Ẹ Maa Baa Lọ ni Rírìn Ninu Imọlẹ ati Ifẹ
Awọn Koko Itẹnumọ lati inu Johanu Kìn-ínní
JEHOFA ni Orisun imọlẹ ati ifẹ. Awa gbọdọ wo Ọlọrun fun imọlẹ tẹmi. (Saamu 43:3) Ifẹ sì jẹ ọkan lara awọn èso ẹmi mimọ rẹ̀.—Galatia 5:22, 23.
Imọlẹ, ifẹ, ati awọn nǹkan miiran ni a jiroro ninu lẹta apọsteli Johanu akọkọ ti a misi, ti o ṣeeṣe ki a kọ ni tabi lẹbaa Efesu ni nǹkan bii 98 C.E. Idi pataki fun kikọ ọ ni lati daabobo awọn Kristian kuro lọwọ ipẹhinda ki a sì ran wọn lọwọ lati maa baa lọ ni ririn ninu imọlẹ. Niwọn bi a ti ndojukọ awọn ipenija nipa ifẹ, igbagbọ, ati ipawatitọ mọ́ wa otitọ, ayẹwo lẹta yii dajudaju yoo ṣanfaani fun wa.
‘Rìn ninu Imọlẹ’
Johanu mu ki o ṣe kedere pe awọn Kristian oluṣotitọ gbọdọ rìn ninu imọlẹ tẹmi. (1:1–2:29) Oun wipe: “Imọlẹ ni Ọlọrun, òkùnkùn kankan kò sí [ko si ohun ti nṣe ibi, ìwà palapala, aijootọ, tabi àìmọ́] lọdọ rẹ̀ rara.” Nitori naa awọn Kristian ẹni ami ororo ti a fi ẹmi yàn ‘nrin ninu imọlẹ,’ wọn ni “ipin” pẹlu Ọlọrun, Kristi, ati araawọn. Awọn pẹlu ni a ti wẹ̀nù kuro ninu ẹ̀ṣẹ̀ nipasẹ ẹ̀jẹ̀ Jesu.
Yala awa jẹ Kristian ẹni ami-ororo pẹlu ireti ti ọrun tabi awa nfojusọna fun iye ayeraye lori ilẹ-aye, awa yoo maa baa lọ lati janfaani lati inu irubọ Jesu kiki bi awa ba fẹran awọn arakunrin wa ṣugbọn kii ṣe aye. Awa pẹlu gbọdọ yẹra fun didi ẹni ti a nipa le lori nipasẹ awọn apẹhinda, iru awọn bii “aṣodisi Kristi,” awọn ti wọn sẹ́ Baba ati Ọmọkunrin. Ki awa ma sì ṣe gbagbe lae pe iye ayeraye ni awọn wọnni ti wọn rọ̀mọ́ otitọ ti wọn sì sọ ododo dàṣà yoo gbadun.
Awọn Ọmọ Ọlọrun Fi Ìfẹ́ Hàn
Lẹhin naa Johanu fi awọn ọmọ Ọlọrun hàn yatọ. (3:1–4:21) Fun ohun kan, wọn nṣe ohun ti o jẹ ododo. Awọn pẹlu nṣegbọran si aṣẹ Jehofa Ọlọrun ‘pe wọn ni igbagbọ ninu orukọ Ọmọkunrin rẹ̀, Jesu Kristi, ti wọn sì fẹran ara wọn ẹnikinni keji.’
Eniyan kan ti o ni “ìmọ̀ Ọlọrun” mọ̀ nipa awọn ète Jehofa ati bi a ṣe fi ifẹ Rẹ̀ han. Eyi nilati ran ẹni naa lọwọ lati fi ifẹ hàn. Nitootọ, “ẹni ti ko ba ni ifẹ kò mọ Ọlọrun; nitori pe ifẹ ni Ọlọrun.” Ifẹ atọrunwa ni a fihan nigba ti Ọlọrun “ran ọmọ rẹ̀ lati jẹ etutu fun ẹ̀ṣẹ̀ wa.” Bi Jehofa ba fẹran wa lọna ti o gbooro bayii, o jẹ aigbọdọmaṣe fun wa lati fẹran ẹnikinni keji. Bẹẹni, ẹnikẹni ti o sọ pe oun fẹran Ọlọrun gbọdọ nifẹẹ arakunrin rẹ̀ nipa tẹmi pẹlu.
Igbagbọ ‘Ṣẹgun Aye’
Ifẹ sun awọn ọmọ Ọlọrun lati pa awọn àṣẹ rẹ̀ mọ́, ṣugbọn nipa igbagbọ ni wọn fi lè ‘ṣẹgun aye.’ (5:1-21) Igbagbọ wa ninu Ọlọrun, Ọ̀rọ̀ rẹ̀, ati Ọmọkunrin rẹ̀ mu ki o ṣeeṣe fun wa lati ‘ṣẹgun aye’ nipa kikọ ironu ti ko tọna ati awọn ọna rẹ̀ silẹ ati nipa pipa awọn àṣẹ Jehofa mọ. Ọlọrun ti fun ‘awọn oluṣẹgun aye’ ni ireti naa fun iye ayeraye ti o sì ngbọ awọn adura wọn ti o wà ni ibamu pẹlu ifẹ inu rẹ. Nitori pe ẹnikẹni “ti a bí nipa ti Ọlọrun” kii dẹṣẹ, Satani kii nawọ́ gán iru awọn ẹni bawọnyi. Ṣugbọn awọn ti wọn jẹ ẹni ami-ororo ati awọn iranṣẹ Jehofa ti wọn ni ireti ti ilẹ aye nilati ranti pe ‘gbogbo aye wà labẹ agbara ẹni buburu nì.’
[Àpótí/Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 29]
Ẹbọ Etutu Ipẹtu: Jesu “ni ẹbọ etutu ipẹtu fun awọn ẹ̀ṣẹ̀ wa [ti awọn wọnni ti wọn jẹ ẹni ami-ororo ọmọlẹhin rẹ̀], sibẹ kii ṣe fun tiwa nikan bikoṣe fun ti gbogbo aye pẹlu,” iran araye ti o ṣẹ́kù. (1 Johanu 2:2, NW) Iku rẹ̀ jẹ “etutu ipẹtu” (Giriiki, hi·la·smosʹ, ti o duro fun “ọna lati tù lójú,” “ètùtù”) ṣugbọn kii ṣe ni ero itumọ ti títu awọn imọlara irora lójú niha ọdọ Ọlọrun. Kaka bẹẹ, irubọ Jesu Kristi tù lójú, tabi doju iwọn, awọn ohun ti idajọ ododo atọrunwa ti o pe perepere beere fun. Bawo? Nipa pipese ipilẹ ti o jẹ òdodo ti o sì duroṣinṣin fun didari ẹ̀ṣẹ̀ ji ni, ki Ọlọrun “baa lè jẹ olododo ani nigba ti o ba nka ẹnikẹni [ẹlẹṣẹ lọna ajogunba] ti o ni igbagbọ ninu Jesu si olododo.” (Roomu 3:23-26, NW; 5:12) Nipa pipese ọna fun mimu itẹlọrun ti o pe perepere wá fun ẹ̀ṣẹ̀ eniyan, irubọ Jesu mu ki o jẹ etutu ipẹtu, tabi olojurere, fun eniyan lati wá ki o sì gba imupadabọsipo si ipo ibatan didara pẹlu Jehofa. (Efesu 1:7; Heberu 2:17) Bawo ni gbogbo wa ṣe gbọdọ kun fun ọpẹ to fun eyi!