Ìtòlẹ́sẹẹsẹ Tuntun fún Àpéjọ Àyíká
“Pa Àwọn Àṣẹ Ọlọ́run Mọ́ Kí O Sì Wà Láàyè” ni ẹṣin ọ̀rọ̀ ìtòlẹ́sẹẹsẹ àpéjọ àyíká ọlọ́jọ́ méjì tí yóò bẹ̀rẹ̀ ní oṣù January. (Òwe 4:4) Yóò tẹnu mọ́ ìdí tí ṣíṣègbọràn sí àwọn àṣẹ Ọlọ́run kò fi jẹ́ ẹrù ìnira. Síwájú sí i, yóò fi hàn bí ṣíṣe ohun tí Ọlọ́run fẹ́ ṣe ń mú ìtura àti ayọ̀ tòótọ́ wá, tí ó sì ń pèsè ìrètí nípa ọjọ́ ọ̀la pẹ̀lú.—Mát. 11:28-30; Jòh. 13:17.
Kí àwọn tí ń fẹ́ láti ṣe batisí ní àpéjọ yìí, ní ìgbọràn sí àṣẹ Kristi, bá alábòójútó olùṣalága sọ̀rọ̀, òun yóò sì ṣe ètò tí ó yẹ.—Mát. 28:19, 20.
Àpínsọ ọ̀rọ̀ àsọyé kan yóò ṣàlàyé àwọn ọ̀nà gbígbéṣẹ́ tí a lè gbà fi ìfẹ́ wa fún Ọlọ́run àti àwọn arákùnrin wa hàn. (Jòh. 13:34, 35; 1 Jòh. 5:3) Ìmọ̀ràn tí ń runi lọ́kàn sókè láti inú Sáàmù kọkàndínlógun [19] àti ìkọkàndínlọ́gọ́fà [119] yóò wà nínú ìtòlẹ́sẹẹsẹ náà. Bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé ó ti tó ẹgbẹẹgbẹ̀rún ọdún tí a ti kọ ìṣílétí tí a mí sí tí ó wà nínú àwọn sáàmù yìí, a óò rí i bí yóò ṣe ṣàǹfààní fún ẹnì kọ̀ọ̀kan wa lónìí.
Ọ̀rọ̀ àsọyé fún gbogbo ènìyàn tí alábòójútó àgbègbè yóò sọ ni a pe àkòrí rẹ̀ ní “Bẹ̀rù Ọlọ́run Kí O Sì Pa Àwọn Àṣẹ Rẹ̀ Mọ́.” (Oníw. 12:13) Ọ̀rọ̀ àsọyé tí alábòójútó àyíká yóò sọ kẹ́yìn yóò jẹ́ kí àwọn ọ̀dọ́ mọ bí wọ́n ṣe lè jàǹfààní lọ́nà dídára jù lọ nínú ìgbésí ayé nísinsìnyí àti ìdí tí wọ́n fi lè ní ìgbọ́kànlé nínú ọjọ́ ọ̀la tí kò nípẹ̀kun. Alábòójútó àgbègbè yóò mú ìtòlẹ́sẹẹsẹ náà wá sópin nípa mímẹ́nukan àwọn àǹfààní tí a ń rí nínú gbígbé ìgbé ayé ní ìbámu pẹ̀lú ìfẹ́ tí ń ṣe “ọba òfin.” (Ják. 2:8) Ní tòótọ́, ìtòlẹ́sẹẹsẹ àpéjọ tí ẹnikẹ́ni kì yóò fẹ́ pàdánù ni èyí!