Àtúnyẹ̀wò Ilé Ẹ̀kọ́ Ìjọba Ọlọ́run
Àwọn ìbéèrè àtúnyẹ̀wò tó wà nísàlẹ̀ yìí la óò gbé yẹ̀ wò ní Ilé Ẹ̀kọ́ Ìjọba Ọlọ́run lọ́sẹ̀ tó bẹ̀rẹ̀ ní June 25, 2007. Alábòójútó ilé ẹ̀kọ́ yóò darí àtúnyẹ̀wò yìí fún ọgbọ̀n ìṣẹ́jú, èyí tó dá lórí àwọn iṣẹ́ ilé ẹ̀kọ́ tá a ṣe lọ́sẹ̀ May 7 sí June 25, 2007. [Àkíyèsí: Níbi tá ò bá ti sọ ibi tá a ti mú ìdáhùn jáde lẹ́yìn ìbéèrè kan, kó o ṣe ìwádìí láti wá ìdáhùn sí ìbéèrè náà.—Wo ìwé Ilé Ẹ̀kọ́ Ìjọba Ọlọ́run, ojú ìwé 36 àti 37.]
ÀNÍMỌ́ Ọ̀RỌ̀ SÍSỌ
1. Nígbà tá a bá ń sọ̀rọ̀, báwo la ṣe lè dín àyà jíjá kù kí ohùn wa bàa lè dún ketekete? [be-YR ojú ìwé 184 ìpínrọ̀ 3 sí ojú ìwé 185 ìpínrọ̀ 2]
2. Báwo la ṣe lè “di ohun gbogbo fún ènìyàn gbogbo” nígbà tá a bá wà lóde ẹ̀rí? (1 Kọ́r. 9:20-23) [be-YR ojú ìwé 186 ìpínrọ̀ 2 sí 4]
3. Báwo la ṣe máa tẹ̀ lé àpẹẹrẹ Jèhófà nípa fífetísílẹ̀ sáwọn èèyàn nígbà tí wọ́n bá ń sọ̀rọ̀? (Jẹ́n. 18:23-33;1 Ọba 22:19-22) [be-YR ojú ìwé 187 ìpínrọ̀ 1 sí 2 àti 5]
4. Onírúurú ọ̀nà wo la lè gbà ran àwọn ẹlòmíì lọ́wọ́ láti tẹ̀ síwájú nínú ọ̀nà tí wọ́n gbà ń jọ́sìn Ọlọ́run? [be-YR ojú ìwé 187 ìpínrọ̀ 6 sí ojú ìwé 188 ìpínrọ̀ 3]
5. Kí nìdí tá a fi ní láti fọwọ́ pàtàkì mú fífi ọ̀wọ̀ àwọn èèyàn wọ̀ wọ́n? [be-YR ojú ìwé 190 ìpínrọ̀ 3 àti àpótí]
IṢẸ́ AKẸ́KỌ̀Ọ́ KÌÍNÍ
6. Kí nìdí tá a fi gbọ́dọ̀ rí i pé ọ̀rọ̀ wa wọ àwọn tá à ń kọ́ lọ́kàn? [be-YR ojú ìwé 59 ìpínrọ̀ 1]
7. Ipa wo ni àpẹẹrẹ tá à ń fi lélẹ̀ ń ní lórí àwọn tá à ń kọ́ lẹ́kọ̀ọ́? [be-YR ojú ìwé 61 ìpínrọ̀ 1]
8. Báwo la ṣe lè mú ọ̀nà tá a gbà ń fọ̀rọ̀ wérọ̀ nínú ilé sunwọ̀n sí i? [be-YR ojú ìwé 62 ìpínrọ̀ 3]
9. Kí ló ran Jeremáyà lọ́wọ́ tí kò fi gbà kí ìnira àti ìrẹ̀wẹ̀sì pa òun lẹ́nu mọ́? [w06-YR 2/1 ojú ìwé 20 ìpínrọ̀ 15]
10. Ẹ̀kọ́ wo la rí kọ́ nínú ìwé Ìdárò? [w88-YR 9/1 ojú ìwé 27 ìpínrọ̀ 5]
BÍBÉLÌ KÍKÀ Ọ̀SỌ̀Ọ̀SẸ̀
11. Níbàámu pẹ̀lú ohun tó ṣẹlẹ̀ sí Jeremáyà gẹ́gẹ́ bó ṣe wà nínú Jeremáyà 37:21, ìdánilójú wo la lè ní?
12. Kí ló ṣeé ṣe kó mú kí Bárúkù sọ pé Jèhófà ti ‘fi ẹ̀dùn-ọkàn kún ìrora òun’ pé ‘agara’ ti ń dá òun, ojútùú wo sì ni Bárúkù kọ́kọ́ wá sí ìṣòro yẹn? (Jer. 45:1-5)
13. Ìgbà wo ló di pé kò sẹ́nì kankan tó ń gbé inú ìlú Bábílónì mọ́, tó wá “di ahoro látòkè délẹ̀”? (Jer. 50:13)
14. Ìlànà wo nípa àdúrà ni Ìdárò 3:8, 9, 42-45 mú kó ṣe kedere?
15. Kí ni kẹ̀kẹ́ ẹṣin tí Ìsíkíẹ́lì orí 1 sọ nípa rẹ̀ dúró fún?