Ṣe Ohun Tó Máa Mú Kó O Láyọ̀ Lákòókò Ìrántí Ikú Kristi Tó Ń Bọ̀
1. Kí la lè ṣe láti fi kún ayọ̀ wa lákòókò Ìrántí Ikú Kristi tó ń bọ̀?
1 Ṣé wàá fẹ́ túbọ̀ láyọ̀ ní oṣù March, April àti May? Ọ̀nà kan tó o lè gbà ṣe bẹ́ẹ̀ ni pé kó o ṣe púpọ̀ sí i lẹ́nu iṣẹ́ ìsìn Jèhófà, o sì lè ṣe aṣáájú-ọ̀nà olùrànlọ́wọ́. Báwo lèyí ṣe máa fi kún ayọ̀ rẹ?
2. Tá a bá ń ṣe púpọ̀ sí i lẹ́nu iṣẹ́ ìsìn Jèhófà, báwo nìyẹn ṣe máa mú kí ayọ̀ wa pọ̀ sí i?
2 Mú Kí Ayọ̀ Rẹ Pọ̀ Sí I: Jèhófà dá wa ká lè láyọ̀, kí ọkàn wa sì balẹ̀ bá a ṣe ń sìn ín. (Mát. 5:3) Ọlọ́run tún dá wa ká lè máa láyọ̀ tá a bá ń fún àwọn ẹlòmíì ní nǹkan. (Ìṣe 20:35) Iṣẹ́ ìwàásù máa ń jẹ́ ká lè jọ́sìn Ọlọ́run, ó sì tún ń jẹ́ ká lè ran àwọn èèyàn lọ́wọ́. Abájọ tí ayọ̀ wa fi máa ń pọ̀ sí i tá a bá ṣe púpọ̀ sí i lẹ́nu iṣẹ́ ìwàásù. Ohun kan tún ni pé, bá a bá ṣe ń wàásù léraléra tó bẹ́ẹ̀ lá ó máa mọwọ́ ẹ̀ sí i. Èyí á jẹ́ ká túbọ̀ nígboyà, á sì jẹ́ kí ara wa balẹ̀ nígbà tá a bá ń wàásù. Á tún jẹ́ ká láǹfààní púpọ̀ sí i láti wàásù, ká sì bẹ̀rẹ̀ ìkẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì. Àwọn nǹkan yìí máa ń mú kí iṣẹ́ òjíṣẹ wa túbọ̀ gbádùn mọ́ni.
3. Kí nìdí tó fi máa dára ká ṣe aṣáájú-ọ̀nà olùrànlọ́wọ́ lóṣù March àti April?
3 Ó máa dáa gan-an ká ṣe aṣáájú-ọ̀nà olùrànlọ́wọ́ lóṣù March àti April tórí a lè yàn bóyá ọgbọ̀n [30] wákàtí la fẹ́ ní lóṣù yẹn tàbí àádọ́ta [50] wákàtí. Bákan náà, bẹ̀rẹ̀ láti Sátidé, March 22, títí di ọjọ́ tá a máa ṣe Ìrántí Ikú Kristi ní Monday, April 14, a máa pín ìwé ìkésíni sí Ìrántí Ikú Kristi fún àwọn èèyàn. Inú gbogbo àwọn ará máa dùn bí ọ̀pọ̀ ti ń ṣiṣẹ́ ní “ìfẹ̀gbẹ́kẹ̀gbẹ́” lẹ́nu iṣẹ́ ìwàásù kí wọ́n lè kárí ìpínlẹ̀ ìwàásù wọn láàárín àkókò tá a yàn.—Sef. 3:9.
4. Tá a bá fẹ́ ṣe aṣáájú-ọ̀nà olùrànlọ́wọ́, kí ló yẹ ká ṣe?
4 Bẹ̀rẹ̀ Sí Í Múra Sílẹ̀: Tètè bẹ̀rẹ̀ sí í ṣètò àkókò rẹ báyìí, bí o kò báà tíì ṣe bẹ́ẹ̀, kó o lè mọ àwọn àyípadà tó yẹ kó o ṣe kó o bàa lè ṣe púpọ̀ sí i lẹ́nu iṣẹ́ ìsìn Jèhófà fún oṣù kan tàbí jù bẹ́ẹ̀ lọ. Gbádùrà sí Jèhófà nípa rẹ̀. (Ják. 1:5) Sọ ohun tó o fẹ́ ṣe fún ìdílé rẹ àtàwọn ará ìjọ rẹ. (Òwe 15:22) Bó o bá tilẹ̀ ní àìléra tàbí tí ọwọ́ rẹ bá máa ń dí gan-an, o ṣì lè ṣe iṣẹ́ aṣáájú-ọ̀nà olùrànlọ́wọ́, ó sì máa fún ẹ láyọ̀.
5. Kí ló máa ṣẹlẹ̀ tá a bá ṣe púpọ̀ sí i lẹ́nu iṣẹ́ òjíṣẹ́ lákòókò Ìrántí Ikú Kristi tó ń bọ̀?
5 Jèhófà fẹ́ káwọn ìránṣẹ́ rẹ̀ láyọ̀. (Sm. 32:11) Tá a bá sapá láti ṣe púpọ̀ sí i lẹ́nu iṣẹ́ òjíṣẹ́ lákòókò Ìrántí Ikú Kristi tó ń bọ̀, ayọ̀ wa máa pọ̀ sí i, a sì tún máa mú inú Baba wa ọ̀run dùn.—Òwe 23:24; 27:11.