ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍNTÁNẸ́Ẹ̀TÌ ti Watchtower
ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍŃTÁNẸ́Ẹ̀TÌ
ti Watchtower
Yorùbá
ọ́
  • ẹ
  • ọ
  • ṣ
  • ń
  • ẹ́
  • ẹ̀
  • ọ́
  • ọ̀
  • BÍBÉLÌ
  • ÌTẸ̀JÁDE
  • ÌPÀDÉ
  • km 3/11 ojú ìwé 4
  • Àwọn Ìfilọ̀

Kò sí fídíò kankan ní apá yìí.

Má bínú, fídíò yìí kò jáde.

  • Àwọn Ìfilọ̀
  • Iṣẹ́ Òjíṣẹ́ Ìjọba Wa—2011
Iṣẹ́ Òjíṣẹ́ Ìjọba Wa—2011
km 3/11 ojú ìwé 4

Àwọn Ìfilọ̀

◼ Ìwé tá a máa lò ní March: Kí Ni Bíbélì Fi Kọ́ni Gan-an? Ẹ sapá gidigidi láti àwọn bẹ̀rẹ̀ àwọn ìkẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì. April àti May: Ìwé ìròyìn Ilé Ìṣọ́ àti Jí! Nígbà tẹ́ ẹ bá ń ṣe ìpadàbẹ̀wò sọ́dọ̀ àwọn tó fìfẹ́ hàn tó fi mọ́ àwọn tó wá síbi Ìrántí Ikú Kristi tàbí àwọn àpéjọ míì tí ètò Ọlọ́run ṣètò àmọ́ tí wọn kò tíì máa dara pọ̀ mọ́ ìjọ déédéé, ẹ fún wọn ní ìwé Kí Ni Bíbélì Fi Kọ́ni Gan-an? Kẹ́ ẹ sì ní in lọ́kàn láti bẹ̀rẹ̀ ìkẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì pẹ̀lú wọn. June: Kí Ni Bíbélì Fi Kọ́ni Gan-an? Bí onílé bá ti ní ìwé yìí, ẹ fún un ní ìwé èyíkéyìí tí ọjọ́ rẹ̀ ti pẹ́ tí ìjọ bá ní lọ́wọ́. Ẹ tún lè lo Jọ́sìn Ọlọ́run Tòótọ́ Kan Ṣoṣo Náà gẹ́gẹ́ bí àfidípò.

◼ Ọ̀sẹ̀ tó bẹ̀rẹ̀ ní April 25, 2011 la máa sọ àkànṣe àsọyé tó wà fún àkókò Ìrántí Ikú Kristi ti ọdún 2011. Ẹṣin ọ̀rọ̀ rẹ̀ ni “Ǹjẹ́ Àwọn Ìlànà Bíbélì Lè Ràn Wá Lọ́wọ́ Láti Kojú Àwọn Ìṣòrò Òde Òní?” Kí àwọn ìjọ tí wọ́n bá ní ìbẹ̀wò alábòójútó àyíká, àpéjọ àyíká, tàbí àpéjọ àkànṣe lópin ọ̀sẹ̀ yẹn sọ àkànṣe àsọyé náà lọ́sẹ̀ tó tẹ̀ lé e. Kí ìjọ kankan má ṣe sọ àkànṣe àsọyé yìí ṣáájú ọ̀sẹ̀ April 25.

◼ A máa jíròrò fídíò Jehovah’s Witnesses—Organized to Share the Good News ní Ìpàdé Iṣẹ́ Ìsìn kan lóṣù August. Bó bá pọn dandan, ẹ lè béèrè fún ẹ̀dà fídíò yìí nípasẹ̀ ìjọ láìjáfara.

    Yorùbá Publications (1987-2025)
    Jáde
    Wọlé
    • Yorùbá
    • Fi Ráńṣẹ́
    • Èyí tí mo fẹ́ràn jù
    • Copyright © 2025 Watch Tower Bible and Tract Society of Pennsylvania
    • Àdéhùn Nípa Lílò
    • Òfin
    • Ètò Nípa Ìsọfúnni Rẹ
    • JW.ORG
    • Wọlé
    Fi Ráńṣẹ́