Ìtòlẹ́sẹẹsẹ fún Ọ̀sẹ̀ April 4
Ọ̀SẸ̀ TÓ BẸ̀RẸ̀ NÍ APRIL 4
Orin 116 àti Àdúrà
□ Ìkẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì Ìjọ:
bt orí 2 ìpínrọ̀ 1 sí 7, àpótí tó wà lójú ìwé 13 (25 min.)
□ Ilé Ẹ̀kọ́ Ìjọba Ọlọ́run:
Bíbélì kíkà: Jóòbù 16-20 (10 min.)
No. 1: Jóòbù 18:1-21 (4 min. tàbí kó máà tó bẹ́ẹ̀)
No. 2: Amágẹ́dọ́nì Ni Ogun Tó Máa Fi Òpin sí Ìwà Burúkú—td 4A (5 min.)
No. 3: Ìdí Tí Àwọn Aláṣẹ Tó Mọ Àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà Dáadáa Fi Máa Ń Yìn Wá—Róòmù 13:3 (5 min.)
□ Ìpàdé Iṣẹ́ Ìsìn:
5 min: Àwọn ìfilọ̀.
15 min: “Lẹ́tà Látọ̀dọ̀ Ìgbìmọ̀ Olùdarí.” Ìjíròrò tó dá lórí àpilẹ̀kọ olójú ewé méjì tá a fi ránṣẹ́ pẹ̀lú Iṣẹ́ Òjíṣẹ́ Ìjọba Wa ti oṣù March 2011. Ní kí àwọn ará sọ̀rọ̀ lórí ohun tó gbàfiyèsí nínú ìròyìn ọdọọdún tó wà nínú àkìbọnú Iṣẹ́ Òjíṣẹ́ Ìjọba Wa ti oṣù February 2011. Tó bá ṣeé ṣe ṣètò pé kí ẹnì kan sọ ìrírí tó fúnni níṣìírí látinú ìwé ọdọọdún tí àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà, ìyẹn 2011 Yearbook . Parí ìjíròrò náà nípa fífún àwọn ará níṣìírí pé kí wọ́n ka ìwé ọdọọdún wa, 2011 Yearbook tán.
15 min: Àwọn ọ̀ràn tó ń fẹ́ àbójútó nínú ìjọ.
Orin 103 àti Àdúrà