Ìtòlẹ́sẹẹsẹ fún Ọ̀sẹ̀ February 11
Ọ̀SẸ̀ TÓ BẸ̀RẸ̀ NÍ FEBRUARY 11
Orin 106 àti Àdúrà
□ Ìkẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì Ìjọ:
jr orí 5 ìpínrọ̀ 7 sí 12 (30 min.)
□ Ilé Ẹ̀kọ́ Ìjọba Ọlọ́run:
Bíbélì kíkà: Mátíù 26-28 (10 min.)
No. 1: Mátíù 27:24-44 (4 min. tàbí kó máà tó bẹ́ẹ̀)
No. 2: Báwo Ni Sùúrù Ọlọ́run Ṣe Ń Yọrí sí Ìgbàlà fún Wa?—2 Pét. 3:9, 15 (5 min.)
No. 3: Kí Ni Ẹ̀ṣẹ̀?—td 15A (5 min.)
□ Ìpàdé Iṣẹ́ Ìsìn:
10 min: Kí La Rí Kọ́? Ìjíròrò. Ẹ ka Mátíù 6:19-21 àti Lúùkù 16:13. Kẹ́ ẹ sì jíròrò bí àwọn ẹsẹ Ìwé Mímọ́ yìí ṣe lè wúlò fún wa lẹ́nu iṣẹ́ òjíṣẹ́ wa.
20 min: “Ǹjẹ́ O Lè Ṣe Aṣáájú-Ọ̀nà Olùrànlọ́wọ́?” Ìbéèrè àti ìdáhùn. Alábòójútó iṣẹ́ ìsìn ni kó ṣe iṣẹ́ yìí. Lẹ́yìn tẹ́ ẹ bá ti jíròrò ìpínrọ̀ 2, fọ̀rọ̀ wá ọ̀rọ̀ wò ní ṣókí lẹ́nu àwọn akéde méjì tó fẹ́ ṣe aṣáájú-ọ̀nà olùrànlọ́wọ́ lóṣù March. Kí ọ̀kan nínú wọn jẹ́ ẹni tó ń ṣe iṣẹ́ oúnjẹ òòjọ́ tó ń mú kí ọwọ́ rẹ̀ dí. Kí èkejì sì jẹ́ ẹni tó ní ìṣòro àìlera. Àwọn ìyípadà wo ni wọ́n ń wéwèé láti ṣe kí wọ́n lè ṣe aṣáájú-ọ̀nà? Lẹ́yìn tẹ́ ẹ bá ti jíròrò ìpínrọ̀ 3, ṣe àṣefihàn tó dá lórí bí tọkọtaya kan tàbí ìdílé kan tó láwọn ọmọ ṣe ń wéwèé nígbà Ìjọsìn Ìdílé wọn nípa bí wọ́n ṣe máa ṣe púpọ̀ sí i lẹ́nu iṣẹ́ ìwàásù.
Orin 122 àti Àdúrà