Ìsinsìnyí Ló Yẹ Ká Wàásù!
1. Kí nìdí tó fi jẹ́ pé ìsinsìnyí ló yẹ ká wàásù?
1 Bí áńgẹ́lì Ọlọ́run ti ń darí wa, à ń wàásù “fún gbogbo orílẹ̀-èdè àti ẹ̀yà àti ahọ́n àti ènìyàn” pé, “ẹ bẹ̀rù Ọlọ́run, kí ẹ sì fi ògo fún un.” Kí nìdí tá a fi ń wàásù bẹ́ẹ̀? “Nítorí wákàtí ìdájọ́ láti ọwọ́ [Ọlọ́run] ti dé.” Lóde òní, à ń gbé ní “wákàtí ìdájọ́” yẹn, èyí tí yóò wá sópin nígbà ìparun ètò àwọn nǹkan ìsinsìnyí. Ó ṣe pàtàkì pé káwọn èèyàn máa “jọ́sìn Ẹni tí ó dá ọ̀run àti ilẹ̀ ayé àti òkun àti àwọn ìsun omi.” Kò sí iṣẹ́ míì tá à ń ṣe lónìí tó tún ṣe pàtàkì, tó sì jẹ́ kánjúkánjú bíi pípolongo “ìhìn rere àìnípẹ̀kun.” Ìyẹn gan-an ló fi jẹ́ pé ìsinsìnyí ló yẹ ká wàásù!—Ìṣí. 14:6, 7.
2. Báwo làwọn ìránṣẹ́ Jèhófà ṣe ń fi hàn pé àwọn mọ̀ pé àkókò kánjúkánjú là ń gbé?
2 Láti ọdún mẹ́wàá sẹ́yìn, àwọn ìránṣẹ́ Jèhófà ti lo nǹkan bíi bílíọ̀nù méjìlá wákàtí lẹ́nu iṣẹ́ ìwàásù Ìjọba Ọlọ́run àti sísọni di ọmọ ẹ̀yìn. Ọ̀pọ̀ ti yí ìgbésí ayé wọn padà kí wọ́n lè túbọ̀ máa kópa sí i nínú iṣẹ́ ìkórè tẹ̀mí. (Mát. 9:37, 38) Bí àpẹẹrẹ, lọ́dún tó kọjá, ó tó akéde ọ̀kẹ́ méjìlélógójì ó lé ẹgbàárùn-ún [850,000] tó ṣe iṣẹ́ aṣáájú ọ̀nà lóṣooṣù. Àádọ́rin wákàtí làwọn aṣáájú ọ̀nà déédéé fi ń wàásù lóṣooṣù, nígbà táwọn aṣáájú ọ̀nà olùrànlọ́wọ́ sì ń fi àádọ́ta wákàtí wàásù lóṣooṣù.
3. Kí ni ìyípadà táwọn akéde sábà máa ń ṣe kí wọ́n bàa lè ṣe iṣẹ́ aṣáájú ọ̀nà?
3 Béèyàn Ṣe Lè Di Aṣáájú Ọ̀nà: Nítorí pé àwọn aṣáájú ọ̀nà mọ̀ pé “àkókò tí ó ṣẹ́ kù ti dín kù,” wọ́n máa ń sapá láti gbé ìgbésí ayé ṣe-bó-o-ti-mọ. (1 Kọ́r. 7:29, 31) Wọ́n máa ń wá ọ̀nà tí wọ́n lè gbà dín owó tí wọ́n ń ná kù kí àkókò tí wọ́n fi ń ṣiṣẹ́ oúnjẹ òòjọ́ lè dín kù sí i. Bí àpẹẹrẹ, àwọn kan ti kó lọ sínú ilé tí kò tó èyí tí wọ́n ń gbé tẹ́lẹ̀. Àwọn kan sì ti dín àwọn ohun ìní tara tí kò pọn dandan kù. (Mát. 6:19-21) Lọ́pọ̀ ìgbà, wọ́n ní láti jáwọ́ nínú àwọn nǹkan tí wọ́n fẹ́ gbé ṣe. Ìdí tí wọ́n sì fi ń ṣe gbogbo èyí ni kí àkókò tí wọn yóò máa lò lẹ́nu iṣẹ́ òjíṣẹ́ lè pọ̀ sí i. (Éfé. 5:15, 16) Nítorí pé ọ̀pọ̀ akéde ò káàárẹ̀, tí wọ́n lo ẹ̀mí ìfara-ẹni-rúbọ, tí wọn ò sì yé gbàdúrà sí Jèhófà fún ìrànlọ́wọ́, ó ti ṣeé ṣe fún wọn láti ṣètò àkókò wọn débi tí wọ́n fi lè ṣe iṣẹ́ aṣáájú ọ̀nà.
4. Bó o bá fẹ́ di aṣáájú ọ̀nà, àwọn nǹkan wo ló máa dára pé kó o ṣe?
4 Ṣé ìwọ náà lè ṣe iṣẹ́ aṣáájú ọ̀nà? O ò ṣe bá àwọn tó ti wà lẹ́nu iṣẹ́ náà sọ̀rọ̀, kó o bàa lè mọ bí wọ́n ṣe ń ṣe é? Bá wọn ṣiṣẹ́ lóde ẹ̀rí, kó o sì láyọ̀ bíi tiwọn. Fara balẹ̀ ka àwọn àpilẹ̀kọ tó dá lórí iṣẹ́ aṣáájú ọ̀nà nínú àwọn ìtẹ̀jáde wa. Ní àfojúsùn tó o lè lé bá, táá sì lè ràn ọ́ lọ́wọ́ láti di aṣáájú ọ̀nà. Bí àwọn nǹkan kan bá ń dí ọ lọ́wọ́ báyìí tí kò lè jẹ́ kó o ṣe aṣáájú ọ̀nà, kó wọn tọ Jèhófà lọ nínú àdúrà, kó o sì bẹ̀ ẹ́ pé kó ràn ọ́ lọ́wọ́ láti mú wọn kúrò.—Òwe 16:3.
5. Báwo ni iṣẹ́ aṣáájú ọ̀nà ṣe lè ràn wá lọ́wọ́ láti túbọ̀ jáfáfá nínú iṣẹ́ òjíṣẹ́ wa?
5 Ìbùkún àti Ayọ̀: Iṣẹ́ aṣáájú ọ̀nà máa ń mú ká túbọ̀ di ọ̀jáfáfá nínú lílo Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run, bá a bá sì mọ Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run lò, ńṣe láá mú kí ayọ̀ wa máa kún sí i. Ọ̀dọ́bìnrin aṣáájú ọ̀nà kan sọ pé: “Ìbùkún ńlá gbáà ni kéèyàn mọ bá a ṣeé lo Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run dáadáa. Béèyàn bá ń ṣe aṣáájú ọ̀nà, á máa lo Bíbélì lemọ́lemọ́. Ní báyìí, bí mo bá ń wàásù láti ilé dé ilé, mo lè ronú nípa àwọn ẹsẹ Ìwé Mímọ́ tó bá ipò onílé kọ̀ọ̀kan mu.”—2 Tím. 2:15.
6. Ẹ̀kọ́ wo lèèyàn máa ń rí kọ́ lẹ́nu iṣẹ́ aṣáájú ọ̀nà?
6 Iṣẹ́ aṣáájú ọ̀nà tún máa ń kọ́ni ní ọ̀pọ̀ nǹkan tó lè wúlò nígbèésí ayé. Ó lè ran àwọn ọ̀dọ́ lọ́wọ́ láti mọ bá a ti í fọgbọ́n ṣètò àkókò ẹni, bá a ṣeé ṣúnwó ná àti bá a ṣeé báwọn èèyàn gbé láìjà láìta. Iṣẹ́ aṣáájú ọ̀nà tí ọ̀pọ̀ èèyàn ń ṣe ló mú kí wọ́n túbọ̀ máa fojú tó bá Bíbélì mu wo ìgbésí ayé. (Éfé. 4:13) Síwájú sí i, àwọn aṣáájú ọ̀nà tún máa ń láǹfààní láti rí bí Jèhófà ṣe ń bù kún iṣẹ́ ọwọ́ wọn.—Ìṣe 11:21; Fílí. 4:11-13.
7. Báwo ni iṣẹ́ aṣáájú ọ̀nà ṣe lè ràn wá lọ́wọ́ láti sún mọ́ Jèhófà?
7 Àfàìmọ̀ ni kì í ṣe pé ọ̀kan lára ìbùkún títóbi jù lọ téèyàn ń rí nínú iṣẹ́ aṣáájú ọ̀nà ni pé ó ń ranni lọ́wọ́ láti sún mọ́ Jèhófà. Èyí lè gbé wa ró jálẹ̀ àkókò tá a bá ń dojú kọ àdánwò. Arábìnrin kan tó fara da ìṣòro líle koko sọ pé: “Àjọṣe tímọ́tímọ́ tí iṣẹ́ aṣáájú ọ̀nà ti mú kí n ní pẹ̀lú Jèhófà ló ràn mí lọ́wọ́ láti kógo já.” Ó fi kún ọ̀rọ̀ rẹ̀ pé: “Inú mi dùn gan-an pé mo ti lo ìgbà ìbàlágà mi láti sin Jèhófà gẹ́gẹ́ bí òjíṣẹ́ alákòókò kíkún. Ó ti mú kó ṣeé ṣe fún mi láti lo ara mi ní onírúurú ọ̀nà tí mi ò rò tì.” (Ìṣe 20:35) Ǹjẹ́ kí àwa náà rí ọ̀pọ̀ ìbùkún bá a ti ń ṣe gbogbo ohun tá a lè ṣe lẹ́nu iṣẹ́ ìwàásù tó ṣe pàtàkì náà.—Òwe 10:22.