Apá Kọkànlá: Bí A Ṣe Lè Darí Ìkẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì Tí Yóò Máa Tẹ̀ Síwájú
Bá A Ṣe Lè Kọ́ Akéde Tuntun Kó Lè Máa Ṣe Ìpadàbẹ̀wò
1 Bí akẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì kan bá bẹ̀rẹ̀ sí lọ́wọ́ nínú iṣẹ́ ìwàásù, ó máa báwọn tó nífẹ̀ẹ́ sí ìhìn rere pàdé. Báwo la ṣe lè ran akéde tuntun náà lọ́wọ́ kó lè mọ bá a ṣe ń ṣe ìpadàbẹ̀wò lọ́nà tó múná dóko kó sì mú kí ìfẹ́ ẹni tó wàásù fún jinlẹ̀ sí i?
2 Ìgbà àkọ́kọ́ tá a bá wàásù fẹ́ni kan ló yẹ ká ti bẹ̀rẹ̀ sí múra sílẹ̀ fún ìpadàbẹ̀wò. Gba akẹ́kọ̀ọ́ náà níyànjú pé kó máa fi àwọn tó ń wàásù fún sọ́kàn. (Fílí. 2:4) Máa kọ́ ọ ní ṣísẹ̀-n-tẹ̀lé bó ṣe lè mú kí wọ́n máa sọ èrò inú wọn jáde, bó ṣe lè máa fetí sílẹ̀ bí wọ́n bá ń sọ̀rọ̀ àti bó ṣe lè máa fiyè sí ohun tó ń jẹ wọ́n lọ́kàn. Bí ẹnì kan bá fìfẹ́ hàn, sọ fún akéde tuntun náà pé kó kọ ohun tó bá ẹni náà jíròrò sílẹ̀. Àkọsílẹ̀ yẹn ni kó o lò láti fi bá a múra ìjíròrò tó máa tẹ̀lé e.
3 Kọ́ Ọ Bó Ṣe Lè Múra Sílẹ̀ Kó Tó Lọ Ṣe Ìpadàbẹ̀wò: Ẹ jọ jíròrò ohun tó bá ẹni náà sọ nígbà àkọ́kọ́ tí wọ́n pàdé, kó o sì fi hàn án bó ṣe máa múra kókó ọ̀rọ̀ tó máa fa onílé náà mọ́ra sílẹ̀. (1 Kọ́r. 9:19-23) Ẹ jọ múra ọ̀nà ìgbọ́rọ̀kalẹ̀ ṣókí. Kí èyí dá lórí ẹsẹ Bíbélì tó wà nínú ìpínrọ̀ kan nínú ìwé kan tá a fi ń ṣe ìkẹ́kọ̀ọ́. Láfikún sí i, ẹ múra ìbéèrè kan tó máa fi kádìí ìjíròrò náà èyí tó máa jẹ́ kó ṣeé ṣe láti lè ṣe ìpadàbẹ̀wò mìíràn. Jẹ́ kí akéde tuntun náà mọ bó ṣe lè fi kún ìmọ̀ tẹ́ni náà ní nínú Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run ní gbogbo ìgbà tó bá ń bẹ̀ ẹ́ wò.
4 Ó tún dáa láti bá akẹ́kọ̀ọ́ náà múra ọ̀nà ìgbọ́rọ̀kalẹ̀ tó rọrùn, èyí tó lè lò nígbà ìpadàbẹ̀wò. Lẹ́yìn tó bá ti kí onílé, ó lè sọ pé: “Mo gbádùn ìfèròwérò wa ọjọ́sí, ìdí nìyẹn tí mo ṣe ní kí n padà wá ká lè tún sọ̀rọ̀ díẹ̀ lórí ohun tí Bíbélì sọ nípa [mẹ́nu ba ẹṣin ọ̀rọ̀ kan].” O tún lè kọ́ akéde tuntun náà bó ṣe máa fèsì bó bá jẹ́ ẹlòmíì ló bá nílé dípò ẹni tó ń kọ́ lẹ́kọ̀ọ́.
5 Máa Padà Lọ Láìjáfara: Gba akẹ́kọ̀ọ́ náà níyànjú pé kó fi àpẹẹrẹ tó dáa lélẹ̀ nípa yíyára ṣèbẹ̀wò sọ́dọ̀ àwọn tó bá fìfẹ́ hàn. Ká bàa lè máa bá àwọn èèyàn nílé, àfi ká rí i pé à ń padà lọ bẹ̀ wọ́n wò léraléra. Kọ́ akẹ́kọ̀ọ́ náà bó ṣe lè máa bá wọn ṣàdéhùn pé òun á padà bẹ̀ wọ́n wò, kó o sì ràn án lọ́wọ́ bó ṣe lè máa mú àdéhùn náà ṣẹ. (Mát. 5:37) Kọ́ akéde tuntun yìí bó ṣe lè jẹ́ onínúure, bó ṣe lè máa gba tàwọn ẹlòmíràn rò àti bó ṣe lè máa fọ̀wọ̀ àwọn èèyàn wọ̀ wọ́n lẹ́nu iṣẹ́ wíwá àwọn ẹni bí àgùntàn kiri àti lásìkò tó bá ń kọ́ wọn kí ìfẹ́ tí wọ́n ní lè máa jinlẹ̀ sí i.—Títù 3:2.