Àwọn Ìfilọ̀
◼ Ìwé ìkẹ́kọ̀ọ́ tá ó lò lóṣù June: Ẹ lo ìwé Àṣírí Ayọ̀ Ìdílé tàbí ìwé Kẹ́kọ̀ọ́ Lọ́dọ̀ Olùkọ́ Ńlá Náà. July àti August: Ẹ lè lo èyíkéyìí lára àwọn ìwé pẹlẹbẹ olójú ewé 32 yìí: Akoso Naa Ti Yoo Mu Paradise Wá, Ẹ Máa Ṣọ́nà!, Àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà—Ta Ni Wọ́n? Kí Ni Wọ́n Gbà Gbọ́?, Ẹmi Awọn Oku—Wọn Ha Le Ran Ọ Lọwọ Tabi Pa Ọ Lara Bi? Wọn Ha Wa Niti Gidi Bi?, Gbádùn Iwalaaye lori Ilẹ Ayé Titilae!, Iwọ Ha Nilati Gbàgbọ́ Ninu Mẹtalọkan Bí?, Ìwọ Lè Di Ọ̀rẹ́ Ọlọ́run!, Ki Ni Ète Igbesi—Aye? Bawo Ni Ìwọ Ṣe Le Rí I?, Kí Ní Ń Ṣẹlẹ̀ sí Wa Nígbà Tí A Bá Kú?, Nígbà Tí Ẹnìkan Tí Ìwọ Fẹ́ràn Bá Kú, Orukọ Atọrunwa naa Tí Yoo Wà Titilae, Ọlọ́run Ha Bikita Nipa Wa Niti Gidi Bi?, Ọ̀nà Tó Lọ sí Ìyè Àìnípẹ̀kun—Ṣé O Ti Rí I? àti “Sawo O! Emi Nsọ Ohun Gbogbo Di Ọtun.” September: Ìwé Bíbélì Fi Kọ́ni la ó lò. Ká sapá lákànṣe láti bẹ̀rẹ̀ ìkẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì nígbà àkọ́kọ́ tá a bá bá onítọ̀hún pàdé. Báwọn tẹ́ ẹ fẹ́ fún ní ìwé náà bá sọ pé àwọn ti ní i tẹ́lẹ̀, ẹ jẹ́ kí wọ́n mọ bí wọ́n ṣe lè jàǹfààní rẹ̀ nípa fífi bá a ṣe ń ṣe ìkẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì hàn wọ́n ní ṣókí.
◼ Kí alága àwọn alábòójútó tàbí ẹnì kan tó bá yàn ṣàyẹ̀wò àkáǹtì ìjọ ti oṣù March, April àti May. Bó bá ti ṣe èyí, ẹ ṣèfilọ̀ rẹ̀ fún ìjọ lẹ́yìn tẹ́ ẹ bá ti ka ìròyìn ìnáwó ti oṣù tó ń bọ̀. Ẹ wo ìwé tó ṣàlàyé nípa bó ṣe yẹ ká bójú tó àkáǹtì ìjọ, ìyẹn Instructions for Congregation Accounting (S-27).