Àwọn Aṣáájú-Ọ̀nà Ń Fìbùkún Jíǹkí Ẹni Wọ́n Sì Ń Rí I Gbà
“ṢÍṢE aṣáájú-ọ̀nà níyelórí lọ́pọ̀lọpọ̀ ju ìṣẹ́-ìgbésí-ayé oúnjẹ-òòjọ́ aláṣeyọrísírere kan lọ. Kò sí ohun kan tí ń mú ìtẹ́lọ́rùn wá ju ríran àwọn ènìyàn lọ́wọ́ láti mọ Jehofa àti òtítọ́ rẹ̀.” Bí Kristian obìnrin kan tí ó yan ṣíṣe aṣáájú-ọ̀nà—ìwàásù Ìjọba alákòókò kíkún—gẹ́gẹ́ bí iṣẹ́-ìgbésí-ayé rẹ̀ ti sọ nìyẹn. Mélòó nínú àwọn iṣẹ́-ìgbésí-ayé mìíràn ni ó lè fúnni ní irú ayọ̀ bẹ́ẹ̀?
Ṣíṣe aṣáájú-ọ̀nà jẹ́ góńgó gíga fíofío kan ó sì tún jẹ́ àǹfààní ṣíṣeyebíye. Báwo ni ẹnìkan ṣe lè yan irú ìgbésí-ayé bẹ́ẹ̀? Kí ni ohun tí a nílò láti dúró ti ṣíṣe aṣáájú-ọ̀nà fún àkókò gígùn tó láti kórè àwọn ìbùkún tí ó ń nawọ́ rẹ̀ síni?
Àwọn ohun méjì ṣekókó. Àkọ́kọ́, àwọn ayíká-ipò yíyẹ. Ọ̀pọ̀ ń gbé nínú àwọn àyíká-ipò kan tí ó mú kí ó ṣe kedere pé aṣáájú-ọ̀nà kò ṣeéṣe fún wọn. Àti èkejì, àwọn ohun tẹ̀mí tí a béèrè fún àti ìṣarasíhùwà yíyẹ. Àmọ́ ṣáá o, yálà àwọn àyíká-ipò yọ̀ọ̀da fún ẹnìkan láti ṣe aṣáájú-ọ̀nà tàbí bẹ́ẹ̀kọ́, gbogbo wa lè ṣiṣẹ́ láti mú àwọn ànímọ́ ti Kristian kan tí ó dàgbàdénú dàgbà.
Ìdí tí Àwọn kan Fi Ń Ṣe Aṣáájú-Ọ̀nà
Kí ni àwọn ohun tí a béèrè fún láti ṣe aṣáájú-ọ̀nà ní àṣeyọrísírere? Ó dára, òye-iṣẹ́ ìwàásù ṣekókó. Ó yẹ kí àwọn aṣáájú-ọ̀nà mọ bí a ti ń gbé ọ̀rọ̀ ìhìnrere kalẹ̀ fún àwọn àjèjì, ṣe ìpadàbẹ̀wò àwọn olùfìfẹ́hàn, kí wọ́n sì darí àwọn ìkẹ́kọ̀ọ́ Bibeli inú ilé. Àìní àwọn òye-iṣẹ́ wọ̀nyí lè kó ìrẹ̀wẹ̀sì bá aṣáájú-ọ̀nà kan. Bí ó tilẹ̀ rí bẹ́ẹ̀, àwọn nǹkan mìíràn tún ṣe pàtàkì pẹ̀lú.
Fún àpẹẹrẹ, gbogbo ohun tí ó níí ṣe pẹ̀lú ìjọsìn wa wépọ̀ mọ́ ipò-ìbátan wa pẹ̀lú Jehofa àti ètò-àjọ rẹ̀. Èyí ní nínú ṣíṣe aṣáájú-ọ̀nà. Ọ̀dọ́ aṣáájú-ọ̀nà kan tí ń jẹ́ Rado ṣàlàyé pé: “Fún ẹnìkan tí ó jẹ́ ọ̀dọ́, kò sí ohun kan tí ó dara ju rírántí Jehofa àti rírìn nínú ọ̀nà òtítọ́.” Bẹ́ẹ̀ni, ṣíṣe aṣáájú-ọ̀nà jẹ́ ọ̀nà dídára tí àwọn èwe lè gbà ṣàṣefihàn ìfẹ́ wọn fún Jehofa àti bí wọ́n ṣe súnmọ́ ọn tó.—Oniwasu 12:1.
Ìmọ̀ àti òye tún jẹ́ kòṣeémánìí. (Filippi 1:9-11) Nítòótọ́, ìwọ̀nyí ni epo tí ń mú kí ẹ̀rọ tẹ̀mí wa máa ṣiṣẹ́. Ìdákẹ́kọ̀ọ́ déédéé ṣekókó láti lè yẹra fún dídi ẹni tí àárẹ̀ mú nípa tẹ̀mí, ní pípàdánù ìtara-ọkàn àti ohun tí a gbàgbọ́ dájú. Àmọ́ ṣáá ó, kìí ṣe ọgbọ́n ìrònúmòye nìkan ni ìmọ̀ tí a ń gbà sínú níláti nípa lélórí bíkòṣe ọkàn-àyà pẹ̀lú. (Owe 2:2) Nítorí náà, ní àfikún sí ìdákẹ́kọ̀ọ́, a nílò àkókò fún àdúrà àti àṣàrò kí ìmọ̀ tí a jèrè baà lè wọ ọkàn-àyà ṣinṣin. Nígbà náà, bí àwọn àyíká-ipò wa bá yọ̀ọ̀da, àwa yóò fẹ́ láti ṣe aṣáájú-ọ̀nà.—Fiwé Esra 7:10.
Títẹ́wọ́gba iṣẹ́-ìsìn aṣáájú-ọ̀nà tún béèrè fún ẹ̀mí ìfara-ẹni-rúbọ. Ọ̀dọ́kùnrin kan tí ń jẹ́ Ron tí ṣe gbogbo ètò tán pátá fún ṣíṣe aṣáájú-ọ̀nà. Ó wulẹ̀ ń dúró de àwọn àyíká-ipò tí ó tọ́ kí ó baà lè bẹ̀rẹ̀ ni. Ní pàtó, ó fẹ́ iṣẹ́ kan tí yóò lè yọ̀ọ̀da fún un láti ṣe aṣáájú-ọ̀nà àti ní àkókò kan náà kí ó tún gbádùn díẹ̀ lára àwọn adùn ìgbésí-ayé. Nígbà tí ó mẹ́nukan èyí fún arábìnrin kan tí ó dàgbàdénú, ìdáhùn rẹ̀ gbọ̀n ọ́n jìgìjìgì. Ó sọ pé: “Àwọn ohun tí a bá ṣe ni Jehofa máa ń bùkún, kìí ṣe ìlérí.” Ọ̀dọ́kùnrin náà rí iṣẹ́ tí owó-oṣù rẹ̀ túbọ̀ dínkù tí ó fàyèsílẹ̀ fún ṣíṣe aṣáájú-ọ̀nà. Fífi Matteu 6:25-34 sílò yóò ran ẹnìkan lọ́wọ́ láti máa báa nìṣó pẹ̀lú owó kékeré tí ń wọlé.
Ìfẹ́-ìmúratán onírẹ̀lẹ̀-ọkàn láti tẹ̀lé àwọn ìdámọ̀ràn dídára tún lè ṣèrànlọ́wọ́ dáradára láti mú kí a kówọnú iṣẹ́-ìsìn aṣáájú-ọ̀nà. Ní kùtùkùtù ìgbésí-ayé rẹ̀ gẹ́gẹ́ bíi Kristian kan, Hanna mú ìfẹ́-ọkàn láti ṣe aṣáájú-ọ̀nà dàgbà. Ṣùgbọ́n kò ṣe aṣáájú-ọ̀nà nígbà tí ó ń tọ́ àwọn ọmọ dàgbà, ó sì wá bẹ̀rẹ̀ iṣẹ́-ajé kan lẹ́yìn náà. Ní kíkọbiara sí ìmọ̀ràn rere láti ọ̀dọ̀ àwọn alàgbà tí wọ́n wà lójúfò, ó fi iṣẹ́ oúnjẹ òòjọ́ tí ó nífẹ̀ẹ́-ọkàn sí náà sílẹ̀ ó sì tẹ́wọ́gba iṣẹ́-ìsìn aṣáájú-ọ̀nà. Nísinsìnyí, Hanna ń ní ìrírí ayọ̀ ńlá nínú ríran àwọn ẹlòmíràn lọ́wọ́ latí ṣe ìyàsímímọ́ àti ríran àwọn aláìṣedéédéé lọ́wọ́.
Fífi ìmoore hàn fún ohun tí òtítọ́ ti ṣe nínú ìgbésí-ayé ẹni tún lè jẹ́ ìṣírí láti súnniṣe aṣáájú-ọ̀nà. Ṣàgbéyẹ̀wò ọ̀ràn ti obìnrin kan tí ó ní ìsoríkọ́ tí ó jinlẹ̀ ẹni tí ìgbéyàwó rẹ̀ ti fẹ́rẹ̀ẹ́ túká. Ipò-ọ̀ràn yìí yípadà lọ́nà mímúnijígìrì nígbà tí ó kẹ́kọ̀ọ́ òtítọ́ Ọ̀rọ̀ Ọlọrun tí ó sì fi í sílò. Bí ohun tí òtítọ́ ti ṣe fún un ti ru ìmọ̀lára rẹ̀ sókè, ó pínnu pé ọ̀nà dídára jùlọ fún òun láti fi ìmọrírì hàn yóò jẹ́ láti ṣe aṣáájú-ọ̀nà kí òun sì ran àwọn ẹlòmíràn lọ́wọ́. Èyí ni ohun tí ó ṣe, ó sì ń ní ìrírí àwọn ìbùkún ti ìkẹ́kọ̀ọ́ Bibeli púpọ̀ àti ìgbésí-ayé ìdílé aláyọ̀.
Àwọn Mìíràn Lè Ṣèrànlọ́wọ́
Àwọn aṣáájú-ọ̀nà sábà máa ń mú àwọn aṣáájú-ọ̀nà mìíràn jáde. Rado, tí a mẹ́nukàn ṣáájú, jẹ́ ọmọ ọdún mẹ́fà nígbà tí àwọn aṣáájú-ọ̀nà méjì bá àwọn òbí rẹ̀ kẹ́kọ̀ọ́ Bibeli. Nígbà tí ó ṣì jẹ́ ọ̀dọ́ gan-an, ó máa ń jáde fún iṣẹ́-òjíṣẹ́ pápá déédéé pẹ̀lú àwọn oníwàásù alákòókò kíkún wọ̀nyí. Rado fúnraarẹ̀ di aṣáájú-ọ̀nà déédéé ní ọmọ ọdún 17. Ọ̀dọ́kùnrin mìíràn, Arno, ni a tọ́ dàgbà nínú ilé Kristian ṣùgbọ́n ó di aláìlera nípa tẹ̀mí. Nígbà tí ó yá, ó pinnu láti jèrè okun tẹ̀mí rẹ̀ padà, ó sì sọ nísinsìnyí pé: “Mo rí ìṣírí púpọ̀ gbà láti ọ̀dọ̀ àwọn aṣáájú-ọ̀nà. Mó ń darapọ̀ mọ́ wọn pàápàá jùlọ ní àwọn àkókò ìsinmi kúrò ní ilé-ẹ̀kọ́ àti ní àwọn ìgbà mìíràn mo ń ròyìn iye tí ó pọ̀ tó 60 wákàtí lóṣù nínú iṣẹ́-ìsìn pápá. Lẹ́yìn ìyẹn, ìgbésẹ̀ náà wọnú iṣẹ́-ìsìn aṣáájú-ọ̀nà déédéé [tí ń béèrè fún 90 wákàtí lóṣooṣù] kò fi bẹ́ẹ̀ ga jù.” Ṣíṣàṣàrò lórí ìmọ̀ràn inú 1 Korinti 7:29-31 láti máṣe lo ayé dé ẹ̀kúnrẹ́rẹ́ tí ran irú àwọn ọ̀dọ́ bẹ́ẹ̀ lọ́wọ́ níti gidi.
Ẹ̀mí aṣáájú-ọ̀nà lè yára ta gbòǹgbò nínú ilé kan níbi tí wọ́n ti fi àwọn àǹfààní-ire tẹ̀mí sí ipò àkọ́kọ́ tí àwọn òbí sì ń fún àwọn ọmọ wọn ní ìṣírí láti wọnú iṣẹ́-òjíṣẹ́ alákòókò kíkún. Philo, tí ó dàgbà nínú irú ilé kan bẹ́ẹ̀, sọ ọ̀rọ̀-àkíyèsí pé: “Àwọn púpọ̀ fún mi ní ìṣírí láti máa bá ẹ̀kọ́-ìwé mi lọ, láti ṣiṣẹ́ fún ọjọ́-ọ̀la kan nínú ayé. Ṣùgbọ́n àwọn òbí mi ràn mí lọ́wọ́ láti ṣe ìpinnu tí ó túbọ̀ bọ́gbọ́nmu. Wọn sọ fún mi pé bí mo bá fẹ́ láti ní ọjọ́-ọ̀la níti tòótọ́, ohun àkọ́múṣe mi níláti jẹ́ mímú ipò-ìbátan kan dàgbà pẹ̀lú Jehofa.”
Ọ̀ṣọ́ọ́rọ́ obìnrin kan tí ń jẹ́ Thamar tún gbà pé iṣẹ́-ìsìn aṣáájú-ọ̀nà òun jẹ́ àbáyọrí àpẹẹrẹ àti ìsapá àwọn òbí òun. Ó sọ pé: “Èmi kò lè sọ níti gidi ìgbà tí mó mú ojú-ìwòye tẹ̀mí dàgbà nípa ìgbésí-ayé, ṣùgbọ́n mo mọ̀ pé a kò bí ọ̀kan mọ́ mi. Àṣà àwọn òbí mi láti máa kópa déédéé nínú iṣẹ́-ìsìn pápá àti lílọ sí àwọn ìpàdé, àti ìfẹ́ jíjinlẹ̀ tí wọ́n ní fún òtítọ́, ràn mí lọ́wọ́ gidigidi láti mú ìṣarasíhùwà tẹ̀mí mí dàgbà.”
Rírọ̀mọ́ Ìpinnu Rẹ
Lẹ́yìn tí ẹnìkan bá ti wọnú iṣẹ́-ìsìn aṣáájú-ọ̀nà, títẹpẹlẹ mọ́ ọn yóò mú kí ó ṣeéṣe fún un láti kórè àǹfààní kíkún ti ìpinnu ọlọgbọ́n yẹn. Ọ̀pọ̀ ni ìmọ̀ràn gbígbéṣẹ́ tí a lè fifúnni lórí ìyẹn. Fún àpẹẹrẹ, àwọn aṣáájú-ọ̀nà yóò ṣe dáradára láti kọ́ bí wọ́n ṣe lè ṣètò àkókò wọn láti jẹ́ kí ó mésojáde bí ó bá ti lè ṣeéṣe tó. Síbẹ̀, kókó-abájọ tí ó ṣe pàtàkì jùlọ ṣì jẹ́ ipò-ìbátan ẹnìkan pẹ̀lú Jehofa àti ètò-àjọ Rẹ̀.
Èyí tí ó tanmọ́ ọn ni ẹ̀mí-ìrònú tí ó kún fún àdúrà. “Nígbà tí mo wá sínú òtítọ́, ó wù mí lọ́pọ̀lọpọ̀ láti ṣe aṣáájú-ọ̀nà,” ní Cor sọ. Bí ó ti wù kí ó rí, baba rẹ̀ fi dandan lé e pé kí ó kọ́kọ́ parí abala ẹ̀kọ́ kan ní Yunifásítì Ẹ̀kọ́sẹ́-Ọ̀gbìn. Lẹ́yìn ìgbà náà, Cor bẹ̀rẹ̀ síí ṣe aṣáájú-ọ̀nà. Láìpẹ́ ó ṣègbéyàwó, ìyàwó rẹ̀ sì darapọ̀ mọ́ ọn nínú iṣẹ́ aṣáájú-ọ̀nà. Nígbà tí ó lóyún, ṣíṣeéṣe náà pé kí ó fi iṣẹ́ aṣáájú-ọ̀nà sílẹ̀ dojúkọ ọ́. “Mo ń gbàdúrà sí Jehofa nígbà gbogbo mo sì ń mú ìfẹ́ ọkàn-àyà mi láti máa ṣe aṣáájú-ọ̀nà nìṣó wá sí iwájú rẹ̀,” ni Cor sọ. Ní àsẹ̀yìnwá-àsẹ̀yìnbọ̀ Cor rí irú iṣẹ́ tí ó mú kí ó ṣeéṣe fún un láti ṣe aṣáájú-ọ̀nà nígbà tí ó ń tọ́ àwọn ọmọ dàgbà.
Níní ìtẹ́lọ́rùn pẹ̀lú àwọn ohun tí ó jẹ́ kòṣeémánìí nípa tí ara ni kókó-abájọ mìíràn tí ó sábà máa ń ran ẹnìkan lọ́wọ́ láti máa bá iṣẹ́-òjíṣẹ́ aṣáájú-ọ̀nà nìṣó. Aposteli Paulu kọ̀wé pé: “Kí ọkàn yín kí ó máṣe fà sí ìfẹ́ owó, kí ohun tí ẹ ní kí ó tó yín; nítorí òun tìkáláarẹ̀ ti wí pé, Èmi kò jẹ́ fi ọ́ sílẹ̀, bẹ́ẹ̀ ní èmi kò jẹ́ kọ̀ ọ́ sílẹ̀.” (Heberu 13:5) Níní ìtẹ́lọ́rùn pẹ̀lú ohun tí ó ní ran Harry àti Irene lọ́wọ́ láti máa bá ṣíṣe aṣáájú-ọ̀nà nìṣó. Irene, tí ó jẹ́ afọ́jú, ti jẹ́ aṣáájú-ọ̀nà fún ọdún mẹ́jọ. “Àwa kò wo ipò-ọ̀ràn wa níti ìṣúnná-owó gẹ́gẹ́ bí ìṣòro rí,” ni ó sọ. “A wulẹ̀ ń ṣọ́ra láti máṣe ru àwọn ẹrù ọ̀ràn-ìnáwó tí kò pọndandan. Nígbà gbogbo ni a máa ń gbé ohun tí yóò ná wa yẹ̀wò. Ìgbésí-ayé wa tí máa ń fìgbà gbogbo jẹ́ èyí tí ó rọrùn, bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé ó gbádùnmọ́ni gan-an, wọ́n sì ti kún fún àwọn ìbùkún dídọ́ṣọ̀.”
Ọ̀pọ̀ Ayọ̀ àti Ìbùkún
Ní bíbojúwẹ̀yìn wo àwọn ọdún mẹ́sàn-án ti ṣíṣe aṣáájú-ọ̀nà, Thamar sọ pé: “Ìwọ a wá súnmọ́ Jehofa gidigidi, bí ẹní pé ó di ọwọ́ rẹ̀ mú níti gidi.” (Orin Dafidi 73:23) Àwọn àdánwò kan tún wá sọ́kàn. “Àwọn àìpé tèmi fúnraàmi papọ̀ pẹ̀lú ti àwọn ẹlòmíràn máa ń yọ mí lẹ́nu nígbà gbogbo,” ni Thamar fikún un. “Jù bẹ́ẹ̀ lọ, èmi yóò wo àwọn arákùnrin àti arábìnrin tí wọ́n yan ọ̀nà ìgbésí-ayé tí ó túbọ̀ ń mú èrè ohun ti ara wá, ó sì dàbí ẹni pé yíyàn wọn fanimọ́ra nígbà tí èmi bá ń lọ láti ẹnu-ọ̀nà dé ẹnu-ọ̀nà nínú òjò àti nínú otútù. Ṣùgbọ́n nísàlẹ̀ ọkàn-àyà mi lọ́hùn-ún, èmi kì yóò fẹ́ láti fi ọ̀kan rọ́pò èkejì. Ohun mìíràn wo yàtọ̀ sí ṣíṣe aṣáájú-ọ̀nà ni ó lè mú irú ayọ̀ bẹ́ẹ̀, irú ìtẹ́lọ́rùn tẹ̀mí bẹ́ẹ̀, àti irú ìbùkún bẹ́ẹ̀ wá?” Ìwọ yóò ha mọyì irú ayọ̀ àti ìbùkún bẹ́ẹ̀ lọ́nà gíga bí?
Nítorí pé àwọn aṣáájú-ọ̀nà ń lo àkókò púpọ̀ nínú iṣẹ́-òjíṣẹ́ Kristian, wọ́n wà ní ipò láti ran ọ̀pọ̀ àwọn ẹnìkọ̀ọ̀kan lọ́wọ́ láti jèrè ìmọ̀ òtítọ́ Bibeli. Harry àti Irene, tí a mẹ́nukàn ṣáájú wí pé: “Àwọn àǹfààní púpọ̀ ni ó wà tí ẹnìkan lè ní nínú ètò-àjọ Jehofa, ṣùgbọ́n ríran olùfìfẹ́hàn titun kan lọ́wọ́ láti tẹ̀síwájú dé orí kókó náà tí yóò fi di ìráńṣẹ́ Jehofa ni èyí tí ó tóbilọ́lá jùlọ nínú gbogbo rẹ̀.”
Aṣáájú-ọ̀nà mìíràn sọ àwọn nǹkan lọ́nà dídára nígbà tí ó wí pé: “Àwọn ọ̀rọ̀ ìwé Owe 10:22 (NW) ti jásí òtítọ́ nínú ọ̀ràn tèmi: ‘Ìbùkún Jehofa—ní ń sọnidọlọ́rọ̀, kìí ṣìí fi ìrora pẹ̀lú rẹ̀.’ Ní ọ̀pọ̀ ìgbà, ẹsẹ ìwé mímọ́ yìí ti ní ìmúṣẹ sí mi lára nínú àwọn ọdún tí mo ti fi ṣiṣẹ́ṣin Jehofa.”
Ẹ̀yin òbí, ẹ ha ń fi ìfẹ́-ọkàn náà láti ṣe aṣáájú-ọ̀nà sínú àwọn ọmọ yín bí? Ẹ̀yin aṣáájú-ọ̀nà, ẹ ha ń sakun láti tanná ran ìfẹ́-ọkàn yìí nínú àwọn ẹlòmíràn bí? Ẹ̀yin alàgbà, ẹ ha ń kọ́wọ́ti àwọn aṣáájú-ọ̀nà nínú ìjọ yín tí ẹ sì ń ṣèrànlọ́wọ́ láti mú ẹ̀mí aṣáájú-ọ̀nà dàgbà nínú àwọn ẹlòmíràn bí? Ǹjẹ́ kí a lè sún ọ̀pọ̀lọpọ̀ púpọ̀ síi nínú àwọn ènìyàn Jehofa láti nàgà sí irúfẹ́ ìbùkún dídọ́ṣọ̀ bẹ́ẹ̀ bí wọ́n ti ń kópa nínú iṣẹ́-ìsìn aṣáájú-ọ̀nà.