Iṣẹ́ Ìsìn Aṣáájú Ọ̀nà—Ǹjẹ́ O Lè Ṣe É?
1 “N kò rò pé ohun mìíràn wà tí ǹ bá tún ṣe. N kò rò pé ohun mìíràn wà tí ó lè mú irú ayọ̀ kan náà wá.” Ta ló sọ èyí? Ọ̀kan lára ẹgbẹẹgbẹ̀rún lọ́nà ọgọ́rọ̀ọ̀rún Àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà tí ó ti sọ iṣẹ́ òjíṣẹ́ alákòókò kíkún di iṣẹ́ onídùnnú nínú ìgbésí ayé ni. O ha ti ronú tàdúràtàdúrà bóyá o lè ṣe iṣẹ́ ìsìn aṣáájú ọ̀nà bí? Níwọ̀n bí a ti ya ara wa sí mímọ́ sí Jèhófà láìkù síbì kan, ó dájú pé ó yẹ kí a ronú bóyá a lè ní ìpín kíkún sí i nínú títan ìhìn rere Ìjọba náà kálẹ̀. Láti lè ṣe ìyẹn, jọ̀wọ́ ṣàgbéyẹ̀wò àwọn ìbéèrè kan tí ọ̀pọ̀ máa ń béèrè nípa iṣẹ́ ìsìn aṣáájú ọ̀nà.
ÌBÉÈRÈ 1: “Àwọn kan sọ pé kì í ṣe gbogbo ènìyàn ló lè ṣe aṣáájú ọ̀nà. Báwo ni mo ṣe lè mọ̀ bí mo bá lè ṣe é?”
2 Ìdáhùn rẹ̀ sinmi lórí àyíká ipò àti àwọn iṣẹ́ àìgbọdọ̀máṣe rẹ lójú Ìwé Mímọ́. Ọ̀pọ̀ ń bẹ tí ipò ìlera tàbí ipò tí wọ́n wà lọ́wọ́lọ́wọ́ nínú ìgbésí ayé kò jẹ́ kí wọ́n ya 90 wákàtí lóṣù sọ́tọ̀ fún iṣẹ́ òjíṣẹ́. Wo àpẹẹrẹ ti ọ̀pọ̀ olùṣòtítọ́ arábìnrin tí wọ́n jẹ́ Kristẹni aya àti ìyá. Wọ́n ń ṣàjọpín nínú iṣẹ́ òjíṣẹ́ nígbàkúùgbà bí wọ́n bá ti lè ṣe tó títí dé àyè tí àyíká ipò wọn bá yọ̀ǹda. Bí àǹfààní bá ṣí sílẹ̀, wọ́n máa ń ṣe aṣáájú ọ̀nà olùrànlọ́wọ́ lóṣù kan tàbí jù bẹ́ẹ̀ lọ lọ́dọọdún, wọ́n ń rí ìdùnnú tí ń wá láti inú mímú tí wọ́n ń mú ìpín wọn nínú iṣẹ́ òjíṣẹ́ gbòòrò sí i. (Gál. 6:9) Bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé àyíká ipò wọn lè má gbà wọ́n láyè láti sìn gẹ́gẹ́ bí aṣáájú ọ̀nà alákòókò kíkún ní lọ́wọ́lọ́wọ́ báyìí, wọ́n ń gbé ẹ̀mí aṣáájú ọ̀nà lárugẹ wọ́n sì jẹ́ ìbùkún fún ìjọ gẹ́gẹ́ bí onítara akéde ìhìn rere náà.
3 Ní ọwọ́ mìíràn, ọ̀pọ̀ arákùnrin àti arábìnrin tí wọn kò fi bẹ́ẹ̀ ní àwọn iṣẹ́ àìgbọdọ̀máṣe ti wá àyè fún iṣẹ́ ìsìn aṣáájú ọ̀nà nípa yíyí àwọn ohun àkọ́múṣe wọn padà. Ìwọ ńkọ́? O ha jẹ́ èwe tí ó ti parí ilé ẹ̀kọ́ bí? O ha jẹ́ aya tí ọkọ rẹ̀ lè pèsè tẹ́rùntẹ́rùn fún ìdílé bí? O ha ti ṣègbéyàwó tí o kò sì ní ọmọ tí o ń tọ́ bí? O ha ti fẹ̀yìn tì lẹ́nu iṣẹ́ bí? Láti ṣe aṣáájú ọ̀nà tàbí láti má ṣe aṣáájú ọ̀nà jẹ́ ìpinnu tí ẹnì kọ̀ọ̀kan gbọ́dọ̀ fúnra rẹ̀ ṣe. Ìbéèrè náà ni pé, O ha lè wá àyè nínú ìgbésí ayé rẹ fún ṣíṣe aṣáájú ọ̀nà bí?
4 Sátánì ń lo ètò àwọn nǹkan rẹ̀ ti ayé láti fi àwọn ohun tí ń pín ọkàn níyà kún ìgbésí ayé wa, kí ó sì mú kí a tira bọ ọ̀nà ìgbésí ayé onímọtara-ẹni-nìkan. Bí a bá pinnu láti máa bá a nìṣó láti má ṣe jẹ́ apá kan ayé, Jèhófà yóò ràn wá lọ́wọ́ láti fi àwọn ire Ìjọba náà ṣe èkíní kí a sì nàgà fún àwọn àǹfààní iṣẹ́ ìsìn ìṣàkóso Ọlọ́run tí ó wà lárọ̀ọ́wọ́tó wa kí ọwọ́ wa sì tẹ̀ wọ́n. Bí o bá lè yí àwọn àyíká ipò rẹ padà kí o lè sìn gẹ́gẹ́ bí aṣáájú ọ̀nà, èé ṣe tí o kò fi ṣe bẹ́ẹ̀?
ÌBÉÈRÈ 2: “Báwo ni mo ṣe lè ní ìdánilójú pé èmi yóò lè máa gbọ́ bùkátà ara mi nínú iṣẹ́ òjíṣẹ́ alákòókò kíkún?”
5 Òtítọ́ ni pé ní ọ̀pọ̀ ilẹ̀, wákàtí iṣẹ́ tí a ń béèrè lọ́sọ̀ọ̀sẹ̀ láti lè rí àwọn ohun tí a wò gẹ́gẹ́ bí kò-ṣeé-má-nìí ti pọ̀ sí i jálẹ̀ àwọn ọdún wá. Síbẹ̀síbẹ̀, ọ̀pọ̀ ti ṣe aṣáájú ọ̀nà fún ọ̀pọ̀ ẹ̀wádún, Jèhófà sì ń bá a lọ láti máa mú wọn dúró. Láti ṣàṣeyọrí gẹ́gẹ́ bí aṣáájú ọ̀nà, ìgbàgbọ́ àti ẹ̀mí ìfara-ẹni-rúbọ ṣe pàtàkì. (Mát. 17:20) A ní ìdánilójú tí ó wà ní Sáàmù 34:10 pé ‘àwọn tí ń wá Jèhófà kì yóò ṣaláìní ohun rere èyíkéyìí.’ Kí ẹnikẹ́ni tí ó bá fẹ́ wọ iṣẹ́ ìsìn aṣáájú ọ̀nà ṣe bẹ́ẹ̀ pẹ̀lú ìgbọ́kànlé kíkún pé Jèhófà yóò pèsè fún òun. Ó ń ṣe bẹ́ẹ̀ gẹ́lẹ́ fún àwọn olùṣòtítọ́ aṣáájú ọ̀nà níbi gbogbo! (Sm. 37:25) Àmọ́ ṣá o, ní ìbámu pẹ̀lú ìlànà tí ó wà nínú 2 Tẹsalóníkà 3:8, 10, àti 1 Tímótì 5:8, àwọn aṣáájú ọ̀nà kì í retí pé kí àwọn ẹlòmíràn máa fi owó ṣe ìrànwọ́ fún wọn.
6 Ó yẹ kí ẹnikẹ́ni tí ó bá ń ronú nípa iṣẹ́ ìsìn aṣáájú ọ̀nà ṣe gẹ́gẹ́ bí Jésù ṣe sọ pé: ‘kọ́kọ́ jókòó, kí o sì gbéṣirò lé ìnáwó.’ (Lúùkù 14:28) Ṣíṣe èyí ń fi ọgbọ́n ṣíṣeé múlò hàn. Bá àwọn tí wọ́n ti ṣàṣeyọrí fún ọdún mélòó kan nínú ṣíṣe aṣáájú ọ̀nà sọ̀rọ̀. Béèrè nípa bí Jèhófà ṣe mú wọn dúró. Alábòójútó àyíká yín jẹ́ aṣáájú ọ̀nà onírìírí tí yóò láyọ̀ láti fún ọ ní àbá nípa bí o ṣe lè ṣàṣeyọrí nínú iṣẹ́ òjíṣẹ́ alákòókò kíkún.
7 Ẹnì kan lè má nírìírí ìjótìítọ́ ìlérí Jésù ní Mátíù 6:33 títí di ìgbà tí ó bá tó fi ara rẹ̀ lé Jèhófà lọ́wọ́. Olùṣòtítọ́ aṣáájú ọ̀nà kan ṣàlàyé pé: “Nígbà tí èmi àti alájọṣiṣẹ́ mi dé ibi iṣẹ́ àyànfúnni tuntun gẹ́gẹ́ bí aṣáájú ọ̀nà, ọ̀gbìn oko àti bọ́tà díẹ̀ la ní, a kò sì ní owó. A parí oúnjẹ náà lálẹ́, a sì sọ pé, ‘Wàyí o, kò sí ohun tí a óò jẹ́ lọ́la.’ A gbàdúrà nípa rẹ̀, a sì lọ sùn. Ní òwúrọ̀ kùtù ọjọ́ kejì, Ẹlẹ́rìí kan láti àgbègbè náà tọ̀ wá wá, ó sì sọ ẹni tí ó jẹ́ nípa sísọ pé, ‘Mo gbàdúrà pé kí Jèhófà rán àwọn aṣáájú ọ̀nà wá. Nítorí náà, màá pẹ́ lóde pẹ̀lú yín lónìí, ṣùgbọ́n níwọ̀n bí ó ti jẹ́ pé ìgbèríko ni mo ń gbé, màá bá a yín jẹ oúnjẹ ọ̀sán, ìdí nìyí tí mo fi gbé oúnjẹ yìí wá fún gbogbo wa.’ Ẹran màlúù àti ọ̀gbìn oko púpọ̀ ni.” Abájọ tí Jésù ṣe mú un dá wa lójú pé a lè ‘dẹ́kun ṣíṣàníyàn nípa ọkàn wa’! Lẹ́yìn náà, ó fi kún un pé: “Ta ni nínú yín, nípa ṣíṣàníyàn, tí ó lè fi ìgbọ̀nwọ́ kan kún ìwọ̀n gígùn ìwàláàyè rẹ̀?”—Mát. 6:25, 27.
8 Ayé tí ó yí wa ká túbọ̀ ń di onífẹ̀ẹ́ ọrọ̀ àlùmọ́ọ́nì sí i. Agbára ìdarí tí ń pọ̀ sí i ni ó ń mú wá sórí wa láti sọ wá dà bí ó ṣe dà. Ṣùgbọ́n, níní ìmọrírì onírẹ̀lẹ̀ fún iṣẹ́ òjíṣẹ́ alákòókò kíkún ni ó ń mú kí a ní ìtẹ́lọ́rùn pẹ̀lú àwọn nǹkan ìní díẹ̀. (1 Tím. 6:8) Àwọn aṣáájú ọ̀nà tí wọ́n mú kí ìgbésí ayé wọn wà níwọ̀ntúnwọ̀nsì àti létòlétò ń ní àkókò tí ó pọ̀ sí i fún iṣẹ́ ìsìn, wọ́n sì ń jèrè ìdùnnú gíga jù àti okun tẹ̀mí láti inú kíkọ́ àwọn ẹlòmíràn ní òtítọ́. Bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé wọn kì í gbé ìgbé ayé ìṣẹ́ra ẹni níṣẹ̀ẹ́, ọ̀nà wíwà déédéé tí wọ́n ń gbà bójú tó ipò ìṣúnná owó wọn ti mú kí wọ́n lè gbádùn ìbùkún ṣíṣe aṣáájú ọ̀nà.
9 Bí o bá mọ̀ dájú pé a ń gbé ní àwọn ọjọ́ ìkẹyìn, àti pé àkókò ayé búburú yìí ń tán lọ, a óò sún ọ nípa tẹ̀mí láti ṣe àwọn ìrúbọ tí a ń béèrè láti wàásù ìhìn rere náà ní gbogbo ìgbà tí àǹfààní bá ṣí sílẹ̀. Nípa yíyẹ ipò ìṣúnná owó rẹ wò lẹ́ẹ̀kan sí i, àti nípa fífi ọ̀ràn náà sí ọwọ́ Jèhófà, o lè rí i pé o lè sìn ín ní àkókò kíkún. Àní bí o bá ní láti yááfì àwọn ohun ìní ti ara kan tí o fẹ́ nítorí kí o lè ṣe aṣáájú ọ̀nà, ìwọ yóò gbádùn àwọn ìbùkún dídọ́ṣọ̀ láti ọ̀dọ̀ Jèhófà.—Sm. 145:16.
ÌBÉÈRÈ 3: “Gẹ́gẹ́ bí ọ̀dọ́langba, èé ṣe tí ó fi yẹ kí n ronú nípa iṣẹ́ ìsìn aṣáájú ọ̀nà gẹ́gẹ́ bí iṣẹ́ tí mo lè yàn?”
10 Nígbà tí o bá ń parí àwọn ọdún díẹ̀ tí ó kẹ́yìn ọdún ilé ẹ̀kọ́ rẹ, lọ́nà ti ẹ̀dá, ìwọ yóò ronú nípa ọjọ́ ọ̀la. O fẹ́ kí ó dájú, kí ó jẹ́ aláyọ̀, kí o sì ṣàṣeyọrí. Àwọn olùgbaninímọ̀ràn ní ilé ẹ̀kọ́ lè gbìyànjú láti darí rẹ sí iṣẹ́ tí ń mówó gọbọi wọlé tí ń béèrè kíkẹ́kọ̀ọ́ fún ọ̀pọ̀lọpọ̀ ọdún ní yunifásítì. Ẹ̀rí-ọkàn Kristẹni rẹ tí a ti dá lẹ́kọ̀ọ́ dáadáa yóò sọ fún ọ pé kí o múra láti sin Jèhófà ní kíkún bí ó bá ti ṣeé ṣe tó. (Oníw. 12:1) O tún lè ronú nípa ṣíṣègbeyàwó àti níní ìdílé lẹ́yìn-ọ̀-rẹyìn. Kí ni ìwọ yóò ṣe?
11 Àwọn ìpinnu tí o bá ṣe ní àkókò yìí nínú ìgbésí ayé rẹ lè ní ipa lórí ọjọ́ ọ̀la rẹ látòkè délẹ̀. Bí o bá jẹ́ Ẹlẹ́rìí Jèhófà, ti ó ti ṣe ìyàsímímọ́ àti batisí, o ti fi ara rẹ fún Jèhófà tọkàntọkàn. (Héb. 10:7) Ní àǹfààní àkọ́kọ́ tí o bá ní, gbìyànjú láti ṣe aṣáájú ọ̀nà olùrànlọ́wọ́ fún oṣù kan tàbí jù bẹ́ẹ̀ lọ. Èyí yóò fún ọ ní ìtọ́wò ìdùnnú àti ẹrù iṣẹ́ tí ń bá ṣíṣe aṣáájú ọ̀nà déédéé rìn, ó sì dájú pé ojú ìwòye rẹ nípa ohun tí ó yẹ kí o fi ìgbésí ayé rẹ ṣe yóò ṣe kedere sí i. Nítorí náà, dípò fífi iṣẹ́ oúnjẹ òòjọ́ alákòókò kíkún kún àyè tí ó ṣí sílẹ̀ lẹ́yìn tí o parí ilé ẹ̀kọ́ rẹ, èé ṣe tí o kò fi bẹ̀rẹ̀ ṣíṣe aṣáájú ọ̀nà déédéé? Àwọn kan tí wọ́n dúró títí di àkókò pípẹ́ nínú ìgbésí ayé wọn kí wọ́n tó bẹ̀rẹ̀ sí gbádùn iṣẹ́ ìsìn aṣáájú ọ̀nà kábàámọ̀ pé àwọn kò tètè bẹ̀rẹ̀.
12 Gẹ́gẹ́ bí ọ̀dọ́, lo àǹfààní tí o ní láti wà láìṣègbéyàwó, kí o sì gbádùn àwọn àǹfààní tí ó ń fúnni nínú ìgbòkègbodò ìwàásù alákòókò kíkún. Bí ó bá jẹ́ ìfẹ́-ọkàn rẹ láti ṣègbéyàwó lọ́jọ́ iwájú, kò sí ìpìlẹ̀ tí ó dára jù tí a lè fi lélẹ̀ fún ìgbéyàwó ju sísìn lákọ̀ọ́kọ́ nínú iṣẹ́ aṣáájú ọ̀nà déédéé. Bí o ti ń dàgbàdénú, tí o sì ń dàgbà nípa tẹ̀mí, o lè yàn láti fi ṣíṣe aṣáájú ọ̀nà ṣiṣẹ́ ṣe pẹ̀lú alábàáṣègbéyàwó tí ó ní èrò inú kan náà. Àwọn tọkọtaya kan tí wọ́n ti ṣe aṣáájú ọ̀nà pa pọ̀ ti bẹ̀rẹ̀ iṣẹ́ aláàbójútó àyíká tàbí lọ sí ẹnu iṣẹ́ míṣọ́nnárì. Ọ̀nà ìgbésí ayé tí ń tẹ́ni lọ́rùn ni ní tòótọ́!
13 Láìka bí o ṣe pẹ́ tó nínú iṣẹ́ aṣáájú ọ̀nà sí, ìwọ yóò ti parí ẹ̀kọ́ rẹ, ìwọ yóò sì gba ìdálẹ́kọ̀ọ́ ṣíṣeyebíye tí iṣẹ́ èyíkéyìí mìíràn lórí ilẹ̀ ayé kò lè fúnni. Ṣíṣe aṣáájú ọ̀nà ń kọ́ni ní ìlànà ìwà híhù, ìṣètò ara ẹni, bí ó ṣe yẹ kí a máa hùwà sí àwọn ènìyàn, ìgbáralé Jèhófà, àti bí ó ṣe yẹ láti mú sùúrù àti inú rere dàgbà—àwọn ànímọ́ tí yóò mú ọ gbára dì láti tẹ́wọ́ gba àwọn ẹrù iṣẹ́ tí ó pọ̀ sí i.
14 Ìgbésí ayé kò tíì di aláìdánilójú fún aráyé tó èyí rí. Yàtọ̀ sí àwọn nǹkan tí Jèhófà ṣèlérí, àwọn nǹkan tí ó lálòpẹ́ ní tòótọ́ kò fi bẹ́ẹ̀ tó nǹkan. Níwọ̀n bí ọjọ́ ọ̀la rẹ ti lọ salalu níwájú rẹ, àkókò wo ni ó tún lè sàn ju ìsinsìnyí lọ láti ronú jinlẹ̀ nípa ohun tí ìwọ yóò fi ìgbésí ayé rẹ ṣe ní àwọn ọdún tí ń bọ̀? Fara balẹ̀ gbé àǹfààní ṣíṣe aṣáájú ọ̀nà yẹ̀ wò. Ìwọ kì yóò kábàámọ̀ láé pé o yàn láti fi iṣẹ́ ìsìn aṣáájú ọ̀nà ṣiṣẹ́ ṣe.
ÌBÉÈRÈ 4: “Ṣé kì í ṣe pákáǹleke ìgbà gbogbo ni yóò jẹ́ láti kúnjú wákàtí tí a ń béèrè? Bí wákàtí mi kò bá pé ńkọ́?”
15 Nígbà tí o bá kọ̀wé béèrè fún iṣẹ́ aṣáájú ọ̀nà déédéé, o gbọ́dọ̀ dáhùn ìbéèrè náà pé: “Ǹjẹ́ o ti ṣètò àwọn àlámọ̀rí ara rẹ débi tí o fi lè fi ìlọ́gbọ́n-nínú fojú sọ́nà láti kájú 1,000 wákàtí tí a béèrè fún lọ́dọọdún bí?” Kí ọwọ́ rẹ lè tẹ̀ ẹ́, ó gbọ́dọ̀ lè máa ní ìpíndọ́gba wákàtí mẹ́ta lóòjọ́ nínú iṣẹ́ ìsìn. Ní kedere, èyí ń béèrè fún ìṣètò rere àti bíbá ara ẹni wí. Láàárín oṣù díẹ̀, àwọn aṣáájú ọ̀nà tí ó pọ̀ jù lọ máa ń ṣètò ìgbòkègbodò tí ó ṣeé mú lò, tí ó sì gbéṣẹ́.
16 Ṣùgbọ́n, Oníwàásù 9:11 sọ ní tòótọ́ pé, ‘Ìgbà àti ìṣẹ̀lẹ̀ tí a kò rí tẹ́lẹ̀ ni ó ń ṣẹlẹ̀ sí gbogbo wa.’ Àìsàn líle koko tàbí àwọn àyíká ipò mìíràn tí a kò rí tẹ́lẹ̀ lè mú kí aṣáájú ọ̀nà kan ṣàìní wákàtí rẹ̀ pé. Bí ìṣòro náà kò bá wà fún àkókò pípẹ́ tí ó sì wáyé ní ìbẹ̀rẹ̀ ọdún iṣẹ́ ìsìn, ó lè jẹ́ pé ìṣètò àkókò púpọ̀ sí i ni gbogbo ohun tí a nílò láti kájú àkókò tí a pàdánù. Ṣùgbọ́n bí ìṣòro wíwúwo bá dìde ńkọ́ tí ó sì jẹ́ pé oṣù díẹ̀ ló kù nínú ọdún iṣẹ́ ìsìn tí aṣáájú ọ̀nà náà kò sì lè kúnjú ìwọ̀n ohun tí a béèrè?
17 Bí o bá ṣàìsàn fún àwọn oṣù díẹ̀ tàbí bí ó bá ṣẹlẹ̀ pé fún àwọn ìdí kánjúkánjú mìíràn tí ó kọjá agbára rẹ, o kò lè kúnjú wákàtí tí a ń béèrè, o lè tọ ọ̀kan lára mẹ́ńbà Ìgbìmọ̀ Iṣẹ́ Ìsìn Ìjọ lọ kí o sì ṣàlàyé ìṣòro rẹ. Bí àwọn alàgbà wọ̀nyí bá ronú pé yóò bọ́gbọ́n mu pé kí a gbà ọ́ láyè láti máa bá a nìṣó nínú iṣẹ́ ìsìn aṣáájú ọ̀nà láìbéèrè pé kí o dí àlàfo àkókò tí o ti pàdánù, wọ́n lè pinnu bẹ́ẹ̀. Akọ̀wé yóò kọ ọ̀rọ̀ sórí káàdì Congregation’s Publisher Record láti fi hàn pé a kò béèrè pé kí o dí àlàfo àkókò tí o ti pàdánù. Èyí kì í ṣe ìyọ̀ǹda fún ìsinmi kúrò lẹ́nu iṣẹ́, ṣùgbọ́n kàkà bẹ́ẹ̀, ó jẹ́ àkànṣe ìgbatẹnirò nítorí àyíká ipò rẹ.—Wo àkìbọnú Iṣẹ́ Òjíṣẹ́ Ìjọba Wa ti September 1986, ìpínrọ̀ 18.
18 Àwọn aṣáájú ọ̀nà onírìírí máa ń ní wákàtí wọn lé ní apá ìbẹ̀rẹ̀ ọdún iṣẹ́ ìsìn. Iṣẹ́ ìsìn aṣáájú ọ̀nà wọn ni ó gba ipò àkọ́kọ́, nítorí náà, wọ́n máa ń rí i nígbà mìíràn pé ó ṣe pàtàkì pé kí wọ́n dín àwọn ìgbòkègbodò tí kò pọndandan kù. Bí aṣáájú ọ̀nà kan kò bá kúnjú ìwọ̀n nítorí ìṣètò tí kò dára tàbí nítorí àìkòbá ara rẹ̀ wí ní ti títẹ̀lé ìṣètò náà, ó gbọ́dọ̀ mọ̀ pé ẹrù iṣẹ́ òun ni láti dí àlàfo àkókò tí ó pàdánù náà kí ó má sì ṣe retí àkànṣe ìgbatẹnirò.
19 Àwọn àkókò máa ń wà nígbà tí aṣáájú ọ̀nà máa ń nírìírí ìyípadà tí kò ṣeé yẹ̀ sílẹ̀ nínú àwọn àyíká ipò rẹ̀. Ó lé rí i pé, fún ìgbà pípẹ́, òun kò lè kúnjú wákàtí tí a ń béèrè, nítorí àìlera tí ń bá a nìṣó, nítorí ẹrù ìdílé tí ó pọ̀ sí i àti bẹ́ẹ̀ bẹ́ẹ̀ lọ. Bí ọ̀ràn bá rí báyìí, ipa ọ̀nà ọgbọ́n yóò jẹ́ láti padà sí òtú akéde kí ó sì máa nípìn-ín nígbàkígbà tí ó bá ṣeé ṣe nínú iṣẹ́ ìsìn aṣáájú ọ̀nà olùrànlọ́wọ́. Kò sí ìpèsè tí a ń ṣe nígbà gbogbo fún jíjẹ́ kí ẹnì kan máa ṣe aṣáájú ọ̀nà nìṣó bí àwọn àyíká ipò rẹ̀ kò bá gbà á láyè mọ́ láti kúnjú wákàtí tí a ń béèrè.
20 A retí pé ìpèsè ti fífún àwọn tí ó bá tóótun ní àkànṣe ìgbatẹnirò yóò fún ọ̀pọ̀ sí i níṣìírí láti forúkọ sílẹ̀ fún iṣẹ́ ìsìn aṣáájú ọ̀nà láìdààmú lọ́nà tí kò yẹ. Ó tún yẹ kí ó fún àwọn tí ó ti wà nínú iṣẹ́ ìsìn alákòókò kíkún níṣìírí láti máa bá ṣíṣe aṣáájú ọ̀nà nìṣó. A fẹ́ kí àwọn aṣáájú ọ̀nà ṣàṣeyọrí nínú iṣẹ́ ìsìn alákòókò kíkún wọn.
ÌBÉÈRÈ 5: “Mo fẹ́ kí ń ṣe nǹkan láṣeparí kí n sì láyọ̀ nígbà tí mo bá ń ṣe é. Iṣẹ́ ìsìn aṣáájú ọ̀nà yóò ha tẹ́ mi lọ́rùn bí?”
21 Ayọ̀ tòótọ́ sinmi gidigidi lórí níní ipò ìbátan tímọ́tímọ́ lẹ́nì kọ̀ọ̀kan pẹ̀lú Jèhófà kí a sì ní ìdánilójú pé a ń fi ìṣòtítọ́ sìn ín. Jésù fara da igi oró “nítorí ìdùnnú tí a gbé ka iwájú rẹ̀.” (Héb. 12:2) Ayọ̀ rẹ̀ wá láti inú ṣíṣe ìfẹ́ Ọlọ́run. (Sm. 40:8) Nínú ètò àwọn nǹkan ìsinsìnyí, a lè gbádùn ayọ̀ tòótọ́ bí ọ̀pọ̀ jù lọ nínú ìgbòkègbodò ìgbésí ayé wa bá ní í ṣe pẹ̀lú ìjọsìn wa sí Jèhófà. Àwọn ìlépa tẹ̀mí ń fún wa ní èrò náà pé a ní ète nítorí nínú wa lọ́hùn-ún, a mọ̀ pé a ń ṣe ohun tí ó tọ́. Ayọ̀ ń wá láti inú fífúnni, a kò sì mọ ọ̀nà mìíràn tí ó sàn jù tí a fi lè fi ara wa fúnni ju láti kọ́ àwọn ẹlòmíràn nípa bí wọ́n ṣe lè jèrè ìyè àìnípẹ̀kun nínú ayé tuntun Ọlọ́run.—Ìṣe 20:35.
22 Aṣáájú ọ̀nà tí a fa ọ̀rọ̀ rẹ̀ yọ ní ìpínrọ̀ àkọ́kọ́ ṣàlàyé rẹ̀ lọ́nà yìí pé: “Ayọ̀ wo ni ó lè ju rírí kí ẹnì kan tí o bá kẹ́kọ̀ọ́ di aláápọn olùyin Jèhófà? Ó ń wúni lórí, ó sì ń fún ìgbàgbọ́ ẹni lókun láti rí bí Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run ti lágbára tó ní sísún àwọn ènìyàn láti ṣe ìyípadà nínú ìgbésí ayé wọn láti lè wu Jèhófà.” (Wo Ilé Ìṣọ́, October 15, 1997, ojú ìwé 18 sí 23.) Nítorí náà, kí ní ń fún ọ láyọ̀? Bí ó bá jẹ́ pé dípò ìgbádùn ìgbà díẹ̀ tí ayé ń fúnni, o mọrírì ṣíṣe ìsapá tí ó wà pẹ́ títí, tí ó sì yẹ, ṣíṣe aṣáájú ọ̀nà yóò fún ọ ní àgbàyanu èrò ṣíṣàṣeyọrí tí yóò mú kí o láyọ̀ ní tòótọ́.
ÌBÉÈRÈ 6: “Bí kì í bá í ṣe ohun tí a béèrè fún ìyè àìnípẹ̀kun, ǹjẹ́ kì í ṣe ọwọ́ mi ló kù sí láti ṣe aṣáájú ọ̀nà tàbí láti má ṣe é?”
23 Ní tòótọ́, ìwọ lo ni ìpinnu ti ṣíṣe aṣáájú ọ̀nà. Jèhófà nìkan ni ó lè mọ bí àyíká ipò rẹ nínú ìgbésí ayé ṣe rí. (Róòmù 14:4) Ó fi ẹ̀tọ́ retí pé kí o sin òun pẹ̀lú gbogbo ọkàn-àyà, ọkàn, èrò-inú, àti okun rẹ. (Máàkù 12:30; Gál. 6:4, 5) Ó fẹ́ràn olùfúnni ọlọ́yàyà, ẹni tí ń sìn ín tìdùnnútìdùnnú, kì í ṣe pẹ̀lú kùnrùngbùn tàbí ìfagbára múni. (2 Kọ́r. 9:7; Kól. 3:23) Ìfẹ́ fún Jèhófà àti fún àwọn ènìyàn tí ń bẹ́ ní ìpínlẹ̀ rẹ ni ó yẹ kí ó jẹ́ ìdí fún sísìn fún àkókò kíkún. (Mát. 9:36-38; Máàkù 12:30, 31) Bí ó bá jẹ́ bí ìmọ̀lára rẹ ṣe rí nìyí, nígbà náà, ó yẹ kí o ronú jinlẹ̀ nípa iṣẹ́ ìsìn aṣáájú ọ̀nà.
24 A retí pé ohun tí a ti là lẹ́sẹẹsẹ níhìn-ín yóò ràn ọ́ lọ́wọ́ láti díwọ̀n àwọn ìfojúsọ́nà rẹ fún ṣíṣe aṣáájú ọ̀nà. O ha lè yí àwọn àyíká ipò rẹ padà láti ṣe aṣáájú ọ̀nà bí? A tẹ kàlẹ́ńdà kan sí ìsàlẹ̀, a pe àkọlé rẹ̀ ní “Ìṣètò Iṣẹ́ Ìsìn Aṣáájú Ọ̀nà Mi Lọ́sọ̀ọ̀sẹ̀.” Wò ó bí o bá lè ṣàkọsílẹ̀ ìṣètò ṣíṣe é múlò kan fún ara rẹ sínú rẹ̀, èyí tí yóò jẹ́ kí o lè máa ní ìpíndọ́gba nǹkan bí wákàtí 23 lọ́sọ̀ọ̀sẹ̀ nínú iṣẹ́ òjíṣẹ́. Lẹ́yìn náà, fi ìgbàgbọ́ àti ìgbẹ́kẹ̀lé rẹ ní kíkún sínú Jèhófà. Pẹ̀lú ìrànwọ́ rẹ̀, ìwọ yóò ṣàṣeyọrí! Ó ti ṣèlérí pé: ‘Èmi yóò tú ìbùkún dà sórí yín ní ti tòótọ́ títí kì yóò fi sí àìní mọ́.’—Mál. 3:10.
25 Nítorí náà, a béèrè pé, “Iṣẹ́ ìsìn aṣáájú ọ̀nà—ǹjẹ́ o lè ṣe é?” Bí o bá lè sọ pé “Bẹ́ẹ̀ ni,” yan déètì kan láti bẹ̀rẹ̀ ṣíṣe aṣáájú ọ̀nà déédéé láìpẹ́, kí ó sì dá ọ lójú pé Jèhófà yóò fi ìgbésí ayé onídùnnú bù kún ọ!
[Àtẹ Ìsọfúnnni tó wà ní ojú ìwé]
(Láti rí bá a ṣe to ọ̀rọ̀ sójú ìwé, wo ìtẹ̀jáde náà gan-an)
Ìṣètò Iṣẹ́ Ìsìn Aṣáájú Ọ̀nà Mi Lọ́sọ̀ọ̀sẹ̀
MONDAY Òwúrọ̀ iṣẹ́ ìsìn pápá
TUESDAY Òwúrọ̀ iṣẹ́ ìsìn pápá
WEDNESDAY Òwúrọ̀ iṣẹ́ ìsìn pápá
THURSDAY Òwúrọ̀ iṣẹ́ ìsìn pápá
FRIDAY Òwúrọ̀ iṣẹ́ ìsìn pápá
SATURDAY Òwúrọ̀ iṣẹ́ ìsìn pápá
SUNDAY Òwúrọ̀ iṣẹ́ ìsìn pápá
MONDAY Ọ̀sán iṣẹ́ ìsìn pápá
TUESDAY Ọ̀sán iṣẹ́ ìsìn pápá
WEDNESDAY Ọ̀sán iṣẹ́ ìsìn pápá
THURSDAY Ọ̀sán iṣẹ́ ìsìn pápá
FRIDAY Ọ̀sán iṣẹ́ ìsìn pápá
SATURDAY Ọ̀sán iṣẹ́ ìsìn pápá
SUNDAY Ọ̀sán iṣẹ́ ìsìn pápá
MONDAY Ìrọ̀lẹ́ iṣẹ́ ìsìn pápá
TUESDAY Ìrọ̀lẹ́ iṣẹ́ ìsìn pápá
WEDNESDAY Ìrọ̀lẹ́ iṣẹ́ ìsìn pápá
THURSDAY Ìrọ̀lẹ́ iṣẹ́ ìsìn pápá
FRIDAY Ìrọ̀lẹ́ iṣẹ́ ìsìn pápá
SATURDAY Ìrọ̀lẹ́ iṣẹ́ ìsìn pápá
SUNDAY Ìrọ̀lẹ́ iṣẹ́ ìsìn pápá
Lo pẹ́ńsù láti ṣàkọsílẹ̀ ìṣètò rẹ fún ọjọ́ kọ̀ọ̀kan nínú ọ̀sẹ̀.
Ṣètò àròpọ̀ nǹkan bí wákàtí 23 lọ́sẹ̀ nínú iṣẹ́ ìsìn pápá.
Àròpọ̀ wákàtí tí mo ṣètò lọ́sẹ̀ ․․․․․․․․․․․․․․․․․․․․