ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍNTÁNẸ́Ẹ̀TÌ ti Watchtower
ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍŃTÁNẸ́Ẹ̀TÌ
ti Watchtower
Yorùbá
ọ́
  • ẹ
  • ọ
  • ṣ
  • ń
  • ẹ́
  • ẹ̀
  • ọ́
  • ọ̀
  • BÍBÉLÌ
  • ÌTẸ̀JÁDE
  • ÌPÀDÉ
  • w98 1/1 ojú ìwé 6-11
  • Ẹ Má Ṣe Juwọ́ Sílẹ̀ Nínú Eré Ìje Fún Ìyè!

Kò sí fídíò kankan ní apá yìí.

Má bínú, fídíò yìí kò jáde.

  • Ẹ Má Ṣe Juwọ́ Sílẹ̀ Nínú Eré Ìje Fún Ìyè!
  • Ilé Ìṣọ́ Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—1998
  • Ìsọ̀rí
  • Àpilẹ̀kọ Míì Tó Jọ ọ́
  • ‘Ẹ fún Àwọn Ohun Tí Ẹ Ń Gbọ́ Ní Àfiyèsí Tí Ó Ju Ti Àtẹ̀yìnwá Lọ’
  • “Ẹ Máa Bá A Nìṣó Ní Gbígba Ara Yín Níyànjú Lẹ́nì Kíní Kejì”
  • “Ẹ Nílò Ìfaradà”
  • A Lè Fara Dà
  • O Lè Fara Dà á Dé Òpin
    Ilé Ìṣọ́ Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—1999
  • Ẹ Fi Ìfaradà Sá Eré Ìje Náà
    Ilé Ìṣọ́ Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—2011
  • Ṣọ́ra fún Àìnígbàgbọ́
    Ilé Ìṣọ́ Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—1998
  • Sisa Eré-Ìje Naa Pẹlu Ifarada
    Ilé-Ìṣọ́nà Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—1991
Àwọn Míì
Ilé Ìṣọ́ Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—1998
w98 1/1 ojú ìwé 6-11

Ẹ Má Ṣe Juwọ́ Sílẹ̀ Nínú Eré Ìje Fún Ìyè!

“Ẹ . . . jẹ́ kí a fi ìfaradà sá eré ìje tí a gbé ka iwájú wa.”—HÉBÉRÙ 12:1.

1, 2. Àwọn ìṣẹ̀lẹ̀ arùmọ̀lárasókè wo ni ó ti mú inú àwọn ìránṣẹ́ Jèhófà yọ̀ ṣẹ̀ṣẹ̀ ní àwọn ọjọ́ ìkẹyìn wọ̀nyí?

AŃ GBÉ ní àkókò arùmọ̀lárasókè, tí ó sì nira gidigidi. Ní ohun tí ó lé ní 80 ọdún sẹ́yìn, ní ọdún 1914, a gbé Jésù gorí ìtẹ́ gẹ́gẹ́ bí Ọba Ìjọba Ọlọ́run lókè ọ̀run. Ìgbà náà ni “ọjọ́ Olúwa” àti “ìgbà ìkẹyìn” ti ètò ìgbékalẹ̀ àwọn nǹkan ìsinsìnyí bẹ̀rẹ̀. (Ìṣípayá 1:10; Dáníẹ́lì 12:9) Láti ìgbà náà, eré ìje Kristẹni fún ìyè ti túbọ̀ di ọ̀ràn kánjúkánjú. Àwọn ìránṣẹ́ Ọlọ́run ti tiraka tokuntokun láti má ṣe jẹ́ kí kẹ̀kẹ́ ẹṣin òkè ọ̀run ti Jèhófà, ètò àjọ rẹ̀ ti ọ̀run, tí ń rìn lọ́nà tí kò ṣeé dá dúró láti mú àwọn ète Jèhófà ṣẹ, yà wọ́n lẹ́sẹ̀ kan.—Ìsíkẹ́ẹ̀lì 1:4-28; Kọ́ríńtì Kíní 9:24.

2 Àwọn ènìyàn Ọlọ́run ha ti rí ìdùnnú bí wọ́n ti ń ‘sáré ìje náà’ síhà ìyè àìnípẹ̀kun? Bẹ́ẹ̀ ni, wọ́n ti ṣe bẹ́ẹ̀! Wọ́n yọ̀ ṣẹ̀ṣẹ̀ láti rí ìkójọ àwọn tí ó ṣẹ́ kù nínú àwọn arákùnrin Jésù, inú wọn sì dùn láti mọ̀ pé a ti fẹ́rẹ̀ẹ́ parí àṣekágbá fífi èdìdì di àwọn tí ó ṣẹ́ kù nínú 144,000 náà. (Ìṣípayá 7:3, 4) Ní àfikún sí i, a ru ìmọ̀lára wọn sókè láti fòye mọ̀ pé Ọba tí Jèhófà yàn sípò ti tẹ dòjé rẹ̀ bọ̀ ọ́ láti kárúgbìn “ìkórè ilẹ̀ ayé.” (Ìṣípayá 14:15, 16) Ẹ sì wo irú ìkórè rẹpẹtẹ tí èyí jẹ́! (Mátíù 9:37) Títí di báyìí, a ti kó ọkàn tí ó lé ní mílíọ̀nù márùn-ún jọ—“ogunlọ́gọ̀ ńlá kan, èyí tí ẹnì kankan kò lè kà, láti inú gbogbo àwọn orílẹ̀-èdè àti ẹ̀yà àti ènìyàn àti ahọ́n.” (Ìṣípayá 7:9) Kò sí ẹni tí ó lè sọ bí ogunlọ́gọ̀ náà yóò ṣe di ńlá tó nígbẹ̀yìngbẹ́yín, níwọ̀n bí kò ti sí ènìyàn kankan tí ó lè kà á.

3. A gbọ́dọ̀ máa gbìyànjú láti ní ẹ̀mí ìdùnnú nígbà gbogbo láìka irú àwọn ipò wo sí?

3 Ní tòótọ́, Sátánì ń gbìyànjú láti mú kí a kọsẹ̀ tàbí láti mú kí a dẹ eré wa bí a ti ń sáré ìje náà lọ. (Ìṣípayá 12:17) Kì í sì í ṣe ohun tí ó rọrùn láti máa bá eré ìje náà nìṣó nínú ogun, ìyàn, àjàkálẹ̀ àrùn, àti gbogbo ìnira yòó kù tí ó sàmì sí àkókò òpin. (Mátíù 24:3-9; Lúùkù 21:11; Tímótì Kejì 3:1-5) Síbẹ̀, ọkàn àyà wa kún fún ayọ̀ bí òpin eré ìje náà ti ń sún mọ́lé. A ń làkàkà láti fi ẹ̀mí náà tí Pọ́ọ̀lù rọ àwọn Kristẹni ẹlẹgbẹ́ rẹ̀ ní ọjọ́ rẹ̀ láti ní hàn: “Ẹ máa yọ̀ nígbà gbogbo nínú Olúwa. Lẹ́ẹ̀kan sí i dájúdájú èmi yóò wí pé, Ẹ máa yọ̀!”—Fílípì 4:4.

4. Irú ẹ̀mí wo ni àwọn Kristẹni ní Fílípì fi hàn?

4 Kò sí iyè méjì kankan pé àwọn Kristẹni tí Pọ́ọ̀lù sọ ọ̀rọ̀ wọnnì sí rí ìdùnnú nínú ìgbàgbọ́ wọn, nítorí Pọ́ọ̀lù wí fún wọn pé: “Ẹ máa bá a lọ ní yíyọ̀ nínú Olúwa.” (Fílípì 3:1) Àwọn ará Fílípì jẹ́ ìjọ tí ó lawọ́, tí ó nífẹ̀ẹ́, tí ó fi ìtara àti ìgbónára sìn. (Fílípì 1:3-5; 4:10, 14-20) Ṣùgbọ́n kì í ṣe gbogbo àwọn Kristẹni ọ̀rúndún kìíní ni ó ní irú ẹ̀mí yẹn. Fún àpẹẹrẹ, ọ̀ràn àwọn kan lára àwọn Kristẹni tí ó jẹ́ Júù tí Pọ́ọ̀lù kọ ìwé Hébérù sí jẹ́ ohun tí ń kọni lóminú.

‘Ẹ fún Àwọn Ohun Tí Ẹ Ń Gbọ́ Ní Àfiyèsí Tí Ó Ju Ti Àtẹ̀yìnwá Lọ’

5. (a) Ẹ̀mí wo ni àwọn Kristẹni tí wọ́n jẹ́ Hébérù ní nígbà tí a dá ìjọ Kristẹni àkọ́kọ́ sílẹ̀? (b) Ṣàpèjúwe ẹ̀mí tí àwọn Kristẹni kan tí wọ́n jẹ́ Hébérù ní, ní nǹkan bí ọdún 60 Sànmánì Tiwa.

5 Àwọn Júù àbínibí àti àwọn aláwọ̀ṣe ni wọ́n para pọ̀ jẹ́ mẹ́ńbà ìjọ Kristẹni àkọ́kọ́ nínú ìtàn ayé, a sì dá a sílẹ̀ ní Jerúsálẹ́mù ní ọdún 33 Sànmánì Tiwa. Irú ẹ̀mí wo ni ó ní? Kíka àwọn orí tí ó bẹ̀rẹ̀ ìwé Ìṣe ti tó fún ẹnì kan láti mọ ìtara àti ayọ̀ ìjọ náà, àní lójú inúnibíni pàápàá. (Ìṣe 2:44-47; 4:32-34; 5:41; 6:7) Ṣùgbọ́n, bí àwọn ẹ̀wádún ti ń kọjá, nǹkan yí pa dà, ó sì hàn gbangba pé ọ̀pọ̀ àwọn Kristẹni tí ó jẹ́ Júù dẹ̀rìn nínú eré ìje náà fún ìyè. Ohun tí ìtọ́kasí kan sọ nípa ipò wọn gẹ́gẹ́ bí ó ṣe wà ni nǹkan bí ọdún 60 Sànmánì Tiwa nìyí: “Ipò ẹni sùẹ̀sùẹ̀ tí àárẹ̀ ti mú, tí a ti já kulẹ̀, tí ìrètí rẹ̀ ti ṣákìí, tí ó ti gbà pé òun kò lè ta á mú mọ́, tí kò sì nígbàgbọ́ nínú ohunkóhun mọ́. Kristẹni ni wọ́n lóòótọ́, ṣùgbọ́n, ìmọrírì wọn fún ògo tí a pè wọ́n sí kò tó nǹkan.” Kí ni ó lè mú kí àwọn Kristẹni ẹni àmì òróró bọ̀ sínú irú ipò yẹn? Gbígbé apá kan nínú lẹ́tà Pọ́ọ̀lù (tí ó kọ ní nǹkan bí ọdún 61 Sànmánì Tiwa) sí àwọn Hébérù yẹ̀ wò yóò ràn wá lọ́wọ́ láti dáhùn ìbéèrè yẹn. Irú àyẹ̀wò bẹ́ẹ̀ yóò ran gbogbo wa pátá lónìí lọ́wọ́ láti yẹra fún rírì sínú irú ipò àárẹ̀ nípa tẹ̀mí bẹ́ẹ̀.

6. Àwọn ìyàtọ̀ díẹ̀ wo ni ó wà láàárín ìjọsìn lábẹ́ Òfin Mósè àti ìjọsìn tí a gbé ka ìgbàgbọ́ nínú Jésù Kristi?

6 Àwọn Kristẹni tí ó jẹ́ Hébérù wá láti inú ẹ̀sìn àwọn Júù, ètò kan tí ó sọ pé òun ń ṣègbọràn sí Òfin tí Jèhófà fúnni nípasẹ̀ Mósè. Ó dà bíi pé Òfin yẹn ṣì ń fa ọ̀pọ̀ àwọn Kristẹni tí ó jẹ́ Júù mọ́ra, bóyá nítorí pé fún ọ̀pọ̀ ọ̀rúndún òun nìkan ṣoṣo ní ọ̀nà tí a lè gbà tọ Jèhófà lọ, tí ó sì jẹ́ ètò ẹ̀sìn kan tí ó fani mọ́ra, tí ó ní àlùfáà, ìrúbọ déédéé, àti tẹ́ńpìlì Jerúsálẹ́mù tí a mọ̀ káàkiri àgbáyé. Ẹ̀sìn Kristẹni yàtọ̀. Ó ń béèrè fún ojú ìwòye tẹ̀mí, bíi ti Mósè, tí ó “fi tọkàntara wo sísan èrè ẹ̀san náà [bí ó tilẹ̀ ṣì wà ní iwájú],” tí ó sì “ń bá a lọ ní fífẹsẹ̀múlẹ̀ ṣinṣin bí ẹni tí ń rí Ẹni náà tí a kò lè rí.” (Hébérù 11:26, 27) Ó hàn gbangba pé ọ̀pọ̀ àwọn Kristẹni tí ó jẹ́ Júù kò ní irú ojú ìwòye yẹn. Wọ́n ń tiro dípò tí wọn yóò fi máa sáré lọ́nà tí ó ní ète nínú.

7. Báwo ni ètò ìgbékalẹ̀ tí a ti inú rẹ jáde ṣe lè nípa lórí ọ̀nà tí a gbà ń sáré ìje fún ìyè?

7 Ipò tí ó jọra ha wà lónìí bí? Tóò, ipò nǹkan kò rí bákan náà gẹ́lẹ́. Síbẹ̀, àwọn Kristẹni wá láti inú ètò ìgbékalẹ̀ àwọn nǹkan tí ń fọ́nnu lọ́nà kíkàmàmà. Ayé ń fi àwọn àǹfààní tí ń múni yọ̀ ṣẹ̀ṣẹ̀ lọ àwọn ènìyàn, ṣùgbọ́n, lọ́wọ́ kan náà, ó ń di ẹrù nínira rù wọ́n. Ní àfikún sí i, ọ̀pọ̀ nínú wa ń gbé ní àwọn ilẹ̀ tí ẹ̀mí tàbí-tàbí ti wọ́pọ̀, tí àwọn ènìyàn sì ti jẹ́ onímọtara-ẹni-nìkan, ẹlẹ́mìí-tèmi-làkọ́kọ́. Bí a bá yọ̀ǹda kí irú ètò ìgbékalẹ̀ bẹ́ẹ̀ nípa lórí wa, ‘ojú ọkàn àyà wa’ lè di bàìbàì. (Éfésù 1:18) Báwo ni a óò ṣe lè sa eré ìje náà dáradára bí a kò bá lè rí ibi tí a ń lọ mọ́ dáradára?

8. Àwọn ọ̀nà wo ni ẹ̀sìn Kristẹni gbà ṣe pàtàkì ju ìjọsìn lábẹ́ Òfin lọ?

8 Láti lè sún àwọn Kristẹni tí ó jẹ́ Júù ṣiṣẹ́, Pọ́ọ̀lù rán wọn létí pé ètò ẹ̀sìn Kristẹni ṣe pàtàkì ju Òfin Mósè lọ. Lóòótọ́, nígbà tí orílẹ̀-èdè Ísírẹ́lì nípa ti ara jẹ́ ènìyàn Jèhófà lábẹ́ Òfin náà, Jèhófà bá a sọ̀rọ̀ nípasẹ̀ àwọn wòlíì tí ó mí sí. Ṣùgbọ́n, Pọ́ọ̀lù sọ pé, lónìí ó ń “tipasẹ̀ Ọmọkùnrin kan” bá wa sọ̀rọ̀ “ẹni tí òun yàn sípò gẹ́gẹ́ bí ajogún ohun gbogbo, àti nípasẹ̀ ẹni tí òun dá àwọn ètò ìgbékalẹ̀ àwọn nǹkan.” (Hébérù 1:2) Síwájú sí i, Jésù tóbi ju gbogbo àwọn ọba tí ó ti jẹ ní ìlà Dáfídì, “àwọn alájọṣe” rẹ̀, lọ. Ó tilẹ̀ ga ju àwọn áńgẹ́lì pàápàá lọ.—Hébérù 1:5, 6, 9.

9. Èé ṣe tí àwa, bí àwọn Kristẹni tí ó jẹ́ Júù ní ọjọ́ Pọ́ọ̀lù, fi ní láti fún ohun tí Jèhófà ń sọ ní àfiyèsí “tí ó ju ti àtẹ̀yìnwá lọ”?

9 Nítorí náà, Pọ́ọ̀lù gba àwọn Júù Kristẹni nímọ̀ràn pé: “Ó . . . pọn dandan fún wa láti fún àwọn ohun tí a gbọ́ ní àfiyèsí tí ó ju ti àtẹ̀yìnwá lọ, kí a má baà sú lọ láé.” (Hébérù 2:1) Bí kíkẹ́kọ̀ọ́ nípa Kristi tilẹ̀ jẹ́ ìbùkún àgbàyanu, ohun púpọ̀ sí i ṣì pọn dandan. Ó pọn dandan kí wọ́n fiyè sí Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run dáradára láti lè sọ ipa tí ayé àwọn Júù tí ó yí wọn kà ní di aláìgbéṣẹ́. Ó pọn dandan fún àwa pẹ̀lú láti fún ohun tí Jèhófà ń sọ “ní àfiyèsí tí ó ju ti àtẹ̀yìnwá lọ” lójú ìwòye ìgbékèéyíde ìgbà gbogbo tí ayé yìí ń ṣe nípa wa. Èyí túmọ̀ sí mímú àṣà ìkẹ́kọ̀ọ́ dídán mọ́rán dàgbà àti títẹ̀lé ìtòlẹ́sẹẹsẹ dáradára ti Bíbélì kíkà. Gẹ́gẹ́ bí Pọ́ọ̀lù ṣe sọ lẹ́yìn náà nínú lẹ́tà rẹ̀ sí àwọn Hébérù, ó tún túmọ̀ sí pípésẹ̀ déédéé sí àwọn ìpàdé àti kíkópa déédéé nínú pípolongo ìgbàgbọ́ wa fún àwọn ẹlòmíràn. (Hébérù 10:23-25) Irú ìgbòkègbodò bẹ́ẹ̀ yóò ràn wá lọ́wọ́ láti wà lójúfò nípa tẹ̀mí kí a má baà gbàgbé ìrètí wa ológo. Bí a bá fi èrò Jèhófà kún inú wa, ọkàn wa kò ní pòrúurùu tàbí kí ohunkóhun tí ayé yìí lè ṣe sí wa mú kí a máà mọ ohun tí a óò ṣe mọ́.—Orin Dáfídì 1:1-3; Òwe 3:1-6.

“Ẹ Máa Bá A Nìṣó Ní Gbígba Ara Yín Níyànjú Lẹ́nì Kíní Kejì”

10. (a) Kí ni ó lè ṣẹlẹ̀ sí ẹnì kan tí kò fún Ọ̀rọ̀ Jèhófà ní àfiyèsí tí ó ju ti àtẹ̀yìnwá lọ? (b) Báwo ni a ṣe lè ‘máa bá a nìṣó ní gbígba ara wa níyànjú lẹ́nì kíní kejì’?

10 Bí a kò bá fiyè sí àwọn nǹkan tẹ̀mí dáradára, àwọn ìlérí Ọlọ́run lè dà bí èyí tí kò lè ṣẹ mọ́. Èyí tilẹ̀ ṣẹlẹ̀ ní ọ̀rúndún kìíní pàápàá nígbà tí ó jẹ́ pé àwọn Kristẹni ẹni àmì òróró nìkan ni ó wà nínú ìjọ, tí àwọn kan lára àwọn àpọ́sítélì ṣì wà láàyè. Pọ́ọ̀lù kìlọ̀ fún àwọn Hébérù pé: “Ẹ kíyè sára, ẹ̀yin ará, kí ọkàn àyà burúkú tí ó ṣaláìní ìgbàgbọ́ má baà dìde nínú ẹnikẹ́ni nínú yín láé nípa fífà kúrò lọ́dọ̀ Ọlọ́run alààyè; ṣùgbọ́n ẹ máa bá a nìṣó ní gbígba ara yín níyànjú lẹ́nì kíní kejì lójoojúmọ́, níwọ̀n ìgbà tí a bá ti lè pè é ní ‘Òní,’ kí agbára ìtannijẹ ẹ̀ṣẹ̀ má baà sọ ẹnikẹ́ni nínú yín di aláyà líle.” (Hébérù 3:12, 13) Gbólóhùn Pọ́ọ̀lù náà “ẹ kíyè sára” tẹnu mọ́ ìjẹ́pàtàkì wíwà lójúfò. Ewu rọ̀ dẹ̀dẹ̀! Àìnígbàgbọ́—“ẹ̀ṣẹ̀”—lè dìde nínú ọkàn àyà wa, a sì lè fà kúrò lọ́dọ̀ Ọlọ́run dípò kí a sún mọ́ ọn. (Jákọ́bù 4:8) Pọ́ọ̀lù rán wa létí láti ‘máa bá a nìṣó ní gbígba ara wa níyànjú lẹ́nì kíní kejì.’ A nílò ìfararora ẹgbẹ́ ará. “Ẹni tí ó ya ara rẹ̀ sọ́tọ̀ yóò lépa ìfẹ́ ara rẹ̀, yóò sì kọjú ìjà ńlá sí ohunkóhun tí í ṣe ti òye.” (Òwe 18:1) Ìjẹ́pàtàkì irú ìkẹ́gbẹ́pọ̀ bẹ́ẹ̀ ń sún àwọn Kristẹni lónìí láti máa pésẹ̀ sí àwọn ìpàdé ìjọ, àpéjọ, àti àpéjọpọ̀ déédéé.

11, 12. Èé ṣe tí mímọ kìkì àwọn lájorí ẹ̀kọ́ ìgbàgbọ́ Kristẹni kò fi yẹ kí ó tẹ́ wa lọ́rùn?

11 Lẹ́yìn náà nínú lẹ́tà rẹ̀, Pọ́ọ̀lù fúnni nímọ̀ràn pàtàkì míràn yí: “Bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé ó yẹ kí ẹ jẹ́ olùkọ́ ní ojú ìwòye ibi tí àkókò dé yìí, ẹ̀yin tún nílò ẹnì kan láti máa kọ́ yín láti ìbẹ̀rẹ̀pẹ̀pẹ̀ àwọn ohun àkọ́bẹ̀rẹ̀ nínú àwọn ọ̀rọ̀ ìkéde [ọlọ́wọ̀] ti Ọlọ́run; ẹ sì ti di irúfẹ́ àwọn ẹni tí ó nílò wàrà, kì í ṣe oúnjẹ líle. . . . Oúnjẹ líle jẹ́ ti àwọn ènìyàn tí ó dàgbà dénú, ti àwọn wọnnì tí wọ́n tipasẹ̀ lílò kọ́ agbára ìwòye wọn láti fi ìyàtọ̀ sáàárín ohun tí ó tọ́ àti ohun tí kò tọ́.” (Hébérù 5:12-14) Ó hàn gbangba pé, àwọn Kristẹni kan tí ó jẹ́ Júù kùnà láti tẹ̀ síwájú nínú òye. Wọ́n lọ́ra láti tẹ́wọ́ gba ìmọ́lẹ̀ tí ó ń mọ́lẹ̀ sí i nípa Òfin àti ìkọlà. (Ìṣe 15:27-29; Gálátíà 2:11-14; 6:12, 13) Àwọn kan sì ti lè gbé irú àwọn àṣà bíi Sábáàtì ọ̀sọ̀ọ̀sẹ̀ àti ayẹyẹ ìsìn ọdọọdún ti Ọjọ́ Ètùtù gẹ̀gẹ̀.—Kólósè 2:16, 17; Hébérù 9:1-14.

12 Nítorí náà, Pọ́ọ̀lù sọ pé: “Nísinsìnyí tí a ti fi àkọ́kọ́bẹ̀rẹ̀ ẹ̀kọ́ ìgbàgbọ́ nípa Kristi sílẹ̀, ẹ jẹ́ kí a tẹ̀ síwájú sí ìdàgbàdénú.” (Hébérù 6:1) Eléré ẹlẹ́mìí ẹṣin kan tí ń fiyè sí ìlànà ìṣóúnjẹjẹ rẹ̀ dáradára yóò lè fara da eré ìje onígbà pípẹ́, tí ń tánni lókun. Bákan náà, Kristẹni kan tí ń fiyè sí oúnjẹ tẹ̀mí dáradára—tí kò fi mọ sórí lájorí, ‘ìpìlẹ̀ ẹ̀kọ́ ìgbàgbọ́’—yóò lè máa ba eré ìje náà lọ, yóò sì lè parí rẹ̀. (Fi wé Tímótì Kejì 4:7.) Èyí túmọ̀ sí mímú ọkàn ìfẹ́ dàgbà nínú ohun tí “ìbú àti gígùn àti gíga àti jíjìn” òtítọ́ náà jẹ́, ní títipa báyìí dàgbà dénú.—Éfésù 3:18.

“Ẹ Nílò Ìfaradà”

13. Báwo ni àwọn Kristẹni tí wọ́n jẹ́ Hébérù ṣe fi ìgbàgbọ́ wọn hàn ní ìgbà àtijọ́?

13 Ní sáà tí ó tẹ̀ lé Pẹ́ńtíkọ́sì ọdún 33 Sànmánì Tiwa, àwọn Kristẹni tí ó jẹ́ Júù dúró ṣinṣin láìka àtakò lílekoko sí. (Ìṣe 8:1) Bóyá Pọ́ọ̀lù ní èyí lọ́kàn nígbà tí ó kọ̀wé pé: “Ẹ máa bá a nìṣó ní rírántí àwọn ọjọ́ àtijọ́ nínú èyí tí, lẹ́yìn tí a ti là yín lóye, ẹ fara da ìjà ìdíje ńláǹlà lábẹ́ àwọn ìjìyà.” (Hébérù 10:32) Irú ìfaradà oníṣòtítọ́ bẹ́ẹ̀ fi ìfẹ́ wọn fún Ọlọ́run hàn, ó sì fún wọn ní òmìnira ọ̀rọ̀ sísọ níwájú rẹ̀. (Jòhánù Kíní 4:17) Pọ́ọ̀lù rọ̀ wọ́n láti má ṣe sọ àǹfààní yẹn nù nítorí àìnígbàgbọ́. Ó rọ̀ wọ́n pé: “Ẹ nílò ìfaradà, kí ó baà lè jẹ́ pé, lẹ́yìn tí ẹ ti ṣe ìfẹ́ inú Ọlọ́run tán, kí ẹ lè rí ìmúṣẹ ìlérí náà gbà. Nítorí ní ‘ìgbà díẹ̀ kíún’ sí i, àti pé ‘ẹni tí ń bọ̀ yóò dé kì yóò sì jáfara.’”—Hébérù 10:35-37.

14. Àwọn kókó wo ni ó yẹ kí ó ràn wá lọ́wọ́ láti fara dà àní lẹ́yìn sísin Jèhófà fún ọ̀pọ̀ ọdún?

14 Àwa lónìí ńkọ́? Ọ̀pọ̀ jù lọ lára wa ní ìtara nígbà tí a kọ́kọ́ kẹ́kọ̀ọ́ òtítọ́ Kristẹni. A ha ṣì ní ìtara náà bí? Àbí a ti ‘fi ìfẹ́ tí a ní ní àkọ́kọ́ sílẹ̀’? (Ìṣípayá 2:4) A ha ti rẹ̀wẹ̀sì, àbí a ti sọ̀rètí nù, àbí dídúró de Amágẹ́dọ́nì ti sú wa? Ṣùgbọ́n, dúró ná kí o sì ronú jinlẹ̀. Òtítọ́ náà ṣì jẹ́ àgbàyanu bí ó ti jẹ́ nígbà tí a mọ̀ ọ́n. Jésù ṣì ni Ọba wa ọ̀run. A ṣì ń retí ìyè àìnípẹ̀kun lórí párádísè ilẹ̀ ayé kan, bẹ́ẹ̀ sì ni a ṣì ní ipò ìbátan wa pẹ̀lú Jèhófà. Má sì ṣe gbàgbé láé pé: “Ẹni tí ń bọ̀ yóò dé kì yóò sì jáfara.”

15. Bíi Jésù, báwo ni àwọn Kristẹni kan ti ṣe fara da inúnibíni gbígbóná janjan?

15 Nítorí náà, ọ̀rọ̀ Pọ́ọ̀lù tí a kọ sílẹ̀ nínú Hébérù 12:1, 2 bá a mu wẹ́kú pé: “Ẹ jẹ́ kí àwa pẹ̀lú mú gbogbo ẹrù wíwúwo kúrò àti ẹ̀ṣẹ̀ [àìnígbàgbọ́] tí ó máa ń wé mọ́ wa pẹ̀lú ìrọ̀rùn, ẹ sì jẹ́ kí a fi ìfaradà sá eré ìje tí a gbé ka iwájú wa, bí a ti ń fi tọkàntara wo Olórí Aṣojú àti Aláṣepé ìgbàgbọ́ wa, Jésù. Nítorí [ìdùnnú] tí a gbé ka iwájú rẹ̀ ó fara da òpó igi oró, ó tẹ́ńbẹ́lú ìtìjú, ó sì ti jókòó ní ọwọ́ ọ̀tún ìtẹ́ Ọlọ́run.” Ọ̀pọ̀ nǹkan ni àwọn ìránṣẹ́ Ọlọ́run ti fara dà ní àwọn ọjọ́ ìkẹyìn wọ̀nyí. Bíi Jésù, tí ó jẹ́ olùṣòtítọ́ títí dé ojú ikú oró, àwọn arákùnrin àti arábìnrin wa kan ti fi ìṣòtítọ́ fara da inúnibíni mímúná jù lọ—ọgbà ẹ̀wọ̀n, ìdálóró, ìfipábánilòpọ̀, àní ikú pàápàá. (Pétérù Kíní 2:21) Ọkàn àyà wa kì í ha ń kún fún ìfẹ́ wọn nígbà tí a bá ronú nípa ìwà títọ́ wọn?

16, 17. (a) Àwọn ohun wo tí ó ń pe ìgbàgbọ́ wọn níjà ni ọ̀pọ̀ jù lọ Kristẹni ń dojú kọ? (b) Kí ni a lè máa rántí tí yóò ràn wá lọ́wọ́ láti máa bá sísáré ìje náà fún ìyè lọ?

16 Ṣùgbọ́n, ọ̀rọ̀ tí Pọ́ọ̀lù sọ síwájú sí i ṣì bá ọ̀pọ̀ jù lọ wí: “Ní bíbá ìjà ìdíje yín nìṣó lòdì sí ẹ̀ṣẹ̀ yẹn ẹ kò tí ì dúró tiiri títí dé orí ẹ̀jẹ̀ síbẹ̀.” (Hébérù 12:4) Síbẹ̀síbẹ̀, nínú ètò ìgbékalẹ̀ yí ọ̀nà òtítọ́ kò rọrùn fún ẹnikẹ́ni nínú wa láti tọ̀. ‘Òdì ọ̀rọ̀ láti ẹnu àwọn ẹlẹ́ṣẹ̀’ níbi iṣẹ́ àti nílé ẹ̀kọ́, fífarada ìfiniṣẹlẹ́yà tàbí dídènà fífòòró ẹ̀mí ẹni láti dẹ́ṣẹ̀ ti mú kí àwọn kan rẹ̀wẹ̀sì. (Hébérù 12:3) Ìdẹwò lílágbára ti bá ìpinnu àwọn kan, láti di ọ̀pá ìdiwọ̀n gíga ti Ọlọ́run mú, jẹ́. (Hébérù 13:4, 5) Àwọn apẹ̀yìndà ti nípa lórí ìwàdéédéé nípa tẹ̀mí àwọn díẹ̀ tí wọ́n tẹ́tí sí ìgbékèéyíde onímájèlé wọn. (Hébérù 13:9) Àwọn ìṣòro tí ìyàtọ̀ nínú àkópọ̀ ìwà olúkúlùkù mú wá ti ba ayọ̀ àwọn kan jẹ́. Ṣíṣeré ìnàjú àti àwọn ìgbòkègbodò fàájì jù ti kó àárẹ̀ bá àwọn Kristẹni kan. Àwọn ìṣòro gbígbé nínú ètò àwọn nǹkan ìsinsìnyí sì ń fòòró ẹ̀mí àwọn kan.

17 Lóòótọ́, kò sí èyíkéyìí lára àwọn ipò wọ̀nyí tí ó jẹ́ ‘dídúró tiiri títí dé orí ẹ̀jẹ̀.’ A sì lè tọpasẹ̀ àwọn kan dórí àwọn ìpinnu òdì tí àwa fúnra wa ti ṣe. Ṣùgbọ́n gbogbo wọn ni ó pe ìgbàgbọ́ wa níjà. Ìdí nìyẹn tí ó fi yẹ kí a máa tẹjú wa mọ́ àpẹẹrẹ ìfaradà kíkọyọyọ ti Jésù. Ǹjẹ́ kí a má ṣe gbàgbé bí ìrètí wa ti jẹ́ àgbàyanu tó láé. Ǹjẹ́ kí a má ṣe sọ ìdálójú ìgbàgbọ́ wa pé Jèhófà “di olùṣẹ̀san fún àwọn wọnnì tí ń fi taratara wá a,” nù láé. (Hébérù 11:6) Nígbà náà, a óò ní okun tẹ̀mí láti máa bá eré ìje fún ìyè náà lọ.

A Lè Fara Dà

18, 19. Àwọn ìṣẹ̀lẹ̀ inú ìtàn wo ni ó fi hàn pé àwọn Kristẹni tí wọ́n jẹ́ Hébérù ní Jerúsálẹ́mù kọbi ara sí ìmọ̀ràn Pọ́ọ̀lù tí a mí sí?

18 Báwo ni àwọn Kristẹni tí ó jẹ́ Júù ṣe dáhùn pa dà sí lẹ́tà Pọ́ọ̀lù? Ní nǹkan bí ọdún mẹ́fà lẹ́yìn tí ó ti kọ lẹ́tà tí ó kọ sí àwọn Hébérù, ogun bẹ́ sílẹ̀ ní Jùdíà. Ní ọdún 66 Sànmánì Tiwa, ẹgbẹ́ ọmọ ogun Róòmù sàga ti Jerúsálẹ́mù, ní mímú ọ̀rọ̀ Jésù ṣẹ pé: “Nígbà tí ẹ bá rí tí àwọn ẹgbẹ́ ọmọ ogun adótini bá yí Jerúsálẹ́mù ká, nígbà náà ni kí ẹ mọ̀ pé ìsọdahoro rẹ̀ ti sún mọ́lé.” (Lúùkù 21:20) Ṣùgbọ́n, fún àǹfààní àwọn Kristẹni tí yóò wà ní Jerúsálẹ́mù nígbà náà, Jésù wí pé: “Nígbà náà ni kí àwọn wọnnì tí ń bẹ ní Jùdíà bẹ̀rẹ̀ sí í sá lọ sí àwọn òkè ńlá, kí àwọn wọnnì tí wọ́n sì wà ní àárín rẹ̀ fi ibẹ̀ sílẹ̀, kí àwọn wọnnì tí wọ́n sì wà ní àwọn ibi ìgbèríko má ṣe wọ inú rẹ̀.” (Lúùkù 21:21) Nítorí náà, ogun tí wọ́n bá Róòmù jà gbé ìdánwò kan dìde: Àwọn Kristẹni wọnnì tí ó jẹ́ Júù yóò ha fi Jerúsálẹ́mù, ojúkò ìjọsìn àwọn Júù àti ibùdó tẹ́ńpìlì ológo ni, sílẹ̀ bí?

19 Lójijì, àti fún ìdí tí a kò mọ̀, àwọn ará Róòmù kógun wọn lọ. Ó ṣeé ṣe pé, àwọn Júù onítara ìsìn ka èyí sí ẹ̀rí pé Ọlọ́run ń dáàbò bo ìlú mímọ́ wọn. Àwọn Kristẹni ńkọ́? Ìtàn sọ fún wa pé wọ́n ti fẹsẹ̀ fẹ. Lẹ́yìn náà, ní ọdún 70 Sànmánì Tiwa, àwọn ará Róòmù pa dà wá, wọ́n sì pa Jerúsálẹ́mù run pátápátá, ẹ̀mí sì run lọ́nà tí ó kó jìnnìjìnnì báni. “Ọjọ́ . . . Olúwa” tí Jóẹ́lì sọ tẹ́lẹ̀ ti dé sórí Jerúsálẹ́mù. Ṣùgbọ́n àwọn Kristẹni olùṣòtítọ́ kò sí níbẹ̀ mọ́. Wọ́n ‘rí ìgbàlà.’—Jóẹ́lì 2:30-32; Ìṣe 2:16-21.

20. Kí ni mímọ̀ pé ‘ọjọ́ ńlá Olúwa’ ti sún mọ́lé yẹ kí ó sún wa láti ṣe?

20 Lónìí, a mọ̀ pé ‘ọjọ́ ńlá Olúwa’ mìíràn yóò nípa lórí gbogbo ètò ìgbékalẹ̀ àwọn nǹkan ìsinsìnyí látòkè délẹ̀ láìpẹ́. (Jóẹ́lì 3:12-14) A kò mọ ìgbà tí ọjọ́ yẹn yóò dé. Ṣùgbọ́n Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run mú un dá wa lójú pé yóò dé dandan! Jèhófà wí pé kì yóò pẹ́. (Hábákúkù 2:3; Pétérù Kejì 3:9, 10) Nítorí náà, ẹ jẹ́ kí a “fún àwọn ohun tí a gbọ́ ní àfiyèsí tí ó ju ti àtẹ̀yìnwá lọ.” Yẹra fún àìnígbàgbọ́, “ẹ̀ṣẹ̀ tí ó máa ń wé mọ́ wa pẹ̀lú ìrọ̀rùn.” Pinnu láti fara dà á bí ó ti wù kí ó lè pẹ́ tó. Rántí pé, ètò àjọ Jèhófà ti òkè ọ̀run tí ó dà bíi kẹ̀kẹ́ ẹṣin ńlá wà lórí ìrìn. Yóò mú ète rẹ̀ ṣẹ. Nítorí náà, ǹjẹ́ kí gbogbo wa pátá máa bá eré ìje náà nìṣó, kí a má sì ṣe juwọ́ sílẹ̀ nínú eré ìje náà fún ìyè!

Ìwọ Ha Rántí Bí?

◻ Kíkọbiara sí ọ̀rọ̀ ìyànjú Pọ́ọ̀lù wo sí àwọn ará Fílípì ni yóò ràn wá lọ́wọ́ láti fara dà á nínú eré ìje fún ìyè?

◻ Kí ni yóò ràn wá lọ́wọ́ láti dènà ìtẹ̀sí ayé yìí láti gba àfiyèsí wa?

◻ Báwo ni a ṣe lè ran ara wa lẹ́nì kíní kejì lọ́wọ́ láti fara dà á nínú eré ìje náà?

◻ Kí ni díẹ̀ lára àwọn nǹkan tí ó lè mú kí Kristẹni kan dẹwọ́?

◻ Báwo ni àpẹẹrẹ Jésù ṣe lè ràn wá lọ́wọ́ láti fara dà?

[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 8, 9]

Àwọn Kristẹni, gẹ́gẹ́ bí àwọn eléré ìje, kò gbọ́dọ̀ jẹ́ kí ohunkóhun pín ọkàn wọn níyà

[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 10]

Kò sí ohun tí ó lè dí kẹ̀kẹ́ ẹṣin ńlá ti òkè ọ̀run ti Jèhófà lọ́wọ́ láti mú ète Ọlọ́run ṣẹ

    Yorùbá Publications (1987-2025)
    Jáde
    Wọlé
    • Yorùbá
    • Fi Ráńṣẹ́
    • Èyí tí mo fẹ́ràn jù
    • Copyright © 2025 Watch Tower Bible and Tract Society of Pennsylvania
    • Àdéhùn Nípa Lílò
    • Òfin
    • Ètò Nípa Ìsọfúnni Rẹ
    • JW.ORG
    • Wọlé
    Fi Ráńṣẹ́