Ṣètò Báyìí Láti Ṣe Púpọ̀ Sí I Lẹ́nu Iṣẹ́ Òjíṣẹ́ Rẹ
1. Kí nìdí tí àkókò Ìrántí Ikú Kristi fi ṣe pàtàkì, báwo la sì ṣe lè múra sílẹ̀?
1 Ní gbogbo àkókò Ìrántí Ikú Kristi, a máa ń láǹfààní láti “gbé Jèhófà lárugẹ gidigidi.” (Sm. 109:30) Ṣé wàá ṣe púpọ̀ sí i lẹ́nu iṣẹ́ òjíṣẹ́ rẹ ní oṣù March, kó o lè tipa bẹ́ẹ̀ fi ìmọrírì hàn fún Olùpèsè ìràpadà náà? Bẹ̀rẹ̀ sí í ṣètò bó o ṣe máa ṣe é láti ìsinsìnyí lọ.—Òwe 21:5.
2. Báwo ló ṣe rí lára rẹ nígbà tá a dín iye wákàtí tí àwọn aṣáájú-ọ̀nà olùrànlọ́wọ́ lè ròyìn kù ní oṣù April ọdún tó kọjá, báwo ló sì ṣe rí lára àwọn míì pẹ̀lú?
2 Aṣáájú-ọ̀nà Olùrànlọ́wọ́: Inú gbogbo ìjọ kárí ayé ló dùn lọ́dún tó kọjá nígbà tá a gbọ́ pé a dín iye wákàtí tí àwọn aṣáájú-ọ̀nà olùrànlọ́wọ́ lè ròyìn kù ní oṣù April. Arákùnrin kan kọ̀wé pé: “Ilé ẹ̀kọ́ girama ni mo ṣì wà, kò sì tíì ṣeé ṣe fún mi láti di aṣáájú-ọ̀nà déédéé. Ṣùgbọ́n, màá gba aṣáájú-ọ̀nà olùrànlọ́wọ́ ti mo ti lè ròyìn ọgbọ̀n [30] wákàtí ní oṣù April, bó tilẹ̀ jẹ́ pé màá sapá láti ròyìn àádọ́ta wákàtí.” Arábìnrin kan tó máa ń wà ní ibiṣẹ́ látàárọ̀ ṣúlẹ̀ kọ̀wé pé: “Ọgbọ̀n [30] wákàtí, ìyẹn kò pọ̀ ju ohun tí mo lè ṣe lọ!” Nígbà tí wọ́n ṣe ìfilọ̀ wákàtí tá a dín kù yìí, arábìnrin kan tó ti lé ní ẹni ọgọ́rin [80] ọdún tó jẹ́ aṣáájú-ọ̀nà déédéé tẹ́lẹ̀ sọ pé: “Àkókò tí mò ń dúró dè gan-an nìyí! Jèhófà mọ̀ pé iṣẹ́ aṣáájú-ọ̀nà ni iṣẹ́ tí mo gbádùn jù lọ láyé mi!” Àwọn míì tí wọn ò lè ṣe aṣáájú-ọ̀nà olùrànlọ́wọ́ fi ṣe àfojúsùn wọn láti ṣe púpọ̀ sí i lẹ́nu iṣẹ́ òjíṣẹ́ wọn.
3. Kí nìdí tó fi yẹ ká ṣètò láti ṣe aṣáájú-ọ̀nà olùrànlọ́wọ́ lóṣù March, April àti May?
3 Oṣù March jẹ́ ìgbà tó dára gan-an láti ṣe aṣáájú-ọ̀nà olùrànlọ́wọ́, nítorí pé a tún máa láǹfààní láti yan iye wákàtí tí a máa lè ròyìn, bóyá ọgbọ̀n [30] tàbí àádọ́ta [50]. Bákan náà, bẹ̀rẹ̀ láti Saturday, March 17, a máa bẹ̀rẹ̀ sí í ṣe ìpolongo àkànṣe láti pe àwọn èèyàn kí wọ́n lè dara pọ̀ mọ́ wa láti ṣe Ìrántí Ikú Kristi ní April 5. Ọ̀pọ̀ nínú wa ló máa fẹ́ láti ṣe púpọ̀ sí i lẹ́nu iṣẹ́ òjíṣẹ́ wọn débi pé wọ́n máa fẹ́ láti ṣe aṣáájú-ọ̀nà olùrànlọ́wọ́ lóṣù April àti May pẹ̀lú, tí wọ́n á sì lo àádọ́ta [50] wákàtí.
4. Báwo la ṣe lè ṣe púpọ̀ sí i lẹ́nu iṣẹ́ òjíṣẹ́ wa, èrè wo ló sì wà níbẹ̀?
4 Nígbà tẹ́ ẹ bá tún máa ṣe Ìjọsìn Ìdílé yín, ẹ ò ṣe jíròrò bí ẹnì kọ̀ọ̀kan nínú ìdílé yín ṣe lè ṣe púpọ̀ sí i lẹ́nu iṣẹ́ òjíṣẹ́ rẹ̀ nígbà Ìrántí Ikú Kristi? (Òwe 15:22) Ẹ bẹ Jèhófà pé kí ó tì yín lẹ́yìn bẹ́ ẹ ṣe ń sapá láti ṣe púpọ̀ sí i lẹ́nu iṣẹ́ òjíṣẹ́ yín. (1 Jòhánù 3:22) Bí ẹ ṣe ń sapá láti ṣe púpọ̀ sí i lẹ́nu iṣẹ́ òjíṣẹ́ yín, èyí á mú kẹ́ ẹ túbọ̀ máa yin Jèhófà, ẹ ó sì túbọ̀ máa láyọ̀.—2 Kọ́r. 9:6.