Awọn Olùtan Ìmọ́lẹ̀—Fun Ète Wo?
“Mo ti gbe ọ kalẹ fun ìmọ́lẹ̀ awọn [orilẹ-ede, NW].”—IṢE 13:47.
1. Bawo ni àṣẹ ti a tọka si ni Iṣe 13:47 ṣe nipa lori aposteli Paulu?
“OLUWA sá ti paṣẹ fun wa pe, Mo ti gbe ọ kalẹ fun ìmọ́lẹ̀ awọn [orilẹ-ede, NW], ki iwọ ki o lè jẹ fun igbala titi de opin ayé,” ni aposteli Paulu wi. (Iṣe 13:47) Kìí ṣe pe oun sọ iyẹn nikan ni ṣugbọn oun tun mọ ijẹpataki rẹ̀ dunju. Lẹhin dídi Kristian kan, Paulu ya igbesi-aye rẹ̀ si mímọ́ fun mímú àṣẹ yẹn ṣẹ. (Iṣe 26:14-20) A ha ti gbé àṣẹ yẹn kà wá lori bi? Bi o bá ri bẹẹ, eeṣe ti o fi ṣe pataki ni ọjọ wa?
Nigba ti ‘Ìmọ́lẹ̀ Ṣokunkun’ fun Iran-araye
2. (a) Bi ayé ṣe kó wọnu akoko opin rẹ̀, ki ni ó ṣẹlẹ ti ó nipa lori ayika tẹmi ati ti iwarere rẹ̀ lọna ti o rinlẹ? (b) Bawo ni aṣaaju oṣelu ọmọ Britain kan ṣe huwa pada si ohun ti ó rí tí ń ṣẹlẹ ni August 1914?
2 Ṣaaju ki a tó bí ọpọ julọ awọn eniyan ti wọn walaaye lonii, ayé yii ti wọnu akoko opin rẹ̀. Awọn iṣẹlẹ pataki ṣẹlẹ tẹleratẹlera lọna ti ó yára kánkán. Satani Eṣu, olori agbatẹru okunkun tẹmi ati ti iwarere, ni a fi sọko silẹ sori ilẹ̀-ayé. (Efesu 6:12; Ìfihàn 12:7-12) Araye ni a ti rì sínú ogun agbaye kìn-ín-ní rẹ̀. Ni ibẹrẹ August 1914, nigba ti ogun jọ bi eyi ti o daju, Sir Edward Grey, aṣaaju oṣelu ọmọ Britain fun awọn àlámọ̀rí ilẹ ajeji, duro nibi ferese ọfiisi rẹ̀ ni London ó sì sọ pe: “Awọn ifojusọna ati ireti mimọlẹyoo fun eniyan ń kú lọ kaakiri gbogbo Europe; a kì yoo ri ki wọn tàn mọ́ ni ìgbà ayé wa.”
3. Aṣeyọri wo ni awọn aṣaaju ayé ti ní ninu gbigbiyanju lati mú irisi ode araye mọ́lẹ̀yòò?
3 Ninu isapa lati mú ki awọn ifojusọna ati ireti mimọlẹyoo fun eniyan wọnyẹn pada wá, Imulẹ Awọn Orilẹ-ede bẹrẹ iṣẹ́ ni 1920. Ṣugbọn agbárakáká ni awọn ifojusọna mimọlẹyoo ati ireti fun eniyan naa fi wà rara. Ni opin ogun agbaye keji, awọn aṣaaju aye tun gbiyanju sii, ni akoko yii pẹlu eto-ajọ Iparapọ Awọn Orilẹ-ede. Lẹẹkan sii, awọn ifojusọna ati ireti mimọlẹyoo fun eniyan naa kò mọlẹyoo daradara. Bi o ti wu ki o ri, loju iwoye awọn iṣẹlẹ lọwọlọwọ yii, awọn aṣaaju aye ti ń sọrọ nipa “eto ayé titun kan.” Ṣugbọn ekukaka ni a fi lè sọ pe “ayé titun” eyikeyii ti o jẹ́ atọwọda tiwọn tii pese alaafia ati ailewu tootọ. Lodisi iyẹn, iforigbari ológun, rogbodiyan laaarin awọn ará ilu, iwa-ọdaran, ainiṣẹlọwọ, òṣì, bíba ayika jẹ́, ati oniruuru amodi ni gbogbo wọn ń baa lọ lati ba igbadun iwalaaye awọn eniyan jẹ.
4, 5. (a) Nigba wo ati bawo ni okunkun ṣe bà lé idile eniyan? (b) Ki ni ó pọndandan ki a baà lè pese itura alaafia?
4 Niti gidi, tipẹtipẹ ṣaaju 1914 ni awọn ifojusọna ati ireti mimọlẹyoo fun eniyan ti ṣokunkun fun iran-araye. Iyẹn ṣẹlẹ ni ohun ti o sunmọ 6,000 ọdun sẹhin, ni Edeni, nigba ti awọn òbí wa eniyan akọkọ yàn lati ṣe awọn ipinnu tiwọn funraawọn laika isọjade ifẹ-inu Ọlọrun sí. Awọn iriri aronilara ti iran eniyan lati ìgbà naa wa wulẹ jẹ abala-iṣẹlẹ labẹ ohun ti Bibeli tọkasi gẹgẹ bi “agbara okunkun.” (Kolosse 1:13) Labẹ agbara-idari Satani Eṣu ni ọkunrin akọkọ naa, Adamu, ti ri araye sinu ẹṣẹ; ati lati ọ̀dọ̀ Adamu ẹṣẹ ati iku tankalẹ lọ sọdọ gbogbo araye. (Genesisi 3:1-6; Romu 5:12) Iran-eniyan tipa bẹẹ sọ itẹwọgba Jehofa, Orisun ìmọ́lẹ̀ ati iwalaaye nù.—Orin Dafidi 36:9.
5 Ọ̀nà kanṣoṣo ti a tun lè gbà mú ki ifojusọna ati ireti yẹn mọ́lẹ̀yòò niti tootọ fun iran-araye eyikeyii lẹẹkan sii yoo jẹ bi wọn bá jere itẹwọgba Jehofa Ọlọrun, Ẹlẹdaa araye. Nigba naa ni “ìbòjú naa ti o bo gbogbo eniyan lójú,” ìdálẹ́bi nitori ẹṣẹ, yoo tó lè di eyi ti a mú kuro. Bawo ni eyi yoo ṣe ṣeeṣe?—Isaiah 25:7.
Ẹni Naa Ti A Fifunni “Gẹgẹ bi Ìmọ́lẹ̀ Awọn Orilẹ-ede”
6. Awọn ifojusọna ńláǹlà wo ni Jehofa ti mú ki ó ṣeeṣe fun wa nipasẹ Jesu Kristi?
6 Àní ṣaaju ki a tó lé Adamu ati Efa jade kuro ninu Paradise, Jehofa sọ asọtẹlẹ “iru-ọmọ” kan ti yoo jẹ́ oludande awọn olufẹ òdodo. (Genesisi 3:15) Lẹhin ìbí ẹ̀dá eniyan Iru-ọmọ ti a ṣeleri yẹn, Jehofa mú ki Simeoni arugbo, ni tẹmpili ni Jerusalemu, fi ẹni yẹn hàn gẹgẹ bi “ìmọ́lẹ̀ kan lati mu ìbòjú kuro loju awọn orilẹ-ede.” (Luku 2:29-32, NW) Nipasẹ igbagbọ ninu ẹbọ iwalaaye ẹ̀dá eniyan pípé ti Jesu, iran eniyan lè ri itura kuro lọwọ idalẹbi ti ń jẹyọ lati inu ẹṣẹ ti a bí mọ́ wa. (Johannu 3:36) Ni ibamu pẹlu ifẹ-inu Jehofa, wọn lè fojusọna nisinsinyi fun ìyè ayeraye ninu ijẹpipe gẹgẹ bi apakan Ijọba ọrun tabi gẹgẹ bi ọmọ-abẹ́ rẹ̀ ninu paradise lori ilẹ̀-ayé. Ẹ wo iru ipese agbayanu ti iyẹn jẹ!
7. Eeṣe ti awọn ileri ni Isaiah 42:1-4 ati imuṣẹ ti wọn ní ní ọrundun kìn-ín-ní ṣe fi ireti kún inu wa?
7 Jesu Kristi fúnraarẹ̀ ni ẹri-idaniloju imuṣẹ awọn ifojusọna titobilọla wọnyi. Ni isopọ pẹlu mímú ti Jesu mú awọn eniyan ti a pọnloju larada, aposteli Matteu fi ohun ti a kọsilẹ ninu Isaiah 42:1-4 silo fun un. Ẹsẹ iwe mimọ yẹn sọ, ni apakan pe: “Wo iranṣẹ mi, ẹni ti mo yàn; ayanfẹ mi, ẹni ti inu mi dùn si gidigidi: emi o fi ẹmi mi fun un, yoo sì fi idajọ hàn fun awọn [orilẹ-ede, NW].” Kìí ha ṣe ohun ti awọn eniyan orilẹ-ede gbogbo nilo niyi bi? Asọtẹlẹ naa ń baa lọ pe: “Oun ki yoo jà, ki yoo sì kigbe, bẹẹ ni ẹnikẹni ki yoo jẹ ki a gbọ́ ohùn rẹ̀ ni igboro. Iyè fífọ́ ni oun ki yoo ṣẹ́, òwú fitila ti ń rú eefin ni oun ki yoo sì pa.” Ni ibamu pẹlu eyi, Jesu kò lekoko mọ́ awọn eniyan ti a ti ń pọnloju tẹlẹ. O fi aanu hàn fun wọn, o kọ́ wọn nipa awọn ète Jehofa, o sì wò wọn sàn.—Matteu 12:15-21.
8. Ni èrò itumọ wo ni Jehofa ti gba fi Jesu funni “gẹgẹ bi majẹmu awọn eniyan” ati “gẹgẹ bi imọlẹ awọn orilẹ-ede”?
8 Olufunni ni asọtẹlẹ yii dari afiyesi rẹ̀ si Iranṣẹ rẹ̀, si Jesu, ó sì wi pe: “Emi [Jehofa] ni o ti pe ọ ninu òdodo, emi o si di ọwọ́ rẹ mú, emi o si pa ọ mọ́, emi o si fi ọ ṣe majẹmu awọn eniyan, ìmọ́lẹ̀ awọn [orilẹ-ede, NW]. Lati la oju awọn afọju, lati mú awọn onde kuro ninu túbú, ati awọn ti o jokoo ni okunkun kuro ni ile túbú.” (Isaiah 42:6, 7) Bẹẹni, Jehofa ti pese Jesu Kristi gẹgẹ bii majẹmu kan, gẹgẹ bi ẹri-idaniloju ileri wiwuwo kan. Ẹ wo bi iyẹn ti ń funni niṣiiri tó! Jesu fi idaniyan tootọ hàn fun iran-araye nigba ti o wà lori ilẹ̀-ayé; o tilẹ tun fi iwalaaye rẹ̀ lélẹ̀ fun araye. Eyi ni ẹni naa ti Jehofa ti fa iṣakoso lori gbogbo orilẹ-ede lé lọwọ. Abajọ ti Jehofa fi tọka si i gẹgẹ bi ìmọ́lẹ̀ awọn orilẹ-ede. Jesu funraarẹ sọ pe: “Emi ni ìmọ́lẹ̀ ayé.”—Johannu 8:12.
9. Eeṣe ti Jesu kò fi fi araarẹ̀ fun mímú eto-igbekalẹ awọn nǹkan ti ń bẹ nigba naa sunwọn sii?
9 Fun ète wo ni Jesu ṣiṣẹsin gẹgẹ bi ìmọ́lẹ̀ ayé? Dajudaju kìí ṣe fun ète ti ara tabi ti ọrọ̀ àlùmọ́nì. O kọ̀ lati gbiyanju lati ṣe atunṣe tabi mú eto-igbekalẹ oṣelu ti o wà nigba naa sunwọn sii oun kò sì ni tẹwọgba ipo ọba yala lati ọwọ Satani, oluṣakoso ayé, tabi lati ọwọ́ awọn eniyan. (Luku 4:5-8; Johannu 6:15; 14:30) Jesu fi ìyọ́nú ti o ga hàn fun awọn ti a pọnloju ti o si pese itura fun wọn ni ọna ti awọn miiran kò lè gbà ṣe é. Ṣugbọn o mọ̀ pe itura pipẹtiti ni a kò lè rí ninu ọna-igbekalẹ ẹgbẹ́ awujọ eniyan kan ti o wà labẹ idalẹbi atọrunwa nitori ẹṣẹ ti a bí mọ́ wa ti a si ń dọgbọn dari rẹ̀ lati ọwọ́ awọn agbara ẹmi airi buburu. Pẹlu òye-inú ti Ọlọrun ń funni, Jesu gbé gbogbo igbesi-aye rẹ kari ṣiṣe ifẹ-inu Ọlọrun.—Heberu 10:7.
10. Ni awọn ọ̀nà wo ati fun ète wo ni Jesu fi ṣiṣẹsin gẹgẹ bi ìmọ́lẹ̀ ayé?
10 Ni awọn ọ̀nà wo ati fun ète wo, nigba naa, ni Jesu gba ṣiṣẹsin gẹgẹ bi ìmọ́lẹ̀ ayé? O ya araarẹ̀ sọtọ fun wiwaasu ihinrere Ijọba Ọlọrun. (Luku 4:43; Johannu 18:37) Nipa jijẹrii si otitọ nipa ète Jehofa, Jesu tun ṣe orukọ Baba rẹ̀ ọrun lógo. (Johannu 17:4, 6) Ni afikun si eyi, gẹgẹ bi ìmọ́lẹ̀ ayé, Jesu tudii aṣiri awọn isin èké ti o si tipa bayii pese ominira tẹmi fun awọn wọnni ti a fi sabẹ ìsìnrú isin. Ó tú Satani fó gẹgẹ bi ẹni aiṣeeri ti ó ń dọgbọn dari awọn wọnni ti wọn ba yọnda araawọn fun un lati lò. Jesu tun fi awọn iṣẹ ti ó jẹ́ ti okunkun hàn. (Matteu 15:3-9; Johannu 3:19-21; 8:44) Lọna ti o hàn gbangba-gbàǹgbà, oun fẹ̀rí hàn pe oun jẹ ìmọ́lẹ̀ ayé nipa fifi iwalaaye ẹda eniyan pipe rẹ̀ lelẹ gẹgẹ bi irapada, nipa bayii o ṣí ọ̀nà silẹ fun awọn wọnni ti wọn lo igbagbọ ninu ipese yii lati ni idariji ẹṣẹ, ibatan ti o ṣetẹwọgba pẹlu Ọlọrun, ati ifojusọna fun iwalaaye titilae gẹgẹ bi apakan idile agbaye Jehofa. (Matteu 20:28; Johannu 3:16) Ni paripari rẹ̀, nipa pipa ifọkansin pipe si Ọlọrun mọ́ jalẹ gbogbo igbesi-aye rẹ̀, Jesu di ipo ọba-alaṣẹ Jehofa mú ó sì fi Eṣu hàn bi opurọ kan, ó tipa bayii mú ki anfaani ayeraye ṣeeṣe fun awọn olufẹ òdodo. Ṣugbọn Jesu nikanṣoṣo ni o ha yẹ ki o jẹ olùtan ìmọ́lẹ̀ bi?
“Ẹyin Ni Ìmọ́lẹ̀ Ayé”
11. Fun wọn lati jẹ́ olùtan ìmọ́lẹ̀, ki ni awọn ọmọ-ẹhin Jesu nilati ṣe?
11 Ni Matteu 5:14, Jesu sọ fun awọn ọmọlẹhin rẹ̀ pe: “Ẹyin ni ìmọ́lẹ̀ ayé.” Wọn nilati tẹle ipasẹ rẹ̀. Nipasẹ ọ̀nà igbesi-aye wọn ati nipasẹ iwaasu wọn, wọn nilati dari awọn miiran si Jehofa gẹgẹ bi Orisun ilaloye tootọ. Ni afarawe Jesu, wọn nilati sọ orukọ Jehofa di mímọ̀ ki wọn si di ipo ọba-alaṣẹ Rẹ̀ mú. Gẹgẹ bi Jesu ti ṣe, bẹẹ naa ni wọn nilati pokiki Ijọba Ọlọrun gẹgẹ bi ireti kanṣoṣo fun araye. Wọn tun nilati tú isin èké, awọn iṣẹ́ ti wọn jẹmọ ti okunkun, ati ẹni buruku naa ti o wa lẹhin awọn nǹkan wọnyi fó. Awọn ọmọlẹhin Kristi nilati sọ fun awọn eniyan nibi gbogbo nipa ipese onifẹẹ ti Jehofa fun igbala nipasẹ Jesu Kristi. Ẹ sì wo ìtara naa ti awọn Kristian ijimiji fi mú iṣẹ́ ayanfunni yẹn ṣẹ, ni bibẹrẹ lakọọkọ ni Jerusalemu ati Judea ati lẹhin naa wọ inu Samaria, gẹgẹ bi Jesu ti pàṣẹ!—Iṣe 1:8.
12. (a) Ìwọ̀n wo ni ó yẹ́ ki ìmọ́lẹ̀ tẹmi gbooro dé? (b) Ki ni ẹmi Jehofa mú ki ó ṣeeṣe fun Paulu lati fòyemọ̀ nipa Isaiah 42:6, bawo sì ni asọtẹlẹ yẹn ṣe nilati nipa lori igbesi-aye wa?
12 Bi o ti wu ki o ri, wiwaasu ihinrere naa ni a kò nilati fimọ si pápá yẹn nikan. Jesu fun awọn ọmọlẹhin rẹ̀ ni itọni lati maa ‘sọ awọn eniyan gbogbo orilẹ-ede di ọmọ-ẹhin.’ (Matteu 28:19) Lakooko iyilọkanpada Saulu ará Tarsu, Oluwa fihàn ni pato pe Saulu (ẹni ti o di aposteli Paulu) yoo waasu kìí ṣe fun awọn Ju nikan ni ṣugbọn fun awọn Keferi pẹlu. (Iṣe 9:15) Pẹlu iranlọwọ ẹmi mimọ, Paulu wá mọriri ohun ti iyẹn ni ninu. Nipa bayii, o woye pe asọtẹlẹ ti ó wà ninu Isaiah 42:6, eyi ti o ni imuṣẹ taarata ninu Jesu Kristi, tun jẹ aṣẹ ti a pẹ́sọ fun gbogbo awọn ti o bá lo igbagbọ ninu Kristi. Nitori naa, ni Iṣe 13:47, nigba ti o fa ọ̀rọ̀ yọ lati inu Isaiah, Paulu sọ pe: “Oluwa sá ti paṣẹ fun wa pe, Mo ti gbe ọ kalẹ fun ìmọ́lẹ̀ awọn [orilẹ-ede, NW], ki iwọ ki ó lè jẹ fun igbala titi de opin aye.” Iwọ ń kọ́? Iwọ ha ti fi iṣẹ aigbọdọmaṣe yẹn lati jẹ olùtan ìmọ́lẹ̀ sọ́kàn bi? Bii Jesu ati Paulu, iwọ ha ti gbe igbesi-aye rẹ karí ṣiṣe ifẹ-inu Ọlọrun bi?
Ìmọ́lẹ̀ ati Otitọ Lati Ọ̀dọ̀ Ọlọrun Lati Ṣamọna Wa
13. Ni ibamu pẹlu Orin Dafidi 43:3, ki ni adura onifọkansi wa, ki ni eyi sì daabobo wa lodisi?
13 Bi awa nipa ihumọ tiwa funraawa, bá nilati gbiyanju lati ‘mu ki awọn ifojusọna ati ireti mimọlẹyoo fun eniyan pada wá,’ lati mú ki ọjọ-ọla iran eniyan mọlẹyoo, awa lọna wiwuwo yoo tàsé kókó Ọ̀rọ̀ onimiisi ti Ọlọrun. Laika ohun ti ayé ni gbogbogboo ń ṣe sí, bi o ti wu ki o ri, awọn Kristian tootọ ń wo Jehofa gẹgẹ bi Orisun tootọ fun ìmọ́lẹ̀. Adura wọn rí gẹgẹ bi eyi ti a kọsilẹ ni Orin Dafidi 43:3, eyi ti o sọ pe: “Rán ìmọ́lẹ̀ rẹ ati otitọ rẹ jade, ki wọn ki o maa ṣe amọna mi: ki wọn ki o mú mi gun òkè mímọ́ rẹ, ati sinu àgọ́ rẹ wọnni.”
14, 15. (a) Ni awọn ọ̀nà wo ni Jehofa ń gbà lati rán ìmọ́lẹ̀ ati otitọ rẹ̀ jade nisinsinyi? (b) Bawo ni a ṣe lè fihàn pe ìmọ́lẹ̀ ati otitọ Ọlọrun ń ṣamọna wa niti gidi?
14 Jehofa ń baa lọ lati dahun adura awọn iranṣẹ rẹ̀ aduroṣinṣin yẹn. Ó ń rán ìmọ́lẹ̀ jade nipa pipolongo ète rẹ̀, nipa jijẹ ki awọn iranṣẹ rẹ̀ loye rẹ̀, ati lẹhin naa nipa mímú ki awọn ohun ti o ti polongo ni imuṣẹ. Nigba ti a bá gbadura si Ọlọrun, kìí ṣe eto-aṣa lasan kan, ti a ṣe kiki lati fi ìrísí ìjẹ́mímọ́ hàn. Idaniyan onifọkansin wa ni pe ki ìmọ́lẹ̀ ti ń wá lati ọdọ Jehofa ṣamọna wa, gẹgẹ bi orin naa ti sọ. A tẹwọgba ẹrù-iṣẹ́ ti o ń bá gbigba ìmọ́lẹ̀ ti Ọlọrun ń pese rìn. Gẹgẹ bi aposteli Paulu, a woye pe imuṣẹ Ọ̀rọ̀ Jehofa ní pẹlu rẹ̀ aṣẹ ti a pẹ́sọ fun gbogbo awọn ti wọn lo igbagbọ ninu rẹ̀. A nimọlara bi ajigbese fun awọn eniyan miiran titi di ìgbà ti a bá fun wọn ni ihinrere naa ti Ọlọrun ti fi si ikawọ wa fun ète yẹn.—Romu 1:14, 15.
15 Ìmọ́lẹ̀ ati otitọ tí Jehofa ti rán jade ni ọjọ́ wa mú ki o farahan pe Jesu Kristi ti ń ṣakoso pẹlu igbekankanṣiṣẹ lati ori ìtẹ́ rẹ̀ ni ọ̀run. (Orin Dafidi 2:6-8; Ìfihàn 11:15) Jesu sọtẹlẹ pe lakooko wíwàníhìn-ín rẹ̀ bi ọba, ihinrere Ijọba yii ni a o waasu ni gbogbo ilẹ̀-ayé ti a ń gbé fun ẹ̀rí. (Matteu 24:3, 14) Iṣẹ yẹn ni a ń ṣe nisinsinyi, ati lọna gigalọla pẹlu, yika òbírí ilẹ̀-ayé. Bi awa bá ń fi iṣẹ́ yẹn ṣe ohun pataki julọ ninu igbesi-aye wa, nigba naa ìmọ́lẹ̀ ati otitọ Ọlọrun ń ṣamọna wa, gẹgẹ bi olorin naa ti sọ.
Ògo Jehofa Funraarẹ Ti Tàn Jade
16, 17. Bawo ni Jehofa ṣe mú ki ògo rẹ̀ yọ lara eto-ajọ bi-obinrin rẹ̀ ni 1914, àṣẹ wo sì ni ó fifun un?
16 Ni èdè ti ń munilọkanjipepe, Iwe Mimọ ṣapejuwe iru ọ̀nà ti ìmọ́lẹ̀ atọrunwa gba ń túkáàkiri dé ọ̀dọ̀ awọn eniyan nibi gbogbo. Isaiah 60:1-3, eyi ti a dari rẹ̀ si “obinrin” Jehofa, tabi eto-ajọ ọrun ti awọn aduroṣinṣin iranṣẹ rẹ̀, sọ pe: “Dide, tan ìmọ́lẹ̀: nitori ìmọ́lẹ̀ rẹ dé, ògo Oluwa sì yọ lara rẹ. Nitori kiyesi i, òkùnkùn bo ayé mọ́lẹ̀, ati òkùnkùn biribiri bo awọn eniyan: ṣugbọn Oluwa yoo yọ lara rẹ, a o si ri ògo rẹ̀ lara rẹ. Awọn [orilẹ-ede, NW] yoo wá si ìmọ́lẹ̀ rẹ, ati awọn ọba si títàn yíyọ rẹ.”
17 Ògo Jehofa tàn jade sori eto-ajọ bi obinrin rẹ̀ ti ọrun ni ọdun 1914 nigba ti, lẹhin akoko ti o gùn ti o ti fi ń duro, o bí Ijọba Messia naa, pẹlu Jesu Kristi gẹgẹ bi Ọba. (Ìfihàn 12:1-5) Ìmọ́lẹ̀ ológo ti Jehofa tàn pẹlu itẹwọgba sori akoso yẹn gẹgẹ bi ọ̀kan ti o tọ́ fun gbogbo ilẹ̀-ayé.
18. (a) Eeṣe ti okunkun fi bo ilẹ̀-ayé, gẹgẹ bi a ṣe sọtẹlẹ ni Isaiah 60:2? (b) Bawo ni a ṣe lè dá awọn ẹnikọọkan nídè kuro ninu okunkun ilẹ̀-ayé?
18 Ni iyatọ si yẹn, òkùnkùn bo ayé mọ́lẹ̀ òkùnkùn biribiri sì bo awọn eniyan. Eeṣe? Nitori pe awọn orilẹ-ede ṣá akoso Ọmọkunrin Ọlọrun ọ̀wọ́n tì ni ifaramọ iṣakoso eniyan. Wọn ronu pe nipa mímú irú akoso eniyan kan kuro ati fifayegba omiran, wọn yoo ri ojutuu si awọn iṣoro wọn. Ṣugbọn eyi kò mú itura ti wọn reti wá. Wọn kùnà lati rí ẹni ti o wà lẹhin ìran naa ti ń dọgbọndari awọn orilẹ-ede lati ilẹ ọba ẹmi. (2 Korinti 4:4) Wọn ṣá Orisun ìmọ́lẹ̀ tootọ tì ati nitori naa wọn wà ninu òkùnkùn. (Efesu 6:12) Bi o ti wu ki o ri, laika ohun ti awọn orilẹ-ede ṣe si, ẹnikọọkan ni a lè danide kuro ninu òkùnkùn yẹn. Ni ọ̀nà wo? Nipa lilo ẹkunrẹrẹ igbagbọ ninu Ijọba Ọlọrun ati jijuwọsilẹ fun un.
19, 20. (a) Eeṣe ati bawo ni ògo Jehofa ṣe hàn lara awọn ọmọlẹhin Jesu ẹni-ami-ororo? (b) Fun idi wo ni Jehofa fi sọ awọn ẹni-ami-ororo rẹ̀ di olùtan ìmọ́lẹ̀? (c) Gẹgẹ bi a ṣe sọtẹlẹ, bawo ni “awọn ọba” ati “awọn orilẹ-ede” ṣe di awọn ti a fa sunmọ ìmọ́lẹ̀ ti Ọlọrun fifunni?
19 Kristẹndọm kò lo igbagbọ ninu Ijọba Ọlọrun wọn kò sì juwọsilẹ fun un. Ṣugbọn awọn ẹni-ami-ororo ọmọlẹhin Jesu Kristi ti ṣe bẹẹ. Gẹgẹ bi iyọrisi rẹ̀, ìmọ́lẹ̀ itẹwọgba atọrunwa Jehofa ti tàn sara awọn aṣoju ti o ṣeefojuri ti obinrin rẹ̀ ti ọrun, ògo rẹ̀ si ti hàn lara wọn. (Isaiah 60:19-21) Wọn ń gbadun ìmọ́lẹ̀ tẹmi tí iyipada eyikeyii ninu iran iṣelu tabi ti ọrọ̀-ajé ayé yii kò lè gbà kuro. Wọn ti niriiri idande Jehofa kuro ninu Babiloni Nla. (Ìfihàn 18:4) Wọn gbadun ẹrin musẹ itẹwọgba rẹ̀ nitori pe wọn ti tẹwọgba ibawi rẹ̀ wọn sì ti fi iduroṣinṣin di ipo ọba-alaṣẹ agbaye rẹ̀ mú. Wọn ni ifojusọna mimọlẹyoo fun ọjọ-ọla, wọn sì yọ ayọ ninu ireti ti o ti fi si iwaju wọn.
20 Ṣugbọn fun ète wo ni Jehofa ti fi bá wọn lò ni ọ̀nà yii? Gẹgẹ bi oun funraarẹ ti sọ ni Isaiah 60:21, ó jẹ nitori pe ‘ki a baa lè yin in logo,’ ki a baa lè bọla fun orukọ rẹ̀ ki awọn miiran sì lè fà sunmọ ọn gẹgẹ bi Ọlọrun tootọ kanṣoṣo naa—iyẹn sì jẹ́ pẹlu anfaani ayeraye fun araawọn. Ni iṣedeede pẹlu eyi, ni 1931 awọn olujọsin Ọlọrun tootọ yii gba orukọ naa awọn Ẹlẹ́rìí Jehofa. Gẹgẹ bi iyọrisi ijẹrii wọn, a ha fa “awọn ọba” sunmọ ìmọ́lẹ̀ naa ti wọn gbeyọ, gẹgẹ bi Isaiah ti sọtẹlẹ bi? Bẹẹni! Kìí ṣe awọn oluṣakoso oṣelu ilẹ̀-ayé, ṣugbọn eyi ti o kù lara iye awọn wọnni ti wọn wà ni ila lati ṣakoso bi ọba pẹlu Kristi ninu Ijọba rẹ̀ ti ọrun. (Ìfihàn 1:5, 6; 21:24) Ki sì ni nipa ti “awọn orilẹ-ede”? A ha ti fà wọn sunmọ ìmọ́lẹ̀ yii bi? Dajudaju bẹẹni! Kò si orilẹ-ede oṣelu kankan ti a tii famọra, ṣugbọn ogunlọgọ nla ti awọn eniyan lati inu gbogbo awọn orilẹ-ede wá ti mú iduro wọn siha Ijọba Ọlọrun, wọn sì ń fi iharagaga fojusọna fun idande sinu ayé titun Ọlọrun. Yoo jẹ́ ayé titun kan nitootọ ninu eyi ti òdodo yoo gbilẹ̀.—2 Peteru 3:13; Ìfihàn 7:9, 10.
21. Bawo ni a ṣe lè fihàn pe a kò tíì tàsé ète inurere ailẹtọọsi Jehofa ninu yiyọnda òye ifẹ-inu rẹ̀ fun wa?
21 Iwọ ha jẹ ọ̀kan lara ọpọ awọn eniyan olùtan ìmọ́lẹ̀ ti ń pọ̀ sii yẹn bi? Jehofa ti fi òye ifẹ-inu rẹ̀ fun wa ki awa, bii ti Jesu, baa lè jẹ olùtan ìmọ́lẹ̀. Nipa fifi itara hàn ninu iṣẹ́ ti Jehofa ti fi lé awọn iranṣẹ rẹ̀ lọwọ ni ọjọ wa, ǹjẹ́ ki gbogbo wa fihàn pe awa kò tíì tàsé ète inurere ailẹtọọsi ti Ọlọrun ti nawọ́ rẹ̀ sí wa. (2 Korinti 6:1, 2) Kò si iṣẹ́ miiran ti o ṣe pataki ju ni ọjọ wa. Kò sì sí anfaani giga ju kankan ti o lè jẹ tiwa ju lati fi ogo fun Jehofa nipa ṣiṣagbeyọ ògo ìmọ́lẹ̀ ti ń wa lati ọ̀dọ̀ rẹ̀ fun awọn ẹlomiran.
Bawo ni Iwọ Yoo Ṣe Dahun?
◻ Ki ni gbongbo awọn okunfa iṣoro abanininujẹ ti araye?
◻ Ni awọn ọ̀nà wo ni Jesu ati awọn ọmọlẹhin rẹ̀ gbà jẹ́ “ìmọ́lẹ̀ ayé”?
◻ Bawo ni ìmọ́lẹ̀ ati otitọ Jehofa ṣe ń ṣamọna wa?
◻ Bawo ni Jehofa ṣe jẹ́ ki ògo rẹ̀ di eyi ti ó yọ lara eto-ajọ rẹ?
◻ Fun ète wo ni Jehofa fi sọ awọn eniyan rẹ̀ di olùtan ìmọ́lẹ̀?
[Àwọn àwòrán tó wà ní ojú ìwé 9]
Iṣẹlẹ kan ni Edeni ràn wá lọwọ lati loye awọn iṣoro abanininujẹ ti araye ni lonii
[Àwọn Credit Line]
Tom Haley/Sipa
Paringaux/Sipa