Awọn Wo ni Wọn Ń Tẹle Ìmọ́lẹ̀ Ayé?
“Ẹyin ń tàn bi awọn afúnni ní ìmọ́lẹ̀ ninu ayé.”—FILIPPI 2:15, NW.
1. Ki ni Bibeli sọ nipa awọn ìmọ́lẹ̀ ayédèrú isin?
BIBELI fi Jesu hàn yatọ ni kedere gẹgẹ bi “ìmọ́lẹ̀ ńlá,” “ìmọ́lẹ̀ ayé.” (Isaiah 9:2; Johannu 8:12) Sibẹ, awọn diẹ ni ifiwera ni wọn tẹle e nigba ti o wà lori ilẹ̀-ayé. Ẹgbaagbeje yàn lati tẹle awọn ayederu ìmọ́lẹ̀ ti wọn jẹ, ẹni okunkun niti gidi. Nipa awọn wọnyi ni Ọ̀rọ̀ Ọlọrun sọ pe: “Nitori iru awọn eniyan bẹẹ ni awọn èké Aposteli, awọn ẹni ti ń ṣiṣẹ ẹ̀tàn, ti ń pa araawọn dà di Aposteli Kristi. Kìí sìí ṣe ohun iyanu; nitori Satani tikaraarẹ ń pa araarẹ̀ dà di angẹli ìmọ́lẹ̀. Nitori naa kìí ṣe ohun ńlá bi awọn iranṣẹ rẹ̀ pẹlu bá pa araawọn dà bi awọn iranṣẹ òdodo; igbẹhin awọn ẹni ti yoo rí gẹgẹ bi iṣẹ wọn.”—2 Korinti 11:13-15.
2. Ki ni Jesu sọ pe yoo jẹ́ ipilẹ fun ṣiṣedajọ awọn eniyan?
2 Nipa bayii, kìí ṣe gbogbo eniyan ni o fẹ ìmọ́lẹ̀, bi o ti jẹ agbayanu tó nì. Jesu sọ pe: “Eyi ni idajọ naa pe, ìmọ́lẹ̀ wá si ayé, awọn eniyan sì fẹ́ okunkun ju ìmọ́lẹ̀ lọ, nitori ti iṣẹ wọn buru. Nitori olukuluku ẹni ti o bá huwa buburu nii koriira ìmọ́lẹ̀, kìí sìí wá si ìmọ́lẹ̀, ki a maṣe bá iṣẹ rẹ̀ wí.”—Johannu 3:19, 20.
Awọn Olufẹ Okunkun
3, 4. Bawo ni awọn olori isin ni ọjọ Jesu ṣe fihàn pe awọn kò fẹ́ lati tẹle ìmọ́lẹ̀?
3 Gbé bi iyẹn ṣe jẹ́ ọ̀ràn naa nigba ti Jesu wà lori ilẹ̀-ayé yẹwo. Ọlọrun ti fun Jesu lagbara lati ṣe awọn iṣẹ iyanu arunilọkan soke gẹgẹ bi ọ̀nà kan lati fidi rẹ̀ mulẹ pe oun ni Messia naa. Fun apẹẹrẹ, ni Ọjọ́-ìsinmi kan, ó la oju ọkunrin kan ti a bí ni afọju. Ẹ wo iru iṣẹ aanu oniyanu ti eyi jẹ́! Ẹ wo bi ọkunrin naa ti kun fun imọriri tó! Oun lè ríran fun ìgbà akọkọ gan-an! Bi o ti wu ki o ri, ki ni ihuwapada awọn olori isin? Johannu 9:16 ṣalaye pe: “Nitori naa awọn kan ninu awọn Farisi wi [nipa Jesu] pe, Ọkunrin yii kò ti ọ̀dọ̀ Ọlọrun wá, nitori ti kò pa ọjọ́-ìsinmi mọ́.” Ẹ wo bi ọkàn wọn ti gbòdì tó! Nihin-in iṣẹ iwosan iyanu kan ti ṣẹlẹ, ṣugbọn dipo fifi ayọ hàn nitori ọkunrin afọju tẹlẹri naa ati fifi imọriri hàn fun oniwosan naa, wọn dá Jesu lẹbi! Nipa ṣiṣe bẹẹ, laiṣiyemeji wọn ṣẹ si ìfihàn ẹmi mimọ Ọlọrun, ẹṣẹ kan ti kò ni idariji.—Matteu 12:31, 32.
4 Lẹhin naa, nigba ti awọn alarekereke wọnyẹn beere lọwọ ọkunrin afọju tẹlẹri naa nipa Jesu, ọkunrin naa sọ pe: “Ohun iyanu ṣá ni eyi, pe, ẹyin kò mọ ibi ti ó [Jesu] gbé ti wá, ṣugbọn oun ṣá ti là mi loju. Awa mọ̀ pe, Ọlọrun kìí gbọ́ ti ẹlẹṣẹ: ṣugbọn bi ẹnikan bá ṣe olufọkansin si Ọlọrun, ti ó bá sì ń ṣe ifẹ rẹ̀, oun nii gbọ́ tirẹ̀. Lati ìgbà ti ayé ti ṣẹ̀, a kò tii gbọ́ pe, ẹnikan la oju ẹni ti a bí ni afọju rí. Ìbáṣe pe ọkunrin yii [Jesu] kò ti ọ̀dọ̀ Ọlọrun wa, kì bá ti lè ṣe ohunkohun.” Bawo ni awọn aṣaaju isin naa ṣe dahunpada? “Wọn sì dahun wi fun un pe, Ninu ẹṣẹ ni a bí iwọ patapata, iwọ sì ń kọ́ wa bi? Wọn sì tì í sode.” Ẹ wo bi wọn ṣe jẹ́ aláìníyọ̀ọ́nú tó! Wọn jẹ́ ọlọ́kàn okuta. Nitori naa Jesu sọ fun wọn pe nigba ti wọn lè fi oju ti ara ìyára wọn ríran, wọn jẹ́ afọju nipa tẹmi.—Johannu 9:30-41.
5, 6. Ki ni awọn olori isin ọrundun kin-in-ni ṣe lati fihàn pe awọn nifẹẹ okunkun?
5 Pe awọn alareekereke-isin wọnyi ń ṣẹ̀ si ẹmi Ọlọrun ni a ti rí ná ni akoko iṣẹlẹ miiran, nigba ti Jesu jí Lasaru dide kuro ninu oku. Nitori iṣẹ iyanu yẹn, ọpọlọpọ ninu awọn eniyan gbáàtúù fi igbagbọ hàn ninu Jesu. Bi o ti wu ki o ri, ṣakiyesi ohun ti awọn olori isin ṣe. “Nigba naa ni awọn olori alufaa ati awọn Farisi pe igbimọ jọ, wọn sì wi pe, Ki ni awa ń ṣe? Nitori ọkunrin yii ń ṣe ọpọlọpọ iṣẹ àmì. Bi awa bá jọ̀wọ́ rẹ̀ bẹẹ, gbogbo eniyan ni yoo gbà á gbọ́: awọn ara Romu yoo sì wá gba ilẹ ati orilẹ-ede wa pẹlu.” (Johannu 11:47, 48) Wọn ṣaniyan nipa ipo ati ijamọpataki wọn. Ni gbogbo ọ̀nà wọn fẹ́ lati tẹ́ awọn ara Romu lọ́rùn, kìí ṣe Ọlọrun. Nitori naa, ki ni ohun ti wọn ṣe? “Nitori naa lati ọjọ naa lọ ni wọn ti jọ gbìmọ̀pọ̀ lati pa [Jesu].”—Johannu 11:53.
6 Gbogbo rẹ̀ ha niyẹn bi? Bẹẹkọ. Ohun ti wọn ṣe tẹle e fi bi wọn ṣe ni ifẹ okunkun tó hàn: “Ṣugbọn awọn olori alufaa gbimọ ki wọn lè pa Lasaru pẹlu; nitori pe nipasẹ rẹ̀ ni ọpọ ninu awọn Ju jade lọ, wọn sì gba Jesu gbọ́.” (Johannu 12:10, 11) Ẹ wo bi o ṣe jẹ iwa buburu alaiṣeegbagbọ tó! Bi o tilẹ jẹ pe wọn ṣe gbogbo eyi lati daabobo ipo wọn, ki ni o ṣẹlẹ? Ninu iran yẹn gan-an, wọn ṣọtẹ lodisi awọn ara Romu, awọn ti o dide lodisi wọn ni 70 C.E. ti wọn sì gba ipo wọn, orilẹ-ede wọn, ati iwalaaye wọn pẹlu!—Isaiah 5:20; Luku 19:41-44.
Ìyọ́nú Jesu
7. Eeṣe ti awọn olufẹ otitọ fi rọ́ lọ si ọ̀dọ̀ Jesu?
7 Nitori naa ni akoko wa pẹlu, kìí ṣe gbogbo eniyan ni o fẹ́ ìlàlóye nipa tẹmi. Ṣugbọn awọn wọnni ti wọn nifẹẹ otitọ ń fẹ́ lati wá sọdọ ìmọ́lẹ̀. Wọn fẹ́ Ọlọrun gẹgẹ bi Ọba-alaṣẹ wọn, wọn sì ń fi iharagaga yipada sọdọ Jesu, ẹni ti Ọlọrun ti rán lati ṣalaye ohun ti ìmọ́lẹ̀ jẹ́, wọn sì ń tẹle e. Iyẹn ni ohun ti awọn eniyan onirẹlẹ ṣe nigba ti Jesu wà lori ilẹ̀-ayé. Wọn rọ́ lọ sọdọ rẹ̀. Àní awọn Farisi paapaa nilati gbà pẹlu ìyẹn. Wọn ṣaroye pe: “Ẹ wo bi gbogbo ayé ti ń wọ́ tọ̀ ọ́.” (Johannu 12:19) Awọn ẹni-bi-agutan nifẹẹ Jesu nitori pe oun jẹ́ odikeji awọn olori isin onimọtara-ẹni-nikan, alagidi, ti ebi agbara ń pa awọn ti Jesu sọ nipa wọn pe: “Wọn a di ẹrù wuwo ti o sì ṣoro lati rù, wọn a sì gbé e ka awọn eniyan ni ejika, ṣugbọn awọn tikaraawọn kò jẹ́ fi ìka wọn kan ẹrù naa. Ṣugbọn gbogbo iṣẹ wọn ni wọn ń ṣe nitori ki awọn eniyan ki o baa lè rí wọn.”—Matteu 23:4, 5.
8. Ni iyatọ gédégédé si awọn alagabagebe isin, iṣarasihuwa wo ni Jesu ní?
8 Ni iyatọ gédégédé, ṣakiyesi iṣarasihuwa oníyọ̀ọ́nú ti Jesu: “Ṣugbọn nigba ti ó rí ọpọ eniyan, àánú wọn ṣe é, nitori ti àárẹ̀ mú wọn, wọ́n sì tú kaakiri bi awọn agutan ti kò ni oluṣọ.” (Matteu 9:36) Ki ni ó sì ṣe nipa rẹ̀? Ó sọ fun awọn wọnni tí eto-igbekalẹ Satani ti kó nífà pe: “Ẹ wá sọdọ mi gbogbo ẹyin ti ń ṣíṣẹ̀ẹ́, ti a sì di ẹrù wuwo lé lori, emi ó sì fi isinmi fun yin. Ẹ gba àjàgà mi si ọrùn yin, ki ẹ sì maa kọ́ ẹkọ lọdọ mi; nitori oninututu ati onirẹlẹ-ọkan ni emi; ẹyin ó sì rí isinmi fun ọkàn yin. Nitori àjàgà mi rọrùn, ẹrù mi sì fuyẹ.” (Matteu 11:28-30) Jesu ṣe ohun ti a sọtẹlẹ nipa rẹ̀ ninu Isaiah 61:1, 2, eyi tí ó kà pe: “Ó ti fi àmì ororo yàn mi lati waasu ihinrere fun awọn òtòṣì; ó ti rán mi lati ṣe àwòtán awọn onirobinujẹ-ọkan, lati kede idasilẹ fun awọn igbekun, ati iṣisilẹ tubu fun awọn onde. Lati kede ọdun itẹwọgba Oluwa, ati ọjọ ẹsan Ọlọrun wa; lati tu gbogbo awọn ti ń gbààwẹ̀ ninu.”
Kíkó Awọn Olùtan Ìmọ́lẹ̀ Jọ
9. Iṣẹlẹ ti o ni ijẹpataki wo ni o ṣẹlẹ ni 1914?
9 Lẹhin igoke re ọrun rẹ̀, Jesu ni ó nilati duro titi di akoko ti Ọlọrun yoo fun un ni agbara Ijọba. Nigba naa oun yoo ya “agutan” sọtọ kuro lara “ewurẹ.” (Matteu 25:31-33; Orin Dafidi 110:1, 2) Akoko yẹn dé nigba ti “ikẹhin ọjọ” bẹrẹ ni 1914. (2 Timoteu 3:1-5) Jesu, ti a ti fi agbara fun gẹgẹ bi Ọba Ijọba ọrun ti Ọlọrun, bẹrẹ síí kó awọn wọnni ti wọn fẹ́ lati tẹle ìmọ́lẹ̀ jọ si ọwọ́ ọ̀tún ojurere rẹ̀. Lẹhin Ogun Agbaye I, iṣẹ ikojọ naa tẹsiwaju pẹlu agbara itẹsiwaju ti ń roke sii.
10. Ibeere wo ni a lè beere nipa awọn wọnni ti Jesu ń lò ninu iṣẹ ikojọ naa?
10 Labẹ idari Kristi Jesu, iṣẹ ikojọpọ naa ni a ti san èrè fun pẹlu aṣeyọri giga. Kò tii sí ìgbà kan rí ninu ìtàn ti ọpọlọpọ eniyan lati gbogbo orilẹ-ede tíì korajọpọ bẹẹ ri ninu ijọsin tootọ ti a fi ìmọ̀ kún. Awọn wo lonii ni wọn sì ń tẹle ìmọ́lẹ̀ ti ń wá lati ọ̀dọ̀ Ọlọrun ati Kristi naa? Awọn wo ni wọn ń ṣe ohun ti Filippi 2:15 sọ, “ń tàn bi awọn afúnni ní ìmọ́lẹ̀ ninu ayé,” ni kikesi awọn miiran lati ‘wa ki wọn sì gba omi ìyè naa lọfẹẹ’?—Ìfihàn 22:17.
11. Ki ni ipo Kristẹndọm ni ibatan pẹlu ìmọ́lẹ̀ tẹmi?
11 Ǹjẹ́ Kristẹndọm ń ṣe iyẹn bi? Kristẹndọm, pẹlu isin rẹ̀ ti o pín yẹlẹyẹlẹ, dajudaju ni kò tàn gẹgẹ bi afúnni ní ìmọ́lẹ̀. Nitootọ, awọn alufaa dabii awọn olori isin ni ọjọ Jesu. Wọn kò fi ìmọ́lẹ̀ tootọ lati ọ̀dọ̀ Ọlọrun ati Kristi hàn. Ni ọdun 33 sẹhin, iwe-irohin naa Theology Today sọ pe: “Pẹlu àbámọ̀ a nilati gba pe ìmọ́lẹ̀ yii kò tàn ninu Ṣọọṣi pẹlu ìmọ́lẹ̀ yòò ti ń gbàfiyèsí. . . . Ṣọọṣi ti ní ìtẹ̀sí lati tubọ dabii ẹgbẹ́ awujọ awọn eniyan eyi ti ó yí i ká. Oun kò fi taratara jẹ́ ìmọ́lẹ̀ ayé dipo bẹẹ ó jẹ́ aṣàgbéyọjáde ìmọ́lẹ̀ tí ń tàn lati inu ayé funraarẹ.” Ipo ọ̀ràn ti Kristẹndọm sì tubọ buru paapaa lonii. Ìmọ́lẹ̀ ti a ń fẹnulasan pe bẹẹ tí ó ń gbéyọ lati ọ̀dọ̀ ayé jẹ́ okunkun niti gidi nitori pe iyẹn ni kìkì ohun ti Satani ati ayé rẹ̀ ní lati fifunni. Bẹẹkọ, kò sí ìmọ́lẹ̀ otitọ kan tí ń jade lati inu awọn isin aforigbari ti o sì jẹ́ ti ayé latokedelẹ ninu Kristẹndọm.
12. Awọn wo ni o parapọ jẹ́ eto-ajọ olùtan ìmọ́lẹ̀ tootọ lonii?
12 A lè fi idaniloju sọ pe awujọ ayé titun ti awọn Ẹlẹ́rìí Jehofa ni eto-ajọ otitọ, ti ń tan ìmọ́lẹ̀ lonii. Ni isopọṣọkan, gbogbo mẹmba rẹ̀—awọn ọkunrin, obinrin, ati awọn ọ̀dọ́ bakan naa pẹlu—ńjẹ́ ki ìmọ́lẹ̀ wọn lati ọ̀dọ̀ Jehofa ati Kristi tàn niwaju gbogbo eniyan. Ni ọdun ti o kọja, ní nǹkan ti ó sunmọ 70,000 ijọ awọn Ẹlẹ́rìí Jehofa kaakiri gbogbo agbaye, ohun ti o ju million mẹrin awọn olùtan ìmọ́lẹ̀ ni wọn ń fi igbekankanṣiṣẹ sọ fun awọn ẹlomiran nipa Ọlọrun ati awọn ète rẹ̀. Ati ni ọdọọdun nisinsinyi, a ń rí ikojọpọ gigadabu ti awọn eniyan ti wọn fẹ́ lati di ẹni ti a làlóye nipa tẹmi pẹlu. Ẹgbẹẹgbẹrun lọna ọgọrọọrun ni a baptisi lẹhin kikẹkọọ Bibeli ati nini ìmọ̀ pipeye nipa otitọ. Loootọ, ifẹ Ọlọrun ni “ki gbogbo eniyan ni igbala ki wọn sì wá sinu ìmọ̀ otitọ.”—1 Timoteu 2:4.
13. Ki ni a lè fi ìmọ́lẹ̀ ti ń wa lati ọ̀dọ̀ Jehofa wé?
13 A lè ṣafiwe ìlàlóye ti ń wá nisinsinyi lati ọ̀dọ̀ Jehofa pẹlu ohun ti o ṣẹlẹ nigba ti awọn eniyan Ọlọrun ti ìgbà atijọ fi Egipti silẹ: “OLUWA sì ń lọ niwaju wọn, ninu ọwọ̀n awọsanma ni ọ̀sán, lati maa ṣe amọna fun wọn; ati ni òru ni ọwọ̀n iná lati maa fi ìmọ́lẹ̀ fun wọn; lati maa rìn ní ọ̀sán ati ni òru.” (Eksodu 13:21, 22) Awọsanma ní ọ̀sán ati iná ní òru lati ọ̀dọ̀ Ọlọrun jẹ́ amọna ti o ṣeegbarale. Wọn ṣeegbarale gẹgẹ bi oòrùn ti Ọlọrun dá lati pese awọn wakati ọ̀sán fun wa. Nitori naa, pẹlu, a lè gbarale Jehofa lati maa baa lọ lati tan ìmọ́lẹ̀ si ọ̀nà nipa tẹmi fun awọn olùwá otitọ ni ọjọ ikẹhin buburu wọnyi. Owe 4:18 mu dá wa loju pe: “Ṣugbọn ipa-ọna awọn oloootọ dabi títàn ìmọ́lẹ̀, ti ó ń tàn siwaju ati siwaju titi di ọ̀sán gangan.”
Gbigbe Ìmọ́lẹ̀ Ijọba Yọ
14. Ki ni ó gbọdọ jẹ́ lajori ète awọn olùtan ìmọ́lẹ̀?
14 Nigba ti Jehofa jẹ́ Orisun ìlàlóye, ti Kristi sì jẹ́ Olori Olùṣàgbéyọ ìmọ́lẹ̀ yẹn, awọn ọmọlẹhin Jesu gbọdọ ṣàgbéyọ rẹ̀ pẹlu. Ó sọ nipa wọn pe: “Ẹyin ni ìmọ́lẹ̀ ayé. . . . Ẹ jẹ ki ìmọ́lẹ̀ yin ki o mọ́lẹ̀ tobẹẹ niwaju eniyan, ki wọn ki o lè maa ri iṣẹ rere yin, ki wọn ki o lè maa yin Baba yin ti ń bẹ ni ọrun logo.” (Matteu 5:14, 16) Ki sì ni lajori ẹṣin-ọrọ ìmọ́lẹ̀ yii ti awọn ọmọlẹhin rẹ̀ nilati jẹ ki ó tàn niwaju awọn eniyan? Ki ni ohun ti wọn nilati kọ́ ni ogogoro-opin ìtàn ayé yii? Jesu kò sọ pe awọn ọmọlẹhin oun yoo waasu ijọba dẹmọ, ijọba boofẹ-bookọ, isopọ Ṣọọṣi ati Ilu, tabi èròǹgbà ti ayé miiran. Kaka bẹẹ, ninu Matteu 24:14 ó sọtẹlẹ pe ni oju atako kari-aye, “a o sì waasu ihinrere ijọba yii ni gbogbo ayé lati ṣe ẹ̀rí fun gbogbo orilẹ-ede; nigba naa ni opin yoo sì dé.” Nipa bayii, awọn olùtan ìmọ́lẹ̀ lonii ń sọ fun awọn ẹlomiran nipa Ijọba Ọlọrun, eyi ti yoo mú ayé Satani wá si opin ti yoo sì mú ayé titun òdodo wọle.—1 Peteru 2:9.
15. Awọn ti wọn fẹ́ ìmọ́lẹ̀ yoo yipada sibo?
15 Awọn ti wọn nifẹẹ ìmọ́lẹ̀ ni a kò ni rọ́ sẹgbẹẹ nipasẹ awọn ijẹwọ ati ilepa ayé yii. Gbogbo ijẹwọ ati ilepa wọnyẹn yoo pòórá laipẹ, niwọn bi ayé yii ti ń sunmọ opin rẹ̀. Kaka bẹẹ, awọn olùfẹ́ òdodo yoo fẹ́ lati yipada si ihinrere ti a ń polongo rẹ̀ lati ẹnu awọn wọnni ti wọn ń jẹ ki ìmọ́lẹ̀ Ijọba Ọlọrun tàn sí awọn igun jijinnarere ori ilẹ̀-ayé. Awọn wọnyi ni a sọ asọtẹlẹ wọn ninu Ìfihàn 7:9, 10, ti o sọ pe: “Lẹhin naa, mo rí, sì kiyesi i, ọpọlọpọ eniyan ti ẹnikẹni kò lè kà, lati inu orilẹ-ede gbogbo, ati ẹ̀yà, ati eniyan, ati lati inu èdè gbogbo wá, wọn duro niwaju ìtẹ́ [ti Ọlọrun], ati niwaju Ọ̀dọ́-Àgùtàn naa [Kristi], . . . wọn sì kigbe ni ohùn rara, wi pe, Igbala ni ti Ọlọrun wa ti o jokoo lori ìtẹ́, ati ti Ọ̀dọ́-Àgùtàn.” Ẹsẹ 14 sọ pe: “Awọn wọnyi ni o jade lati inu ipọnju ńlá.” Bẹẹni, wọn la opin ayé yii já sinu ayé titun alailopin labẹ Ijọba Ọlọrun.
Ayé Titun naa Ti A Fi Ìmọ̀ Kún
16. Ki ni yoo ṣẹlẹ si ayé Satani nigba ipọnju ńlá?
16 Ayé titun naa ni ìmọ́lẹ̀ rokoṣo ti otitọ yoo bò latokedelẹ. Nitootọ, gbé ohun ti ipo ọ̀ràn yoo jẹ́ ni ọjọ naa lẹhin ti Ọlọrun bá mú eto-igbekalẹ awọn nǹkan yii wá si opin rẹ̀ yẹwo. Satani, awọn ẹmi eṣu rẹ̀, ati awọn eto-igbekalẹ oṣelu, ti iṣowo, ati ti isin ni yoo ti lọ láú—gbogbo wọn pata! Gbogbo ohun-eelo igbekeeyide Satani pata ni yoo lọ pẹlu. Nipa bayii, lẹhin ipọnju ńlá, kò tun ni sí iwe agberohinjade, iwe-irohin, iwe, iwe-pẹlẹbẹ, tabi iwe pélébé kankan ti yoo gbé ayé buburu yii larugẹ mọ́. Kò ni si ipá asọnidibajẹ ti a ń gbejade lati inu ile-iṣẹ tẹlifiṣọn tabi redio ayé mọ́. Gbogbo ayika onimajele ti ayé Satani ni a o palẹ rẹ̀ mọ́ pẹlu ikọlu alagbara kanṣoṣo!—Matteu 24:21; Ìfihàn 7:14; 16:14-16; 19:11-21.
17, 18. Bawo ni iwọ yoo ṣe ṣapejuwe ayika tẹmi lẹhin opin ayé Satani?
17 Ẹ wo iru itura pupọ jaburata ti iyẹn yoo jẹ́! Lati ọjọ yẹn lọ, kìkì ìmọ́lẹ̀ gbigbamuṣe, ti ń gbeniro nipa tẹmi ti ó wá lati ọ̀dọ̀ Jehofa ati Ijọba rẹ̀ ni yoo nipa lori iran eniyan. Isaiah 54:13 sọtẹlẹ pe: “A o sì kọ́ gbogbo awọn ọmọ rẹ lati ọ̀dọ̀ Oluwa wá; alaafia awọn ọmọ rẹ yoo sì pọ̀.” Pẹlu ifẹ Ọlọrun ti o ń jẹgaba lori gbogbo ilẹ̀-ayé, ileri rẹ̀ ni pe, gẹgẹ bi Isaiah 26:9 ṣe sọ, “awọn ti ń bẹ ni ayé yoo kọ́ òdodo.”
18 Lọ́gán, gbogbo ayika ti ero-ori ati tẹmi yoo yipada si rere. Awọn nǹkan ti ń gbeniro yoo jẹ́ iṣẹlẹ ojoojumọ dipo awọn nǹkan akinimọlẹ, oniwa-palapala ti ó gbodekan nisinsinyi tobẹẹ. Gbogbo ẹni ti ń gbé nigba naa ni a o kọ́ ni otitọ nipa Ọlọrun ati awọn ète rẹ̀. Ni paripari opin rẹ̀, asọtẹlẹ inu Isaiah 11:9 ni a o muṣẹ, ti o sọ wi pe: “Ayé yoo kun fun ìmọ̀ Oluwa gẹgẹ bi omi ti bo òkun.”
Ó Jẹ́ Kanjukanju Lati Tẹle Ìmọ́lẹ̀ Naa
19, 20. Eeṣe ti awọn wọnni ti wọn ń fẹ lati tẹle ìmọ́lẹ̀ ṣe nilati ṣọra?
19 Nisinsinyi, ni awọn ọjọ ikẹhin eto-igbekalẹ buburu yii, ó jẹ́ kanjukanju lati tẹle ìmọ́lẹ̀ ayé. A sì nilati ṣọra, nitori pe ogun kikankikan kan wà ti a ń jà lati dá wa duro kuro ninu rírìn ninu ìmọ́lẹ̀. Atako yii ń wá lati inu agbara okunkun—lati ọ̀dọ̀ Satani, awọn ẹmi eṣu rẹ̀, ati eto-ajọ ori ilẹ̀-ayé rẹ̀. Idi niyii ti aposteli Peteru fi kilọ pe: “Ẹ maa wà ni airekọja, ẹ maa ṣọra; nitori Eṣu, ọ̀tá yin, bii kinniun ti ń ké ramuramu, ó ń rìn kaakiri, ó ń wá ẹni ti yoo pajẹ kiri.”—1 Peteru 5:8.
20 Satani yoo fi gbogbo idena si oju-ọna awọn wọnni ti wọn bá ìmọ́lẹ̀ pade, nitori pe oun fẹ́ lati mú ki wọn maa baa lọ ninu okunkun. Ó lè jẹ́ ikimọlẹ lati ọ̀dọ̀ awọn ibatan tabi awọn ọ̀rẹ́ tẹlẹri ti wọn tako otitọ. Ó lè jẹ́ iyemeji nipa Bibeli nitori jijẹ ẹni ti a ti fọ́ lójú nipasẹ awọn ẹkọ isin èké tabi igbekeeyide awọn alaigbọlọrungbọ ati awọn onígbàgbọ́ Ọlọ́run-kò-ṣeémọ̀ ti wọn jẹ́ aláìṣeégbáralé. Ó lè jẹ́ itẹsi ẹṣẹ ti ẹnikan funraarẹ ni ó mú ki o ṣoro fun un lati gbé ni ibamu pẹlu ohun abeerefun atọrunwa.
21. Igbesẹ wo ni gbogbo awọn ti wọn fẹ lati gbé ninu ayé titun Ọlọrun nilati gbé?
21 Ohun yoowu ki awọn idena naa jẹ́, iwọ ha fẹ lati gbadun iwalaaye ninu ayé titun kan ti o bọ́ lọwọ ipo òṣì, iwa-ọdaran, aiṣedajọ-ododo, ati ogun bi? Iwọ ha fẹ́ lati gbadun ilera pipe ati ìyè ayeraye ninu paradise ilẹ̀-ayé bi? Nigba naa tẹwọgba Jesu ki o sì tẹle e gẹgẹ bi ìmọ́lẹ̀ ayé ki o sì tẹtisilẹ si ihin-iṣẹ awọn wọnni ti wọn ń dirọ mọ “ọ̀rọ̀ ìyè” ti wọn sì “ń tàn bi awọn afúnni ni ìmọ́lẹ̀ ninu ayé.”—Filippi 2:15, 16, NW.
Bawo ni Iwọ Yoo Ṣe Dahun?
◻ Bawo ni awọn aṣaaju isin ṣe fihàn pe awọn jẹ́ olufẹ okunkun?
◻ Iṣarasihuwa wo ni Jesu ni si awọn eniyan?
◻ Bawo ni ikojọpọ awọn olùtan ìmọ́lẹ̀ ṣe ń tẹsiwaju?
◻ Awọn iṣẹlẹ ti o ṣe pataki wo ni yoo ṣẹlẹ laipẹ?
◻ Eeṣe ti o fi jẹ́ kanjukanju lati tẹle ìmọ́lẹ̀ ayé naa lonii?
[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 14, 15]
Awọn Farisi ọlọkan líle ti ọkunrin ti Jesu la oju rẹ̀ jade