọ̀nà rí, àmọ́ kí ẹnì kan nínú ìdílé rẹ ti fi iṣẹ́ aṣáájú-ọ̀nà sílẹ̀ kó bàa lè bójú tó ẹnì kan nínú ìdílé yín, irú bí òbí tó ti dàgbà. (1 Tím.5:4, 8) Tó bá ri bẹ́ẹ̀, ǹjẹ́ ìwọ tàbí ẹlòmíì nínú ìdílé yín lè túbọ̀ ṣèrànwọ́ fún ẹni tó fi aṣáájú-ọ̀nà sílẹ̀? Ẹ lè jíròrò ọ̀ràn náà pa pọ̀. (Òwe 15:22) Bí àwọn tó wà nínú ìdílé bá fọwọ́ sowọ́ pọ̀ kí ẹnì kan lè ṣe aṣáájú-ọ̀nà, gbogbo wọn ló máa nímọ̀lára pé àwọn ń lọ́wọ́ nínú iṣẹ́ náà.
4. Tí kò bá wá ṣeé ṣe fún ẹ láti pa dà di aṣáájú-ọ̀nà ní báyìí ńkọ́?
4 Má ṣe rẹ̀wẹ̀sì bí ipò tó o wà báyìí kò bá lè jẹ́ kó o pa dà bẹ̀rẹ̀ iṣẹ́ aṣáájú-ọ̀nà. Bó o ṣe múra tán láti ṣe é ń dùn mọ́ Jèhófà nínú. (2 Kọ́r. 8:12) Máa lo ìrírí tó o ti ní nígbà tó o ṣì ń ṣe aṣáájú-ọ̀nà lẹ́nu iṣẹ́ òjíṣẹ́ tó o láǹfààní rẹ̀ báyìí. Gbàdúrà sí Jèhófà nípa ohun tó ń jẹ ẹ́ lọ́kàn, kó o sì wà lójúfò láti mọ̀ bí àǹfààní bá ti ṣí sílẹ̀ fún ẹ láti ṣàtúnṣe ipò rẹ. (1 Jòh. 5:14) Bí àkókò ti ń lọ, Jèhófà lè ṣí “ilẹ̀kùn ńlá tí ń ṣamọ̀nà sí ìgbòkègbodò” sílẹ̀ fún ẹ, kó o lè pa dà ní ayọ̀ tó wà nínú iṣẹ́ aṣáájú-ọ̀nà déédéé!—1 Kọ́r. 16:9.