Máyà Le Láti Ṣe Ìpadàbẹ̀wò
1 O ha máa ń gbádùn ṣíṣe ìpadàbẹ̀wò bí? Ọ̀pọ̀ akéde ń ṣe bẹ́ẹ̀. Ẹ̀rù ti lè bà ọ́ ní àkọ́kọ́, ní pàtàkì nígbà tí o bá ń pa dà lọ sọ́dọ̀ àwọn onílé tí kò fi ọkàn ìfẹ́ hàn tó bẹ́ẹ̀ nígbà tí o kọ́kọ́ kàn sí wọn. Ṣùgbọ́n bí o ti ń ‘máyà le nípasẹ̀ Ọlọ́run wa láti sọ ìhìn rere náà’ ní ṣíṣe ìpadàbẹ̀wò, ẹnu lè yà ọ́ láti rí i bí iṣẹ́ yìí ti lè rọrùn tí ó sì lè lérè tó. (1 Tẹs. 2:2) Báwo ni ó ṣe rí bẹ́ẹ̀?
2 Ní tòótọ́, ìyàtọ̀ pàtàkì kan wà láàárín ìpadàbẹ̀wò àti ìkésíni àkọ́kọ́. A ń ṣe ìpadàbẹ̀wò sọ́dọ̀ ojúlùmọ̀ kan, kì í ṣe sọ́dọ̀ àjèjì, ó sì máa ń rọrùn ní gbogbogbòò láti bá ojúlùmọ̀ jíròrò ju àjèjì lọ. Ní ti èrè tí ń tẹ́ni lọ́rùn tí ń jẹ yọ láti inú nínípìn-ín nínú iṣẹ́ yìí, ìpadàbẹ̀wò lè ṣamọ̀nà sí ìkẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì inú ilé tí ń méso jáde.
3 Nígbà tí a bá ń ṣiṣẹ́ láti ilé dé ilé, lemọ́lemọ́, a máa ń pa dà dé ọ̀dọ̀ àwọn ènìyàn tí kò fi ọkàn ìfẹ́ hàn nígbà tí a bẹ̀ wọ́n wò ṣáájú. Nítorí náà, èé ṣe tí a fi ń bá a nìṣó láti máa dé ọ̀dọ̀ wọn? A kíyè sí i pé àyíká ipò àwọn ènìyàn máa ń yí pa dà àti pé ẹnì kan tí ó lè dà bíi pé ó dágunlá tàbí tí ó tilẹ̀ ṣàtakò pàápàá nígbà ìbẹ̀wò tí ó ṣáájú lè ní ọkàn ìfẹ́ nígbà míràn tí a bá dé ọ̀dọ̀ rẹ̀. Nípa níní èrò yẹn lọ́kàn, a máa ń múra sílẹ̀ dáradára, a sì máa ń gbàdúrà fún ìbùkún Jèhófà kí ó lè jẹ́ pé ohun tí a bá sọ lọ́tẹ̀ yí yóò mú ìdáhùnpadà rere wá.
4 Bí ó bá jẹ́ pé, nínú iṣẹ́ wa ilé dé ilé, a ń fi ìmúratán wàásù fún àwọn ènìyàn tí kò fi ọkàn ìfẹ́ hàn rárá ní ìṣáájú, kò ha yẹ kí a fi ìmúratán tí ó pọ̀ sí i pa dà dé ọ̀dọ̀ ẹnikẹ́ni tí ó bá fi ọkàn ìfẹ́ díẹ̀ hàn nínú ìhìn iṣẹ́ Ìjọba náà bí?—Ìṣe 10:34, 35.
5 Ọ̀pọ̀ lára wa wà nínú òtítọ́ lónìí nítorí pé akéde kan fi sùúrù ṣe ìpadàbẹ̀wò sí ọ̀dọ̀ wa. Bí o bá jẹ́ ọ̀kan lára àwọn wọ̀nyí, o lè bí ara rẹ pé: ‘Èrò ọkàn wo ni mo mú kí akéde yẹn ní lákọ̀ọ́kọ́? Mo ha tẹ́wọ́ gba ìhìn iṣẹ́ Ìjọba náà lọ́gán nígbà tí mo kọ́kọ́ gbọ́ ọ bí? Ó ha ti lè dà bíi pé mo dágunlá bí?’ Ó yẹ kí a láyọ̀ pé akéde tí ó pa dà dé ọ̀dọ̀ wa kà wá sí ẹni tí ó yẹ fún ìpadàbẹ̀wò, pé ó ‘máyà le nípasẹ̀ Ọlọ́run,’ pé ó ṣe ìkésíni náà, tí ó sì tẹ̀ síwájú láti kọ́ wa ní òtítọ́. Ní ti àwọn tí wọ́n fi ọkàn ìfẹ́ díẹ̀ hàn nígbà àkọ́kọ́, ṣùgbọ́n tí ó dà bíi pé wọ́n bẹ̀rẹ̀ sí í sá fún wa lẹ́yìn náà ńkọ́? Ìṣarasíhùwà rere ṣe pàtàkì, gẹ́gẹ́ bí ìrírí tí ó tẹ̀ lé e yìí ti fi hàn.
6 Nígbà tí wọ́n ń lọ́wọ́ nínú ìjẹ́rìí òpópónà ní àárọ̀ kùtù ọjọ́ kan, àwọn akéde méjì pàdé ọ̀dọ́bìnrin kan pẹ̀lú ọmọ rẹ̀. Obìnrin náà gba ìwé ìròyìn kan, ó sì ké sí àwọn arábìnrin náà láti wá sí ilé rẹ̀ ní ọjọ́ Sunday tí ó tẹ̀ lé e. Wọ́n débẹ̀ ní àkókò tí wọ́n fàdéhùn sí, ṣùgbọ́n onílé náà sọ fún wọn pé òun kò ní àkókò láti sọ̀rọ̀. Ṣùgbọ́n, ó ṣèlérí láti dúró dè wọ́n ní ọ̀sẹ̀ tí ó tẹ̀ lé e. Àwọn arábìnrin náà ṣiyè méjì nípa pé yóò pa àdéhùn náà mọ́, ṣùgbọ́n obìnrin náà ti ń dúró dè wọ́n nígbà tí wọ́n fi máa débẹ̀. Wọ́n bẹ̀rẹ̀ ìkẹ́kọ̀ọ́ kan, ìtẹ̀síwájú obìnrin náà sì yani lẹ́nu. Láàárín àkókò kúkúrú, ó ti bẹ̀rẹ̀ sí í wá sí ìpàdé déédéé, ó sì ń nípìn-ín nínú iṣẹ́ ìsìn pápá. Ó ti ṣe batisí nísinsìnyí.
7 Fi Ìpìlẹ̀ Lélẹ̀ Nígbà Ìkésíni Àkọ́kọ́: Ìpìlẹ̀ fún ìpadàbẹ̀wò aláṣeyọrí ni a sábà máa ń fi lélẹ̀ nígbà ìkésíni àkọ́kọ́. Fetí sílẹ̀ dáradára sí ìlóhùnsí onílé. Kí ni wọ́n sọ fún ọ? Ó ha ní ìtẹ̀sí ní ti ìsìn bí? Àwọn ọ̀ràn ẹgbẹ́ òun ọ̀gbà ha ń jẹ ẹ́ lọ́kàn bí? Ó ha ní ọkàn ìfẹ́ nínú ìmọ̀ ìjìnlẹ̀ bí? ìtàn ńkọ́? àyíká ńkọ́? Ní ìparí ìkésíni náà, o lè gbé ìbéèrè tí ń múni ronú kan dìde, kí o sì ṣèlérí láti jíròrò ìdáhùn Bíbélì nígbà tí o bá pa dà wá.
8 Fún àpẹẹrẹ, bí onílé náà bá dáhùn pa dà sí ìlérí Bíbélì nípa párádísè ilẹ̀ ayé kan, jíjíròrò àkòrí náà síwájú sí i lè bá a mu wẹ́kú. Ṣáájú kí o tó fi ibẹ̀ sílẹ̀, o lè béèrè pé: “Báwo ni a ṣe lè ní ìdánilójú pé Ọlọ́run yóò mú ìlérí yìí ṣẹ?” Fi kún un lẹ́yìn náà pé: “Bóyá mo lè wá nígbà tí àwọn yòó kù nínú ìdílé bá wà nílé, nígbà náà, mo sì lè fi ìdáhùn Bíbélì sí ìbéèrè yí hàn ọ́.”
9 Bí onílé náà kò bá tí ì fi ọkàn ìfẹ́ hàn nínú kókó ẹ̀kọ́ kan pàtó, o lè béèrè ọ̀kan nínú àwọn ìbéèrè tí a gbé jáde nínú àwọn ìgbékalẹ̀ ọ̀rọ̀ tí ó wà lẹ́yìn Iṣẹ́ Òjíṣẹ́ Ìjọba Wa, kí o sì lo ìyẹn gẹ́gẹ́ bí ìpìlẹ̀ fún ìjíròrò rẹ tí ó tẹ̀ lé e.
10 Pa Àkọsílẹ̀ Pípéye Mọ́: Àkọsílẹ̀ ilé dé ilé rẹ gbọ́dọ̀ péye, kí ó sì kún rẹ́rẹ́. Kọ orúkọ àti àdírẹ́sì onílé sílẹ̀ gbàrà tí o bá ti kúrò ní ilé náà. Má ṣe méfòó nọ́ńbà ilé náà tàbí orúkọ àdúgbò náà—ṣàyẹ̀wò ìsọfúnni láti rí i dájú pé ó péye. Kọ àpèjúwe ẹni náà sílẹ̀. Ṣàkọsílẹ̀ àkòrí tí ẹ jíròrò, ẹsẹ Ìwé Mímọ́ tí ẹ kà, ìwé ìkẹ́kọ̀ọ́ èyíkéyìí tí o fi sóde, àti ìbéèrè tí ìwọ yóò dáhùn nígbà tí o bá pa dà lọ. Fi ọjọ́ àti àkókò tí o ṣe ìkésíni àkọ́kọ́, àti ìgbà tí o sọ pé ìwọ yóò pa dà wá kún un. Nísinsìnyí tí àkọsílẹ̀ rẹ ti kún rẹ́rẹ́, má ṣe sọ ọ́ nù! Fi sí ibi ìpamọ́ kí o baà lè lò ó lẹ́yìn náà. Máa ronú nípa ẹni náà àti bí ìwọ yóò ṣe ṣe ìkésíni náà, nígbà tí o bá pa dà lọ.
11 Mọ Ohun Tí Àwọn Ète Ìlépa Rẹ Jẹ́: Lákọ̀ọ́kọ́, nípa jíjẹ́ ọlọ́yàyà, àti akónimọ́ra, ṣe gbogbo ohun tí o bá lè ṣe láti mú kí ara tu onílé. Fi hàn pé o ní ọkàn ìfẹ́ nínú rẹ̀ gẹ́gẹ́ bí ẹnì kan, láìṣe òfíntótó jù. Lẹ́yìn náà, rán an létí ìbéèrè èyíkéyìí tí o béèrè nígbà ìbẹ̀wò tí ó ṣáájú. Fetí sílẹ̀ dáradára sí èrò ọkàn rẹ̀, kí o sì sọ ìmọrírì àtọkànwá jáde fún ìlóhùnsí rẹ̀. Lẹ́yìn náà, fi ìdí tí ojú ìwòye Bíbélì fi ṣeé mú lò hàn. Bí ó bá ṣeé ṣe, darí rẹ̀ sí èrò tí ó tan mọ́ ọn nínú ìwé Ìmọ̀ Tí Ń Sinni Lọ sí Ìyè Àìnípẹ̀kun. Fi sọ́kàn dáradára pé olórí ète ìlépa rẹ nígbà ìpadàbẹ̀wò jẹ́ láti bẹ̀rẹ̀ ìkẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì kan.
12 Ṣíṣetààràtà tí ìwé Ìmọ̀ ṣe tààràtà ti sún ọ̀pọ̀ lára wa láti ‘máyà le’ nínú àwọn ìkẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì láti fún àwọn akẹ́kọ̀ọ́ níṣìírí láti wá sí àwọn ìpàdé, kí wọ́n sì bá ètò àjọ Jèhófà kẹ́gbẹ́ pọ̀. Ní ìgbà àtijọ́, a ní ìtẹ̀sí láti dúró títí di ìgbà tí ẹnì kọ̀ọ̀kan bá ti kẹ́kọ̀ọ́ fún ìgbà gígùn kan ṣáájú kí a tó máa ké sí wọn láti bá wa kẹ́gbẹ́ pọ̀. Nísinsìnyí, ọ̀pọ̀ akẹ́kọ̀ọ́ ń wá sí àwọn ìpàdé gbàrà tí wọ́n bá ti bẹ̀rẹ̀ ìkẹ́kọ̀ọ́, wọ́n sì ń tẹ̀ síwájú lọ́nà tí ó túbọ̀ yára kánkán ní ìyọrísí èyí.
13 Tọkọtaya kan jẹ́rìí láìjẹ́ bí àṣà fún òṣìṣẹ́ ẹlẹgbẹ́ wọn kan. Nígbà tí ó fi ọkàn ìfẹ́ hàn nínú òtítọ́, wọ́n ké sí i láti ṣe ìkẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì nínú ìwé Ìmọ̀. Lákòókò kan náà, wọ́n sọ fún un pé ó yẹ kí ó máa wá sí àwọn ìpàdé, níbi tí a óò ti dáhùn púpọ̀ nínú àwọn ìbéèrè rẹ̀. Kì í ṣe pé ọkùnrin náà fi ìmúratán tẹ́wọ́ gba ìkésíni wọn láti kẹ́kọ̀ọ́ nìkan ni, ṣùgbọ́n ó tún ń ṣe ìkẹ́kọ̀ọ́ lẹ́ẹ̀mejì lọ́sẹ̀, ó sì bẹ̀rẹ̀ sí í wá sí àwọn ìpàdé déédéé ní Gbọ̀ngàn Ìjọba.
14 Lo Ìwé Pẹlẹbẹ Náà, Kí Ni Ọlọrun Ń Béèrè Lọ́wọ́ Wa?: Ní Àpéjọpọ̀ Àgbègbè “Àwọn Ońṣẹ́ Àlàáfíà Ọlọ́run” a gba ìwé pẹlẹbẹ náà, Kí Ni Ọlọrun Ń Béèrè Lọ́wọ́ Wa? Ìwé pẹlẹbẹ yìí wúlò ní bíbẹ̀rẹ̀ àwọn ìkẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì pẹ̀lú àwọn ènìyàn tí wọ́n bẹ̀rù Ọlọ́run láìka bí wọ́n ṣe kàwé tó sí. Ó ní ìtòlẹ́sẹẹsẹ ẹ̀kọ́ tí ó kún rẹ́rẹ́, tí ó kárí àwọn ẹ̀kọ́ pàtàkì ti Bíbélì. Ìtẹ̀jáde náà yóò jẹ́ irin iṣẹ́ gbígbéṣẹ́ fún fífúnni ní ìmọ̀ Ọlọ́run. Ó ṣàlàyé òtítọ́ ní kedere àti lọ́nà rírọrùn tó bẹ́ẹ̀ tí ó fi fẹ́rẹ̀ẹ́ jẹ́ pé gbogbo wa ni yóò lè lò ó láti kọ́ àwọn ẹlòmíràn ní àwọn ohun tí Ọlọ́run ń béèrè. Ó ṣeé ṣe pé, ọ̀pọ̀ akéde yóò ní àǹfààní dídarí ìkẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì nínú ìwé pẹlẹbẹ yìí.
15 Àwọn kan tí wọ́n ronú pé àwọn kò ní àkókò láti kẹ́kọ̀ọ́ ìwé Ìmọ̀ lè múra tán láti lo sáà kúkúrú láti kẹ́kọ̀ọ́ ìwé pẹlẹbẹ Béèrè. Inú wọn yóò dùn sí ohun tí wọ́n bá kọ́! Nínú ojú ìwé méjì tàbí mẹ́ta péré, wọn yóò rí ìdáhùn sí àwọn ìbéèrè tí àwọn ènìyàn ti ń fi ọ̀pọ̀ ọ̀rúndún ronú sí: Ta ni Ọlọ́run? Ta ni Èṣù? Kí ni ète Ọlọ́run fún ilẹ̀ ayé? Kí ni Ìjọba Ọlọ́run? Báwo ni o ṣe lè rí ìsìn tòótọ́? Bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé ìwé pẹlẹbẹ náà gbé òtítọ́ kalẹ̀ ní èdè tí ó rọrùn, ìhìn iṣẹ́ rẹ̀ lágbára gidigidi. Ó kárí àwọn kókó pàtàkì tí àwọn alàgbà yóò bá àwọn olùnàgà fún batisí ṣàtúnyẹ̀wò rẹ̀, ó sì lè ṣiṣẹ́ gẹ́gẹ́ bí àtẹ̀gùn sí ìkẹ́kọ̀ọ́ tí ó túbọ̀ kún rẹ́rẹ́ nínú ìwé Ìmọ̀.
16 Láti fi ìkẹ́kọ̀ọ́ lọni nígbà ìpadàbẹ̀wò kan, o wulẹ̀ lè sọ pé: “O ha mọ̀ pé nípa lílo ìṣẹ́jú díẹ̀ péré, o lè rí ìdáhùn sí ìbéèrè Bíbélì pàtàkì kan?” Lẹ́yìn náà, béèrè ìbéèrè kan tí ó wà ní ìbẹ̀rẹ̀ ọ̀kan nínú àwọn ẹ̀kọ́ tí ń bẹ nínú ìwé pẹlẹbẹ náà. Fún àpẹẹrẹ, bí o bá ń ké sí àgbàlagbà kan, o lè sọ pé: “A mọ̀ pé ní ìgbà àtijọ́, Jésù mú àwọn ènìyàn lára dá. Ṣùgbọ́n ní ọjọ́ iwájú, kí ni Jésù yóò ṣe fún àwọn aláìsàn? àwọn àgbàlagbà? àwọn òkú?” Àwọn ìdáhùn náà wà ní ẹ̀kọ́ 5. Ẹnì kan tí ìsìn jẹ lọ́kàn ni a lè ru lọ́kàn sókè nípasẹ̀ ìbéèrè náà pé: “Ọlọrun ha ń tẹ́tí sí gbogbo àdúrà bí?” A dáhùn rẹ̀ ní ẹ̀kọ́ 7. Àwọn mẹ́ńbà ìdílé yóò fẹ́ láti mọ: “Kí ni Ọlọrun ń béèrè lọ́wọ́ àwọn òbí àti àwọn ọmọ?” Wọn yóò rí i bí wọ́n ṣe ń kẹ́kọ̀ọ́ ẹ̀kọ́ 8. Àwọn ìbéèrè míràn ni: “Òkú ha lè pa alààyè lára bí?” tí a ṣàlàyé ní ẹ̀kọ́ 11; “Èé ṣe tí ìsìn tí ń jẹ́wọ́ pé wọ́n jẹ́ Kristian fi pọ̀ tó bẹ́ẹ̀?” tí a jíròrò ní ẹ̀kọ́ 13; àti “Kí ni o gbọ́dọ̀ ṣe láti lè di ọ̀rẹ́ Ọlọrun?” tí a kárí ní ẹ̀kọ́ 16.
17 Ran Àwọn Tí Ń Sọ Èdè Míràn Lọ́wọ́: Àwọn onílé tí ń sọ èdè míràn ńkọ́? Bí ó bá ṣeé ṣe, èdè tí wọn mọ̀ jù lọ ni ó yẹ kí a fi kọ́ wọn. (1 Kọ́r. 14:9) A gbọ́dọ̀ kíyè sí orúkọ àti àdírẹ́sì irú àwọn ẹni bẹ́ẹ̀ kí a sì ṣètò akéde kan tí ó ń sọ èdè wọn láti pa dà lọ kí ó sì bá wọn kẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì. Bí kò bá sí àwọn ìjọ tàbí àwùjọ nítòsí, tí kò sì sí akéde ìjọ tí ó lè sọ èdè onílé náà, akéde náà lè gbìyànjú láti bá onílé náà kẹ́kọ̀ọ́ ní lílo ìwé pẹlẹbẹ Béèrè ní èdè méjèèjì.
18 Akéde kan tí ń sọ èdè Gẹ̀ẹ́sì bẹ̀rẹ̀ ìkẹ́kọ̀ọ́ kan pẹ̀lú ọkùnrin kan tí ń sọ èdè Vietnam àti pẹ̀lú ìyàwó rẹ̀ tí ń sọ èdè Thai. Wọ́n lo àwọn ìtẹ̀jáde àti Bíbélì ní èdè Gẹ̀ẹ́sì, Vietnam, àti Thai ní àkókò ìkẹ́kọ̀ọ́ náà. Bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé ìdènà èdè jẹ́ ìṣòro lákọ̀ọ́kọ́, akéde náà kọ̀wé pé: “Ìdàgbàsókè tẹ̀mí tọkọtaya náà ti jẹ́ lọ́gán. Wọ́n ti rí ìdí náà láti bẹ̀rẹ̀ sí í wá sí àwọn ìpàdé pẹ̀lú àwọn ọmọ wọn méjì, wọ́n sì ń ka Bíbélì ní alaalẹ́ gẹ́gẹ́ bí ìdílé kan. Ọmọbìnrin wọn ọlọ́dún mẹ́fà ń darí ìkẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì tirẹ̀ fúnra rẹ̀.”
19 Nígbà tí o bá ń bá àwọn ènìyàn tí ń sọ èdè míràn ṣe ìkẹ́kọ̀ọ́, rọra máa sọ̀rọ̀, pe àwọn ọ̀rọ̀ ketekete, sì lo àwọn ọ̀rọ̀ àti àpólà ọ̀rọ̀ rírọrùn. Bí ó ti wù kí ó rí, fi sọ́kàn pé a gbọ́dọ̀ buyì fún àwọn ènìyàn tí ń sọ èdè míràn. A kò gbọ́dọ̀ bá wọn lò bí ẹni pé ọmọdé ni wọ́n.
20 Lo àwọn àwòrán ẹlẹ́wà tí ń bẹ nínú ìwé pẹlẹbẹ Béèrè dáradára. Bí “àwòrán kan bá jẹ́ iye kan náà pẹ̀lú ẹgbẹ̀rún ọ̀rọ̀,” ọ̀pọ̀ àwòrán tí ń bẹ nínú ìwé pẹlẹbẹ náà yóò pèsè ìsọfúnni púpọ̀ fún onílé. Ké sí i láti ka àwọn ẹsẹ Ìwé Mímọ́ nínú Bíbélì tirẹ̀. Bí a bá lè darí ìkẹ́kọ̀ọ́ náà nígbà tí mẹ́ńbà ìdílé kan tí ó mọ èdè Gẹ̀ẹ́sì bá wà lárọ̀ọ́wọ́tó láti ṣe ògbufọ̀, ó dájú pé ìyẹn yóò ṣàǹfààní.—Wo Iṣẹ́ Òjíṣẹ́ Ìjọba Wa, July 1984, ojú ìwé 8.
21 Ṣe Ìpadàbẹ̀wò Láìjáfara: Báwo ni ó ṣe yẹ kí o dúró pẹ́ tó kí o tó ṣe ìpadàbẹ̀wò? Àwọn akéde kan ń pa dà lọ láàárín ọjọ́ kan tàbí méjì tí wọ́n kọ́kọ́ ṣe ìkésíni. Àwọn mìíràn pa dà lọ ní ọjọ́ kan náà! Ìyẹn ha ti yá jù bí? Ní gbogbogbòò, ó dà bí ẹni pé àwọn onílé kì í kọ̀. Lọ́pọ̀ ìgbà, akéde tí ń ké síni náà ni ó ní láti túbọ̀ mú ìṣarasíhùwà rere àti ìmáyàle dàgbà sí i. Gbé àwọn ìrírí tí ó tẹ̀ lé e yìí yẹ̀ wò.
22 Akéde ọmọ ọdún 13 kan ń ṣiṣẹ́ láti ilé dé ilé ní ọjọ́ kan nígbà tí ó rí àwọn obìnrin méjì tí wọ́n jọ ń rìn lọ. Bí ìṣírí náà láti wàásù fún àwọn ènìyàn níbikíbi tí a bá ti rí wọn ti jẹ ẹ́ lọ́kàn, ó tọ àwọn obìnrin tí ń bẹ ní òpópónà náà lọ. Wọ́n fi ọkàn ìfẹ́ hàn nínú ìhìn iṣẹ́ Ìjọba náà, ẹnì kọ̀ọ̀kan wọn sì gba ìwé Ìmọ̀. Arákùnrin ọ̀dọ́ náà gba àdírẹ́sì wọn, ó pa dà lọ ní ọjọ́ méjì lẹ́yìn náà, ó sì bẹ̀rẹ̀ ìkẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì pẹ̀lú ọ̀kọ̀ọ̀kan lára wọn.
23 Arábìnrin kan ṣètò láti pa dà ṣe ìkésíni ní ọ̀sẹ̀ tí ó tẹ̀ lé e. Ṣùgbọ́n ọjọ́ kan tàbí méjì lẹ́yìn ìkésíni àkọ́kọ́, ó yà láti fún onílé náà ní ìwé ìròyìn kan lórí kókó ẹ̀kọ́ tí wọ́n jíròrò ṣáájú. Ó sọ fún onílé náà pé: “Mo rí àpilẹ̀kọ yìí mo sì ronú pé ìwọ yóò fẹ́ láti kà á. N kò ní lè dúró sọ̀rọ̀ báyìí, ṣùgbọ́n, n óò pa dà wá ní ọ̀sán Wednesday gẹ́gẹ́ bí a ti wéwèé. Ṣé àkókò yẹn ṣì wọ̀ fún ọ?”
24 Nígbà tí ẹnì kan bá fi ọkàn ìfẹ́ hàn nínú òtítọ́, a lè ní ìdánilójú pé òun yóò dojú kọ àtakò lọ́nà kan tàbí òmíràn. Títètè pa dà lọ lẹ́yìn tí a bá ti ṣe ìkésíni àkọ́kọ́ yóò fún un lókun láti kápá ìfúngunmọ́ èyíkéyìí tí òun ń dojú kọ láti ọ̀dọ̀ àwọn ìbátan, àwọn ọ̀rẹ́ tímọ́tímọ́, àti àwọn ẹlòmíràn.
25 Mú Ọkàn Ìfẹ́ Àwọn Tí O Bá Bá Pàdé Ní Gbangba Dàgbà: Ọ̀pọ̀ lára wa máa ń gbádùn wíwàásù ní àwọn òpópónà, ní àwọn ibùdókọ̀, nínú ọkọ̀ èrò, ní àwọn ilé ìtajà kéékèèké, ní àwọn ibi ìṣeré, àti bẹ́ẹ̀ bẹ́ẹ̀ lọ. Ní àfikún sí fífi àwọn ìwé ìkẹ́kọ̀ọ́ sóde, a ní láti mú ọkàn ìfẹ́ dàgbà. Láti lè ṣe ìyẹn, a gbọ́dọ̀ sapá láti gba orúkọ, àdírẹ́sì àti bí ó bá ṣeé ṣe, nọ́ńbà tẹlifóònù gbogbo ẹni tí a bá bá pàdé tí ó bá fi ọkàn ìfẹ́ hàn. Kò ṣòro tó bí o ti lè rò láti gba àwọn ìsọfúnni wọ̀nyí. Bí ìjùmọ̀sọ̀rọ̀ náà ti ń lọ sí ìparí, mú ìwé tí o ń kọ nǹkan sí jáde kí o sì béèrè pé: “Ọ̀nà èyíkéyìí ha wà tí a lè gbà máa bá ìjùmọ̀sọ̀rọ̀ yí nìṣó ní ìgbà míràn bí?” Tàbí kí o sọ pé: “Èmi yóò fẹ́ kí o ka àpilẹ̀kọ kan tí ó dá mi lójú pé ìwọ yóò ní ọkàn ìfẹ́ sí. Ṣé kí n mú un wá sí ilé tàbí sí ibi iṣẹ́ rẹ?” Arákùnrin kan wulẹ̀ béèrè pé: “Nọ́ńbà tẹlifóònù wo ni mo ti lè kàn sí ọ?” Ó sọ pé nínú oṣù mẹ́ta, gbogbo ènìyàn tí òun bá pàdé ni ó fún òun ní nọ́ńbà fóònù wọn àyàfi kìkì ẹni mẹ́ta ni kò ṣe bẹ́ẹ̀.
26 Lo Tẹlifóònù Láti Wá Ọkàn Ìfẹ́, Kí O Sì Mú Un Dàgbà: Arábìnrin aṣáájú ọ̀nà kan lo tẹlifóònù láti dé ọ̀dọ̀ àwọn ènìyàn tí ń gbé ní àwọn ilé tí a dáàbò bò gidigidi. Ó tún ń ṣe ìpadàbẹ̀wò lọ́nà kan náà pẹ̀lú. Nígbà tí ó bá ń ṣe ìkésíni àkọ́kọ́, ó máa ń wí pé: “Mo mọ̀ pé ìwọ kò mọ̀ mí. Mo ń ṣe ìsapá àkànṣe láti kàn sí àwọn ènìyàn ní àgbègbè rẹ láti ṣàjọpín èrò kan láti inú Bíbélì. Bí ìwọ bá ní àyè díẹ̀, èmi yóò fẹ́ láti ka ìlérí tí ń bẹ nínú . . .” Lẹ́yìn kíka ẹsẹ Ìwé Mímọ́ náà, yóò sọ pé: “Kò ha ní jẹ́ ìyanu bí a bá lè rí i kí àkókò yẹn dé? Mo gbádùn kíka èyí fún ọ. Bí ìwọ pẹ̀lú bá gbádùn rẹ̀, èmi yóò fẹ́ láti tẹ̀ ọ́ láago lẹ́ẹ̀kan sí i, kí n sì jíròrò ẹsẹ Ìwé Mímọ́ mìíràn.”
27 Nígbà tí ó bá ṣe ìpadàkésíni orí fóònù, yóò rán onílé náà létí ìjùmọ̀sọ̀rọ̀ wọn ìṣáájú, yóò sì sọ pé òun yóò fẹ́ láti ka bí ipò nǹkan yóò ṣe rí nígbà tí a bá ti mú ìwà ibi kúrò, jáde láti inú Bíbélì. Lẹ́yìn náà, yóò ní ìjíròrò kúkúrú láti inú Bíbélì pẹ̀lú onílé náà. Lẹ́yìn ọ̀pọ̀ ìjùmọ̀sọ̀rọ̀ lórí tẹlifóònù, ènìyàn 35 ti ké sí i sí ilé wọn, ó sì ti bẹ̀rẹ̀ ìkẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì inú ilé méje! Ó ha máa ń ṣòro fún ọ nígbà míràn láti ṣe ìpadàbẹ̀wò sọ́dọ̀ àwọn olùfìfẹ́hàn nígbà òjò nítorí àwọn ọ̀nà tí kò ṣeé gbà kọjá, tàbí àìsàn bí? Bí ó bá rí bẹ́ẹ̀, èé ṣe tí ìwọ kò fi máa dé ọ̀dọ̀ wọn nípasẹ̀ tẹlifóònù?
28 Pa Dà Ṣiṣẹ́ Lórí Ọkàn Ìfẹ́ Tí O Rí ní Àwọn Ibi Ìṣòwò: Ṣíṣiṣẹ́ láti ilé ìtajà dé ilé ìtajà ní ohun púpọ̀ sí i nínú ju wíwulẹ̀ fi ìwé ìròyìn lọni lọ. Ọ̀pọ̀ àwọn onílé ìtajà ní ọkàn ìfẹ́ olótìítọ́ inú nínú òtítọ́, a sì gbọ́dọ̀ mú ọkàn ìfẹ́ yẹn dàgbà. Nínú àwọn ọ̀ràn kan, ó lè ṣeé ṣe láti ní ìjíròrò Bíbélì tàbí láti ṣe ìkẹ́kọ̀ọ́ níbi ìtajà wọn pàápàá. Nínú àwọn ọ̀ràn míràn, ìwọ àti olùfìfẹ́hàn náà lè pàdé nígbà ìsinmi ọ̀sán tàbí ní àkókò míràn tí ó bá wọ̀.
29 Alábòójútó arìnrìn-àjò kan kàn sí onílé ìtajà kékeré kan tí ń ta àwọn èlò oúnjẹ, ó sì yọ̀ǹda láti ṣàṣefihàn ìkẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì kan. Nígbà tí ó béèrè bí àṣefihàn náà yóò ti pẹ́ tó, alábòójútó arìnrìn-àjò náà sọ pé ìṣẹ́jú 15 péré ni yóò gbà. Nítorí ìyẹn, ẹni tí ń bójú tó ilé ìtajà náà fi àmì kan há sí ara ilẹ̀kùn pé: “Pa Dà Wá ní 20 Ìṣẹ́jú,” ó sún ìjókòó méjì mọ́ra, àwọn méjèèjì sì jíròrò ìpínrọ̀ márùn-ún àkọ́kọ́ nínú ìwé Ìmọ̀. Ohun tí ọkùnrin olóòótọ́ inú yìí kẹ́kọ̀ọ́ wú u lórí tó bẹ́ẹ̀ gẹ́ẹ́ tí ó fi wá sí Ìpàdé fún Gbogbo Ènìyàn àti ìkẹ́kọ̀ọ́ Ilé Ìṣọ́ ní Sunday yẹn, ó sì gbà láti máa bá ìkẹ́kọ̀ọ́ náà nìṣó ní ọ̀sẹ̀ tí ó tẹ̀ lé e.
30 Láti fi ìkẹ́kọ̀ọ́ lọni ní ibi ìṣòwò, o lè sọ èyí: “Ìtòlẹ́sẹẹsẹ ìkẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì wa máa ń gba ìṣẹ́jú 15 péré láti ṣàṣefihàn rẹ̀. Bí ó bá rọgbọ, èmi yóò láyọ̀ láti fi bí a ṣe ń ṣe é hàn ọ́.” Nígbà náà, pa ààlà àkókò mọ́. Bí kò bá ṣeé ṣe láti ní ìjíròrò gígùn ní ibi ìṣòwò, ó lè túbọ̀ bá a mu wẹ́kú láti kàn sí ẹni tí ń bójú tó ilé ìtajà náà, ní ilé rẹ̀.
31 Pa Dà Lọ Nígbà Tí O Kò Bá Fi Ìwé Ìkẹ́kọ̀ọ́ Kankan Sóde Pàápàá: Gbogbo ọkàn ìfẹ́ tí a bá fi hàn ń fẹ́ ìpadàbẹ̀wò, yálà a ti fi ìwé ìkẹ́kọ̀ọ́ sóde tàbí a kò tí ì ṣe bẹ́ẹ̀. Àmọ́ ṣáá o, bí ó bá wá ṣe kedere pé onílé náà kò ní ọkàn ìfẹ́ ní ti gidi nínú ìhìn iṣẹ́ Ìjọba náà, ó dára jù lọ pé kí o darí ìsapá rẹ sí ibòmíràn.
32 Nínú iṣẹ́ ẹnu ọ̀nà dé ẹnu ọ̀nà, arábìnrin kan pàdé ọ̀dọ́bìnrin kan tí ó kóni mọra, ṣùgbọ́n tí ó kọ ìfilọni àwọn ìwé ìròyìn pátápátá. Akéde náà kọ̀wé pé: “Mo ronú nípa rẹ̀ fún ọ̀pọ̀ ọjọ́, mo sì pinnu pé mo tún fẹ́ bá a sọ̀rọ̀ lẹ́ẹ̀kan sí i.” Níkẹyìn, arábìnrin náà gbàdúrà, ó máyà le, ó sì kan ilẹ̀kùn ọ̀dọ́bìnrin náà. Sí ìdùnnú rẹ̀, onílé náà ké sí i wọlé. Ó bẹ̀rẹ̀ ìkẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì kan, ó sì tún darí rẹ̀ ní ọjọ́ kejì. Bí àkókò ti ń lọ, onílé náà wá sínú òtítọ́.
33 Wéwèé Ṣáájú Láti Ṣàṣeparí Èyí Tí Ó Pọ̀ Jù Lọ: A dábàá pé kí a máa lo àkókò díẹ̀ lọ́sọ̀ọ̀sẹ̀ láti ṣe ìpadàbẹ̀wò. Ohun púpọ̀ ni a lè ṣàṣeparí bí a bá wéwèé dáradára. Ṣètò láti ṣe ìkésíni ní àgbègbè kan náà tí ìwọ yóò ti ṣiṣẹ́ láti ilé dé ilé.
34 Àwọn tí wọ́n kẹ́sẹ járí nínú ṣíṣe ìpadàbẹ̀wò àti nínú bíbẹ̀rẹ̀ ìkẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì inú ilé sọ pé ó ṣe pàtàkì láti fi ọkàn ìfẹ́ olótìítọ́ hàn nínú àwọn ènìyàn, kí a sì máa ronú nípa wọn àní lẹ́yìn tí a bá ti kàn sí wọn tán pàápàá. Ó tún ṣe pàtàkì pẹ̀lú láti ní kókó ẹ̀kọ́ Bíbélì tí ń fani mọ́ra láti jíròrò, kí a sì fi ìpìlẹ̀ lélẹ̀ fún ìpadàbẹ̀wò kí a tó kúrò nígbà ìkésíni àkọ́kọ́. Síwájú sí i, ó ṣe pàtàkì láti pa dà lákòókò láti ṣiṣẹ́ lórí ọkàn ìfẹ́ náà. A gbọ́dọ̀ máa fi ète ìlépa ti bíbẹ̀rẹ̀ ìkẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì kan sọ́kàn dáradára nígbà gbogbo.
35 Ìgboyà jẹ́ ànímọ́ ṣíṣe kókó fún àṣeyọrí nínú iṣẹ́ ìpadàbẹ̀wò. Báwo ni a ṣe ń ní in? Àpọ́sítélì Pọ́ọ̀lù dáhùn nípa sísọ pé a “máyà le” láti polongo ìhìn rere náà fún àwọn ẹlòmíràn “nípasẹ̀ Ọlọ́run wa.” Bí o bá ní láti dàgbà sókè ní àgbègbè yí, gbàdúrà fún ìrànwọ́ Jèhófà. Lẹ́yìn náà, ní ìbámu pẹ̀lú àdúrà rẹ, ṣiṣẹ́ lórí gbogbo ọkàn ìfẹ́. Dájúdájú, Jèhófà yóò bù kún ìsapá rẹ!
[Àpótí tó wà ní ojú ìwé 3]
Bí A Ṣe Lè Kẹ́sẹ Járí Nínú Ṣíṣe Ìpadàbẹ̀wò
■ Fi ọkàn ìfẹ́ olótìítọ́ inú hàn nínú àwọn ènìyàn.
■ Yan kókó ẹ̀kọ́ Bíbélì kan tí ń fani mọ́ra láti jíròrò.
■ Fi ìpìlẹ̀ lélẹ̀ fún ìbẹ̀wò kọ̀ọ̀kan tí yóò tẹ̀ lé e.
■ Máa ronú nípa ẹni náà lẹ́yìn tí o bá ti kúrò níbẹ̀.
■ Pa dà lọ níwọ̀n ọjọ́ kan tàbí méjì láti ṣiṣẹ́ lórí ọkàn ìfẹ́ náà.
■ Fi ète ìlépa rẹ láti bẹ̀rẹ̀ ìkẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì kan sọ́kàn.
■ Gbàdúrà fún ìrànwọ́ láti máyà le fún iṣẹ́ yìí.