Ṣé Wàá Gba Ẹnu Ọ̀nà “Ńlá Tí Ń Ṣamọ̀nà sí Ìgbòkègbodò” Wọlé?
1. “Ilẹ̀kùn ńlá tí ń ṣamọ̀nà sí ìgbòkègbodò” wo ló ṣí sílẹ̀ fún wa?
1 Nígbà tí “ilẹ̀kùn ńlá tí ń ṣamọ̀nà sí ìgbòkègbodò” ṣí sílẹ̀ fún àpọ́sítélì Pọ́ọ̀lù, kò jáfara láti gbá àǹfààní náà mú, èyí tó jẹ́ kó lè máa wàásù nìṣó láìfi ti ọ̀pọ̀ àwọn alátakò pè. (1 Kọ́r. 16:9) Lónìí, nǹkan bí ọ̀kẹ́ méjìlélọ́gbọ̀n ó lé ẹgbàá [642,000] oníwàásù ló wà kárí ayé tí wọ́n ti gba ẹnu ọ̀nà ńlá tí ń ṣamọ̀nà sí ìgbòkègbodò wọlé nípa gbígbaṣẹ́ aṣáájú-ọ̀nà déédéé.
2. Kí nìdí tó fi bọ́gbọ́n mu pé ká máa ṣàyẹ̀wò ipò wa lóòrèkóòrè?
2 Bí Ipò Àwọn Nǹkan Bá Yí Padà: Bó tilẹ̀ jẹ́ pé ipò tí kálukú wa wà lè má lè jẹ́ ká ṣe tó bá a ṣe fẹ́, síbẹ̀ ipò yẹn lè yí padà. Nítorí náà, ó bọ́gbọ́n mu pé ká máa ṣàyẹ̀wò ipò tiwa fúnra wa lóòrèkóòrè dípò tá a ó fi máa dúró dìgbà tí gbogbo nǹkan á rí bá a ṣe fẹ́. (Oníw. 11:4) Ṣé ọ̀dọ́ tó ti fẹ́rẹ̀ẹ́ kẹ́kọ̀ọ́ yege ni ẹ́? Ṣé òbí tó ní ọmọ tó máa tó bẹ̀rẹ̀ ilé ìwé ni ẹ́? Ṣé kò ní pẹ́ mọ́ tó o fi máa fẹ̀yìn tì lẹ́nu iṣẹ́? Irú àwọn àyípadà yìí lè jẹ́ kó o túbọ̀ ní àkókò tó pọ̀ sí i tó o lè lò láti máa fi ṣiṣẹ́ aṣáájú-ọ̀nà déédéé. Arábìnrin ẹni ọdún mọ́kàndínláàádọ́rùn-ún kan tó ṣòjòjò láìpẹ́ yìí pinnu láti gbaṣẹ́ aṣáájú-ọ̀nà. Èé ṣe? Ó gbà pé ara òun ti mókun tó láti gbaṣẹ́ aṣáájú-ọ̀nà níwọ̀n ìgbà tó ti lé lọ́dún kan tóun ti gbúròó àìsàn náà kẹ́yìn.
3. Àyípadà wo làwọn kan ti ṣe kí wọ́n bàa lè gbaṣẹ́ aṣáájú-ọ̀nà?
3 Bákan náà, ìgbà kan wà tí Pọ́ọ̀lù ní in lọ́kàn pé òun á bẹ àwọn ará tó wà ní Kọ́ríńtì wò. Àmọ́ nítorí ìhìn rere, ó fi ìbẹ̀wò náà sí àkókò mìíràn. Ọ̀pọ̀ àyípadà làwọn tó jẹ́ aṣáájú-ọ̀nà lónìí ti ṣe nínú ìgbòkègbodò wọn kí wọ́n tó lè di aṣáájú-ọ̀nà. Ìgbésí ayé tó wà níwọ̀ntúnwọ̀nsì táwọn kan lára wọn ń gbé ti mú kí àbọ̀ṣẹ́ tó wọn gbọ́ bùkátà wọn. Inú wọn sì máa ń dùn nítorí àǹfààní iṣẹ́ ìsìn tí wọ́n ní. (1 Tím. 6:6-8) Àwọn tọkọtaya kan ti ṣe àyípadà débi pé ọkọ nìkan ló ń ṣiṣẹ́, wọ́n sì jẹ́ kí ìwọ̀nba owó tó ń wọlé tó wọn gbọ́ bùkátà ìdílé wọn, èyí sì ti mú kó ṣeé ṣe fún aya láti ṣe aṣáájú-ọ̀nà.
4. Kí la lè ṣe bí kò bá dá wa lójú pé a lè máa ní iye wákàtí tí aṣáájú-ọ̀nà gbọ́dọ̀ ròyìn?
4 Má ṣe tìtorí pé o lè má lè bá wákàtí tí aṣáájú-ọ̀nà ń ròyìn kó o wá yára gbé èrò gbígbaṣẹ́ aṣáájú-ọ̀nà kúrò lọ́kàn. Bó o bá lè máa ní wákàtí méjì àti díẹ̀ lóòjọ́, àbùṣe bùṣe. Bí kò bá dá ẹ lójú pé wàá lè ní wákàtí méjì lóòjọ́, ìwọ gba aṣáájú-ọ̀nà olùrànlọ́wọ́ fún oṣù kan tàbí méjì kó o sì pinnu lọ́kàn ara ẹ láti ní àádọ́rin wákàtí. Èyí á jẹ́ kíwọ náà tọ́ ayọ̀ tó wà nínú gbígbaṣẹ́ aṣáájú-ọ̀nà wò. (Sm. 34:8) Kódà, o lè fọ̀rọ̀ jomi toro ọ̀rọ̀ pẹ̀lú àwọn tó ṣì wà lẹ́nu iṣẹ́ aṣáájú-ọ̀nà. Ó ṣeé ṣe káwọn náà ti fìgbà kan rí la ìṣòro tó jọ èyí tó ò ń dojú kọ báyìí kọjá. (Òwe 15:22) Bẹ Jèhófà pé kó fìbùkún sí ìsapá rẹ láti fi kún ìwọ̀n tó ò ń ṣe nínú iṣẹ́ òjíṣẹ́ náà.—1 Jòh. 5:14.
5. Kí nìdí tí iṣẹ́ aṣáájú-ọ̀nà déédéé fi jẹ́ iṣẹ́ tó yẹ kéèyàn fi ìgbésí ẹ̀ ṣe?
5 Iṣẹ́ Tó Yẹ Kéèyàn Fi Ìgbésí Ayé Ẹ̀ Ṣe: Àǹfààní tó wà nídìí iṣẹ́ aṣáájú-ọ̀nà déédéé pọ̀. Ó máa mú kí ayọ̀ rẹ kún àkúnwọ́sílẹ̀ bó o bá ṣe ń sọ fífúnni dàṣà. (Ìṣe 20:35) Iṣẹ́ aṣáájú-ọ̀nà á mú kó o mọ bó o ṣe lè fi ọwọ́ tó tọ̀nà mú Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run. (2 Tím. 2:15) Ó máa mú kó o túbọ̀ ní àǹfààní láti rí ọwọ́ Jèhófà nínú ìgbésí ayé ẹ. (Ìṣe 11:21; Fílí. 4:11-13) Iṣẹ́ aṣáájú-ọ̀nà á tún mú kó o ní àwọn ànímọ́ tí Ọlọ́run fẹ́, ọ̀kan lára wọn ni ìfaradà, èyí táá mú kó o sún mọ́ Jèhófà pẹ́kípẹ́kí. (Ják. 4:8) Ṣé wàá gba ẹnu ọ̀nà ńlá tí ń ṣamọ̀nà sí ìgbòkègbodò tó ṣí sílẹ̀ yìí kó o bàa lè di aṣáájú-ọ̀nà déédéé?