ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍNTÁNẸ́Ẹ̀TÌ ti Watchtower
ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍŃTÁNẸ́Ẹ̀TÌ
ti Watchtower
Yorùbá
ọ́
  • ẹ
  • ọ
  • ṣ
  • ń
  • ẹ́
  • ẹ̀
  • ọ́
  • ọ̀
  • BÍBÉLÌ
  • ÌTẸ̀JÁDE
  • ÌPÀDÉ
  • ijwbq àpilẹ̀kọ 131
  • Kí Ni Bíbélì Sọ Nípa Ṣíṣe Ara Lóge?

Kò sí fídíò kankan ní apá yìí.

Má bínú, fídíò yìí kò jáde.

  • Kí Ni Bíbélì Sọ Nípa Ṣíṣe Ara Lóge?
  • Ohun Tí Bíbélì Sọ
  • Ìsọ̀rí
  • Àpilẹ̀kọ Míì Tó Jọ ọ́
  • Ohun tí Bíbélì sọ
  • Bíbélì kò sọ pé ó burú láti ṣara lóge
  • Àṣìlóye nípa ṣíṣe ara lóge
  • Ibeere Lati Ọwọ Awọn Onkawe
    Ilé-Ìṣọ́nà Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—1991
  • Ṣé Káwọn Obìnrin Máa Bo Ẹwà Wọn Mọ́ra Ni?
    Jí!—2005
  • Ẹ Maa Dúró Ṣinṣin Ninu Ìgbàgbọ́
    Ilé-Ìṣọ́nà Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—1991
  • Ǹjẹ́ Ọ̀nà Ìwọṣọ àti Ìmúra Rẹ Já Mọ́ Nǹkan Lójú Ọlọ́run?
    Jí!—1998
Ohun Tí Bíbélì Sọ
ijwbq àpilẹ̀kọ 131
Obìnrin kan wọ ẹ̀gbà ọrùn

Kí Ni Bíbélì Sọ Nípa Ṣíṣe Ara Lóge?

Ohun tí Bíbélì sọ

Bó tilẹ̀ jẹ́ pé Bíbélì kò ṣe kúlẹ̀kúlẹ̀ àlàyé nípa ṣíṣe ara lóge, síbẹ̀ kò sọ pé ó burú téèyàn bá ṣojú lóge, tó lo àtíkè tàbí tó tọ́tè, tó lo ohun ọ̀ṣọ́ tàbí àwọn nǹkan míì téèyàn fi ń ṣara lóge. Àmọ́, dípò tí Bíbélì á fi máa sọ̀rọ̀ ṣáá nípa ìrísí ara, ohun tó sọ̀rọ̀ nípa ẹ̀ jù ni “aṣọ ọ̀ṣọ́ tí kò lè díbàjẹ́ ti ẹ̀mí ìṣejẹ́ẹ́jẹ́ẹ́ àti ti ìwà tútù.”​—1 Pétérù 3:3, 4.

Bíbélì kò sọ pé ó burú láti ṣara lóge

  • Àwọn obìnrin olóòótọ́ nínú Bíbélì ṣe ara wọn lóge. Rèbékà tó fẹ́ Ísákì ọmọ Ábúráhámù wọ òrùka imú tó jẹ́ góòlù, ẹ̀gbà ọwọ́ tó jẹ́ góòlù àtàwọn ohun ọ̀ṣọ́ míì tó jẹ́ olówó ńlá, èyí tí Ábúráhámù tó pa dà di bàbá ọkọ rẹ̀ fún un. (Jẹ́nẹ́sísì 24:22, 30, 53) Bákan náà, Ẹ́sítérì gbà kí wọ́n ṣe “ìwọ́ra obìnrin” fún òun, kí wọ́n lè múra rẹ̀ sílẹ̀ de ipò ayaba Ilẹ̀ Ọba Páṣíà tó ń dúró dè é. (Ẹ́sítérì 2:7, 9, 12) Onírúurú ohun èlò ìṣaralóge ni wọ́n máa ń lò fún ìwọ́ra yìí.

  • Bíbélì máa ń lo ọ̀ṣọ́ láti fi ṣàpèjúwe ohun tó dáa. Bí àpẹẹrẹ, Bíbélì fi ẹni tó fúnni ní ìmọ̀ràn ọlọ́gbọ́n wé “yẹtí tí a fi wúrà ṣe, . . . ní etí tí ń gbọ́ràn.” (Òwe 25:12) Bákan náà, Ọlọ́run fi àjọṣe rẹ̀ pẹ̀lú àwọn ọmọ Ísírẹ́lì wé bí ọkọ kan ṣe máa ń fi àwọn ohun ọ̀ṣọ́ bíi ẹ̀gbà ọwọ́, ẹ̀gbà ọrùn àti yẹtí ṣe ìyàwó rẹ̀ lọ́ṣọ̀ọ́. Ohun ọ̀ṣọ́ yìí mú kí orílẹ̀-èdè náà “lẹ́wà gidigidi.”​—Ìsíkíẹ́lì 16:11-​13.

Àṣìlóye nípa ṣíṣe ara lóge

Àṣìlóye: Ní 1 Pétérù 3:3, Bíbélì dẹ́bi fún ‘irun dídì àti fífi àwọn ohun ọ̀ṣọ́ wúrà sára.’

Òótọ́: Àwọn ẹsẹ tó tẹ̀ lé ẹsẹ yẹn jẹ́ ká rí i pé ohun tí ẹsẹ Bíbélì yẹn ń sọ ni pé ẹwà inú ló ṣe pàtàkì ju ìrísí tàbí ṣíṣe ara lóge lọ. (1 Pétérù 3:3-6) Àwọn ẹsẹ Bíbélì míì náà wà tó ṣe irú àfiwé yìí.​—1 Sámúẹ́lì 16:7; Òwe 11:22; 31:30; 1 Tímótì 2:9, 10.

Àṣìlóye: Bí Jésíbẹ́lì Ayaba búburú ṣe ṣojú lóge tàbí tó “lé tìróò sójú,” fi hàn pé ohun tí kò dáa ni láti máa ṣe ojú lóge.​—2 Àwọn Ọba 9:30

Òótọ́: Ìwà burúkú ọwọ́ Jésíbẹ́lì, irú bíi iṣẹ́ àjẹ́ àti ìpànìyàn ni Ọlọ́run fi dá a lẹ́jọ́, kì í ṣe torí ìrísí rẹ̀.​—2 Àwọn Ọba 9:7, 22, 36, 37.

    Yorùbá Publications (1987-2025)
    Jáde
    Wọlé
    • Yorùbá
    • Fi Ráńṣẹ́
    • Èyí tí mo fẹ́ràn jù
    • Copyright © 2025 Watch Tower Bible and Tract Society of Pennsylvania
    • Àdéhùn Nípa Lílò
    • Òfin
    • Ètò Nípa Ìsọfúnni Rẹ
    • JW.ORG
    • Wọlé
    Fi Ráńṣẹ́