“Imọlẹ Ti Wá Sinu Aye”
“Eyi ni ipilẹ fun idajọ, pe imọlẹ ti wa sinu aye ṣugbọn awọn eniyan nifẹẹ okunkun ju imọlẹ lọ.”—JOHANU 3:19, NW.
1. Eeṣe ti olukuluku fi nilati daniyan nipa idajọ Ọlọrun?
ỌPỌJULỌ awọn eniyan lonii ko bikita nipa idajọ Ọlọrun. Awọn kan gba a si ootọ pe Ọlọrun yoo fi ojurere dá wọn lẹjọ bi wọn ba nlọ si ṣọọṣi deedee ti wọn ko si ṣe ipalara si awọn aladuugbo wọn. Fun ọpọlọpọ, awọn ẹkọ Kristẹndọmu nipa ọrun apaadi ati pọgatori ti mu ki awọn eniyan má gbagbọ ninu gbogbo ero nipa idajọ atọrunwa. Ṣugbọn aibikita tí ńtànkálẹ̀ ati awọn irọ Kristẹndọmu ko le yi otitọ naa pada pe olukuluku eniyan ni Ọlọrun yoo dá lẹjọ ni asẹhinwa asẹhinbọ. (Roomu 14:12; 2 Timoti 4:1; Iṣipaya 20:13) Pupọ yoo si sinmi lori idajọ yii. Awọn wọnni ti a fi ojurere dá lẹjọ yoo gba ẹbun iye ainipẹkun ti Ọlọrun, nigba ti awọn wọnni ti a dá lẹjọ lọna ti ko báradé yoo gba ẹkunrẹrẹ owó ọ̀yà ẹṣẹ naa: iku.—Roomu 6:23.
2. Ki ni ipilẹ fun idajọ Ọlọrun?
2 Fun idi yii, awọn ojulowo Kristẹni daniyan nipa idajọ Ọlọrun, wọn si fi tọkantọkan nifẹẹ lati ṣe ohun ti o wù ú. Bawo ni wọn ṣe le ṣe eyi? Ni Johanu 3:19 (NW), Jesu fun wa ni ojutuu naa. O wipe: “Eyi ni ipilẹ fun idajọ, pe imọlẹ ti wa sinu aye ṣugbọn awọn eniyan nifẹẹ okunkun ju imọlẹ lọ, nitori iṣẹ wọn jẹ buruku.” Bẹẹni, idajọ Ọlọrun ni a o gbekari boya a nifẹẹ imọlẹ dipo okunkun.
“Ọlọrun Jẹ Imọlẹ”
3. Ki ni okunkun naa, ki si ni imọlẹ naa?
3 Ni itumọ tẹmi, okunkun niiṣe pẹlu aimọkan ati aini ireti ti o wà ninu ilẹ-akoso Satani—bi o tilẹ jẹ pe Satani ńdíbọ́n lemọlemọ lati jẹ “angẹli imọlẹ.” (2 Kọrinti 4:4; 11:14; Efesu 6:12) Ni ọwọ keji ẹwẹ, imọlẹ niiṣe pẹlu oye ati ìlàlóye ti o wá lati ọdọ Jehofa Ọlọrun. Pọọlu sọrọ nipa imọlẹ naa nigba ti o kọwe pe: “Nitori Ọlọrun, ẹni ti o wipe ki imọlẹ ki o mọlẹ lati inu okunkun jade, oun ni o ti nmọlẹ ni ọkan wa, lati fun wa ni imọlẹ ìmọ̀ ogo Ọlọrun ni oju Jesu Kristi.” (2 Kọrinti 4:6) Imọlẹ tẹmi ni a mọ̀ mọ Jehofa Ọlọrun timọtimọ debi pe apọsiteli Johanu kọwe pe: “Ọlọrun jẹ imọlẹ.”—1 Johanu 1:5, NW; Iṣipaya 22:5.
4. (a) Bawo ni Jehofa ṣe mu ki imọlẹ wà larọọwọto? (b) Ni ọna wo ni awa lè gbà fi ifẹ fun imọlẹ han sode?
4 Jehofa ti mu ki imọlẹ wà larọọwọto nipasẹ ọrọ rẹ̀, eyi ti o wà larọọwọto lọfẹẹ ni kikọsilẹ ninu Bibeli Mimọ. (Saamu 119:105; 2 Peteru 1:19) Fun idi yii, onisaamu naa nsọ ifẹ rẹ fun imọlẹ naa jade nigba ti o kọwe pe: “Emi ti fẹ ofin rẹ to! Iṣaro mi ni ni ọjọ gbogbo. Ọkan mi ti pa ẹri rẹ mọ; emi si fẹ wọn gidigidi.” (Saamu 119:97, 167) Iwọ ha nifẹẹ imọlẹ gan an gẹgẹ bi onisaamu ti ṣe lọna ti o han gbangba bi? Iwọ ha nka Ọrọ Ọlọrun deedee, ṣe àṣàrò nipa rẹ, ti o si ngbiyanju kára lati fi ohun ti ó sọ si ilo bi? (Saamu 1:1-3) Bi o ba rí bẹẹ, iwọ nwa ọna lati gba idajọ olojurere lati ọdọ Jehofa.
“Emi Ni Imọlẹ Aye”
5. Lori ta ni imọlẹ atọrunwa naa pa afiyesi pọ̀ sí?
5 Imọlẹ ti ngba ẹmi là lati ọdọ Jehofa pa afiyesi pọ sori ẹni tii ṣe Jesu Kristi. Ninu inasẹ ọrọ Ihinrere Johanu, a kà pe: “Ninu rẹ [Jesu] ni ìyè wà; ìyè naa sì ni imọlẹ araye. Imọlẹ naa si nmọlẹ ninu okunkun; okunkun naa ko sì bori rẹ̀.” (Johanu 1:4, 5) Nitootọ, Jesu ni iru isopọ timọtimọ bẹẹ pẹlu imọlẹ ti a fi pe e ni “imọlẹ tootọ naa ti nfun gbogbo oniruuru eniyan ni imọlẹ.” (Johanu 1:9, NW) Jesu funraarẹ wipe: “Niwọn igba ti mo wà ni aye, emi ni imọlẹ aye.”—Johanu 9:5.
6. Ki ni ẹnikan gbọdọ ṣe ki o ba lè jere idajọ olojurere ti nṣamọna si iye ainipẹkun?
6 Nitori naa, awọn wọnni ti wọn nifẹẹ imọlẹ nifẹẹ Jesu wọn si nigbagbọ ninu rẹ̀. Ko ṣeeṣe lati jere idajọ olojurere laika Jesu sí. Bẹẹni, kiki nipa gbigbarale e gẹgẹ bi ọna igbala ti Ọlọrun yàn ni a fi le jere idajọ olojurere kan. Jesu wipe: “Ẹni ti o ba gba Ọmọ gbọ, o ni iye ainipẹkun: ẹni ti ko ba sì gba Ọmọ gbọ́, ki yoo rí iye; ṣugbọn ibinu Ọlọrun nbẹ lori rẹ.” (Johanu 3:36) Bi o ti wu ki o ri, ki ni o tumọ si lati mu igbagbọ lo ninu Jesu?
7. Igbagbọ ninu Jesu tun tumọsi igbagbọ ninu ẹlomiran wo?
7 Lakọọkọ, Jesu funraarẹ wipe: “Ẹni ti o ba ni igbagbọ ninu mi ni igbagbọ, kii ṣe ninu mi nikan, bikoṣe ninu ẹni naa pẹlu ti o rán mi; ẹni ti o si rí mi rí ẹni ti o ran mi [pẹlu]. Mo ti wá gẹgẹ bi imọlẹ sinu aye, ki olukuluku ẹni ti o ba ni igbagbọ ninu mi ma baa wà ninu okunkun.” (Johanu 12:44-46, NW) Awọn wọnni ti wọn nifẹẹ Jesu ti wọn si mu igbagbọ lò ninu rẹ tun gbọdọ ní ifẹ jijinlẹ fun ati igbagbọ ninu Ọlọrun ati Baba Jesu, Jehofa. (Matiu 22:37; Johanu 20:17) Olukuluku awọn ti nlo orukọ Jesu ninu ijọsin wọn ṣugbọn ti wọn kuna lati fi ọla ti o ga julọ fun Jehofa kò fi ojulowo ifẹ fun imọlẹ han.—Saamu 22:27; Roomu 14:7, 8; Filipi 2:10, 11.
“Olori Aṣoju” Ọlọrun
8. Bawo ni imọlẹ atọrunwa ṣe pa afiyesi pọ sori Jesu ani ṣaaju ìbí rẹ gẹgẹ bi eniyan paapaa?
8 Mimu igbagbọ lò ninu Jesu tun tumọsi titẹwọgba ipa tí ó kó ninu awọn ete Jehofa ni kikun. Ijẹpataki ipa yii ni a tẹnumọ nigba ti angẹli naa sọ fun Johanu pe: “Jijẹrii si Jesu ni ohun ti ńmísí isọtẹlẹ.” (Iṣipaya 19:10, NW; Iṣe 10:43; 2 Kọrinti 1:20) Lati ori asọtẹlẹ akọkọ gan an ni Edeni, gbogbo awọn asọtẹlẹ onimiisi atọrunwa ní asẹhinwa asẹhinbọ niiṣe pẹlu Jesu ati ipo rẹ ninu ṣiṣaṣepari awọn ete Ọlọrun. Lọna ti o farajọra, Pọọlu sọ fun awọn Kristẹni ni Galatia pe majẹmu Ofin jẹ “olùtọ́ ti nsinni lọ sọdọ Kristi.” (Galatia 3:24, NW) Majẹmu Ofin igbaani ni a pete lati mura orilẹ-ede naa silẹ fun dide Jesu gẹgẹ bi Mesaya. Nitori naa ṣaaju ìbí rẹ̀ gẹgẹ bi eniyan paapaa, imọlẹ lati ọdọ Jehofa pa afiyesi pọ sori Jesu.
9. Ki ni ninifẹẹ imọlẹ wémọ́ lati 33 C.E.?
9 Ni 29 C.E., Jesu farahan fun iribọmi a sì fami ororo yan an pẹlu ẹmi mimọ, ni titipa bayii di Mesaya ti a ṣeleri naa. Ni 33 C.E. o kú ni ẹni pipe, a jí i dide, o goke re ọrun, ati nibẹ o pese itoye iwalaaye rẹ̀ nititori awọn ẹṣẹ wa. (Heberu 9:11-14, 24) Ọ̀wọ̀ọ̀wọ́ iṣẹlẹ yii sami si koko iyipada kan ninu awọn ibalo Ọlọrun pẹlu eniyan. Jesu nisinsinyi jẹ “Olori Aṣoju iye,” “Olori Aṣoju igbala,” “Olori Aṣoju ati Alaṣepe igbagbọ wa.” (Iṣe 3:15; Heberu 2:10; 12:2; Roomu 3:23, 24, NW) Lati 33 C.E. lọ, awọn olufẹẹ imọlẹ ti mọ, wọn si ti gba pe, yatọ si Jesu “ko si igbala lọdọ ẹlomiran: nitori ko si orukọ miiran labẹ ọrun ti a fifunni ninu eniyan, nipa eyi ti a le fi gbà wá là.”—Iṣe 4:12.
10. Eeṣe ti o fi ṣe pataki tobẹẹ lati fetisilẹ si awọn ọrọ Jesu ki a si ṣegbọran si wọn?
10 Mimu igbagbọ lo ninu Jesu tun tumọsi titẹwọgba a gẹgẹ bi “Ọrọ naa” ati “Agbayanu Olugbaninimọran” naa. (Johanu 1:1; Aisaya 9:6) Ohun ti Jesu sọ maa nfi otitọ atọrunwa han kedere nigba gbogbo. (Johanu 8:28; Iṣipaya 1:1, 2) Fifetisilẹ si i jẹ ọran iku ati iye. Jesu sọ fun awọn Juu ọjọ rẹ̀ pe: “Ẹnikẹni ti o bá gbọ ọrọ mi, ti o ba si gba ẹni ti o rán mi gbọ́, o ni iye ti ko nipẹkun, oun ki yoo sì wá si idajọ; ṣugbọn o ti ré iku kọja bọ́ si iye.” (Johanu 5:24) Ni ọgọrun un ọdun kìn-ínní Sanmani Tiwa, awọn wọnni ti wọn gbé igbesẹ lori awọn ọrọ Jesu ni a gbala kuro ninu okunkun aye Satani ti wọn si wa si iye, gẹgẹ bi a ti le sọ. A polongo wọn ni olododo pẹlu ireti jijẹ ajumọjogun pẹlu rẹ ninu Ijọba rẹ̀ ọrun. (Efesu 1:1; 2:1, 4-7) Lonii, ṣiṣegbọran si awọn ọrọ Jesu ṣí ọna silẹ fun ọpọlọpọ lati di awọn ti a polongo ni olododo pẹlu ireti lila Amagẹdọn já ati jijere iwalaaye eniyan pipe ninu aye titun naa.—Iṣipaya 21:1-4; fiwe Jakọbu 2:21, 25.
“Ori Lori Ohun Gbogbo”
11. Aṣẹ giga wo ni a fifun Jesu ni 33 C.E.?
11 Lẹhin ajinde rẹ, Jesu ṣi apa-iha miiran ti imọlẹ naa paya fun awọn ọmọlẹhin rẹ̀. Ó wipe: “Gbogbo agbara ni ọrun ati ni aye ni a fi fun mi.” (Matiu 28:18) Jesu ni a tipa bayii gbega si ipo titayọ ninu eto-ajọ agbaye Jehofa. Pọọlu funni ni awọn kulẹkulẹ siwaju sii nigba ti o wipe: “[Ọlọrun] gbé [Jesu] dide kuro ninu oku . . . o si fi i jokoo si ọwọ ọtun rẹ ni awọn ibi ọrun, loke fiofio ju olukuluku akoso ati ọla-aṣẹ ati agbara ati ipo oluwa ati olukuluku orukọ ti a ńdá, kii ṣe kiki ninu eto igbekalẹ awọn nǹkan yii, ṣugbọn ninu eyiini ti nbọ pẹlu. O tun mu ohun gbogbo tẹriba sabẹ ẹsẹ rẹ, o si fi ṣe ori lori ohun gbogbo fun ijọ, eyi ti o jẹ ara rẹ.” (Efesu 1:20-23, NW; Filipi 2:9-11) Lati 33 C.E., ninifẹ imọlẹ naa ti papọ pẹlu jijẹwọ ipo giga ti Jesu yii.
12. Ki ni awọn Kristẹni ẹni ami ororo ti fi tayọtayọ gbà gan an lati ibẹrẹ, bawo si ni wọn ṣe fi eyi han lọna ti wọn ngba huwa?
12 Asẹhinwa asẹhinbọ, gbogbo araye yoo nilati jẹwọ ọla-aṣẹ giga ti Jesu. (Matiu 24:30; Iṣipaya 1:7) Bi o ti wu ki o ri, awọn olufẹ imọlẹ, ti fi tayọtayọ da a mọ gan an lati ibẹrẹ. Awọn mẹmba ẹni ami ororo ijọ Kristẹni tẹwọgba Jesu gẹgẹ bi “ori fun ara, ijọ.” (Kolose 1:18, NW; Efesu 5:23) Nigba ti wọn ba di apakan ara yẹn, awọn ni ‘a dánídè kuro lọwọ ọla-aṣẹ okunkun ti a sì ṣí nipo pada lọ sinu ijọba Ọmọkunrin ifẹ Ọlọrun.’ (Kolose 1:13) Lati isinsinyi lọ, wọn nfi tọkantara tẹle ipo aṣiwaju Jesu ninu gbogbo apa iha igbesi-aye wọn, ati ni akoko wa wọn ti kọ “awọn agutan miiran” lẹkọọ lati ṣe bakan naa. (Johanu 10:16) Jijẹwọ ipo ori Jesu jẹ́ ohun àbèèrèfún pataki fun riri idajọ olojurere kan gbà.
13. Nigba wo ni Jesu bẹrẹ sii lo aṣẹ Ijọba, ki ni o si ti tẹle e nihin in lori ilẹ-aye?
13 Nigba igoke re ọrun rẹ ni 33 C.E., Jesu ko lo aṣẹ rẹ dé iwọn ẹkunrẹrẹ loju ẹsẹ. Bi o tilẹ jẹ pe oun jẹ Ori ijọ Kristẹni, o duro fun akoko yiyẹ lati lo aṣẹ kikun lori araye ni gbogbogboo. (Saamu 110:1; Iṣe 2:33-35) Akoko yẹn dé ni 1914, nigba ti a gbé Jesu gori itẹ gẹgẹ bi Ọba Ijọba Ọlọrun “awọn ọjọ ikẹhin” aye yii si bẹrẹ. (2 Timoti 3:1, NW) Lati 1919, ikojọ iyoku awọn ẹni ami ororo ti tẹsiwaju si ẹkunrẹrẹ rẹ. Ni pataki lati 1935, Jesu ti nya araye sọtọ si “awọn agutan,” ti wọn yoo jogun “ijọba naa ti a ti mura silẹ de [wọn],” ati “awọn ewurẹ,” ti wọn yoo “lọ kuro sinu ikekuro ainipẹkun.”—Matiu 25:31-34, 41, 46, NW.
14. Bawo ni ogunlọgọ nla ṣe fi ifẹ fun imọlẹ han, ki ni yoo si yọrisi fun wọn?
14 Lọna ti o muni layọ, awọn agutan ti jasi eyi ti o pọ̀ rẹpẹtẹ ni awọn ọjọ ikẹhin wọnyi. Ogunlọgọ nla wọn ti iye wọn wọ araadọta ọkẹ ti farahan loju iran aye “lati inu gbogbo awọn orilẹ-ede ati ẹya ati eniyan ati ahọn.” Bi awọn alábàárìn wọn, awọn ẹni ami ororo, awọn ẹni bi agutan wọnyi nifẹẹ imọlẹ. Wọn ti “fọ awọn aṣọ igunwa wọn wọ́n sì sọ wọn di funfun ninu ẹjẹ Ọdọ-agutan naa,” wọn si nkigbe ni ohùn rara pe: “Gbese ọpẹ fun igbala ni a jẹ Ọlọrun wa, ti o jokoo lori itẹ, ati Ọdọ-agutan naa.” Nitori eyi, ogunlọgọ nla naa gẹgẹ bi awujọ kan yoo gba idajọ olojurere kan. Awọn mẹmba rẹ “jade lati inu ipọnju nla wa,” ni lila iparun awọn wọnni ti wọn nifẹẹ si okunkun já ni Amagẹdọn.—Iṣipaya 7:9, 10, 14, NW.
“Awọn Ọmọ Imọlẹ”
15. Ni ọna wo ni awọn iwa wa gba fi itẹriba wa fun Ọba wa naa, Jesu Kristi han?
15 Bi o ti wu ki o ri, bawo, lọna ti wọn ngba huwa ni awọn olufẹ imọlẹ, yala ẹni ami ororo tabi awọn agutan miiran ṣe tẹriba fun Jesu gẹgẹ bi ẹni naa ti Ọlọrun gbe gori itẹ gẹgẹ bi Ọba ati aṣoju Onidaajọ? Ọna kan ni nipa gbigbiyanju lati jẹ́ iru awọn eniyan ti Jesu fọwọsi. Nigba ti ó wa lori ilẹ-aye, Jesu fi imọriri han fun iru awọn animọ gẹgẹ bi otitọ inu, ìfínnúfíndọ̀, ati itara ọkan fun otitọ, oun funraarẹ si ṣapẹẹrẹ awọn animọ wọnyi. (Maaku 12:28-34, 41-44; Luuku 10:17, 21) Bi awa ba fẹ idajọ olojurere, awa gbọdọ mu iru awọn animọ bẹẹ dagba.
16. Eeṣe ti o fi ṣe pataki lati bọ́ awọn iṣẹ tii ṣe ti okunkun silẹ?
16 Ni pataki ni eyi jẹ ootọ niwọn bi okunkun aye Satani ti ńṣú biribiri sii gẹgẹ bi opin ti nsunmọle. (Iṣipaya 16:10) Awọn ọrọ tí Pọọlu kọ si awọn ara Roomu ba a mu wẹku gan an nigba naa pe: “Oru ti lọ jinna; ilẹ ti fẹrẹẹ mọ́. Nitori naa ẹ jẹ ki a bọ́ awọn iṣẹ tii ṣe ti okunkun silẹ ki ẹ si jẹ ki a gbe awọn ohun ija imọlẹ wọ̀. Gẹgẹ bi ni akoko ọsan ẹ jẹ ki a maa rin tẹ̀yẹtẹ̀yẹ, kii ṣe ninu awọn ariya alariwo ati ìfagagbága imutiyo, kii ṣe ninu ibalopọ takọtabo alaitọsofin ati iwa ainijanu, kii ṣe ninu rògbòdìyàn ati owú.” (Roomu 13:12, 13) Nigba ti iye ainipẹkun jẹ ẹbun lati ọdọ Ọlọrun, ijojulowo igbagbọ wa ati ifẹ wa fun imọlẹ ni a fihan kedere nipa awọn iṣesi wa. (Jakọbu 2:26) Fun idi yii, idajọ ti a o gbà yoo sinmi ni iwọn titobi lori bi a ti sọ awọn iṣẹ rere daṣa tó ti a si pa awọn iṣẹ buburu tì.
17. Ki ni o tumọ si lati “gbé Jesu Kristi Oluwa wọ̀”?
17 Lẹhin fifunni ni imọran rẹ ni Roomu 3:12, 13 (NW), apọsiteli Pọọlu pari ọrọ nipa wiwipe: “Ẹ gbé Jesu Kristi Oluwa wọ̀, ẹ ma si ṣe maa wéwèé tẹlẹ fun awọn ifẹ ọkan ti ẹran ara.” (Roomu 13:14, NW) Ki ni o tumọ si lati “gbe Jesu Kristi Oluwa wọ̀”? O tumọ si pe awọn Kristẹni nilati tẹle Jesu timọtimọ, ni wiwọ araawọn ni aṣọ, ki a sọ ọ́ lọna bẹẹ, pẹlu apẹẹrẹ rẹ̀ ati iwa rẹ̀, ni lilakaka lati dabi Kristi. Peteru wipe, “Ipa-ọna yii ni a pe yin sí, nitori Kristi paapaa jiya fun yin, o si fi awoṣe silẹ fun yin lati tẹle awọn iṣisẹ rẹ timọtimọ.”—1 Peteru 2:21, NW.
18. Awọn iyipada patapata wo ni o lè pọndandan bi a ba fẹ lati gba idajọ olojurere?
18 Eyi niye igba ti wémọ́ awọn iyipada patapata ninu igbesi-aye Kristẹni kan. “Nitori ẹyin ti jẹ okunkun nigba kan rí,” ni Pọọlu wi, “ṣugbọn nisinsinyi ẹ jẹ́ imọlẹ ni isopọ pẹlu Oluwa. Ẹ maa baa lọ ni rinrin gẹgẹ bi awọn ọmọ imọlẹ, nitori eso ti imọlẹ ní olukuluku oniruuru iwarere iṣeun ati ododo ati otitọ ninu.” (Efesu 5:8, 9, NW) Olukuluku ẹni ti o ba sọ awọn iṣẹ okunkun daṣa kii ṣe olufẹ imọlẹ ki yoo si gba idajọ olojurere ayafi ti o ba ṣe iyipada.
“Ẹyin Ni Imọlẹ Aye”
19. Ni awọn ọna yiyatọ wo ni Kristẹni kan le gba fi imọlẹ han?
19 Ni ikẹhin, ninifẹẹ imọlẹ tumọ si titan imọlẹ naa jade ki awọn ẹlomiran ba le rí i ki o si fà wọn mọra. “Ẹyin ni imọlẹ aye,” ni Jesu wi. O si fi kun un pe: “Ẹ jẹ ki imọlẹ yin mọlẹ niwaju eniyan, ki wọn le ri awọn iṣẹ rere yin ki wọn si fi ogo fun Baba yin ti nbẹ ninu awọn ọrun.” (Matiu 5:14, 16, NW) Awọn iṣẹ rere Kristẹni kan wémọ́ fifi gbogbo oriṣi iwarere iṣeun ati iwa ododo ati otitọ han kedere, niwọn bi iru iwarere iṣeun bẹẹ ti pese ẹri alagbara fun otitọ naa. (Galatia 6:10; 1 Peteru 3:1) Ni pataki ni wọn wémọ́ biba awọn miiran sọrọ nipa otitọ naa. Lonii, eyi tumọ si ṣiṣajọpin ninu igbetaasi jakejado nipa iwaasu “ihinrere ijọba yii ni gbogbo ilẹ-aye gbígbé fun ẹri si gbogbo awọn orilẹ-ede.” Pẹlupẹlu, o tumọ si fifi suuru pada lọ sọdọ awọn olufifẹhan, ni kikẹkọọ Bibeli pẹlu wọn, ati ni riran wọn lọwọ, tẹle e, lati maa mu awọn eso iṣẹ ti o jẹ ti imọlẹ jade.—Matiu 24:14, NW; 28:19, 20.
20. (a) Bawo ni imọlẹ naa ti ntan yanranyanran tó lonii? (b) Awọn ibukun jingbinni wo ni awọn wọnni ti wọn dahun pada si imọlẹ naa ngbadun?
20 Ni ọjọ wa, ọpẹ ni fun igbokegbodo iwaasu onitara ti awọn Kristẹni oluṣotitọ, ihinrere naa ni a ngbọ ni ohun ti o ju 200 ilẹ lọ, imọlẹ naa si ntan yanranyanran ju ti igbakigba rí lọ. Jesu wipe: “Emi ni imọlẹ aye; ẹni ti o ba tọ mi lẹhin ki yoo rin ninu okunkun, ṣugbọn yoo ni imọlẹ iye.” (Johanu 8:12) Ẹ wo ayọ ti o jẹ́ lati ṣajọpin ninu mimu ileri yii ṣẹ! Igbesi-aye wa ni a sọ di ọlọrọ gidigidi nisinsinyi niti pe awa kò lálàṣí ninu okunkun aye Satani mọ. Awọn ifojusọna wa sì jẹ agbayanu nitootọ gẹgẹ bi a ti nwo iwaju fun idajọ olojurere lati ọdọ Onidaajọ tí Jehofa yan. (2 Timoti 4:8) Iru ọran ibanujẹ wo ni iba jẹ́, lẹhin wiwa sinu imọlẹ, bi a ba tun sú lọ pada sinu okunkun ki a si gba idajọ aláìbáradé kan! Ninu ọrọ-ẹkọ ti o tẹle e, a ṣe lè maa duro ṣinṣin niṣo ninu igbagbọ.
Iwọ Ha Le Ṣalaye Bi?
◻ Ki ni ipilẹ fun idajọ Ọlọrun?
◻ Ipa pataki wo ni Jesu kó nipa awọn ete Ọlọrun?
◻ Bawo ni awa ṣe nṣaṣefihan pe a tẹriba fun Jesu gẹgẹ bi ẹni naa ti Jehofa gbékarí itẹ gẹgẹ bi Ọba?
◻ Bawo ni awa ṣe le fi ara wa han pé a jẹ́ “awọn ọmọ imọlẹ”?
◻ Ninu aye okunkun yii, ni ọna wo ni imọlẹ ngba tan ju ti igbakigba rí lọ?
[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 10]
Asẹhinwa asẹhinbọ, gbogbo araye yoo nilati jẹwọ ọla-aṣẹ Jesu
[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 12]
Awa fihan pe a nifẹẹ imọlẹ nigba ti a ba tan an jade fun awọn ẹlomiran