Ǹjẹ́ O Lè Ṣe Aṣáájú-Ọ̀nà Olùrànlọ́wọ́?
1. Kí nìdí tí àsìkò Ìrántí Ikú Kristi fi jẹ́ àsìkò to dáa gan-an tá a lè fi ṣe púpọ̀ sí i lẹ́nu iṣẹ́ ìwàásù?
1 Àsìkò Ìrántí Ikú Kristi jẹ́ àsìkò tó dáa gan-an láti ṣe púpọ̀ sí i lẹ́nu iṣẹ́ ìwàásù. A máa ń fi àsìkò yẹn ronú lórí ìfẹ́ tó jinlẹ̀ tí Jèhófà fi hàn sí wa, ìyẹn bó ṣe fi Ọmọ rẹ̀ san ìràpadà wa. (Jòh. 3:16) Èyí máa ń jẹ́ ká lè túbọ̀ mọyì ohun tí Jèhófà ṣe fún wa. Ó sì máa ń jẹ́ kó túbọ̀ máa wù wá láti sọ fún àwọn èèyàn nípa Jèhófà àtàwọn ohun rere tó ń ṣe fún aráyé. (Aísá. 12:4, 5; Lúùkù 6:45) Lásìkò Ìrántí Ikú Kristi, a tún máa ń pín ìwé ìkésíni tá a dìídì ṣe láti fi pe àwọn èèyàn ní ìpínlẹ̀ ìwàásù wa àtàwọn ojúlùmọ̀ wa síbi Ìrántí Ikú Kristi. A sì tún máa ń ṣe ìpadàbẹ̀wò sọ́dọ̀ àwọn tó bá wá síbi Ìrántí Ikú Kristi. O ò ṣe kúkú ṣe aṣáájú-ọ̀nà olùrànlọ́wọ́ ní oṣù March, April, tàbí May kó o sì tipa bẹ́ẹ̀ ṣe púpọ̀ sí i lẹ́nu iṣẹ́ ìwàásù?
2. Kí nìdí tí oṣù March fi jẹ́ oṣù tó dáa gan-an láti ṣe aṣáájú-ọ̀nà olùrànlọ́wọ́?
2 Fi Oṣù March Ṣe Oṣù Tó Ṣàrà Ọ̀tọ̀: Ó máa dáa gan-an láti ṣe aṣáájú-ọ̀nà olùrànlọ́wọ́ ní oṣù March 2013. Àwọn tó bá ṣe aṣáájú-ọ̀nà olùrànlọ́wọ́ lóṣù yẹn máa láǹfààní láti pinnu bóyá ọgbọ̀n [30] wákàtí tàbí àádọ́ta [50] wákàtí làwọn máa ṣe. Láwọn ìjọ tí alábòójútó àyíká bá bẹ̀ wò ní oṣù náà, gbogbo àwọn tó bá ń ṣe aṣáájú-ọ̀nà olùrànlọ́wọ́ lóṣù yẹn ló máa láǹfààní láti wà ní ìpàdé tí alábòójútó àyíká máa ṣe pẹ̀lú àwọn aṣáájú-ọ̀nà déédéé àtàwọn aṣáájú-ọ̀nà àkànṣe, wọ́n sì máa wà níbẹ̀ látìbẹ̀rẹ̀ dópin. Iye ọjọ́ tá a máa fi pín ìwé ìkésíni láti pe àwọn èèyàn síbi Ìrántí Ikú Kristi tún máa pọ̀ ju ti tẹ́lẹ̀ lọ. Ọjọ́ Tuesday, March 26, 2013 la máa ṣe Ìrántí Ikú Kristi, àmọ́ a ti máa bẹ̀rẹ̀ sí í pín ìwé ìkésíni náà láti March 1. Yàtọ̀ síyẹn, òpin ọ̀sẹ̀ márùn-ún ọ̀tọ̀ọ̀tọ̀ ló wà nínú oṣù March. O ò ṣe rò ó dáadáa bóyá ìwọ náà á lè fi oṣù March ṣe oṣù tó ṣàrà ọ̀tọ̀ lọ́dún 2013?
3. Àwọn ìmúrasílẹ̀ wo la lè ṣe báyìí ká bàa lè ṣe púpọ̀ sí i lẹ́nu iṣẹ́ ìwàásù?
3 Bẹ̀rẹ̀ Sí Í Múra Sílẹ̀ Báyìí: Ìsinsìnyí ló yẹ ká ronú nípa bá a ṣe fẹ́ lo àkókò wa, ká lè mọ àwọn àyípadà tó yẹ ká ṣe ká bàa lè ṣe aṣáájú-ọ̀nà. Ó ṣe pàtàkì gan-an pé kí gbogbo àwọn tó wà nínú ìdílé fọwọ́ sowọ́ pọ̀. Torí náà, a rọ ìdílé kọ̀ọ̀kan pé nígbà Ìjọsìn Ìdílé wọn, kí wọ́n jíròrò ohun tí wọ́n máa fi ṣe àfojúsùn wọn lápapọ̀ gẹ́gẹ́ bí ìdílé, kí wọ́n sì jọ ṣètò bí wọ́n ṣe máa lo àkókò wọn. (Òwe 15:22) Bí o kò bá ní lè ṣe aṣáájú-ọ̀nà olùrànlọ́wọ́, má ṣe rẹ̀wẹ̀sì. O ṣì lè ṣètò àkókò rẹ lọ́nà tí wàá fi lè pẹ́ díẹ̀ sí i lóde ẹ̀rí láwọn ọjọ́ tó o bá jáde. O tún lè fi ọjọ́ kan kún ọjọ́ tó o máa ń jáde òde ẹ̀rí láàárín ọ̀sẹ̀.
4. Àwọn àǹfààní wo la máa rí tá a bá ṣe púpọ̀ sí i lẹ́nu iṣẹ́ ìwàásù lóṣù March, April àti May?
4 Tá a bá ṣe púpọ̀ sí i lẹ́nu iṣẹ́ ìwàásù ní oṣù March, April àti May, a ó lè fi kún ayọ̀ àti ìtẹ́lọ́rùn tá a máa ń rí lẹ́nu iṣẹ́ ìsìn Jèhófà àti nínú fífún àwọn èèyàn ní nǹkan. (Jòh. 4:34; Ìṣe 20:35) Ohun tó tún wá ṣe pàtàkì jù ni pé, tá a bá yááfì àwọn nǹkan kan ká lè ṣe púpọ̀ sí i lẹ́nu iṣẹ́ náà, ó máa múnú Jèhófà dùn gan-an.—Òwe 27:11.