ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍNTÁNẸ́Ẹ̀TÌ ti Watchtower
ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍŃTÁNẸ́Ẹ̀TÌ
ti Watchtower
Yorùbá
ọ́
  • ẹ
  • ọ
  • ṣ
  • ń
  • ẹ́
  • ẹ̀
  • ọ́
  • ọ̀
  • BÍBÉLÌ
  • ÌTẸ̀JÁDE
  • ÌPÀDÉ
  • km 12/98 ojú ìwé 3-4
  • A Ń Fẹ́ Ìkẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì Púpọ̀ Sí I

Kò sí fídíò kankan ní apá yìí.

Má bínú, fídíò yìí kò jáde.

  • A Ń Fẹ́ Ìkẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì Púpọ̀ Sí I
  • Iṣẹ́ Òjíṣẹ́ Ìjọba Wa—1998
  • Àpilẹ̀kọ Míì Tó Jọ ọ́
  • Máyà Le Láti Ṣe Ìpadàbẹ̀wò
    Iṣẹ́ Òjíṣẹ́ Ìjọba Wa—1997
  • Ìpadàbẹ̀wò Ń Ṣamọ̀nà sí Ìkẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì
    Iṣẹ́ Òjíṣẹ́ Ìjọba Wa—2003
  • Àyẹ̀wò Tó Ń Tẹ̀ Síwájú Nípa Ìjẹ́kánjúkánjú Iṣẹ́ Sísọni Di Ọmọ Ẹ̀yìn
    Iṣẹ́ Òjíṣẹ́ Ìjọba Wa—2000
  • Ìmúrasílẹ̀—Ọ̀nà Kan Ṣoṣo Láti Ṣe Ìpadàbẹ̀wò Tó Múná Dóko
    Iṣẹ́ Òjíṣẹ́ Ìjọba Wa—2008
Àwọn Míì
Iṣẹ́ Òjíṣẹ́ Ìjọba Wa—1998
km 12/98 ojú ìwé 3-4

A Ń Fẹ́ Ìkẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì Púpọ̀ Sí I

1 Jèhófà Ọlọ́run ń fi ìbísí tí ń bá a nìṣó bù kún ètò rẹ̀ orí ilẹ̀ ayé. Ní ọdún iṣẹ́ ìsìn 1997, àwọn 375,923 ni a batisí jákèjádò ayé—ìpíndọ́gba tí ó ré kọjá ẹgbẹ̀rún kan àwọn ọmọ ẹ̀yìn tuntun lóòjọ́, tàbí nǹkan bí àwọn mẹ́tàlélógójì ní wákàtí kọ̀ọ̀kan! Láìka ìnira tí àwọn ará wa ti lè fi ọ̀pọ̀ ẹ̀wádún dojú kọ ní onírúurú ibi nínú ayé sí, iṣẹ́ Ìjọba náà ń gbọ̀rẹ̀gẹ̀jigẹ̀, a sì ń rí ìbísí títayọ lọ́lá. Ó mà ń mú inú ẹni dùn o láti kà nípa ìtẹ̀síwájú tí a ti ní nínú títan ìhìn rere náà kálẹ̀!

2 Ní Nàìjíríà, ní ọdún iṣẹ́ ìsìn 1997, àwa pẹ̀lú ní ìbísí nínú ìpíndọ́gba àròpọ̀ iye àwọn akéde àti àwọn aṣáájú ọ̀nà olùrànlọ́wọ́, nínú wákàtí tí a fi wàásù, àti nínú iye àwọn ìwé kékeré, ìwé pẹlẹbẹ, àti ìwé ìròyìn tí a fi sóde. Ìbísí wà nínú iye àwọn tí a batisí àti nínú iye àwọn tí ó wá sí Ìṣe Ìrántí tí ó ju ti ìgbàkígbà rí lọ. Ìgbòkègbodò ìpadàbẹ̀wò àti ìkẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì ńkọ́? A tún ní ìbísí nínú àròpọ̀ iye ìpadàbẹ̀wò àti ìbísí ìpín márùn-ún nínú ọgọ́rùn-ún nínú ìkẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì. Nígbà tí ó jẹ́ pé ìbísí wọ̀nyí mú wa láyọ̀, ìpíndọ́gba iye ìkẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì tí kò tó ẹyọ kan fún ọdún iṣẹ́ ìsìn yẹn fi hàn pé kì í ṣe gbogbo akéde ló ń ṣe ìkẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì lóṣooṣù. Síbẹ̀, apá yìí nínú iṣẹ́ òjíṣẹ́ ṣe pàtàkì gidigidi nínú iṣẹ́ sísọni di ọmọ ẹ̀yìn. Kí ni ẹnì kọ̀ọ̀kan wa lè ṣe láti rí i dájú pé a ń darí àwọn ìkẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì déédéé?

3 Kí A Fún Ìfẹ́-Ọkàn Láti Darí Ìkẹ́kọ̀ọ́ Lókun: Ó yẹ kí àwa fúnra wa fún jíjẹ́ alágbára àti jíjẹ́ ògbóṣáṣá nípa tẹ̀mí ní àfiyèsí. Àwọn ọmọlẹ́yìn Kristi tòótọ́ jẹ́ “onítara fún iṣẹ́ àtàtà.” (Títù 2:14) Nígbà tí a bá ṣàyẹ̀wò iṣẹ́ òjíṣẹ́ wa, ṣé a lè sọ pé a ń fi ìtara-ọkàn mímúná padà ṣiṣẹ́ lórí gbogbo ìwé ìkẹ́kọ̀ọ́ tí a fi sóde? Ṣé a jẹ́ onítara ní ti fífi ìkẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì inú ilé lọ gbogbo àwọn tí ó bá fi ọkàn-ìfẹ́ hàn? (Róòmù 12:11) Tàbí, a ha ní láti mú ìfẹ́-ọkàn tí ó túbọ̀ jinlẹ̀ dàgbà láti ṣe ìpadàbẹ̀wò kí a sì bẹ̀rẹ̀ ìkẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì inú ilé?

4 Dídá ka Bíbélì, lílọ sí ìpàdé déédéé, àti kíkẹ́kọ̀ọ́ àwọn ìtẹ̀jáde náà yóò mú kí a wà láàyè nípa tẹ̀mí kí ẹ̀mí Ọlọ́run sì fún wa lágbára. (Éfé. 3:16-19) Èyí yóò fún ìgbàgbọ́ àti ìgbọ́kànlé wa nínú Jèhófà àti ìfẹ́ wa fún ènìyàn ẹlẹgbẹ́ wa lókun. A óò sún wa láti fi òtítọ́ kọ́ ẹlòmíràn, a óò sì tipa báyìí mú kí iṣẹ́ òjíṣẹ́ wa máa gbádùn mọ́ni, kí ó kẹ́sẹ járí, kí ó sì máa tani jí. Dájúdájú, a ń fẹ́ ìkẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì púpọ̀ sí i!

5 Kọ́kọ́ Ṣèkẹ́kọ̀ọ́ Pẹ̀lú Ìdílé Rẹ: Ó yẹ kí ètò ìkẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì ìdílé tí ó ṣe déédéé jẹ àwọn òbí tí wọ́n ní àwọn ọmọ tí ń gbé lọ́dọ̀ wọn lógún. (Diu. 31:12; Sm. 148:12, 13; Òwe 22:6) Yóò ṣàǹfààní gidigidi pé kí àwọn òbí bá àwọn ọmọ wọn ṣèkẹ́kọ̀ọ́ nínú ìwé pẹlẹbẹ Béèrè àti lẹ́yìn náà nínú ìwé Ìmọ̀ láti múra wọn sílẹ̀ fún títóótun gẹ́gẹ́ bí akéde tí kò tí ì ṣe batisí àti fún ìyàsímímọ́ àti batisí. Àmọ́ ṣá o, wọ́n lè kẹ́kọ̀ọ́ àkójọ ọ̀rọ̀ mìíràn ní àfikún sí i, ó sinmi lórí ohun tí ọmọ kan nílò àti ọjọ́ orí rẹ̀. Òbí tí ó bá ń bá ọmọ tí kò tí ì ṣe batisí kẹ́kọ̀ọ́ lè ka ìkẹ́kọ̀ọ́, àkókò, àti ìpadàbẹ̀wò, bí a ṣe ṣàlàyé rẹ̀ nínú Àpótí Ìbéèrè inú Iṣẹ́ Òjíṣẹ́ Ìjọba Wa ti June 1987.

6 Mú Kí Ìṣètò Rẹ Sunwọ̀n Sí I: Bí a bá ṣàyẹ̀wò iye ìwé ìròyìn, ìwé pẹlẹbẹ, àti ìwé ńlá tí a ti fi sóde, kò sí iyèméjì pé a ti fúnrúgbìn lọ́pọ̀ yanturu. Ó ṣeé ṣe gidigidi pé kí irúgbìn òtítọ́ tí a ti fún yìí mú àwọn ọmọ ẹ̀yìn tuntun jáde. Ṣùgbọ́n ṣé àgbẹ̀ tàbí olùtọ́jú ọgbà kan yóò ní ìtẹ́lọ́rùn ní tòótọ́ bí ó bá jẹ́ pé ṣe ni ó ń fúnrúgbìn ṣáá, tí kò sì gbìyànjú láti kórè lẹ́yìn gbogbo ìsapá rẹ̀? Dájúdájú kì yóò tẹ́ ẹ lọ́rùn. Lọ́nà kan náà, pípadà lọ ṣèbẹ̀wò síbi tí a ti dé tẹ́lẹ̀ nínú iṣẹ́ òjíṣẹ́ pọndandan.

7 Ṣé o máa ń ṣètò déédéé láti ṣe ìpadàbẹ̀wò? Padà lọ ní kánmọ́ sí ibi tí a ti fi ọkàn-ìfẹ́ hàn. Ní in lọ́kàn pé o fẹ́ bẹ̀rẹ̀ ìkẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì nígbà tí o bá lọ ṣe ìpadàbẹ̀wò. Ṣé o máa ń pa àkọsílẹ̀ nípa ìpadàbẹ̀wò rẹ mọ́, èyí tí ó mọ́ tónítóní, tí ìsọfúnni inú rẹ̀ bá àkókò mu, tí o sì ṣètò dáadáa? Ní àfikún sí orúkọ àti àdírẹ́sì onílé, rí i dájú pé o kọ déètì ọjọ́ tí o kọ́kọ́ bá a sọ̀rọ̀, ìwé tí o fi sóde, àlàyé ṣókí nípa ohun tí ẹ jíròrò, àti kókó kan tí ẹ lè jíròrò nígbà tí o bá padà lọ. Fi àlàfo sílẹ̀ lórí ìwé àkọsílẹ̀ rẹ kí o lè máa rí ibi kọ ìsọfúnni sí lẹ́yìn ìpadàbẹ̀wò kọ̀ọ̀kan.

8 Mọ Bí Ó Ṣe Yẹ Kí O Ṣe Ìpadàbẹ̀wò: Kí ni àwọn kókó díẹ̀ tí ó yẹ kí o ní lọ́kàn nígbà tí o bá ń ṣe ìpadàbẹ̀wò sọ́dọ̀ ẹni tí ó fi ọkàn-ìfẹ́ hàn? (1) Jẹ́ ọlọ́yàyà, ẹni tí ó kóni mọ́ra, jẹ́ onítara, kí o sì túra ká. (2) Jíròrò àwọn kókó ẹ̀kọ́ tàbí ìbéèrè tí ó nífẹ̀ẹ́ sí. (3) Mú kí ìjíròrò náà rọrùn kí ó sì bá Ìwé Mímọ́ mu. (4) Nígbà ìpadàbẹ̀wò kọ̀ọ̀kan, sakun láti kọ́ onílé ní ohun tí yóò rí i pé ó wúlò fún òun. (5) Mú kí ó máa fojú sọ́nà fún kókó ẹ̀kọ́ tí ẹ óò jíròrò nígbà tí o bá tún padà wá. (6) Má ṣe wà lọ́dọ̀ onílé fún àkókò pípẹ́ jù. (7) Má ṣe béèrè ìbéèrè tí ń dójú ti onílé tàbí tí ó lè dààmú rẹ̀. (8) Lo ìfòyemọ̀ nípa jíjẹ́ kí onílé mú ìmọrírì fún ohun tẹ̀mí dàgbà, kí o tó sọ pé ojú ìwòye rẹ̀ kò tọ́ tàbí pé ìwà tí ó ń hù kò tọ́.—Wo àkìbọnú Iṣẹ́ Òjíṣẹ́ Ìjọba Wa ti March 1997 fún àfikún ìrànwọ́ lórí bí a ṣe lè kẹ́sẹ járí nínú ṣíṣe ìpadàbẹ̀wò àti bíbẹ̀rẹ̀ ìkẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì.

9 Ṣàwárí Gbogbo Àǹfààní Tí Ó Lè Ṣí Sílẹ̀: Nínú ìjọ kan, ó ṣeé ṣe fún wọn láti gba orúkọ àti nọ́ńbà ibùgbé gbogbo àwọn ayálégbé tí ń gbé ní àgbègbè kan tí a ti dáàbò bo àwọn ilé tí ó wà níbẹ̀ gádígádí. Wọ́n kọ lẹ́tà sí ẹnì kọ̀ọ̀kan tí ń gbé níbẹ̀, wọ́n sì fi ìwé àṣàrò kúkúrú méjì pẹ̀lú rẹ̀. Ní òpin lẹ́tà náà, wọ́n fi ìkẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì inú ilé lọ̀ wọ́n, wọ́n sì kọ nọ́ńbà tẹlifóònù kan tí ó wà ládùúgbò sí i kí ẹni tí ó bá gba lẹ́tà náà lè fèsì. Láàárín ọjọ́ díẹ̀, ọ̀dọ́kùnrin kan fóònù tí ó sì béèrè fún ìkẹ́kọ̀ọ́. A ṣe ìpadàbẹ̀wò sọ́dọ̀ rẹ̀ ní ọjọ́ kejì, a sì bẹ̀rẹ̀ ìkẹ́kọ̀ọ́ nínú ìwé Ìmọ̀. Ní alẹ́ ọjọ́ yẹn gan-an, ó wá sí Ìkẹ́kọ̀ọ́ Ìwé Ìjọ, ó sì ń bá a nìṣó láti máa wá sí gbogbo ìpàdé. Ká ṣáà sọ pé lójú ẹsẹ̀ ni ó bẹ̀rẹ̀ sí ka Bíbélì lójoojúmọ́, ó sì tẹ̀ síwájú láìyẹsẹ̀ síhà batisí.

10 Nínú àwùjọ kan, àwọn akéde ṣètò láti ṣe ìpadàbẹ̀wò pa pọ̀. Nígbà tí arábìnrin kan dé ibi ìpadàbẹ̀wò rẹ̀ kan, ẹni tó ń wá kò sí nílé, ṣùgbọ́n ọ̀dọ́bìnrin mìíràn ló dáhùn, ó sì sọ pé: “Mo ti ń dúró dè ọ́.” Onílé náà ti gba ìwé Ìmọ̀ lọ́wọ́ ẹnì kan tí ó jẹ́ ojúlùmọ̀ rẹ̀. Nígbà tí arábìnrin yẹn fi wá sí ẹnu ọ̀nà ọ̀dọ́bìnrin yìí, ọ̀dọ́bìnrin náà ti ka ìwé yìí tán lẹ́ẹ̀mejì, ìsọfúnni tí ó sì wà nínú rẹ̀ wú u lórí gidigidi. Ó sọ pé ẹnu kò ya òun pé Àwọn Ẹlẹ́rìí wá òun wá lọ́jọ́ yẹn nítorí pé òun ti ń gbàdúrà pé kí wọ́n wá kí wọ́n sì wá bá òun kẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì. Ó bẹ̀rẹ̀ ìkẹ́kọ̀ọ́, ó bẹ̀rẹ̀ sí lọ sí àwọn ìpàdé ìjọ, ó sì tẹ̀ síwájú kíákíá.

11 Lẹ́nu àìpẹ́ yìí, arábìnrin kan tí ó ti ṣe batisí ní nǹkan tí ó fẹ́rẹ̀ẹ́ tó ọdún márùndínlọ́gbọ̀n sẹ́yìn fún ìyá rẹ̀ ní ìwé Ìmọ̀. Ìyá rẹ̀, tí ó jẹ́ mẹ́ńbà ṣọ́ọ̀ṣì kan bẹ̀rẹ̀ sí ka ìwé náà. Lẹ́yìn tí ó ti parí orí méjì, ó ké sí ọmọbìnrin rẹ̀, ó sì ya ọmọbìnrin náà lẹ́nu láti gbọ́ tí ìyá rẹ̀ sọ pé: “Mo fẹ́ di ọ̀kan lára Àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà!” Ìyá náà bẹ̀rẹ̀ sí kẹ́kọ̀ọ́, ó sì ti ṣe batisí nísinsìnyí.

12 Gbìyànjú Àwọn Àbá Wọ̀nyí: O ha ti lo ọ̀nà ìyọsíni tààràtà rí nígbà tí o fẹ́ bẹ̀rẹ̀ ìkẹ́kọ̀ọ́? Lọ́nà rírọrùn, o lè sọ pé: “Bí ìwọ yóò bá fẹ́ ìkẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì inú ilé lọ́fẹ̀ẹ́, mo lè fi bí a ṣe ń ṣe é hàn ọ́ láàárín ìṣẹ́jú díẹ̀. Bí o bá sì gbádùn rẹ̀, o lè máa bá a nìṣó.” Ọ̀pọ̀ ènìyàn ni kì í lọ́tìkọ̀ láti tẹ́wọ́ gba irú ìfilọni bẹ́ẹ̀, wọ́n sì máa ń kíyè sí àṣefihàn bí a ṣe ń kẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì.

13 Ní apá ìbẹ̀rẹ̀ ìkẹ́kọ̀ọ́ náà, fi bí a ṣe ń múra sílẹ̀ han akẹ́kọ̀ọ́, nípa kíka àwọn ẹsẹ Ìwé Mímọ́ ti a tọ́ka sí àti nípa fífàlà sábẹ́ àwọn ọ̀rọ̀ pàtàkì tí ó dáhùn àwọn ìbéèrè tí a tẹ̀. Pọkàn pọ̀ sórí àwọn kókó pàtàkì nìkan. Bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé ó lè di dandan pé kí a kọ́kọ́ máa rọra ṣe ní ìbẹ̀rẹ̀, ó ṣe pàtàkì pé kí a máa ṣe ìkẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì déédéé. Fi bí ìwọ yóò ṣe mú àdúrà wọnú ìkẹ́kọ̀ọ́ náà sọ́kàn gẹ́gẹ́ bí apá pàtàkì nínú rẹ̀ àti bí ìwọ yóò ṣe fi Ìwé Mímọ́ múra akẹ́kọ̀ọ́ náà sílẹ̀ fún àtakò. Ní gbogbo ọ̀nà, mú kí ìkẹ́kọ̀ọ́ náà fani lọ́kàn mọ́ra!

14 Àmọ́ ṣá o, kì í ṣe gbogbo akẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì ló máa ń tẹ̀ síwájú lọ́nà kan náà. Àwọn kan kì í ní ìtẹ̀sí tẹ̀mí bí àwọn mìíràn, bẹ́ẹ̀ ni wọn kì í sì í tètè lóye ohun tí a bá kọ́ wọn. Ìgbésí ayé àwọn mìíràn kún fọ́fọ́, ó sì lè má ṣeé ṣe fún wọn láti ya àkókò tí ó tó sọ́tọ̀ láti kárí orí kan lọ́sọ̀ọ̀sẹ̀. Nípa báyìí, nínú àwọn ọ̀ràn díẹ̀ kan, ó lè pọndandan láti ṣèkẹ́kọ̀ọ́ ju ẹ̀ẹ̀kan lọ láti parí àwọn orí kan, ó sì lè béèrè àfikún oṣù díẹ̀ láti parí ìwé náà. Nígbà mìíràn, a lè kọ́kọ́ ṣèkẹ́kọ̀ọ́ nínú ìwé pẹlẹbẹ Béèrè, lẹ́yìn náà kí a ṣèkẹ́kọ̀ọ́ nínú ìwé Ìmọ̀. A óò ran akẹ́kọ̀ọ́ kọ̀ọ̀kan lọ́wọ́ láti fìdí múlẹ̀ gbọn-ingbọn-in nínú òtítọ́ bí wọ́n bá fi lílọ sí àwọn ìpàdé kún èyí.

15 Ju gbogbo rẹ̀ lọ, gbàdúrà fún ìkẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì! (1 Jòh. 3:22) Kí Jèhófà loni láti ran ẹnì kan lọ́wọ́ láti di ọmọ ẹ̀yìn Jésù Kristi jẹ́ ọ̀kan nínú ìrírí tí ń mérè wá jù lọ tí Kristẹni kan lè ní. (Ìṣe 20:35; 1 Kọ́r. 3:6-9; 1 Tẹs. 2:8) Ìsinsìnyí ni àkókò náà tí ó yẹ kí a fi ìtara gidigidi hàn nínú iṣẹ́ ìkẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì, kí a ní ìgbọ́kànlé kíkún pé Jèhófà yóò bù kún ìsapá wa ní jìngbìnnì láti bẹ̀rẹ̀ ìkẹ́kọ̀ọ́ púpọ̀ sí i!

[Ìsọfúnni tá a pàfiyèsí sí ní ojú ìwé 3]

Ìwọ ha ń gbàdúrà fún bíbẹ̀rẹ̀ ìkẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì tuntun bí?

    Yorùbá Publications (1987-2025)
    Jáde
    Wọlé
    • Yorùbá
    • Fi Ráńṣẹ́
    • Èyí tí mo fẹ́ràn jù
    • Copyright © 2025 Watch Tower Bible and Tract Society of Pennsylvania
    • Àdéhùn Nípa Lílò
    • Òfin
    • Ètò Nípa Ìsọfúnni Rẹ
    • JW.ORG
    • Wọlé
    Fi Ráńṣẹ́