“O Lè Ṣe Aṣáájú-Ọ̀nà!”
1. Kí ni arábìnrin kan tó jẹ́ aṣáájú-ọ̀nà sọ?
1 Arábìnrin Kathe B. Palm sọ pé, “Kò sí iṣẹ́ míì tó lè fi mí lọ́kàn balẹ̀ tàbí tó máa jẹ́ kí n túbọ̀ sún mọ́ Ọlọ́run bí iṣẹ́ aṣáájú-ọ̀nà.” Arábìnrin yìí ti fi ọ̀pọ̀ ẹ̀wádún yọ̀ǹda ara rẹ̀ gẹ́gẹ́ bí aṣáájú-ọ̀nà, ó wàásù káàkiri orílẹ̀-èdè Chile, ìyẹn ní Amẹ́ríkà ti Gúúsù. Ó ṣeé ṣe kí ẹnì kan ti ronú nípa bí ìgbésí ayé àwọn tó ń ṣe iṣẹ́ ìsìn alákòókò kíkún ṣe máa ń nítumọ̀, kí onítọ̀hún sì wá sọ fún ọ pé: “O lè ṣe aṣáájú-ọ̀nà!”
2. Ṣàlàyé ìdí tí ọkàn èèyàn fi máa ń balẹ̀ tó bá ń lọ́wọ́ sí àwọn ìgbòkègbodò tẹ̀mí.
2 Ìgbé Ayé Tó Ń Fini Lọ́kàn Balẹ̀: Jésù, tó jẹ́ Àwòfiṣàpẹẹrẹ wa rí ojúlówó ìtura nínú ṣíṣe ìfẹ́ Baba rẹ̀. (Jòh. 4:34) Torí náà, òótọ́ ló sọ nígbà tó kọ́ àwọn ọmọlẹ́yìn rẹ̀ pé ojúlówó ìtẹ́lọ́rùn máa ń wá látinú lílọ́wọ́ sí àwọn ìgbòkègbodò tó jẹ mọ́ ìjọsìn Jèhófà. Ọkàn wa á balẹ̀, bá a bá ń fi ìgbésí ayé wa ṣe àwọn iṣẹ́ tó máa mú kí inú Ọlọ́run dùn sí wa. Yàtọ̀ síyẹn, bá a bá túbọ̀ ń lo àkókò wa, okun wa àtàwọn ohun ìní wa láti fi ran àwọn ẹlòmíì lọ́wọ́, ṣe ni ayọ̀ wa á túbọ̀ máa pọ̀ sí i.—Ìṣe 20:31, 35.
3. Ayọ̀ wo la máa ní bá a bá túbọ̀ ń kópa nínú iṣẹ́ ìwàásù?
3 Bá a bá ṣe ń kópa nínú iṣẹ́ ìwàásù tó, bẹ́ẹ̀ la ó ṣe túbọ̀ máa rí ayọ̀ tó wà nínú kíkọ́ àwọn èèyàn lẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì. Kódà láwọn ibi tí ọ̀pọ̀ èèyàn ti máa ń dágunlá sí iṣẹ́ ìwàásù, iṣẹ́ wa lè túbọ̀ méso jáde ju bá a ṣe kọ́kọ́ rò lọ, bá a bá ṣe túbọ̀ ń kópa nínú iṣẹ́ náà, tá a sì ń lo oríṣiríṣi ọgbọ́n lẹ́nu iṣẹ́ òjíṣẹ́ wa. Àwọn aṣáájú-ọ̀nà lè lo ẹ̀kọ́ ṣíṣeyebíye tí wọ́n ti kọ́ ní Ilé Ẹ̀kọ́ Aṣáájú-Ọ̀nà, ìyẹn ilé ẹ̀kọ́ tí wọ́n máa ń lọ lẹ́yìn tí wọ́n bá ti lo nǹkan bí ọdún kan lẹ́nu iṣẹ́ aṣáájú-ọ̀nà. (2 Tím. 2:15) Bá ò bá jẹ́ kó rẹ̀ wá, a lè tipa bẹ́ẹ̀ gbin irúgbìn òtítọ́ tó máa méso jáde nígbà tó bá yá.—Oníw. 11:6.
4. Kí ló yẹ kí àwọn ọ̀dọ́ tí wọn ò ní pẹ́ jáde iléèwé ronú lé lórí?
4 Ẹ̀yin Ọ̀dọ́: Ǹjẹ́ ẹ ti ronú nípa ohun tẹ́ ẹ máa fi ìgbésí ayé yín ṣe tẹ́ ẹ bá parí ilé ìwé girama? Ní báyìí, iṣẹ́ ilé ìwé ló ń gba èyí tó pọ̀ jù lọ nínú àkókò yín. Kí lẹ ó máa wá fi àkókò yín ṣe lẹ́yìn tẹ́ ẹ bá parí iléèwé? Dípò tẹ́ ẹ ó fi jẹ́ kí iṣẹ́ ajé gbà yín lọ́kàn, ẹ ò ṣe fi ọ̀rọ̀ ṣíṣe iṣẹ́ aṣáájú-ọ̀nà déédéé sínú àdúrà? Àwọn nǹkan tẹ́ ẹ máa kọ́ lẹ́nu iṣẹ́ aṣáájú-ọ̀nà máa wúlò fún yín jálẹ̀ ìgbésí ayé yín, ìyẹn àwọn nǹkan bíi wíwàásù fún àwọn tó wá láti ibi tó yàtọ̀ síra, bẹ́ ẹ ṣe lè borí àwọn ìdíwọ́, bẹ́ ẹ ṣe lè máa fi nǹkan kọ́ra àti bẹ́ ẹ ṣe lè kọ́ àwọn èèyàn lẹ́kọ̀ọ́ lọ́nà tó múná dóko.
5. Báwo ni àwọn òbí àti ìjọ lápapọ̀ ṣe lè mú kí ìfẹ́ láti ṣe aṣáájú-ọ̀nà gbilẹ̀?
5 Ẹ̀yin òbí, ṣé ẹ̀ ń ṣe ohun tó yẹ kẹ́ ẹ ṣe láti ran àwọn ọmọ yín lọ́wọ́ kí wọ́n lè ṣe iṣẹ́ ìsìn alákòókò kíkún? Ọ̀rọ̀ yín àti àpẹẹrẹ rere tẹ́ ẹ bá ń fi lélẹ̀ máa ṣèrànwọ́ gan-an láti jẹ́ kí àwọn ọmọ yín lè fi ire Ìjọba Ọlọ́run sí ipò kìíní. (Mát. 6:33) Arákùnrin Ray, tó bẹ̀rẹ̀ iṣẹ́ aṣáájú-ọ̀nà bó ṣe ń parí ilé ìwé girama sọ pé: “Gbogbo ìgbà ni mọ́mì mi máa ń sọ pé iṣẹ́ aṣáájú-ọ̀nà ni iṣẹ́ tó ń fini lọ́kàn balẹ̀ jù lọ ní ìgbésí ayé.” Gbogbo àwọn ará nínú ìjọ lè mú kí ìfẹ́ láti ṣe iṣẹ́ aṣáájú-ọ̀nà gbilẹ̀ nínú ìjọ nípasẹ̀ ọrọ̀ àti ìtìlẹyìn wọn. Arákùnrin Jose láti orílẹ̀-èdè Sípéènì sọ pé: “Àwọn ará nínú ìjọ wa gbà pé iṣẹ́ aṣáájú-ọ̀nà ni iṣẹ́ tó dára jù lọ tí àwa ọ̀dọ́ lè ṣe. Àwọn ọ̀rọ̀ tí wọ́n máa ń sọ àti bí wọ́n ṣe mọyì iṣẹ́ ìsìn aṣáájú-ọ̀nà títí kan ìrànlọ́wọ́ tí wọ́n ṣe fún mi ló jẹ́ kó rọrùn fún mi láti bẹ̀rẹ̀ iṣẹ́ aṣáájú-ọ̀nà.”
6. Kí la lè ṣe bí iṣẹ́ aṣáájú-ọ̀nà kò bá wù wá ní báyìí?
6 Bó O Ṣe Lè Borí Ìdènà: Kí lo lè ṣe bó bá dà bíi pé kò kàn wù ẹ́ láti ṣe iṣẹ́ aṣáájú-ọ̀nà? O ò ṣe sọ bí ọ̀rọ̀ náà ṣe rí lára rẹ fún Jèhófà, kó o sọ fún un pé, ‘Mi ò mọ̀ bóyá èmi náà lè ṣe aṣáájú-ọ̀nà o, àmọ́ mo fẹ́ ṣe ohun tí inú rẹ máa dùn sí.’ (Sm. 62:8; Òwe 23:26) Lẹ́yìn náà, kó o wá ìtọ́sọ́nà Ọlọ́run nínú Ọ̀rọ̀ rẹ̀ àti ètò rẹ̀. Ọ̀pọ̀ aṣáájú-ọ̀nà déédéé ló ti kọ́kọ́ ‘tọ́ iṣẹ́ aṣáájú-ọ̀nà olùrànlọ́wọ́ wò,’ ayọ̀ tí wọ́n sì rí nínú rẹ̀ mú kí wọ́n fi iṣẹ́ ìsìn alákòókò kíkún ṣe iṣẹ́ ìgbésí ayé wọn.—Sm. 34:8.
7. Báwo la ṣe lè borí iyèméjì, tá a bá ń ronú pé bóyá la máa lè dójú ìlà àádọ́rin wákàtí tí ètò Ọlọ́run ń béèrè lọ́wọ́ àwọn aṣáájú-ọ̀nà?
7 Bí kò bá dá ẹ lójú pé wàá lè dójú ìlà àádọ́rin [70] wákàtí tí à ń béèrè lọ́wọ́ aṣáájú-ọ̀nà ńkọ́? O ò ṣe jíròrò ọ̀rọ̀ náà pẹ̀lú àwọn aṣáájú-ọ̀nà tí ipò wọn jọ tìẹ? (Òwe 15:22) Lẹ́yìn náà, ṣàkọsílẹ̀ onírúurú ètò tó o lè máa tẹ̀ lé. Ó ṣeé ṣe kó o wá rí i pé ó máa rọrùn fún ẹ ju bó o ṣe rò tẹ́lẹ̀ lọ láti ra àkókò pa dà nínú àwọn ohun tí kò fi bẹ́ẹ̀ ṣe pàtàkì, kó o sì wá máa lo àkókò náà lẹ́nu iṣẹ́ òjíṣẹ́.—Éfé. 5:15, 16.
8. Kí nìdí tó fi yẹ ká máa ṣàgbéyẹ̀wò ipò wa látìgbàdégbà?
8 Tún Ọ̀rọ̀ Náà Gbé Yẹ̀ Wò: Àwọn nǹkan kan sábà máa ń yí pa dà nígbèésí ayé ẹni. Á dáa kó o máa ṣàgbéyẹ̀wò ipò rẹ látìgbàdégbà. Bí àpẹẹrẹ, ǹjẹ́ àkókò tó o máa fẹ̀yìn tì lẹ́nu iṣẹ́ oúnjẹ òòjọ́ ti ń sún mọ́? Arákùnrin Randy tó tètè fẹ̀yìn tì lẹ́nu iṣẹ́ oúnjẹ òòjọ́ sọ pé: “Ìpinnu tí mo ṣe yìí ti jẹ́ kó ṣeé ṣe fún èmi àti ìyàwó mi láti bẹ̀rẹ̀ iṣẹ́ aṣáájú-ọ̀nà, èyí sì ti jẹ́ ká láǹfààní láti lọ sìn ní ibi tí wọ́n ti nílò àwọn oníwàásù púpọ̀ sí i. Àwọn ìbùkún tí mo ti ní látàrí ìpinnu tí mo ṣe yìí kò lóǹkà, àmọ́ ìbùkún tó ju gbogbo rẹ̀ lọ ni ẹ̀rí ọkàn rere tí mo ní.”
9. Kí ló yẹ kí àwọn tọkọtaya ronú lé lórí?
9 Lẹ́yìn tí àwọn tọkọtaya kan fara balẹ̀ ṣàyẹ̀wò ipò wọn dáadáa, wọ́n wá rí i pé, kò pọn dandan pé kí àwọn méjèèjì máa lo àkókò púpọ̀ lẹ́nu iṣẹ́ oúnjẹ òòjọ́. Òótọ́ ni pé, èyí lè gba pé kí ìdílé náà jẹ́ kí ìwọ̀nba ohun ìní tara tẹ́ wọn lọ́rùn, àmọ́, ó tó bẹ́ẹ̀, ó jù bẹ́ẹ̀ lọ. Arákùnrin John, tí ìyàwó rẹ̀ fi iṣẹ́ oúnjẹ òòjọ́ tó ń gba ọ̀pọ̀ àkókò sílẹ̀ kó lè máa lo àkókò púpọ̀ sí i lẹ́nu iṣẹ́ òjíṣẹ́, sọ pé: “Inú mi máa ń dùn gan-an pé ẹnu iṣẹ́ ìsìn Jèhófà ni ìyàwó mi máa ń wà látàárọ̀ ṣúlẹ̀.”
10. Kí ló ń mú kí àwa Kristẹni fẹ́ láti ṣe aṣáájú-ọ̀nà?
10 Ó Ń Fi Hàn Pé A Ní Ìfẹ́ àti Ìgbàgbọ́: Jèhófà ti mú kí iṣẹ́ ìwàásù ṣe pàtàkì ju ohunkóhun mìíràn tí ẹnì kọ̀ọ̀kan wa lè ṣe. Ètò ògbólógbòó yìí kò ní pẹ́ pa run, àwọn tó bá ń ké pe orúkọ Jèhófà nìkan sì ni a óò gbà là. (Róòmù 10:13) Tá a bá nífẹ̀ẹ́ Jèhófà dáadáa, tá a sì mọyì àwọn ohun tó ti ṣe fún wa, èyí á mú ká ṣègbọràn sí àṣẹ tí Ọmọ rẹ̀ pa fún wa pé ká máa fìtara wàásù. (Mát. 28:19, 20; 1 Jòh. 5:3) Bákan náà, tá a bá gbà gbọ́ pé òótọ́ là ń gbé ní àwọn ọjọ́ ìkẹyìn, èyí á jẹ́ ká máa ṣe gbogbo ohun tá a bá lè ṣe lẹ́nu iṣẹ́ ìwàásù nígbà tí àkókò ṣì wà, dípò tí a óò fi máa lo ayé dé ẹ̀kún rẹ́rẹ́.—1 Kọ́r. 7:29-31.
11. Bí ẹnì kan bá sọ fún wa pé a lè ṣe aṣáájú-ọ̀nà, irú ojú wo ló yẹ ká fi wo ọ̀rọ̀ náà?
11 Ṣíṣe aṣáájú-ọ̀nà kọjá pé kéèyàn kàn máa lo iye wákàtí kan pàtó tí ètò Ọlọ́run ń béèrè lẹ́nu iṣẹ́ ìwàásù, ó jẹ́ ọ̀nà kan láti fi hàn pé à ń fọkàn sin Ọlọ́run. Torí náà, bí ẹnì kan bá sọ fún ẹ pé o lè ṣe aṣáájú-ọ̀nà, ṣe ni kó o ka ọ̀rọ̀ náà sí pàtàkì. Ronú lé e lórí, kó o sì gbàdúrà pé kí Jèhófà ràn ẹ́ lọ́wọ́, kó o lè dara pọ̀ mọ́ àwọn tó ń ṣe iṣẹ́ ìsìn tó ń fini lọ́kàn balẹ̀ yìí.
[Ìsọfúnni tá a pàfiyèsí sí ní ojú ìwé 4]
Ẹ̀yin òbí, ṣé ẹ̀ ń ṣe ohun tó yẹ kẹ́ ẹ ṣe láti ran àwọn ọmọ yín lọ́wọ́ kí wọ́n lè ṣe iṣẹ́ ìsìn alákòókò kíkún?
[Ìsọfúnni tá a pàfiyèsí sí ní ojú ìwé 5]
Jèhófà ti mú kí iṣẹ́ ìwàásù ṣe pàtàkì ju ohunkóhun mìíràn tí ẹnì kọ̀ọ̀kan wa lè ṣe.