ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍNTÁNẸ́Ẹ̀TÌ ti Watchtower
ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍŃTÁNẸ́Ẹ̀TÌ
ti Watchtower
Yorùbá
ọ́
  • ẹ
  • ọ
  • ṣ
  • ń
  • ẹ́
  • ẹ̀
  • ọ́
  • ọ̀
  • BÍBÉLÌ
  • ÌTẸ̀JÁDE
  • ÌPÀDÉ
  • km 4/03 ojú ìwé 8
  • Ìpadàbẹ̀wò Ń Ṣamọ̀nà sí Ìkẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì

Kò sí fídíò kankan ní apá yìí.

Má bínú, fídíò yìí kò jáde.

  • Ìpadàbẹ̀wò Ń Ṣamọ̀nà sí Ìkẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì
  • Iṣẹ́ Òjíṣẹ́ Ìjọba Wa—2003
  • Àpilẹ̀kọ Míì Tó Jọ ọ́
  • Máyà Le Láti Ṣe Ìpadàbẹ̀wò
    Iṣẹ́ Òjíṣẹ́ Ìjọba Wa—1997
  • A Ń Fẹ́ Ìkẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì Púpọ̀ Sí I
    Iṣẹ́ Òjíṣẹ́ Ìjọba Wa—1998
  • Ran Àwọn Tó Ní “Ìtẹ̀sí-Ọkàn Títọ́” Lọ́wọ́
    Iṣẹ́ Òjíṣẹ́ Ìjọba Wa—2003
  • Ìmúrasílẹ̀—Ọ̀nà Kan Ṣoṣo Láti Ṣe Ìpadàbẹ̀wò Tó Múná Dóko
    Iṣẹ́ Òjíṣẹ́ Ìjọba Wa—2008
Iṣẹ́ Òjíṣẹ́ Ìjọba Wa—2003
km 4/03 ojú ìwé 8

Ìpadàbẹ̀wò Ń Ṣamọ̀nà sí Ìkẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì

1. Kí nìdí tí ṣíṣe ìpadàbẹ̀wò fi ṣe pàtàkì gan-an?

1 Kì í ṣe iṣẹ́ ìwàásù nìkan ni iṣẹ́ tí Jésù yàn fún àwọn ọmọlẹ́yìn rẹ̀ láti ṣe, àmọ́ wọ́n tún ní láti ‘sọ àwọn èèyàn di ọmọ ẹ̀yìn, kí wọ́n sì máa kọ́ wọn.’ (Mát. 28:19, 20) Ọ̀rọ̀ nìkan ni oníwàásù máa ń sọ fún àwọn èèyàn, àmọ́ olùkọ́ máa ń ṣe jù bẹ́ẹ̀ lọ. Ó máa ń kọ́ni lẹ́kọ̀ọ́, á ṣàlàyé ọ̀rọ̀ rẹ̀, á sì fi ẹ̀rí gbe ọ̀rọ̀ rẹ̀ lẹ́sẹ̀. Ọ̀nà kan tá a lè gbà kọ́ àwọn ẹlòmíràn lẹ́kọ̀ọ́ ni nípa ṣíṣe ìpadàbẹ̀wò sọ́dọ̀ àwọn olùfìfẹ́hàn, ká sì máa ní in lọ́kàn láti bẹ̀rẹ̀ ìkẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì pẹ̀lú wọn.

2. Ta ló yẹ ká padà lọ bẹ̀ wò?

2 Ta ló yẹ kó o ṣe ìpadàbẹ̀wò sọ́dọ̀ rẹ̀? Rí i pé o padà lọ ṣèbẹ̀wò sọ́dọ̀ gbogbo àwọn tó gba ìwé ìkẹ́kọ̀ọ́ tàbí àwọn tó jẹ́ pé ìfẹ́ díẹ̀ ni wọ́n fi hàn. Bó o bá rí ẹnì kan tó fìfẹ́ hàn nígbà tó o wà nínú iṣẹ́ ìsìn pápá, gbìyànjú láti gba àdírẹ́sì àti nọ́ńbà tẹlifóònù onítọ̀hún kó lè ṣeé ṣe fún un láti tẹ̀ síwájú. Máa ní in lọ́kàn pé o fẹ́ bẹ̀rẹ̀ ìkẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì pẹ̀lú wọn. Máa bá a nìṣó láti wá àwọn tó máa gbà láti kẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì, ó dájú pé wàá rí wọn.—Mát. 10:11.

3, 4. Àwọn nǹkan wo ló yẹ ká ṣe láti ṣe ìpadàbẹ̀wò tó gbéṣẹ́?

3 Fi Ìfẹ́ Àtọkànwá Hàn sí Wọn: Ìgbà àkọ́kọ́ tí a bá ti bá ẹnì kan sọ̀rọ̀ ni ìmúrasílẹ̀ fún ìpadàbẹ̀wò tó gbéṣẹ́ ti bẹ̀rẹ̀. Àwọn oníwàásù tó ti kẹ́sẹ járí máa ń kíyè sí ohun tó wu àwọn onílé, wọ́n sì máa ń lo ìyẹn láti fi ṣe ìpìlẹ̀ fún ìjíròrò síwájú sí i. Àwọn kan rí i pé ó máa ń dára gan-an láti béèrè ìbéèrè kan ní ìparí ìjíròrò náà, kí onílé náà lè máa wọ̀nà fún ìbẹ̀wò tó máa tẹ̀ lé e. Ìfẹ́ àtọkànwá tá a ní sí àwọn èèyàn yóò jẹ́ ká máa ronú nípa wọn kódà lẹ́yìn tá a bá ti kúrò lọ́dọ̀ wọn, yóò sì sún wa láti padà lọ bẹ̀ wọ́n wò láìjáfara. Bó bá ṣeé ṣe, gbìyànjú láti padà lọ nígbà tí ìfẹ́ yẹn ṣì wà níbẹ̀—bóyá láàárín ọjọ́ kan tàbí méjì lẹ́yìn ìjíròrò yín.

4 Nígbà tó o bá ń ṣe ìpadàbẹ̀wò, gbìyànjú láti bẹ̀rẹ̀ lórí àwọn ohun tẹ́ ẹ jíròrò níṣàájú. Fi ṣe góńgó rẹ pé, wàá máa jíròrò ó kéré tán, kókó kan tí ń gbéni ró látinú Ìwé Mímọ́ ní gbogbo ìgbà tẹ́ ẹ bá ríra, kó o sì múra tán láti fetí sílẹ̀ sí i. Sapá láti mọ onílé náà dunjú. Lẹ́yìn náà, láwọn ìgbà tó o bá tún ṣèbẹ̀wò síbẹ̀, máa jíròrò àwọn ẹ̀kọ́ òtítọ́ tó wà nínú Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run pẹ̀lú rẹ̀, èyí tó dáhùn àwọn ìbéèrè rẹ̀ ní tààràtà.

5. Ọ̀nà tó rọrùn wo la lè gbà bẹ̀rẹ̀ ìkẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì?

5 Máa Lo Àǹfààní Tó Bá Yọ Láti Bẹ̀rẹ̀ Ìkẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì: Máa ní in lọ́kàn pé o fẹ́ bẹ̀rẹ̀ ìkẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì nígbà tó o bá lọ ṣe ìpadàbẹ̀wò. Báwo la ṣe lè ṣe èyí? Sọ fún onílé pé wàá fẹ́ láti jíròrò kókó fífanimọ́ra kan pẹ̀lú rẹ̀, kó o sì ṣí ìwé Ìmọ̀ tàbí ìwé pẹlẹbẹ Béèrè sí ìpínrọ̀ kan tó o rò pé yóò wu onítọ̀hún. Ka ìpínrọ̀ náà, béèrè ìbéèrè tó wà níbẹ̀, kó o sì jíròrò ẹsẹ Ìwé Mímọ́ kan tàbí méjì tá a tọ́ka sí. A lè ṣe èyí ní ẹnu ọ̀nà onílé láàárín ìṣẹ́jú márùn-ún sí mẹ́wàá. Láti parí ìjíròrò náà, béèrè ìbéèrè tó tẹ̀ lé e kó o sì ṣètò láti máa bá ìjíròrò náà lọ nígbà mìíràn.

6. Báwo la ṣe lè fi hàn pé a mọ ìjẹ́pàtàkì ṣíṣe ìpadàbẹ̀wò?

6 Mímú kí gbogbo àwọn tí wọ́n fìfẹ́ hàn tẹ̀ síwájú jẹ́ apá pàtàkì kan nínú iṣẹ́ òjíṣẹ́ wa. Nítorí náà, ya àkókò sọ́tọ̀ nínú ìtòlẹ́sẹẹsẹ rẹ ọ̀sọ̀ọ̀sẹ̀ fún ṣíṣe ìpadàbẹ̀wò. Ṣíṣe bẹ́ẹ̀ yóò mú kí iṣẹ́ òjíṣẹ́ rẹ gbéṣẹ́ sí i, yóò sì fún ọ ní ojúlówó ayọ̀.

    Yorùbá Publications (1987-2025)
    Jáde
    Wọlé
    • Yorùbá
    • Fi Ráńṣẹ́
    • Èyí tí mo fẹ́ràn jù
    • Copyright © 2025 Watch Tower Bible and Tract Society of Pennsylvania
    • Àdéhùn Nípa Lílò
    • Òfin
    • Ètò Nípa Ìsọfúnni Rẹ
    • JW.ORG
    • Wọlé
    Fi Ráńṣẹ́