Àyẹ̀wò Tó Ń Tẹ̀ Síwájú Nípa Ìjẹ́kánjúkánjú Iṣẹ́ Sísọni Di Ọmọ Ẹ̀yìn
1 Ṣáájú kí Jésù tó fi orí ilẹ̀ ayé sílẹ̀, ó pàṣẹ pé kí àwọn ọmọlẹ́yìn òun “máa sọ àwọn ènìyàn gbogbo orílẹ̀-èdè di ọmọ ẹ̀yìn.” Èyí ń béèrè pé kí wọ́n túbọ̀ tẹra mọ́ wíwàásù àti kíkọ́ni, kí wọ́n tún ṣe iṣẹ́ náà dé gbogbo ibi tí èèyàn ń gbé lórí ilẹ̀ ayé. (Mát. 28:19, 20; Ìṣe 1:8) Ǹjẹ́ wọ́n wo iṣẹ́ tí a gbé lé wọn lọ́wọ́ yìí gẹ́gẹ́ bí ẹrù tó ṣòro jù fún wọn láti gbé? Ohun tí àpọ́sítélì Jòhánù sọ fi hàn pé ọ̀rọ̀ kò rí bẹ́ẹ̀. Lẹ́yìn tó ti lo ọdún márùndínláàádọ́rin lẹ́nu sísọ àwọn èèyàn di ọmọ ẹ̀yìn, ó kọ̀wé pé: “Èyí ni ohun tí ìfẹ́ fún Ọlọ́run túmọ̀ sí, pé kí a pa àwọn àṣẹ rẹ̀ mọ́; síbẹ̀ àwọn àṣẹ rẹ̀ kì í ṣe ẹrù ìnira.”—1 Jòh. 5:3.
2 Àkọsílẹ̀ Ìwé Mímọ́ nípa ìgbòkègbodò àwọn Kristẹni àkọ́kọ́bẹ̀rẹ̀ fi hàn pé wọ́n fi ẹ̀mí ìjẹ́kánjúkánjú ṣe iṣẹ́ tí a gbé lé wọn lọ́wọ́ láti sọ àwọn èèyàn di ọmọ ẹ̀yìn Jésù Kristi. (2 Tím. 4:1, 2) Kì í ṣe nítorí pé wọ́n kà á sí ẹrù iṣẹ́ ló wulẹ̀ mú wọn ṣe èyí, ṣùgbọ́n ó jẹ́ nítorí pé wọ́n nífẹ̀ẹ́ láti yin Ọlọ́run kí wọ́n sì sọ nípa ìrètí ìgbàlà fún àwọn ẹlòmíràn. (Ìṣe 13:47-49) Nítorí pé gbogbo àwọn tó di ọmọ ẹ̀yìn làwọn pẹ̀lú tún wá ń sọ àwọn ẹlòmíràn di ọmọ ẹ̀yìn, ìjọ Kristẹni yára kánkán gbèrú ní ọ̀rúndún kìíní.—Ìṣe 5:14; 6:7; 16:5.
3 Iṣẹ́ Sísọni Di Ọmọ Ẹ̀yìn Ń Yára Kánkán: Àkókò táa wà yìí ni a ń ṣe iṣẹ́ sísọni di ọmọ ẹ̀yìn tó tíì ju ti ìgbàkígbà rí lọ! Nítorí èyí, títí di báyìí, àràádọ́ta ọ̀kẹ́ èèyàn ti tẹ́wọ́ gba ìhìn rere náà, wọ́n sì ti ṣe nǹkan nípa rẹ̀. (Lúùkù 8:15) Níwọ̀n bí àkókò tó kù fún ètò àwọn nǹkan yìí ti ń yára kógbá sílé, “ẹrú olóòótọ́ àti olóye” ti pèsè àwọn irin iṣẹ́ fún wa tó ń jẹ́ kó rọrùn fún àwọn aláìlábòsí ọkàn láti tètè kẹ́kọ̀ọ́ òtítọ́.—Mát. 24:45.
4 Lọ́dún 1995, a rí ìwé Ìmọ̀ Tí Ń Sinni Lọ sí Ìyè Àìnípẹ̀kun gbà, èyí tó sì tún jáde lẹ́yìn rẹ̀ ní ọdún 1996 ni ìwé pẹlẹbẹ náà, Kí Ni Ọlọrun Ń Béèrè Lọ́wọ́ Wa? Ní ti ìwé Ìmọ̀, ìtẹ̀jáde Ilé-Ìṣọ́nà January 15, 1996, ojú ìwé 14, sọ pé: “Ìwé olójú ewé 192 yìí ni a lè kẹ́kọ̀ọ́ rẹ̀ tán ní àkókò tí o kúrú gan-an, àwọn ‘tí wọ́n sì ní ìtẹ̀sí ọkàn títọ́ fún ìyè àìnípẹ̀kun’ yẹ kí wọ́n kọ́ ohun tí ó pọ̀ tó nípasẹ̀ kíkẹ́kọ̀ọ́ rẹ̀ láti ṣe ìyàsímímọ́ sí Jehofa, kí wọ́n sì ṣe batisí.”—Ìṣe 13:48.
5 Àkìbọnú Iṣẹ́ Òjíṣẹ́ Ìjọba Wa ti June 1996 tó sọ nípa “Bí A Óò Ṣe Fi Ìwé Ìmọ̀ Sọ Àwọn Ènìyàn Di Ọmọ Ẹ̀yìn,” gbé góńgó yìí kalẹ̀ fún wa, ó ní: “Ní sísinmi lórí bí ipò àyíká akẹ́kọ̀ọ́ bá ti rí àti bí òye rẹ̀ bá ti tó, ó lè ṣeé ṣe fún ọ láti kárí orí tí ó pọ̀ jù lọ ní ìjókòó wákàtí kan tàbí jù bẹ́ẹ̀ lọ díẹ̀, láìkánjú ṣe ìkẹ́kọ̀ọ́ náà. Akẹ́kọ̀ọ́ yóò ní ìtẹ̀síwájú dáradára bí olùkọ́ àti akẹ́kọ̀ọ́ bá ń pa àdéhùn fún ìkẹ́kọ̀ọ́ mọ́ ní ọ̀sọ̀ọ̀sẹ̀.” Àpilẹ̀kọ yìí ń bá ọ̀rọ̀ lọ pé: “Ó yẹ kí a fojú sọ́nà pé nígbà tí ẹnì kan bá fi máa parí ìkẹ́kọ̀ọ́ ìwé Ìmọ̀, òótọ́ inú rẹ̀ àti bí ọkàn ìfẹ́ rẹ̀ láti ṣiṣẹ́ sin Ọlọ́run ti jinlẹ̀ tó yóò ti hàn kedere.” Àpótí Ìbéèrè tó wà nínú Iṣẹ́ Òjíṣẹ́ Ìjọba Wa ti October 1996 ṣàlàyé pé: “A retí pé láàárín àkókò kúkúrú kan ní ìfiwéra, yóò ṣeé ṣe fún olùkọ́ dídáńgájíá kan láti ran akẹ́kọ̀ọ́ olótìítọ́ inú lọ́wọ́ láti gba ìmọ̀ tí ó pọ̀ tó láti lè ṣe ìpinnu tí ó lọ́gbọ́n nínú láti sin Jèhófà.”
6 Ìwé Ìmọ̀ Ń Ṣàṣeyọrí: Nígbà tí ọ̀ṣọ́ọ́rọ́ obìnrin kan ṣe ìrìbọmi, ó ṣàlàyé èrò rẹ̀ nípa kíkẹ́kọ̀ọ́ ìwé Ìmọ̀. Fún ìgbà díẹ̀, ó ti kẹ́kọ̀ọ́ ìwé Walaaye Titilae. Nígbà tí ìwé Ìmọ̀ jáde, arábìnrin tó ń bá a ṣèkẹ́kọ̀ọ́ yí padà sínú ìwé tuntun yìí. Láìpẹ́, akẹ́kọ̀ọ́ yìí rí i pé èyí ń béèrè pé kí òun ṣe ìpinnu, ó sì mú kí ó yára tẹ̀ síwájú láti àkókò yẹn lọ. Ọ̀ṣọ́ọ́rọ́ obìnrin yẹn, tó ti di arábìnrin wa nísinsìnyí sọ pé: “Ìwé Walaaye Titilae ràn mí lọ́wọ́ láti nífẹ̀ẹ́ Jèhófà, ṣùgbọ́n ìwé Ìmọ̀ ràn mí lọ́wọ́ láti ṣe ìpinnu láti sìn ín.”
7 Tún wo bí obìnrin mìíràn ṣe kẹ́kọ̀ọ́ òtítọ́ lọ́nà tó yára kánkán. Lẹ́yìn tó ṣe ìkẹ́kọ̀ọ́ fún ìgbà kejì, ó lọ sí ìpàdé ní Gbọ̀ngàn Ìjọba lákòókò ìbẹ̀wò alábòójútó àyíká. Lọ́sẹ̀ yẹn, nígbà tó ṣe ìkẹ́kọ̀ọ́ fún ìgbà kẹta, obìnrin náà sọ fún un pé òun ti ṣe ìyàsímímọ́ sí Jèhófà, òun sì fẹ́ di akéde tí kò tíì ṣe batisí. Ó lọ bá àwọn alàgbà, wọ́n sì fọwọ́ sí i pé kí ó di akéde, nígbà tó sì di ọ̀sẹ̀ tó tẹ̀ lé e, ó bẹ̀rẹ̀ sí lọ sí òde ẹ̀rí. Ìkẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì rẹ̀ ká a lára débi pé ó gbàyè níbi iṣẹ́ kí ó lè ráyè kẹ́kọ̀ọ́ nígbà méjì tàbí mẹ́ta lọ́sẹ̀, kí ó sì lè lo àkókò púpọ̀ sí i nínú iṣẹ́ òjíṣẹ́. Nígbà mìíràn, wọ́n máa ń parí àkòrí méjì tàbí mẹ́ta lẹ́ẹ̀kan. Ó bẹ̀rẹ̀ sí fi ohun tó ń kẹ́kọ̀ọ́ sílò nínú gbogbo apá ìgbésí ayé rẹ̀, ó parí ìwé Ìmọ̀ láàárín ọ̀sẹ̀ mẹ́rin, ó sì tẹ̀ síwájú débi pé ó ṣe ìrìbọmi!
8 Ọkọ arábìnrin kan sọ pé “ọkọ kan tó jẹ́ aláìgbàgbọ́ hánrán-ún lòun.” Lọ́jọ́ kan, arákùnrin kan fi ìkẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì nínú ìwé Ìmọ̀ lọ̀ ọ́, arákùnrin náà sì sọ fún un pé ó lè jáwọ́ nínú ẹ̀ lẹ́yìn ìkẹ́kọ̀ọ́ àkọ́kọ́ tàbí nígbàkigbà tó bá wù ú lẹ́yìn náà. Ọkọ yẹn gbà láti gbìyànjú ẹ̀ wò, bó tilẹ̀ jẹ́ pé kò fi bẹ́ẹ̀ kàwé, kò sì kẹ́kọ̀ọ́ ìwé ìsìn èyíkéyìí fún èyí tó ju ogún ọdún lọ. Kí ló sọ nígbà tó kẹ́kọ̀ọ́ ìwé Ìmọ̀? Ó ní: “Ó gbádùn mọ́ mi láti mọ̀ pé ọ̀nà tí wọ́n gbà kọ ìwé yìí tó ń ṣàlàyé nípa Bíbélì rọrùn bẹ́ẹ̀. Àlàyé tí wọ́n ṣe ṣe kedere, ó sì bọ́gbọ́n mu débi pé kò pẹ́ tó fi jẹ́ pé ńṣe ni mó máa ń fojú sọ́nà pé kí àkókò ìkẹ́kọ̀ọ́ tí yóò tẹ̀ lé e tètè tó. Ẹni tó ń bá mi ṣèkẹ́kọ̀ọ́ fi òye tẹ̀ lé àwọn ọ̀nà tí Society ṣàlàyé fún sísọni di ọmọ ẹ̀yìn, Jèhófà sì fi ẹ̀mí rẹ̀ ṣèrànwọ́ tó fi jẹ́ pé mo ṣèrìbọmi ní oṣù mẹ́rin lẹ́yìn ìyẹn. Mo lè sọ dáadáa pé bí a bá ní ìfẹ́ láti sọ àwọn èèyàn di ọmọ ẹ̀yìn, tí a ń bá a nìṣó láti máa wá àwọn ọlọ́kàn títọ́ nínú iṣẹ́ òjíṣẹ́ pápá, tí a ń lo ìwé Ìmọ̀ àti àwọn ìwé mìíràn tí Society ṣe tó ń ṣàlàyé Bíbélì, àti ní pàtàkì jù lọ, bí a bá ń gbàdúrà fún ìtọ́sọ́nà Jèhófà, a lè ní àǹfààní àrà ọ̀tọ̀ ti ṣíṣèrànwọ́ láti sọ àwọn èèyàn di ọmọ ẹ̀yìn.” Àwọn ìrírí tí a sọ lókè yìí ṣàrà ọ̀tọ̀ ní ti gidi. Èyí tó pọ̀ jù lọ lára àwọn akẹ́kọ̀ọ́ wa kì í yára wá sínú òtítọ́ lọ́nà yìí.
9 Bí Àwọn Akẹ́kọ̀ọ́ Ṣe Ń Tẹ̀ Síwájú Máa Ń Yàtọ̀ Síra Wọn: A gbọ́dọ̀ mọ̀ pé agbára tí àwọn olùkọ́ àti àwọn akẹ́kọ̀ọ́ Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run ní lè yàtọ̀ síra gidigidi. Ìtẹ̀síwájú tẹ̀mí lè jẹ́ díẹ̀-díẹ̀, ó sì lè yára kánkán. Àwọn akẹ́kọ̀ọ́ kan máa ń ní ìtẹ̀síwájú púpọ̀ láàárín oṣù díẹ̀, èyí sì lè gba àwọn mìíràn ní ọ̀pọ̀lọpọ̀ àkókò. Iye ìwé tí èèyàn kà, bí ó ṣe mọrírì àwọn nǹkan tẹ̀mí tó, àti bí ìfọkànsìn rẹ̀ sí Jèhófà ṣe jinlẹ̀ tó máa ń ní ipa lórí bí ẹnì kan yóò ṣe tètè tẹ̀ síwájú nípa tẹ̀mí tó. Kì í ṣe gbogbo ẹni tí a ń bá ṣèkẹ́kọ̀ọ́ ló ní “ìháragàgà ńláǹlà nínú èrò inú” láti kẹ́kọ̀ọ́ Ìwé Mímọ́ lójoojúmọ́, bí àwọn ará Bèróà tí wọ́n di onígbàgbọ́ ti ṣe.—Ìṣe 17:11, 12.
10 Ìdí nìyẹn tí àkìbọnú Iṣẹ́ Òjíṣẹ́ Ìjọba Wa ti December 1998, to sọ nípa “A Ń Fẹ́ Ìkẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì Púpọ̀ Sí I,” fi pèsè ojúlówó ìtọ́sọ́nà yìí pé: “Àmọ́ ṣá o, kì í ṣe gbogbo akẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì ló máa ń tẹ̀ síwájú lọ́nà kan náà. Àwọn kan kì í ní ìtẹ̀sí tẹ̀mí bí àwọn mìíràn, bẹ́ẹ̀ ni wọn kì í sì í tètè lóye ohun tí a bá kọ́ wọn. Ìgbésí ayé àwọn mìíràn kún fọ́fọ́, ó sì lè má ṣeé ṣe fún wọn láti ya àkókò tí ó tó sọ́tọ̀ láti kárí orí kan lọ́sọ̀ọ̀sẹ̀. Nípa báyìí, nínú àwọn ọ̀ràn díẹ̀ kan, ó lè pọndandan láti ṣèkẹ́kọ̀ọ́ ju ẹ̀ẹ̀kan lọ láti parí àwọn orí kan, ó sì lè béèrè àfikún oṣù díẹ̀ láti parí ìwé náà.”
11 Àwọn Tí Ń Sọni Di Ọmọ Ẹ̀yìn Máa Ń Ní Èrò Tí Ó Tọ́: Ó ṣe pàtàkì pé ká díwọ̀n bí ìkẹ́kọ̀ọ́ yóò ṣe yára kánkán tó ní ìbámu pẹ̀lú ipò àti òye akẹ́kọ̀ọ́. Níwọ̀n bí wọ́n ti fún wa níṣìírí pé kí á bẹ̀rẹ̀ ìkẹ́kọ̀ọ́ nínú ìwé pẹlẹbẹ Béèrè, ó lè gba oṣù méjì sí oṣù mẹ́ta láti parí rẹ̀ kí á tó bẹ̀rẹ̀ ìwé Ìmọ̀. Bí a bá lo gbogbo ìmọ̀ràn tó wà nínú àkìbọnú Iṣẹ́ Òjíṣẹ́ Ìjọba Wa ti June 1996, ó lè gba oṣù mẹ́fà tàbí oṣù mẹ́sàn-án sí i kí á tó lè parí ìwé Ìmọ̀. Àwọn kan tí wọ́n ṣẹ̀ṣẹ̀ bẹ̀rẹ̀ kíkẹ́kọ̀ọ́ ìwé Ìmọ̀ padà lọ bẹ̀rẹ̀ ìwé pẹlẹbẹ Béèrè kí ó lè ran akẹ́kọ̀ọ́ lọ́wọ́ láti kẹ́kọ̀ọ́ àwọn òtítọ́ ìpìlẹ̀ nínú Bíbélì lọ́nà tó túbọ̀ yára kánkán. Lẹ́yìn ìyẹn ni wọ́n wá padà sórí ìkẹ́kọ̀ọ́ ìwé Ìmọ̀. Bí ẹnì kan bá bẹ̀rẹ̀ ìkẹ́kọ̀ọ́ nínú ìwé Ìmọ̀, tí ìkẹ́kọ̀ọ́ náà sì ń tẹ̀ síwájú dáadáa, ó lè dára pé kí ó kẹ́kọ̀ọ́ ìwé pẹlẹbẹ Béèrè lẹ́yìn tó bá parí ìwé ti àkọ́kọ́, yóò sì tipa báyìí yára ṣàtúnyẹ̀wò àwọn òtítọ́ ìpìlẹ̀ nínú Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run. Èyí ó wù kó jẹ́, a kò ní fẹ́ kó jẹ́ pé nítorí ká lè tètè parí ìkẹ́kọ̀ọ́ nínú ìwé náà, kí á máà jẹ́ kí akẹ́kọ̀ọ́ lóye ohun tó ń kọ́. Olúkúlùkù akẹ́kọ̀ọ́ ló nílò ìpìlẹ̀ lílágbára fún ìgbàgbọ́ tuntun tó ṣẹ̀ṣẹ̀ ṣàwárí nínú Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run.
12 Níbi tójú ọjọ́ dé yìí, ó túbọ̀ jẹ́ kánjúkánjú ju ti ìgbàkígbà rí lọ pé kí á ran àwọn ẹlòmíràn lọ́wọ́ láti kẹ́kọ̀ọ́ òtítọ́. Yàtọ̀ sí pé kí á máa gbàdúrà nígbà gbogbo pé kí a lè bẹ̀rẹ̀ àwọn ìkẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì tuntun, ẹ jẹ́ kí a máa gbàdúrà nítorí àwọn tí a ti ń bá ṣèkẹ́kọ̀ọ́. Nígbà náà, inú wa yóò máa dùn láti máa batisí ọmọ ẹ̀yìn púpọ̀ sí i “ní gbogbo àwọn ọjọ́ títí dé ìparí ètò àwọn nǹkan.”—Mát. 28:20.