Ìtòlẹ́sẹẹsẹ Ìpàdé Iṣẹ́ Ìsìn Ọ̀sẹ̀ Tó Bẹ̀rẹ̀ ní February 20
Ọ̀SẸ̀ TÓ BẸ̀RẸ̀ NÍ FEBRUARY 20
Orin 37 àti Àdúrà
□ Ìkẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì Ìjọ:
bt orí 17 ìpínrọ̀ 1 sí 7 (25 min.)
□ Ilé Ẹ̀kọ́ Ìjọba Ọlọ́run:
Bíbélì kíkà: Aísáyà 58-62 (10 min.)
No. 1: Aísáyà 61:1-11 (4 min. tàbí kó máà tó bẹ́ẹ̀)
No. 2: Báwo Ni Ìyàsímímọ́ Ṣe Ń Fi Hàn Pé A Ní Ìfẹ́ àti Ìgbàgbọ́? (5 min.)
No. 3: Bá A Ṣe Lè Mọ Àwọn Ànímọ́ Ọlọ́run—td 34D (5 min.)
□ Ìpàdé Iṣẹ́ Ìsìn:
10 min: Àwọn Ìfilọ̀. Sọ ìwé ìkẹ́kọ̀ọ́ tá a máa lò lóṣù March, kó o sì ṣe àṣefihàn bá a ṣe lè lo ọ̀kan nínú wọn.
10 min: Kí La Rí Kọ́? Ìjíròrò. Ẹ ka Sáàmù 63:3-8 àti Máàkù 1:32-39. Ẹ jíròrò bí àwọn ẹsẹ Ìwé Mímọ́ yìí ṣe lè ràn wá lọ́wọ́ lẹ́nu iṣẹ́ òjíṣẹ́ wa.
15 min: “A Máa Bẹ̀rẹ̀ Sí Í Pín Ìwé Ìkésíni Síbi Ìrántí Ikú Kristi Ní March 17.” Ìbéèrè àti ìdáhùn. Tí ìwé ìkésíni náà bá ti dé sí ìjọ, fún gbogbo àwọn tó wà nípàdé ní ẹ̀dà kọ̀ọ̀kan, kẹ́ ẹ sì jíròrò ohun tó wà níbẹ̀. Tẹ́ ẹ bá dé ìpínrọ̀ kejì, ṣé àṣefihàn bẹ́ ẹ ṣe lè fún àwọn èèyàn ní ìwé ìkésíni náà. Nígbà tẹ́ ẹ bá ń jíròrò ìpínrọ̀ kẹta, ní kí alábòójútó iṣẹ́ ìsìn sọ ètò tí ìjọ ṣe láti pín ìwé ìkésíni ní ìpínlẹ̀ ìwàásù yín.
Orin 8 àti Àdúrà