ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍNTÁNẸ́Ẹ̀TÌ ti Watchtower
ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍŃTÁNẸ́Ẹ̀TÌ
ti Watchtower
Yorùbá
ọ́
  • ẹ
  • ọ
  • ṣ
  • ń
  • ẹ́
  • ẹ̀
  • ọ́
  • ọ̀
  • BÍBÉLÌ
  • ÌTẸ̀JÁDE
  • ÌPÀDÉ
  • km 12/98 ojú ìwé 5-6
  • Àtúnyẹ̀wò Ilé Ẹ̀kọ́ Iṣẹ́ Òjíṣẹ́ Ìṣàkóso Ọlọ́run

Kò sí fídíò kankan ní apá yìí.

Má bínú, fídíò yìí kò jáde.

  • Àtúnyẹ̀wò Ilé Ẹ̀kọ́ Iṣẹ́ Òjíṣẹ́ Ìṣàkóso Ọlọ́run
  • Iṣẹ́ Òjíṣẹ́ Ìjọba Wa—1998
Iṣẹ́ Òjíṣẹ́ Ìjọba Wa—1998
km 12/98 ojú ìwé 5-6

Àtúnyẹ̀wò Ilé Ẹ̀kọ́ Iṣẹ́ Òjíṣẹ́ Ìṣàkóso Ọlọ́run

Àtúnyẹ̀wò láìṣí-ìwé-wò fún àkópọ̀ ẹ̀kọ́ tí a kárí nínú àwọn iṣẹ́ àyànfúnni Ilé Ẹ̀kọ́ Iṣẹ́ Òjíṣẹ́ Ìṣàkóso Ọlọ́run fún àwọn ọ̀sẹ̀ September 7 sí December 21, 1998. Lo abala tákàdá ọ̀tọ̀ láti fi kọ ìdáhùn sí púpọ̀ nínú àwọn ìbéèrè náà, bí ó bá ti lè ṣeé ṣe fún ọ tó, ní ìwọ̀n àkókò tí a yàn.

[Àkíyèsí: Lákòókò àtúnyẹ̀wò alákọsílẹ̀, Bíbélì nìkan ni a lè lò láti dáhùn ìbéèrè èyíkéyìí. Àwọn ìtọ́kasí tí ó tẹ̀ lé àwọn ìbéèrè wà fún ìwádìí fúnra rẹ. Nọ́ńbà ojú ìwé àti ìpínrọ̀ lè má fara hàn nínú gbogbo àwọn ìtọ́ka tí a ṣe sí Ilé Ìṣọ́.]

Dáhùn Òtítọ́ tàbí Èké sí ọ̀kọ̀ọ̀kan àwọn gbólóhùn tí ó tẹ̀ lé e yìí:

1. Ní 2 Tímótì 1:6, “ẹ̀bùn” tọ́ka sí agbára láti lè sọ onírúurú èdè tí a fún Tímótì nípasẹ̀ ìṣiṣẹ́ ẹ̀mí mímọ́ Ọlọ́run. [Bíbélì kíkà ọ̀sọ̀ọ̀sẹ̀; wo w85-YR 11/1 ojú ìwé 16 ìpínrọ̀ 15.]

2. Kristẹni kan tí ó dàgbà dénú ‘máa ń kọ́ agbára ìwòye rẹ̀ láti fi ìyàtọ̀ sáàárín ohun tí ó tọ́ àti ohun tí kò tọ́’ nípa sísọ ọ́ di àṣà láti máa lo ìmọ̀ yòówù tí ó bá ní nípa Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run. (Héb. 5:14) [Bíbélì kíkà ọ̀sọ̀ọ̀sẹ̀; wo w85-YR 12/15 ojú ìwé 9 ìpínrọ̀ 7.]ọ́.

3. Òtítọ́ náà pé Jèhófà “ń mú kí oòrùn rẹ̀ ràn sórí àwọn ènìyàn burúkú àti rere, tí ó sì ń mú kí òjò rọ̀ sórí àwọn olódodo àti aláìṣòdodo” fi hàn pé nínú gbogbo bí Jèhófà ṣe ń bá ìdílé ẹ̀dá ènìyàn lò, òun ti fi hàn nígbà gbogbo pé òun kì í ṣe ojúsàájú. (Mát. 5:45) [w96-YR 11/15 ojú ìwé 25 ìpínrọ̀ 7]ọ́.

4. Jákọ́bù tí ó kọ Bíbélì ni Jákọ́bù tí ó jẹ́ agbẹnusọ fún “àwọn àpọ́sítélì àti àwọn àgbà ọkùnrin” nígbà tí wọ́n ń ṣe ìpinnu lórí ìdádọ̀dọ́. (Ìṣe 15:6, 13; Ják. 1:1) [Wo w91-YR 3/15 ojú ìwé 23 ìpínrọ̀ 2.]

5. Bábílónì ni Pétérù wà nígbà tí ó kọ lẹ́tà rẹ̀ àkọ́kọ́ ní nǹkan bí ọdún 62 sí 64 Sànmánì Tiwa. (1 Pét. 5:13) [w91-YR 3/15 ojú ìwé 30 ìpínrọ̀ 2]

6. Gbólóhùn náà ní 1 Jòhánù 2:18 pé, “aṣòdì sí Kristi ń bọ̀” ń tọ́ka sí ẹnì kan. [Bíbélì kíkà ọ̀sọ̀ọ̀sẹ̀; wo w91-YR 4/15 ojú ìwé 29 ìpínrọ̀ 4.]

7. Àṣẹ tí ó wà ní 2 Jòhánù 10 pé kí a má ṣe gba irú àwọn kan sí ilé wa kí a má sì ṣe kí wọn ń tọ́ka sí kìkì àwọn tí ń ṣagbátẹrù ẹ̀kọ́ èké. [Bíbélì kíkà ọ̀sọ̀ọ̀sẹ̀; wo w86-YR 1/15 ojú ìwé 30 ìpínrọ̀ 1 sí 3.]

8. Ìwé Ìṣípayá ni a tò sí ìgbẹ̀yìn nínú Bíbélì nítorí pé òun ni ìwé tí àpọ́sítélì Jòhánù kọ kẹ́yìn. [Fi w91-YR 5/1 ojú ìwé 21 ìpínrọ̀ 2 wé w91-YR 4/15 ojú ìwé 29 ìpínrọ̀ 2; ojú ìwé 30 ìpínrọ̀ 2.]

9. Lọ́nà tí ó ṣe rẹ́gí, Ìṣípayá 13:11-15 ṣàgbéyọ bí Agbára Ayé Gẹ̀ẹ́sì òun Amẹ́ríkà ṣe di olórí alátìlẹyìn àti ẹni tí ó fún Ìmùlẹ̀ Àwọn Orílẹ̀-Èdè àti fún agbapò rẹ̀, Ìparapọ̀ Àwọn Orílẹ̀-Èdè níyè. [Bíbélì kíkà ọ̀sọ̀ọ̀sẹ̀; wo w88-YR 12/15 ojú ìwé 19 ìpínrọ̀ 3.]

10. Níwọ̀n bí Bíbélì ti fàyè gba mímu ọtí líle, yóò bá a mu pé kí a jẹ́ kí àṣà ìbílẹ̀ àti àṣà àtọwọ́dọ́wọ́ ti àdúgbò pinnu ìwọ̀n tí ó yẹ kí a mu. (Sm. 104:15) [w96 12/15 ojú ìwé 27 ìpínrọ̀ 5]

Dáhùn àwọn ìbéèrè tí ó tẹ̀ lé e yìí:

11. Kí ni ó túmọ̀ sí pé kí alábòójútó má ṣe jẹ́ “aluni”? (Títù 1:7) [Bíbélì kíkà ọ̀sọ̀ọ̀sẹ̀; wo w90-YR 9/1 ojú ìwé 27 ìpínrọ̀ 21.]

12. Sọ ìdí méjì tí Jèhófà fi mú kí fífúnni jẹ́ apá kan ìjọsìn tòótọ́. [w96-YR 11/1 ojú ìwé 29 ìpínrọ̀ 3 sí 6; ojú ìwé 30 ìpínrọ̀ 3]

13. Kí ni Jésù ní lọ́kàn nígbà tí ó sọ pé, “Ẹbọ àti ọrẹ ẹbọ ni ìwọ kò fẹ́”? (Héb. 10:5) [Bíbélì kíkà ọ̀sọ̀ọ̀sẹ̀; wo w96-YR 7/1 ojú ìwé 14 ìpínrọ̀ 3.]

14. Báwo ni àwọn Kristẹni ṣe lè “ṣẹ́gun ayé”? (1 Jòhánù 5:3, 4) [Bíbélì kíkà ọ̀sọ̀ọ̀sẹ̀; wo w91-YR 4/15 ojú ìwé 29 ìpínrọ̀ 7.]

15. Kí ni gbólóhùn Pétérù náà, ‘fífi ọjọ́ Jèhófà sọ́kàn pẹ́kípẹ́kí’ ní nínú? (2 Pét. 3:12) [Bíbélì kíkà ọ̀sọ̀ọ̀sẹ̀; wo w97-YR 9/1 ojú ìwé 19 ìpínrọ̀ 2.]

16. Ní 1 Jòhánù 2:2, àwọn ọ̀rọ̀ pàtàkì wo ni ó ràn wá lọ́wọ́ láti mọ àwùjọ méjì tí ó jàǹfààní láti inú ikú ìrúbọ Jésù? [Bíbélì kíkà ọ̀sọ̀ọ̀sẹ̀; wo w90-YR 1/15 ojú ìwé 12 ìpínrọ̀ 11.]

17. Ní ìbámu pẹ̀lú Ìṣípayá 1:7, báwo ni àwọn tí ó gún Jésù lọ́kọ̀ yóò ṣe rí i tí yóò máa “bọ̀ pẹ̀lú àwọsánmà”? [Bíbélì kíkà ọ̀sọ̀ọ̀sẹ̀; wo w93-YR 5/1 ojú ìwé 22 ìpínrọ̀ 7.]

18. Bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé Jésù Kristi fi ọdún mẹ́ta àti àbọ̀ wàásù láàárín àwọn ọmọ Ísírẹ́lì, èé ṣe tí ọ̀pọ̀ jù lọ fi kọ̀ ọ́ gẹ́gẹ́ bí Mèsáyà náà? [w96-YR 11/15 ojú ìwé 29 ìpínrọ̀ 1, 6; ojú ìwé 30 ìpínrọ̀ 3]

19. Ní Ìṣípayá 13:1, 2, èé ṣe tí ó fi bá a mu pé a ṣàpèjúwe ìjọba ayé gẹ́gẹ́ bí “ẹranko ẹhànnà”? [Bíbélì kíkà ọ̀sọ̀ọ̀sẹ̀; wo w89-YR 4/1 ojú ìwé 20 ìpínrọ̀ 17.]

20. Ní Ìṣípayá 4:4, ta ni “àwọn alàgbà mẹ́rìnlélógún” dúró fún, kí sì ni “adé” àti “ìtẹ́” wọn rán wa létí? [Bíbélì kíkà ọ̀sọ̀ọ̀sẹ̀; wo w95-YR 7/1 ojú ìwé 13 ìpínrọ̀ 17.]

Pèsè ọ̀rọ̀ tàbí àpólà ọ̀rọ̀ tí a nílò láti parí ọ̀kọ̀ọ̀kan nínú àwọn gbólóhùn tí ó tẹ̀ lé e yìí:

21. Pọ́ọ̀lù kọ lẹ́tà rẹ̀ kejì sí Tímótì láti _________________________ ní ọdún _________________________ Sànmánì Tiwa, ó sì ṣeé ṣe kí ó jẹ́ pé Tímótì ṣì wà ní Éfésù nígbà yẹn. [w91-YR 1/15 ojú ìwé 31 ìpínrọ̀ 1]

22. Láti sá eré ìje tí a gbé ka iwájú wa, a gbọ́dọ̀ mú gbogbo ẹrù wíwúwo kúrò àti _________________________ tí ó máa ń fi ìrọ̀rùn wé mọ́ wa, èyí tí í ṣe _________________________. [Bíbélì kíkà ọ̀sọ̀ọ̀sẹ̀; wo w98-YR 1/1 ojú ìwé 10 ìpínrọ̀ 15.]

23. Ní 2 Pétérù 1:5-8, àpọ́sítélì Pétérù dámọ̀ràn _________________________ láti mú àwọn ànímọ́ Ọlọ́run dàgbà tí kì yóò jẹ́ kí a di _________________________ tàbí _________________________. [w91-YR 3/15 ojú ìwé 31 ìpínrọ̀ 3]

24. Ní Ìṣípayá 6:1-8, ẹni tí ó gun ẹṣin aláwọ̀ iná dúró fún _________________________ ; ẹni tí ó gun ẹṣin dúdú dúró fún _________________________ ; ikú ni ó gun ẹṣin ràndánràndán, ó dúró fún _________________________ nítorí àjàkálẹ̀ àrùn àti àwọn ìdí mìíràn. [Bíbélì kíkà ọ̀sọ̀ọ̀sẹ̀; wo w86-YR 5/15 àpótí ojú ìwé 3.]

25. Ó hàn gbangba pé ní _________________________ ṣáájú Kristi ni àwọn Júù bẹ̀rẹ̀ sí gba ẹ̀kọ́ _________________________ láti ọ̀dọ̀ àwọn Gíríìkì. [w96-YR 8/1 ojú ìwé 6 ìpínrọ̀ 2 àti 3]

Mú ìdáhùn tí ó tọ̀nà nínú ọ̀kọ̀ọ̀kan àwọn gbólóhùn tí ó tẹ̀ lé e yìí:

26. Nígbà tí a fi Pọ́ọ̀lù sí ẹ̀wọ̀n ní Róòmù ní ìgbà àkọ́kọ́, (Ónẹ́sífórù; Ónẹ́símù; Ónánì), ẹrú kan tí ó sá lọ kúrò ní agboolé (Fílípì; Fẹ́sítọ́ọ̀sì; Fílémónì), wà lára àwọn tí ó tẹ́tí sí ìwàásù rẹ̀. [w91-YR 2/15 ojú ìwé 23 ìpínrọ̀ 2 àti 3]

27. (Ìfẹ́; Ọ̀wọ̀; Aájò àlejò) ni a túmọ̀ sí “gbígba ti àwọn ẹlòmíràn rò, bíbọlá fún wọn.” [fy-YR ojú ìwé 30 ìpínrọ̀ 7]

28. Ní Lúùkù 14:28, Jésù ń sọ̀rọ̀ nípa (wíwéwèé ṣáájú; ṣíṣàìfi owó ṣòfò; yíyẹra fún yíyá owó). [fy-YR ojú ìwé 40 ìpínrọ̀ 4]

29. “Àwọn ẹni ògo” tí a mẹ́nu kàn ní Júúdà 8 tọ́ka sí (ipò Jésù; ipò ọba aláṣẹ Jèhófà; àwọn tí Ọlọ́run àti Kristi fi ògo kan pàtó dá lọ́lá gẹ́gẹ́ bí alàgbà tí a fi àmì òróró yàn). [w91-YR 4/15 ojú ìwé 31 ìpínrọ̀ 5]

30. Ní Ìṣípayá 11:11, “ọjọ́ mẹ́ta àti ààbọ̀,” nígbà tí àwọn ẹni àmì òróró fara hàn gẹ́gẹ́ bí òkú lójú àwọn ọ̀tá wọn, tọ́ka sí (ọdún mẹ́ta àti ààbọ̀; ìwọ̀n àkókò kúkúrú kan; oṣù mẹ́ta àti ààbọ̀). [Bíbélì kíkà ọ̀sọ̀ọ̀sẹ̀; wo re-E ojú ìwé 167 ìpínrọ̀ 21.]

So àwọn ẹsẹ Ìwé Mímọ́ tí ó tẹ̀ lé e yìí mọ́ àwọn gbólóhùn tí a tò lẹ́sẹẹsẹ sí ìsàlẹ̀ yìí:

1 Kọ́r. 6:9-11; Héb. 2:1; Héb. 10:32; Ják. 4:15; 1 Pét. 3:4

31. Láti lè sọ ìgbékèéyíde ìgbà gbogbo tí ayé yìí ń ṣe nípa wa di aláìgbéṣẹ́, a gbọ́dọ̀ “fún” Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run “ní àfiyèsí tí ó ju ti àtẹ̀yìnwá lọ” nípa sísọ kíkẹ́kọ̀ọ́ lọ́nà dídánmọ́rán dàṣà àti níní ìtòlẹ́sẹẹsẹ dáradára fún Bíbélì kíkà. [Bíbélì kíkà ọ̀sọ̀ọ̀sẹ̀; wo w98-YR 1/1 ojú ìwé 7 ìpínrọ̀ 9.]

32. Nígbàkígbà tí a bá ń wéwèé fún ọjọ́ ọ̀la, ó yẹ kí a fi tàdúràtàdúrà ronú nípa bí wọ́n ṣe bá ète Ọlọ́run mu. [Bíbélì kíkà ọ̀sọ̀ọ̀sẹ̀; wo w97-YR 11/15 ojú ìwé 21 ìpínrọ̀ 10 àti 11.]

33. Kì í ṣe kìkì pé Kristẹni aya kan tí ó sì tún jẹ́ ìyá, tí ó ní “ẹ̀mí ìṣejẹ́ẹ́jẹ́ẹ́ àti ti ìwà tútù” máa ń mú inú ọkọ rẹ̀ dùn nìkan ni, ṣùgbọ́n lọ́nà tí ó túbọ̀ ṣe pàtàkì, òun a máa mú inú Ọlọ́run dùn. [Bíbélì kíkà ọ̀sọ̀ọ̀sẹ̀; wo w89-YR 5/15 ojú ìwé 19 ìpínrọ̀ 12.]

34. Rírántí tí a bá ń rántí àwọn ìṣe àtijọ́ ti ìdúróṣinṣin nínú ogun nípa tẹ̀mí lè fún wa ní ìgboyà láti parí eré ìje fún ìyè. [w96-YR 12/1 ojú ìwé 29 ìpínrọ̀ 3]

35. Àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà kì í yọ̀ǹda kí ẹnikẹ́ni tí ó bá di ọ̀mùtí aláìronúpìwàdà wà nínú ìjọ Kristẹni. [w96-YR 12/15 ojú ìwé 25 ìpínrọ̀ 3]

    Yorùbá Publications (1987-2025)
    Jáde
    Wọlé
    • Yorùbá
    • Fi Ráńṣẹ́
    • Èyí tí mo fẹ́ràn jù
    • Copyright © 2025 Watch Tower Bible and Tract Society of Pennsylvania
    • Àdéhùn Nípa Lílò
    • Òfin
    • Ètò Nípa Ìsọfúnni Rẹ
    • JW.ORG
    • Wọlé
    Fi Ráńṣẹ́