Mú Kí Iṣẹ́ Òjíṣẹ́ Rẹ Sunwọ̀n Sí I—Máa Ṣàkọsílẹ̀ Àwọn Tó Fìfẹ́ Hàn
“Máa fiyè sí ara rẹ nígbà gbogbo àti sí ẹ̀kọ́ rẹ.” (1 Tím. 4:16) Ìmọ̀ràn tí Ọlọ́run mí sí àpọ́sítélì Pọ́ọ̀lù láti fún Tímótì yìí jẹ́ ká mọ̀ pé yálà a ṣẹ̀ṣẹ̀ bẹ̀rẹ̀ sí í wàásù tàbí a ti pẹ́ lẹ́nu ẹ̀, ó yẹ ká máa sapá láti mú kí iṣẹ́ òjíṣẹ́ wa sunwọ̀n sí i. Ká lè mọ bá a ṣe lè ṣe é, a óò máa gbé àwọn àpilẹ̀kọ kan jáde nínú Iṣẹ́ Òjíṣẹ́ Ìjọba Wa lóòrèkóòrè, àkòrí rẹ̀ ni “Bá A Ṣe Lè Mú Kí Iṣẹ́ Òjíṣẹ́ Wa Sunwọ̀n Sí I.” Àpilẹ̀kọ kọ̀ọ̀kan máa jíròrò ohun kan tó ṣe pàtàkì tó yẹ ká máa ṣe lẹ́nu iṣẹ́ òjíṣẹ́ wa, ó sì máa sọ bí a ṣe lè ṣe ohun náà. A rọ gbogbo wa pé ká fún ohun tá a bá jíròrò lóṣooṣù ní àfiyèsí àrà ọ̀tọ̀. Tí oṣù bá parí, apá Ìpàdé Iṣẹ́ Ìsìn kan máa dá lórí àwọn àǹfààní tá a ti rí nígbà tá a fún ohun náà láfiyèsí. Lóṣù yìí a fẹ́ ká sapá láti máa ṣàkọsílẹ̀ àwọn tó bá nífẹ̀ẹ́ sí ìwàásù wa.
Kí Nìdí Tó Fi Ṣe Pàtàkì: Tá a bá fẹ́ ṣe iṣẹ́ tí Ọlọ́run gbé lé wa lọ́wọ́ bó ṣe yẹ, àwọn nǹkan míì wà tá a ní láti ṣe yàtọ̀ sí pé ká wàásù. A gbọ́dọ̀ pa dà lọ sọ́dọ̀ àwọn tó nífẹ̀ẹ́ sí ìwàásù wa, kí á kọ́ wọn lẹ́kọ̀ọ́, ká lè tipa bẹ́ẹ̀ bomi rin irúgbìn òtítọ́ tá a gbìn. (Mát. 28:19, 20; 1 Kọ́r. 3:6-9) Èyí gba pé ká pa dà lọ sọ́dọ̀ onítọ̀hún, ká sọ̀rọ̀ nípa àwọn ohun tó ń jẹ ẹ́ lọ́kàn, ká sì kọ́ ọ lẹ́kọ̀ọ́ síwájú sí i. Nítorí náà, tá a bá rí ẹni tó nífẹ̀ẹ́ sí ìwàásù wa, ó ṣe pàtàkì pé ká ṣàkọsílẹ̀ rẹ̀.
Gbìyànjú Èyí Lóṣù Yìí:
Tó o bá ti ń ṣàkọsílẹ̀, sọ ohun tó ò ń kọ fún àwọn tẹ́ ẹ bá jọ ń wàásù.