ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍNTÁNẸ́Ẹ̀TÌ ti Watchtower
ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍŃTÁNẸ́Ẹ̀TÌ
ti Watchtower
Yorùbá
ọ́
  • ẹ
  • ọ
  • ṣ
  • ń
  • ẹ́
  • ẹ̀
  • ọ́
  • ọ̀
  • BÍBÉLÌ
  • ÌTẸ̀JÁDE
  • ÌPÀDÉ
  • w91 8/1 ojú ìwé 14-19
  • “Ẹ Gbé Awọn Ohun Ija Imọlẹ Wọ̀”

Kò sí fídíò kankan ní apá yìí.

Má bínú, fídíò yìí kò jáde.

  • “Ẹ Gbé Awọn Ohun Ija Imọlẹ Wọ̀”
  • Ilé-Ìṣọ́nà Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—1991
  • Ìsọ̀rí
  • Àpilẹ̀kọ Míì Tó Jọ ọ́
  • Àtakò Lati Ọdọ Awọn Alaṣẹ Isin
  • Imọtara-ẹni-nikan ati Igberaga
  • ‘A Pè Wọn Jade Kuro Ninu Okunkun’
  • ‘Ko si Okunkun Pẹlu Ọlọrun’
  • Animọ Iwa Titun
  • “Nipa Imọle Lati Ọdọ Rẹ Ni Awa Lè Rí Imọlẹ”
  • Ìmọ́lẹ̀ Ọlọ́run Ń lé Òkùnkùn Dà Nù!
    Ilé Ìṣọ́ Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—2002
  • “Imọlẹ Ti Wá Sinu Aye”
    Ilé-Ìṣọ́nà Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—1991
  • Ẹ Tẹle Ìmólẹ̀ Ayé Naa
    Ilé-Ìṣọ́nà Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—1993
  • Awọn Wo ni Wọn Ń Tẹle Ìmọ́lẹ̀ Ayé?
    Ilé-Ìṣọ́nà Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—1993
Àwọn Míì
Ilé-Ìṣọ́nà Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—1991
w91 8/1 ojú ìwé 14-19

“Ẹ Gbé Awọn Ohun Ija Imọlẹ Wọ̀”

“Oru ti lọ jinna; ilẹ ti fẹrẹẹ mọ. Nitori naa ẹ jẹ ki a bọ́ awọn iṣẹ tii ṣe ti okunkun silẹ ki ẹ si jẹ ki a gbe awọn ohun ija imọlẹ wọ̀.” —ROOMU 13:12, NW.

1, 2. Bawo ni ọpọjulọ awọn Juu ni ọgọrun un ọdun kìn-ínní ṣe dahun pada si “imọlẹ tootọ naa,” ati eyi laika awọn anfaani wo sí?

JESU KRISTI ni “imọlẹ tootọ naa ti nfun gbogbo oniruuru eniyan ni imọlẹ.” (Johanu 1:9, NW) Nigba ti o wá gẹgẹ bi Mesaya ni 29 C.E., ó wá si orilẹ-ede kan ti Ọlọrun ti yan lati jẹ awọn ẹlẹrii Rẹ ti a yà si mimọ fun Jehofa o keretan lọna orukọ lasan. (Aisaya 43:10) Ọpọlọpọ awọn ọmọ Isirẹli ti nduro de Mesaya naa, diẹ ninu wọn si mọ diẹ lara awọn asọtẹlẹ naa ti yoo fi i han yatọ. Siwaju sii, Jesu waasu ni gbogbo apa Palẹstini, ni ṣiṣe iṣẹ ami ni kòrókòró oju ọpọlọpọ awọn eniyan. Awọn ogunlọgọ rọ́ wá lati gbọ́ ọ a sì wú wọn lori nipa awọn ohun ti wọn rí ti wọn sì gbọ́.—Matiu 4:23-25; 7:28, 29; 9:32-36; Johanu 7:31.

2 Bi o ti wu ki o ri, ni opin rẹ, ọpọjulọ awọn Juu ṣá Jesu tì. Ihinrere Johanu wipe: “Ó tọ awọn tirẹ wá, awọn ara tirẹ ko si gbà á.” (Johanu 1:11) Eeṣe ti eyi fi rí bẹẹ? Idahun si ibeere yẹn yoo ran wa lọwọ lati yẹra fun ṣiṣe aṣetunṣe aṣiṣe wọn. Yoo ran wa lọwọ lati ‘bọ awọn iṣẹ tii ṣe ti okunkun silẹ ki a sì . . . gbé awọn ohun ija imọlẹ wọ̀,’ ni titipa bayii yẹra fun idajọ alailojurere bi iru eyi ti Isirẹli ọgọrun un ọdun kìn-ínní jiya rẹ.—Roomu 13:12, NW; Luuku 19:43, 44.

Àtakò Lati Ọdọ Awọn Alaṣẹ Isin

3. Ni ọna wo ni awọn aṣaaju isin Juu gba já si “afọju amọna”?

3 Ni Isirẹli awọn aṣaaju isin jẹ agbapo iwaju julọ ninu ṣíṣá imọlẹ naa tì. Laika jijẹ olukọ “amofin” sí, wọn ti gbé awọn ofin arinkinkin dori bín-íntín ti o saba maa ntako Ofin Ọlọrun ka awọn eniyan lori. (Luuku 11:45, 46) Nipa bayii, wọn ‘sọ ọrọ Ọlọrun di alailagbara nipa ofin atọwọdọwọ ti wọn gbé kalẹ.’ (Maaku 7:13; Matiu 23:16, 23, 24) Wọn jẹ “afọju amọna,” ti ńdí imọlẹ lọwọ lati tàn jade.—Matiu 15:14, NW.

4, 5. (a) Bawo ni awọn Farisi ṣe huwa pada nigba ti ọpọlọpọ awọn Juu bẹrẹ si ṣe kayefi boya Jesu ni Mesaya naa? (b) Ọna ironu ọkan buburu wo ni awọn Farisi fihan kedere?

4 Ni akoko kan nigba ti awọn ọmọ Isirẹli nṣe kayefi yala Jesu ni Kristi naa, awọn Farisi ti a ti kó ìdágìrì bá ran awọn oniṣẹ lati faṣẹ ọba mu un. Awọn oniṣẹ pada lọwọ ofo, ni wiwipe: “Ko si ẹni ti o tii sọrọ bi ọkunrin yii ri.” Lai ta wọ́n púkẹ́, awọn Farisi beere lọwọ awọn oniṣẹ naa pe: “A ha tan ẹyin jẹ pẹlu bi? O ha sí ẹnikan ninu awọn ijoye, tabi awọn Farisi ti o gba a gbọ́? Ṣugbọn ijọ eniyan yii ti ko mọ Ofin, di ẹni ifibu.” Nikodemu, mẹmba Sanhẹdirin kan ṣatako pe ko bá ofin mu lati ṣedajọ ọkunrin kan ṣaaju ki a tó gbẹjọ rẹ. Pẹlu irira, awọn Farisi dojukọ ọ wọn si wipe: “Iwọ pẹlu nṣe ara Galili ndan? Wá kiri, ki o si wò ó: nitori ko si wolii kan ti o ti Galili dide.”—Johanu 7:46-52.

5 Eeṣe ti awọn aṣaaju isin ninu orilẹ-ede kan ti a yà si mimọ fun Ọlọrun fi huwa ni iru ọna bẹẹ? Nitori pe wọn ti mu ipo ọkan buburu dagba. (Matiu 12:34) Oju iwoye wọn ti o kún fun ẹgan nipa awọn eniyan gbáàtúù fi ẹmi igberaga wọn han kedere. Ijẹwọ wọn pe ‘ko si ọkan ninu awọn ijoye tabi awọn Farisi ti o gba a gbọ’ jẹ ìgbàṣebí onigbeeraga naa pe Mesaya le jẹ ojulowo kiki bi wọn ba fọwọ sii. Siwaju sii, wọn jẹ alabosi, ni gbigbiyanju lati mu ki awọn eniyan sọ igbagbọ nù ninu Jesu nitori pe oun wá lati Galili, nigba ti iwadii rirọrun iba ti ṣipaya pe oun ni a bí ni Bẹtilẹhẹmu niti tootọ, ibi ìbí Mesaya naa ti a sọtẹlẹ.—Mika 5:2; Matiu 2:1.

6, 7. (a) Bawo ni awọn aṣaaju isin ṣe huwa pada si ajinde Lasaru? (b) Ki ni Jesu sọ lati tudii aṣiiri ifẹ si okunkun ti awọn aṣaaju isin ni?

6 Atako ti a kò le pẹ̀tù sí niha ọdọ awọn aṣaaju isin wọnyi si imọlẹ naa ni a fihan lọna ti o daju nigba ti Jesu jí Lasaru dide. Si ẹnikan ti o bẹru Ọlọrun, iru iṣe bẹẹ yoo ti jẹ ami pe Jesu ní itilẹhin Jehofa. Bi o ti wu ki o ri, awọn aṣaaju isin le rí kiki ihalẹmọ ti o ṣeeṣe si ipo alanfaani wọn. Wọn wipe: “Ki ni awa nṣe? Nitori ọkunrin yii nṣe ọpọlọpọ iṣẹ ami. Bi awa ba jọwọ rẹ bẹẹ, gbogbo eniyan ni yoo gba a gbọ: awọn ara Roomu yoo si wá gba ilẹ ati orilẹ-ede wa pẹlu.” (Johanu 11:44, 47, 48) Nitori naa wọn forikori lati pa Jesu ati Lasaru boya wọn nireti lati fẹ́ imọlẹ naa pa ni ọna yii.—Johanu 11:53, 54; 12:9, 10.

7 Fun idi yii, awọn aṣaaju isin orilẹ-ede Ọlọrun wọnni ni a ti lé sẹhin kuro nibi imọlẹ naa nipasẹ irera, igberaga, imoye aiṣootọ, ati ire ara-ẹni ti o bori wọn. Siha opin iṣẹ-ojiṣẹ rẹ, Jesu tudii aṣiiri ẹbi wọn, ni wiwipe: “Egbe ni fun yin, ẹyin akọwe ati Farisi, agabagebe; nitori ti ẹyin sé ijọba ọrun mọ́ awọn eniyan: nitori ẹyin tikaarayin kò wọle bẹẹ ni ẹyin ko jẹ ki awọn ti nwọle ki o wọle.”—Matiu 23:13.

Imọtara-ẹni-nikan ati Igberaga

8. Awọn iṣẹlẹ wo ni Nasarẹti ni o tudii aṣiiri ipo ọkan buburu awọn eniyan kan nibẹ?

8 Ni gbogbogboo, awọn eniyan Juu ti ọgọrun un ọdun kìn-ínní jọ awọn aṣaaju isin wọn ni ṣiṣa imọlẹ naa tì nitori ọna ironu ọkan buburu. Fun apẹẹrẹ, ni akoko kan Jesu ni a kesi lati sọrọ ninu sinagọgu kan ni Nasarẹti. Oun kà o si ṣalaye ayọka kan lati inu Aisaya, lakọọkọ, ijọ naa fetisilẹ si i. Ṣugbọn nigba ti oun fa awọn afiwe inu itan yọ ti o tudii aṣiiri imọtara-ẹni-nikan ati ainigbagbọ wọn, inu bí wọn gidigidi wọn si gbiyanju lati pá a. (Luuku 4:16-30) Igberaga, laaarin awọn iwa buburu miiran, dí wọn lọwọ lati ma dahun pada lọna titọ si imọlẹ naa.

9. Bawo ni a ṣe tudii aṣiiri awọn isunniṣe odi ti awujọ nla awọn ara Galili kan?

9 Ni akoko miiran, Jesu bọ́ ogunlọgọ nla lẹba Okun Galili lọna iyanu. Awọn ẹlẹrii iṣẹ iyanu yii wipe: “Loootọ eyi ni wolii naa ti nbọwa aye.” (Johanu 6:10-14) Nigba ti Jesu wọ ọkọ oju omi lọ si ọgangan ibomiran, ogunlọgọ naa tẹle e. Bi o ti wu ki o ri, Jesu mọ pe isunniṣe ọpọlọpọ kii ṣe ifẹ fun imọlẹ. O sọ fun wọn pe: “Ẹyin nwa mi, kii ṣe nitori ti ẹyin rí iṣẹ ami, ṣugbọn nitori ẹyin jẹ ìṣù akara wọnni, ẹyin sì yó.” (Johanu 6:26) Ọrọ rẹ jasi otitọ laipẹ nigba ti ọpọlọpọ ti o ti ntọ ọ lẹhin yipada si aye. (Johanu 6:66) Ẹmi ironu, “ki lere temi?” ti ó jẹ́ ti onimọtara-ẹni-nikan dí imọlẹ naa loju.

10. Bawo ni ọpọjulọ awọn Keferi ṣe huwa pada si imọlẹ naa?

10 Lẹhin iku ati ajinde Jesu, awọn Juu ti wọn gbagbọ nbaa lọ lati gbe imọlẹ naa lọ sọdọ awujọ awọn Juu miiran, ṣugbọn iwọnba diẹ ni o dahun pada. Nitori naa, apọsiteli Pọọlu ati awọn miiran, ti wọn nṣiṣẹsin gẹgẹ bi “imọlẹ awọn orilẹ-ede,” tan ihinrere naa kálẹ̀ dé awọn ilẹ miiran (Iṣe 13:44-47, NW) Ọpọlọpọ awọn ti kii ṣe Juu dahun pada, ṣugbọn iṣarasihuwa gbogbogboo wa jẹ gẹgẹ bi Pọọlu ti ṣapejuwe rẹ̀ pe: “Awa nwaasu Kristi ti a kan mọgi, . . . [ihin-iṣẹ kan ti o jẹ] iwa omugọ fun awọn orilẹ-ede.” (1 Kọrinti 1:22, 23, NW) Ọpọjulọ awọn ti kii ṣe Juu ṣá imọlẹ naa tì nitori pe awọn igbagbọ ninu ohun asan tabi awọn ẹkọ ìmọ̀ ọ̀ràn aye fọ́ wọn loju.—Iṣe 14:8-13; 17:32; 19:23-28.

‘A Pè Wọn Jade Kuro Ninu Okunkun’

11, 12. Awọn wo ni wọn dahun pada si imọlẹ naa ni ọgọrun un ọdun kìn-ínní, awọn wo ni wọn si ndahun pada lonii?

11 Ni ọgọrun un ọdun kìn-ínní, laika aidahunpada gbogbogboo sí, ọpọlọpọ awọn ọlọkan rere ni ‘a pè jade kuro ninu okunkun sinu imọlẹ agbayanu Ọlọrun.’ (1 Peteru 2:9) Nipa awọn wọnyi apọsiteli Johanu kọwe pe: “Iye awọn ti o gba [Kristi], awọn ni o fi agbara fun lati di ọmọ Ọlọrun, ani awọn naa ti o gba orukọ rẹ gbọ́.” (Johanu 1:12) Bẹrẹ lati Pẹntikọsi 33 C.E., awọn olufẹ imọlẹ wọnyi ni a baptisi pẹlu ẹmi mimọ wọn si di awọn ọmọkunrin Ọlọrun pẹlu ireti jijọba pẹlu Jesu ninu Ijọba rẹ ọrun.

12 Ni ọjọ wa awọn ẹni ikẹhin ninu awọn ọmọkunrin ẹni ami ororo Ọlọrun wọnyẹn ni a ti kojọpọ, ati ni mimu asọtẹlẹ Daniẹli ṣẹ, wọn “tan bi imọlẹ ofuurufu . . . : nyi ọpọlọpọ pada si ododo,” (Daniẹli 12:3) Wọn ti jẹ ki imọlẹ wọn tan de iru iwọn ti o pọ tobẹẹ debi pe iye ti o ju million mẹrin “awọn agutan miiran” ni a ti fà sunmọ otitọ ti wọn si ngbadun iduro ododo niwaju Ọlọrun. (Johanu 10:16) Awọn wọnyi, ni tiwọn, ngbe imọlẹ naa yọ yika aye, debi pe nisinsinyi imọlẹ yẹn ntan ju ti igbakigba ri lọ. Ni ọjọ wa, gẹgẹ bi o ti ri ni ọgọrun un ọdun kìn-ínní, “okunkun naa ko bori [imọlẹ naa].”—Johanu 1:5.

‘Ko si Okunkun Pẹlu Ọlọrun’

13. Ikilọ wo ni apọsiteli Johanu fifun wa?

13 Bi o ti wu ki o ri, awa ko nilati gbagbe ikilọ apọsiteli Johanu pe: “Ọlọrun jẹ imọlẹ ko sì sí okunkun rara ni irẹpọ pẹlu rẹ. Bi awa ba sọ gbolohun ọrọ naa: ‘Awa ni ajọpin pẹlu rẹ,’ sibẹ ti a ṣì nbaa lọ ni ririn ninu okunkun, awa npurọ awa ko si sọ otitọ di aṣa.” (1 Johanu 1:5, 6, NW) Ni kedere, o ṣeeṣe fun awọn Kristẹni lati ṣubu sinu ikẹkun kan naa gẹgẹ bi awọn Juu, nigba ti wọn jẹ ẹlẹrii ajorukọ lasan fun Ọlọrun, ati lati ṣe awọn iṣẹ okunkun.

14, 15. Awọn iṣẹ okunkun wo ni o fi ara wọn han sode ninu ijọ Kristẹni ọgọrun un ọdun kìn-ínní, ki ni a si kẹkọọ lati inu eyi?

14 Nitootọ, eyi ṣẹlẹ ni ọgọrun un ọdun kìn-ínní. A kà nipa awọn iyapa wiwuwo ni Kọrinti (1 Kọrinti 1:10-17) Apọsiteli Johanu nilati kilọ fun awọn Kristẹni ẹni ami ororo lati maṣe koriira araawọn ẹnikinni keji, Jakọbu sì gba awọn kan nimọran lati maṣe ṣojurere si awọn ọlọrọ ju awọn otoṣi lọ. (Jakọbu 2:2-4; 1 Johanu 2:9, 10; 3 Johanu 11, 12) Ni afikun, nigba ti Jesu bẹ awọn ijọ meje ti Asia Kekere wò gẹgẹ bi a ti ṣakọsilẹ rẹ ninu iwe Iṣipaya, oun rohin iyọwọle awọn iṣẹ okunkun papọ pẹlu ipẹhinda, ibọriṣa, iwa palapala, ati ifẹ ọrọ alumọni. (Iṣipaya 2:4, 14, 15, 20-23; 3:1, 15-17) Ni awọn ọjọ ijimiji wọnni ti ijọ Kristẹni, ọpọlọpọ ni o ti tipa bayii pa imọlẹ naa tì, ti a yọ awọn kan lẹgbẹ ti awọn miiran wulẹ ńsúlọ sinu “okunkun lode.”—Matiu 25:30; Filipi 3:18; Heberu 2:1; 2 Johanu 8-11.

15 Gbogbo awọn irohin wọnyi lati ọgọrun un ọdun kìn-ínní fi oriṣiriṣi awọn ọna ti okunkun aye Satani le gbà yọ́ wọ inu ironu awọn Kristẹni kọọkan tabi odidi ijọ paapaa han. A gbọdọ wà lojufo ki iru nǹkan bẹẹ maṣe ṣẹlẹ si wa lae. Bawo ni awa ṣe le ṣe iyẹn?

Animọ Iwa Titun

16. Imọran yiyekooro wo ni Pọọlu fifun awọn ara Efesu?

16 Pọọlu rọ awọn ara Efesu lati maṣe jẹ ki “ero inu wọn wà ninu okunkun ki a sì sọ wọn dajeji si igbesi-aye ti o jẹ ti Ọlọrun” mọ́. Ki wọn ma baa yọ́ pada sinu okunkun yẹn, wọn nilati mu awọn ironu ọkan ti o jẹ ti imọlẹ dagba. Pọọlu wipe: “Ẹ nilati bọ́ animọ iwa ogbologbo naa silẹ eyi ti o bá ipa-ọna iwa yin ti iṣaaju ṣe deedee ati eyi ti a nsọ dibajẹ gẹgẹ bi awọn ifẹ ọkan itannijẹ rẹ̀; ṣugbọn . . . a nilati sọ yin di titun ninu ipá ti nsun ero inu yin ṣiṣẹ, ẹ si nilati gbe animọ iwa titun naa wọ̀ eyi ti a dá gẹgẹ bi ifẹ inu Ọlọrun ninu ododo tootọ ati iduro ṣinṣin.”—Efesu 4:18, 22-24 NW.

17. Bawo ni awa ṣe le yẹra fun yíyọ̀ tẹ̀rẹ́ pada sinu okunkun lonii?

17 Ni iru ọna kan, nihin in, Pọọlu gbaninimọran iṣẹ abẹ oniyiipada patapata—gige ohun ti o jẹ apakan ara wa tẹlẹ ri danu, animọ iwa ogbologbo wa, ati yiyọnda imudagba odidi ẹmi titun lati ‘sún ero inu wa ṣiṣẹ.’ Oun si nsọrọ kii ṣe si awọn olufifẹhan titun ṣugbọn si awọn Kristẹni ti wọn ti baptisi. Yiyi animọ iwa wa pada ko duro nigba iribọmi. O jẹ ọna iṣe kan ti nbaa lọ. Bi a ba dawọ mimu animọ iwa titun dagba, ti ogbologboo ni o ṣeeṣe ki o tun yọju, pẹlu igberaga, irera, ati imọtara-ẹni-nikan rẹ̀. (Jẹnẹsisi 8:21; Roomu 7:21-25) Eyi le ṣamọna si awọn iṣẹ okunkun.

“Nipa Imọle Lati Ọdọ Rẹ Ni Awa Lè Rí Imọlẹ”

18, 19. Bawo ni Jesu ati Pọọlu ṣe ṣapejuwe ọna ti a o gba mọ “awọn ọmọ imọlẹ”?

18 Ranti pe mimu ki ọwọ wa tẹ iye ayeraye sinmi lori riri idajọ olojurere gba lati ọdọ Ọlọrun, idajọ eyi ti a gbekari bi a ṣe nifẹẹ imọlẹ tó. Lẹhin sisọrọ bá otitọ ti o kẹhin yii, Jesu wipe: “Ẹni ti o ba huwa buburu nii korira imọlẹ, kii si wa si imọlẹ, ki a maṣe bá iṣẹ rẹ̀ wí. Ṣugbọn ẹni ti o ba nṣe otitọ nii wa si imọlẹ, ki iṣẹ rẹ ki o le fi ara han, pe a ṣe wọn nipa ti Ọlọrun.”—Johanu 3:19-21.

19 Pọọlu kín ironu yii lẹhin nigba ti o kọwe si awọn ara Efesu pe: “Ẹ maa rin gẹgẹ bi awọn ọmọ imọlẹ: (nitori eso ẹmi wà niti iṣoore gbogbo, ati ododo, ati otitọ.)” (Efesu 5:8, 9) Nitori naa awọn iṣẹ wa fihan yala awa jẹ ọmọ imọlẹ tabi ti okunkun. Ṣugbọn awọn iṣẹ títọ́ le jade kiki lati inu ọkan rere. Idi niyii ti a fi nilati maa ṣọ ọkan wa, ki a jẹ ki aini fun sisọ animọ iwa wa di titun maa jẹ wá lọkan leralera, ki a ṣora nipa ẹmi ti ńsún ero inu wa ṣiṣẹ.—Owe 4:23.

20, 21. (a) Ipenija akanṣe wo ni awọn ọmọ ti a bi sinu idile Kristẹni dojukọ? (b) Ipenija wo ni o dojukọ gbogbo awọn ọmọ Kristẹni obi?

20 Ninu awọn ọran kan, eyi ti jasi ipenija akanṣe kan fun awọn ọmọ ti Ẹlẹrii oluyasimimọ fun Jehofa bí. Eeṣe? O dara, ni ọwọ kan, iru awọn ọmọ bẹẹ gbadun ibukun agbayanu. Mimọ otitọ lati igba ọmọ ọwọ patapata tumọ nitootọ si, pe ẹnikan ko nilati niriiri wiwa ninu okunkun aye Satani bi o ṣe ri gan an lae. (2 Timoti 3:14, 15) Ni ọwọ keji ẹwẹ, awọn ọmọ kan ninu ipo yii foju tẹmbẹlu otitọ wọn kò si fi tootọtootọ kọ́ lati nifẹẹ imọlẹ naa lae. Bayi ni ọran rí pẹlu ọpọjulọ awọn Juu ọgọrun un ọdun kìn-ínní. Wọn dagba ni orilẹ-ede ti a yà si mimọ fun Jehofa, ati dé iwọn kan wọn ni imọ otitọ. Ṣugbọn ko si ninu ọkan wọn.—Matiu 15:8, 9.

21 Awọn Kristẹni obi ni ẹru iṣẹ niwaju Ọlọrun lati tọ́ ọmọ wọn dagba ninu imọlẹ. (Deutaronomi 6:4-9; Efesu 6:4) Bi o ti wu ki o ri, ni opin rẹ, ọmọ naa funraarẹ nilati wá nifẹẹ imọlẹ ju okunkun lọ. Oun nilati sọ imọlẹ otitọ naa di tirẹ funraarẹ. Gẹgẹ bi oun ti ndagba, awọn apa ẹka aye Satani le jọ bi eyi ti o fanimọra. Awọn aṣa igbesi-aye alaibikita tabi aláìmẹrù iṣẹ niṣẹ ti awọn ojugba rẹ le dabi eyi ti o gbadunmọni. Ẹmi ti a fi nkọni ni ile-ẹkọ le fanilọkanmọra. Ṣugbọn oun ko nilati gbagbe lae pe lẹhin ode imọlẹ, ‘okunkun bo ilẹ-aye.’ (Aisaya 60:2) Asẹhinwa asẹhinbọ, aye ti a sọ dokunkun patapata yii ko ni ohun rere kan lati fifunni.—1 Johanu 2:15-17.

22. Bawo ni Jehofa ṣe nbukun awọn wọnni ti wọn wa sinu imọlẹ nisinsinyi, bawo ni oun yoo si ṣe bukun wọn ni ọjọ ọla?

22 Ọba Dafidi kọwe pe: “Pẹlu rẹ [Jehofa] ni orisun iye; nipa imọlẹ lati ọdọ rẹ [ni] awa le rí imọlẹ. Maa bá iṣeun-ifẹ rẹ lọ pẹlu awọn wọnni ti ńmọ̀ ọ́.” (Saamu 36:9, 10, NW) Awọn wọnni ti wọn nifẹẹ imọlẹ wá lati mọ Jehofa, eyi si le tumọsi iye fun wọn. (Johanu 17:3) Ninu iṣeun-ifẹ rẹ̀, Jehofa tì wọn lẹhin nisinsinyi, ati nigba ti ipọnju nla ba bẹ́ silẹ, oun yoo gbe wọn kọja sinu aye titun kan. Eyi le jẹ iriri wa bi awa ba ṣá okunkun aye Satani tì. Ninu aye titun naa, araye ni a o mu padabọsipo si igbesi-aye pipe ninu Paradise. (Iṣipaya 21:3-5) Awọn wọnni ti wọn gba idajọ olojurere nigba naa yoo ni ireti gbigbadun ninu imọlẹ Jehofa fun gbogbo sanmani si nbọ. Iru ifojusọna ologo wo ni eyi jẹ! Ẹ si wo iru isunniṣe alagbara ti ó jẹ́ nisinsinyi lati “bọ awọn iṣẹ tii ṣe ti okunkun silẹ ki [a] sì . . . gbé awọn ohun ija imọlẹ wọ̀”!—Roomu 13:12, NW.

Iwọ Ha Ranti Bi?

◻ Eeṣe ti ọpọjulọ awọn Juu ni ọjọ Jesu ṣe ṣá imọlẹ naa tì?

◻ De iwọn wo ni imọlẹ ti ntan ni awọn akoko ode oni?

◻ Awọn ikilọ wo nipa imọtara-ẹni-nikan ati igberaga ni awọn apẹẹrẹ ọgọrun un ọdun kìn-ínní pese?

◻ Ki ni ó pọndandan bi awa ba nilati maa wà niṣo ninu imọlẹ?

◻ Awọn ibukun wo ni o wà ni ipamọ fun awọn olufẹ imọlẹ?

[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 15]

Ọpọjulọ awọn Juu ni ọjọ Jesu kò dahun pada si imọlẹ naa

[Àwọn àwòrán tó wà ní ojú ìwé 17]

La ọpọ ẹ̀wádún já oniruuru awọn ọna ni a ti lo lati jẹ ki imọlẹ tan ninu sisọni di ọmọ-ẹhin

[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 18]

“Ẹ nilati bọ́ animọ iwa ogbologboo naa silẹ . . . ẹ si nilati gbé animọ iwa titun wọ̀”

    Yorùbá Publications (1987-2025)
    Jáde
    Wọlé
    • Yorùbá
    • Fi Ráńṣẹ́
    • Èyí tí mo fẹ́ràn jù
    • Copyright © 2025 Watch Tower Bible and Tract Society of Pennsylvania
    • Àdéhùn Nípa Lílò
    • Òfin
    • Ètò Nípa Ìsọfúnni Rẹ
    • JW.ORG
    • Wọlé
    Fi Ráńṣẹ́