A Máa Bẹ̀rẹ̀ Sí Í Pín Ìwé Ìkésíni Síbi Ìrántí Ikú Kristi Ní March 17
1. Kí la máa bẹ̀rẹ̀ sí í ṣe láti March 17?
1 Ìrántí Ikú Kristi tá a máa ń ṣe lọ́dọọdún máa ń jẹ́ ká lè pòkìkí ikú Jésù. (1 Kọ́r. 11:26) Nítorí náà, a máa ń fẹ́ kí àwọn míì wá dara pọ̀ mọ́ wa kí wọ́n lè gbọ́ nípa bí Jèhófà ṣe fún wa ní ẹ̀bùn ìràpadà náà tìfẹ́tìfẹ́. (John 3:16) Lọ́dún yìí, ọjọ́ Saturday, March 17 la máa bẹ̀rẹ̀ sí í pe àwọn èèyàn wá sí Ìrántí Ikú Kristi. Ṣé o ti múra tán láti kópa nínú ìpolongo yìí?
2. Kí la lè sọ nígbà tá a bá fẹ́ fún àwọn èèyàn ní ìwé ìkésíni náà?
2 Ohun Tá A Lè Sọ: Á dára ká jẹ́ kí ọ̀rọ̀ wa ṣe ṣókí. Lẹ́yìn tá a bá ti kí onílé, a lè sọ pé: “A fẹ́ fún ìdílé yín ní ìwé ìkésíni sí Ìrántí Ikú Kristi tá a máa ń ṣe lọ́dọọdún, èyí tó máa wáyé jákèjádò ayé ní April 5. A máa gbọ́ àsọyé Bíbélì kan tó dá lórí ohun tí ikú Jésù mú kó ṣeé ṣe àti ohun tí Jésù ń ṣe lọ́wọ́ báyìí. Ọjọ́ tá a máa ṣe é àti àkókò tó máa bẹ̀rẹ̀ ní àdúgbò yìí wà nínú ìwé ìkésíni yìí.” Tẹ́ ẹ bá ń pín ìwé ìkésíni náà lópin ọ̀sẹ̀, ẹ tún lè fún àwọn èèyàn ní àwọn ìwé ìròyìn nígbà tó bá yẹ bẹ́ẹ̀.
3. Kí la lè ṣe láti pe ọ̀pọ̀ èèyàn bó bá ti lè ṣeé ṣe tó?
3 Pe Ọ̀pọ̀ Èèyàn Bó Bá Ti Lè Ṣeé Ṣe Tó: Àfojúsùn wa ni pé ká pe ọ̀pọ̀ èèyàn bó bá ti lè ṣeé ṣe tó. Torí náà, rí i pé o pe àwọn tó ò ń kọ́ lẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì, ìpadàbẹ̀wò, ìbátan, àwọn tẹ́ ẹ jọ ń ṣiṣẹ́, àwọn tẹ́ ẹ jọ ń lọ síléèwé, àwọn aládùúgbò àti àwọn míì tó o bá mọ̀. Àwọn alàgbà máa ṣètò bẹ́ ẹ ṣe máa kárí ìpínlẹ̀ ìwàásù yín. Bá a ṣe máa ń pe àwọn èèyàn wá sí Ìrántí Ikú Kristi lọ́dọọdún máa ń so èso rere. Lọ́dún tó kọjá, nígbà tí obìnrin kan dé ibi tá a ti fẹ́ ṣe Ìrántí Ikú Kristi, arákùnrin tó ń bójú tó èrò sọ fún obìnrin náà pé kó jẹ́ kí òun bá a wá akéde tó pè é wá. Àmọ́, obìnrin náà sọ pé òun kò mọ ẹnikẹ́ni níbẹ̀ àti pé ọwọ́ àwọn kan tó ń wàásù láti ilé dé ilé ni òun ti gba ìwé ìkésíni náà láàárọ̀ ọjọ́ náà.
4. Kí nìdí tó fi yẹ ká fi ìtara pín ìwé ìkésíni náà?
4 Ó ṣeé ṣe kó jẹ́ pé ìwé ìkésíni tó o fún ẹnì kan ló máa mú kí onítọ̀hún wá sí Ìrántí Ikú Kristi. Bóyá àwọn tó o fún ní ìwé ìkésíni wá tàbí wọn kò wá, ẹ̀rí ni ìsapá rẹ máa jẹ́. Àwọn ìwé ìkésíni tó o pín máa jẹ́ kí àwọn èèyàn mọ̀ pé Jésù ti di Ọba alágbára báyìí. Tó o bá fi ìtara pín ìwé ìkésíni náà, èyí á mú kí gbogbo àwọn tó bá rí ọ mọ̀ pé o mọyì ẹ̀bùn ìràpadà náà lóòótọ́, ì báà jẹ́ àwọn tó wà ní ìpínlẹ̀ ìwàásù yín, àwọn akéde bíi tiẹ̀, àti ní pàtàkì Jèhófà.—Kól. 3:15.