Ìtòlẹ́sẹẹsẹ fún Ọ̀sẹ̀ February 17
Ọ̀SẸ̀ TÓ BẸ̀RẸ̀ NÍ FEBRUARY 17
Orin 15 àti Àdúrà
Ìkẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì Ìjọ:
cl orí 3 ìpínrọ̀ 1 sí 10 (30 min.)
Ilé Ẹ̀kọ́ Ìjọba Ọlọ́run:
Bíbélì kíkà: Jẹ́nẹ́sísì 29-31 (10 min.)
No. 1: Jẹ́nẹ́sísì 29:21-35 (4 min. tàbí kó máà tó bẹ́ẹ̀)
No. 2: Ọlọ́run Kò Fọwọ́ Sí Ìgbàgbọ́ Wò-ó-sàn Òde Òní—td 32D (5 min.)
No. 3: Ìgbọràn Ń Dáàbò Bò Ọ́—lr orí 7 (5 min.)
Ìpàdé Iṣẹ́ Ìsìn:
10 min: Àwọn Àṣeyọrí Wo La Ṣe? Ìjíròrò. Alábòójútó iṣẹ́ ìsìn ni kó ṣe iṣẹ́ yìí. Jẹ́ kí ìjọ mọ bẹ́ ẹ ṣe kárí ìpínlẹ̀ ìwàásù yín tó nígbà tẹ́ ẹ pín Ìròyìn Ìjọba No. 38. Ní kí àwọn ará sọ àwọn àǹfààní tí wọ́n rí nígbà tí wọ́n ń pín ìwé náà àtàwọn ìrírí tó gbádùn mọ́ni tí wọ́n ní.
5 min: Ṣé Ò Ń Lo Ìkànnì jw.org Lẹ́nu Iṣẹ́ Òjíṣẹ́ Rẹ? Ìjíròrò. Ní kí àwọn ará sọ àwọn ìrírí tó gbádùn mọ́ni tí wọ́n ní nígbà tí wọ́n lo ìkànnì jw.org lẹ́nu iṣẹ́ òjíṣẹ́ wọn. Fún àwọn ará ní ìṣírí pé kí wọ́n máa sọ fún àwọn èèyàn nípa ìkànnì jw.org ní gbogbo ìgbà tí wọ́n bá rí i pé ó yẹ bẹ́ẹ̀.
15 min: “Ṣe Ohun Tó Máa Mú Kó O Láyọ̀ Lákòókò Ìrántí Ikú Kristi Tó Ń Bọ̀!” Ìbéèrè àti ìdáhùn. Fọ̀rọ̀ wá ọ̀rọ̀ wò lẹ́nu àwọn tó ní ìṣòro àìlera tàbí tí ọwọ́ wọn dí gan-an àmọ́ tí wọ́n ti ń ṣètò láti ṣe aṣáájú-ọ̀nà olùrànlọ́wọ́ lákòókò Ìrántí Ikú Kristi. Ní kí wọ́n sọ àwọn ìyípada tí wọ́n máa ṣe kí wọ́n lè lo àkókò púpọ̀ sí i lẹ́nu iṣẹ́ ìwàásù. Tẹ́ ẹ bá ń jíròrò ìpínrọ̀ 3, ní kí alábòójútó iṣẹ́ ìsìn sọ ètò tí ìjọ ṣe fún ìpàdé iṣẹ́ ìsìn pápá ní oṣù March, April àti May.
Orin 8 àti Àdúrà