Ẹ Maa Dúró Ṣinṣin Ninu Ìgbàgbọ́
Awọn Kókó Itẹnumọ Lati inu Peteru Kìn-ínní
AWỌN Ẹlẹrii Jehofa dojukọ oniruuru awọn adanwo, tabi ìdánwo ìgbàgbọ́ wọn. Ni awọn ilẹ kan, iṣẹ iwaasu Ijọba wọn ni a nṣe loju inunibini nla. Satani Eṣu ni o wa lẹhin iwọnyi ati awọn isapa miiran lati pa ipo ibatan wọn pẹlu Ọlọrun run. Ṣugbọn ohun ki yoo ṣaṣeyọri si rere, nitori Jehofa mu awọn iranṣẹ rẹ̀ duro gbọnyingbọnyin—bẹẹni, duroṣinṣin ninu igbagbọ.
Apọsteli Peteru ni anfaani lati ‘fun awọn arakunrin rẹ̀ lokun’ awọn ti a “ko ẹ̀dùn-ọkàn ba nipa oniruuru awọn adanwo.” (Luuku 22:32; 1 Peteru 1:6, 7, NW) Oun ṣe bẹẹ ninu lẹta rẹ̀ akọkọ, ti a kọ ni nnkan bii 62-64 C.E. lati Babiloni. Ninu rẹ̀ Peteru gba awọn Kristian Juu ati Keferi niyanju, o tù wọn ninu, o sì fun wọn ni iṣiri, ni riran wọn lọwọ lati farada awọn ikọlu Satani ki wọn sì “duroṣinṣin ninu igbagbọ.” (1 Peteru 1:1, 2; 5:8, 9) Nisinsinyi ti akoko Eṣu ti di kukuru ti awọn igbejako rẹ̀ sì rorò tobẹẹ, dajudaju awọn eniyan Jehofa lè janfaani lati inu awọn ọ̀rọ̀ onimiisi Peteru.
Ìwà Ti A Gbekari Awọn Ilana Oniwa-bi-Ọlọrun
Yala ireti wa jẹ ti ọrun tabi ti ilẹ-aye, o nilati ran wa lọwọ lati farada awọn adanwo ki a sì huwa ni ọna oniwa-bi-Ọlọrun. (1:1–2:12) Ireti ogún ti ọ̀run mu ki awọn ẹni-ami-ororo yọ̀ loju awọn adanwo, eyi ti o ńyọ́ igbagbọ wọn mọ́ niti gidi. Gẹgẹ bi ile tẹmi ti a kọ sori ipilẹ Kristi, wọn rú awọn ẹbọ tẹmi ti o ṣetẹwọgba lọdọ Ọlọrun wọn sì dari araawọn ni ọna rere ti o mu ògo wa fun Un.
Awọn ibalo wa pẹlu awọn eniyan ẹlẹgbẹ wa ni awọn ilana oniwa-bi-Ọlọrun nilati ṣakoso. (2:13–3:12) Peteru fihan pe awa nilati wà ni ijuwọsilẹ fun awọn oluṣakoso eniyan. Awọn iranṣẹ ile ni wọn nilati wa labẹ awọn oluwa wọn, ati awọn aya si awọn ọkọ wọn. Iwa bi Ọlọrun ti aya Kristian kan lè jere ọkọ rẹ̀ alaigbagbọ wá sinu igbagbọ tootọ. Ọkọ onigbagbọ kan si nilati ‘fi ọla fun aya rẹ̀ gẹgẹ bi ohun-eelo ti ko lagbara.’ Gbogbo awọn Kristian nilati fi imọlara fun ọmọnikeji hàn, ki wọn ni ifẹni ara, ṣe ohun ti o dara, ki wọn sì lepa alaafia.
Ifarada Maa Nmu Awọn Ibukun Wa
Fifi iṣotitọ farada ijiya niha ọ̀dọ̀ Kristian tootọ yoo yọrisi awọn ibukun. (3:13–4:19) Bi awa ba njiya nitori òdodo, awa nilati layọ. Ju bẹẹ lọ, niwọnbi Kristi ti jiya ninu ara lati ṣamọna wa si ọ̀dọ̀ Ọlọrun, awa kò nilati gbe ni ibamu pẹlu awọn ifẹ ti ẹran-ara. Bi awa ba farada awọn adanwo pẹlu iṣotitọ, awa yoo ṣajọpin ninu idunnu nlanla nigba iṣipaya Jesu. Mimu ẹgan mọra nitori orukọ Kristi, tabi gẹgẹ bi awọn ọmọ-ẹhin rẹ̀, nilati mu wa layọ nitori pe o fi ẹri hàn pe awa ni ẹmi Jehofa. Nitori naa gẹgẹ bi awa ti jiya ni ibamu pẹlu ifẹ-inu Ọlọrun, ẹ jẹ ki a fi araawa si abẹ itọju rẹ̀ ki a sì maa baa lọ lati ṣe rere.
Gẹgẹ bi Kristian, awa nilati mu awọn ojuṣe wa ṣe pẹlu iṣotitọ ki a sì rẹ araawa silẹ labẹ ọwọ́ agbara Ọlọrun. (5:1-14) Awọn alagba gbọdọ bojuto agbo Ọlọrun tinutinu, gbogbo wa sì nilati kó gbogbo aniyan wa sori Jehofa, ni mimọ daju pe oun bikita fun wa. Awa tun nilati mu iduro wa lodisi Eṣu ki a ma sì ṣe sọ ireti nu, nitori awọn arakunrin wa ńjìyà lọna kan naa bii tiwa. Maa ranti nigba gbogbo pe Jehofa Ọlọrun yoo mu wa duro gbọnyin yoo sì fun wa lagbara lati maa duro ṣinṣin ninu igbagbọ.
[Àpótí/Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 30]
Ọ̀ṣọ́ Obinrin: Ninu imọran si awọn obinrin Kristian, Peteru wipe: “Ẹ ma si ṣe jẹ ki ọ̀ṣọ́ yin jẹ ti irun dídì ode ati fifi ohun-ọ̀ṣọ́ wura sára tabi ti wíwọ awọn ẹ̀wù àwọ̀lé, ṣugbọn ẹ jẹ ki o jẹ eniyan ìkọ̀kọ̀ ọkan-aya ninu aṣọ ọ̀ṣọ́ ti ko ṣee sọ dibajẹ ti ẹmi idakẹjẹẹ, eyi ti o jẹ iyebiye nla ni oju Ọlọrun.” (1 Peteru 3:3, 4, NW) Laaarin ọrundun kìn-ínní C.E., awọn obinrin oloriṣa saba maa nni awọn àṣà irun dídì gígọntiọ, ni dídi irun wọn gígùn si awọn ọ̀nà afẹfẹyẹ̀yẹ̀ oníṣekárími ati sísín awọn ohun-ọ̀ṣọ́ wura sara awọn irun dídì naa. O dabi ẹni pe, ọpọlọpọ ṣe bẹẹ gẹgẹ bi ifihansode alaṣehan—ohun kan ti kò tọ́ fun awọn Kristian. (1 Timoti 2:9, 10) Sibẹ, kii ṣe gbogbo ọ̀ṣọ́ ni kò tọna, nitori Peteru fi “wíwọ awọn ẹ̀wù àwọ̀lé” kún un.—ni kedere ohun kan ti a kò lè ṣe alaini. Okuta iyebiye ni awọn iranṣẹ Ọlọrun tun ńlò ni awọn akoko igbaani. (Jẹnẹsisi 24:53; Ẹkisodu 3:22; 2 Samuẹli 1:24; Jeremaya 2:32; Luuku 15:22) Bi o ti wu ki o ri, obinrin Kristian kan fi pẹlu ọgbọ́n yẹra fun awọn ohun-ọ̀ṣọ́ oníṣekárími ati aṣọ imura ọ̀ṣọ́ ti ńtẹ́ imọlara ara lọrun, o sì nilati ri i daju pe lílo awọn ohun ìṣaralóge jẹ eyi ti o bojumu. Koko imọran apọsteli naa ni pe oun nilati fi itẹnumọ sori, kii ṣe ọ̀ṣọ́ ti ita, ṣugbọn ti inu. Lati jẹ afanimọra nitootọ, oun gbọdọ wọṣọ ní iwọntunwọnsi ki o sì ni itẹsi ọkan ẹni ti o bẹru Ọlọrun.—Owe 31:30; Mika 6:8.
[Credit Line]
Ẹka Iṣẹ awọn Nnkan Igbaani ati Ile Akojọ Ohun Iṣẹmbaye ni Israel;
Ile Akojọ Ohun Iṣẹmbaye Israel/David Harris