Ìtòlẹ́sẹẹsẹ Tuntun fún Àpéjọ Àyíká
A mọ̀ pé ìfẹ́ wa àti ìfọkànsìn wa tí a yà sọ́tọ̀ gedegbe tọ́ sí Jèhófà Ọlọ́run. Ṣùgbọ́n, ayé yìí máa ń wá ọ̀nà láti ré wa lọ kí a má bàa máa bá àjọṣe tímọ́tímọ́ tí a ń ní pẹ̀lú Ọlọ́run nìṣó. (Jòh. 17:14) Láti mú kí ìfẹ́ wa fún Jèhófà túbọ̀ lágbára, kí a sì fún wa lókun láti dènà àwọn nǹkan ti ayé tí ó lè fi ipò tẹ̀mí wa sínú ewu, ìtòlẹ́sẹẹsẹ tuntun fún àpéjọ àyíká ti ọdún iṣẹ́ ìsìn 2001 yóò ní àkọlé tó sọ pé “Ẹ Nífẹ̀ẹ́ Ọlọ́run—Ẹ Má Ṣe Nífẹ̀ẹ́ Àwọn Ohun Tí Ń Bẹ Nínú Ayé.”—1 Jòh. 2:15-17.
Ìfẹ́ jíjinlẹ̀ tí a ní sí Jèhófà ń mú ká jẹ́rìí nípa rẹ̀. Bí ó tilẹ̀ rí bẹ́ẹ̀, iṣẹ́ ìsìn pápá kò rọrùn fún ọ̀pọ̀ èèyàn Ọlọ́run. Wá gbọ́ bí ọ̀pọ̀ ti ṣe borí ìtìjú àti àwọn ìdènà mìíràn kí wọ́n lè kópa ní kíkún nínú iṣẹ́ yìí. A ó sọ èyí nínú apá tí a pè ní “Ìfẹ́ Táa Ní sí Ọlọ́run Ń Sún Wa Ṣe Iṣẹ́ Òjíṣẹ́ Wa.”
Báwo ni ọ̀pá ìdiwọ̀n ayé tó ń jó rẹ̀yìn ṣe ń ní ipa lórí wa? Àwọn ìwà kan tí wọ́n ti fìgbà kan rí kà sí ohun búburú ni wọ́n wá ń sọ pé kò burú báyìí. Àsọyé náà, “Ẹ̀yin Tí Ẹ Nífẹ̀ẹ́ Jèhófà Ẹ Kórìíra Ohun tó Burú” àti àpínsọ àsọyé náà, “Àwọn Ohun Tí Ń Bẹ Nínú Ayé—Ojú Wo La Fi Ń Wò Wọ́n?” yóò fún ìpinnu wa lágbára láti má ṣe bẹ̀rẹ̀ sí nífẹ̀ẹ́ ohun tí kò tọ́.
Ilé Ẹ̀kọ́ Iṣẹ́ Òjíṣẹ́ Ìṣàkóso Ọlọ́run àti Ìpàdé Iṣẹ́ Ìsìn tó jẹ́ àwòfiṣàpẹẹrẹ títí kan àkópọ̀ àpilẹ̀kọ tí a óò kẹ́kọ̀ọ́ nínú Ilé Ìṣọ́ ní ọ̀sẹ̀ yẹn yóò wà lára ìtòlẹ́sẹẹsẹ yìí. Àsọyé fún gbogbo èèyàn, tí a pe àkòrí rẹ̀ ní, “Fífi Ìfẹ́ àti Ìgbàgbọ́ Ṣẹ́gun Ayé,” yóò fún wa níṣìírí láti ṣàfarawé Jésù ní dídènà ẹ̀mí ṣíṣe bí ayé ti ń ṣe. (Jòh. 16:33) Rí i dájú pé o ké sí àwọn tóo ń kọ́ lẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì láti wá. Kí ẹnikẹ́ni tó bá fẹ́ ṣe ìrìbọmi tètè sọ fún alábòójútó olùṣalága kí ó lè ṣe àwọn ètò tó bá yẹ.
Àpéjọ àyíká yìí yóò pe àfiyèsí wa sí ibi tó yẹ ká darí ìfẹ́ wa sí gan-an kí a lè gbádùn ìbùkún jìngbìnnì látọ̀dọ̀ Jèhófà. Má ṣe tàsé èyíkéyìí nínú ìtòlẹ́sẹẹsẹ náà o!