Ojú Ìwòye Bíbelì
Ǹjẹ́ Ọ̀nà Ìwọṣọ àti Ìmúra Rẹ Já Mọ́ Nǹkan Lójú Ọlọ́run?
“Bí atọ́ka ìwé kan ti ń fi ohun tó wà nínú rẹ̀ hàn, . . . ni ìrísí àti aṣọ tí ọkùnrin tàbí obìnrin kan wọ̀ ṣe ń fi bí ìrònú rẹ̀ ṣe rí hàn.”—Òǹkọ̀wé eré ìtàgé tí ó jẹ́ ọmọ ilẹ̀ Gẹ̀ẹ́sì, Philip Massinger.
NÍ Ọ̀RÚNDÚN kẹta Sànmánì Tiwa, òǹkọ̀wé fún ṣọ́ọ̀ṣì náà, Titus Clemens, ṣàkọsílẹ̀ àwọn òfin rẹpẹtẹ kan lórí ọ̀nà ìwọṣọ àti ìmúra. Ó ka lílo àwọn ohun ọ̀ṣọ́ àti aṣọ olówó ńlá tàbí aláwọ̀ mèremère léèwọ̀. Àwọn obìnrin kò gbọ́dọ̀ pa irun wọn láró, wọn kò sì gbọ́dọ̀ “kun ojú wọn.” Ó ní kí àwọn ọkùnrin fá orí wọn kodoro nítorí pé, “bí ọkùnrin bá gẹ irun rẹ, . . . ó ń fi í hàn bí ẹni iyì,” àmọ́ wọn kò gbọ́dọ̀ ṣe ohunkóhun sí irùgbọ̀n wọn, nítorí pé ó “ń jẹ́ kí ojú ní iyì àti ọlá àṣẹ tí bàbá ní.”a
Ní ọ̀rúndún mélòó kan lẹ́yìn náà, aṣáájú ìjọ Pùròtẹ́sítáǹtì náà, John Calvin, gbé àwọn òfin tí ń tọ́ka àwọ̀ àti oríṣi aṣọ tí àwọn ọmọlẹ́yìn rẹ̀ lè wọ̀ kalẹ̀. Ó fagi lé lílo àwọn ohun ọ̀ṣọ́ àti léèsì, wọ́n sì lè ju obìnrin tí ó bá ṣe irun rẹ̀ lọ́ṣọ̀ọ́, tí ó fi ga dé “ìwọ̀n àìmọ́” sẹ́wọ̀n.
Irú àwọn èrò aláṣejù bẹ́ẹ̀, tí àwọn aṣáájú ìsìn ti ń gbé lárugẹ láti ọdún púpọ̀ wá náà, ti mú kí ọ̀pọ̀ àwọn aláìlábòsí ṣe kàyéfì pé, Ǹjẹ́ ohun tí mo ń wọ̀ já mọ́ nǹkan lójú Ọlọ́run? Ǹjẹ́ ó fagi lé irú àwọn àṣà ìṣoge kan tàbí lílo èròjà ìṣojúlóge? Kí ni Bíbélì fi kọ́ni?
Ọ̀ràn Ara Ẹni
Bí a ṣe ṣàkọsílẹ̀ rẹ̀ nínú Jòhánù 8:31, 32, ó dùn mọ́ni pé Jésù sọ fún àwọn ọmọ ẹ̀yìn rẹ̀ pé: “Bí ẹ bá dúró nínú ọ̀rọ̀ mi, . . . ẹ ó sì mọ òtítọ́, òtítọ́ yóò sì dá yín sílẹ̀ lómìnira.” Bẹ́ẹ̀ ló rí, òtítọ́ tí Jésù fi kọ́ni jẹ́ láti dá àwọn ènìyàn sílẹ̀ lómìnira lọ́wọ́ àwọn ìnira apọ́nnilójú tí àwọn àṣà àtọwọ́dọ́wọ́ àti ẹ̀kọ́ èké máa ń mú wá. A pète wọn láti fi tu àwọn “tí ń ṣe làálàá, tí a sì di ẹrù wọ̀ lọ́rùn” lára. (Mátíù 11:28) Kò sí lọ́kàn Jésù tàbí Bàbá rẹ̀, Jèhófà Ọlọ́run, láti máa ṣàkóso ìgbésí ayé àwọn ènìyàn débi tí wọn kò tún ní lè dánú ṣe nǹkan, kí wọ́n sì lo ìrònú wọn nínú àwọn ọ̀ràn ara ẹni. Jèhófà ń fẹ́ kí wọ́n di ènìyàn tí ó dàgbà dénú, tí “wọ́n tipasẹ̀ lílò kọ́ agbára ìwòye wọn láti fi ìyàtọ̀ sáàárín ohun tí ó tọ́ àti ohun tí kò tọ́.”—Hébérù 5:14.
Nípa bẹ́ẹ̀, Bíbélì kò la àwọn òfin lórí ọ̀nà ìwọṣọ àti ìmúra tàbí lílo àwọn ohun ìṣaralóge kalẹ̀ fúnni, yàtọ̀ sí irú àwọn aṣọ pàtó kan tí Òfin Mósè béèrè pé kí àwọn Júù máa wọ̀ pẹ̀lú ète láti ràn wọ́n lọ́wọ́ láti ya ara wọn sọ́tọ̀ lọ́dọ̀ àwọn orílẹ̀-èdè tí ó yí wọn ká àti ipá àìmọ́ wọn. (Númérì 15:38-41; Diutarónómì 22:5) Nínú ìṣètò ìjọ Kristẹni, ọ̀nà ìwọṣọ àti ìmúra jẹ́ ọ̀ràn bí olúkúlùkù bá ṣe fẹ́ ẹ.
Bí ó tilẹ̀ rí bẹ́ẹ̀, ìyẹn kò wá túmọ̀ sí pé ohun tí a wọ̀ kò ṣe nǹkan lójú Ọlọ́run tàbí pé, ‘kò sí ohun tí a kò lè wọ̀.’ Kàkà bẹ́ẹ̀, Bíbélì ní àwọn ìtọ́sọ́nà tí ó bọ́gbọ́n mu tí ń fi èrò Ọlọ́run lórí ọ̀nà ìwọṣọ àti ìmúra hàn.
“Pẹ̀lú Ìmẹ̀tọ́mọ̀wà àti Ìyèkooro Èrò Inú”
Àpọ́sítélì Pọ́ọ̀lù kọ̀wé pé kí àwọn obìnrin Kristẹni “máa fi aṣọ tí ó wà létòletò ṣe ara wọn lọ́ṣọ̀ọ́, pẹ̀lú ìmẹ̀tọ́mọ̀wà àti ìyèkooro èrò inú, kì í ṣe pẹ̀lú àwọn àrà irun dídì àti wúrà tàbí péálì tàbí aṣọ àrà olówó ńlá gan-an.” Pétérù pẹ̀lú gbani nímọ̀ràn lòdì sí “irun dídì lóde ara àti ti fífi àwọn ohun ọ̀ṣọ́ wúrà sára.”—1 Tímótì 2:9; 1 Pétérù 3:3.
Ṣé Pétérù àti Pọ́ọ̀lù ń sọ pé àwọn Kristẹni lóbìnrin àti lọ́kùnrin kò gbọ́dọ̀ mú ìrísí wọn sunwọ̀n ni? Rárá o! Ní ti gidi, Bíbélì dárúkọ àwọn ọkùnrin àti obìnrin olùṣòtítọ́ tí wọ́n lo àwọn ohun ọ̀ṣọ́ tàbí òróró ìṣaralóge àti lọ́fíńdà. Kí Ẹ́sítérì tó wọlé lọ bá Ahasuwérúsì Ọba, ó lo àwọn òróró onílọ́fínńdà àti ìlànà ìwọ́ra láti mú ẹwà rẹ̀ dára sí i. Wọ́n sì fi aṣọ ọ̀gbọ̀ àtàtà wọ Jósẹ́fù, wọ́n sì fi ìlẹ̀kẹ̀ ọrùn tí a fi wúrà ṣe sí ọrùn rẹ̀.—Jẹ́nẹ́sísì 41:42; Ẹ́kísódù 32:2, 3; Ẹ́sítérì 2:7, 12, 15.
Bí Pọ́ọ̀lù ṣe lo gbólóhùn náà, “ìyèkooro èrò inú,” ràn wá lọ́wọ́ láti lóye ìmọ̀ràn náà. Ọ̀rọ̀ èdè Gíríìkì náà gangan túmọ̀ sí jíjẹ́ oníwọ̀ntúnwọ̀nsì àti olùkóra-ẹni-níjàánu. Ó túmọ̀ sí fífìrẹ̀lẹ̀ ronú nípa ara ẹni, kí a má pe àfiyèsí tí kò tọ́ síra ẹni. Àwọn ìtumọ̀ Bíbélì mìíràn pe ọ̀rọ̀ yìí ní “pẹ̀lú ọgbọ́n inú,” “pẹ̀lú làákàyè,” “mú jẹ́ mímọ́,” tàbí “pẹ̀lú ìkára-ẹni-lọ́wọ́kò.” Ànímọ́ yìí jẹ́ ohun pàtàkì kan tí a ń béèrè lọ́wọ́ àwọn Kristẹni alàgbà.—1 Tímótì 3:2.
Nítorí náà, nígbà tí Ìwé Mímọ́ wí fún wa pé ọ̀nà ìwọṣọ àti ìmúra wa gbọ́dọ̀ jẹ́ pẹ̀lú ìmẹ̀tọ́mọ̀wà, kí ó sì wà létòlétò, ó rọ̀ wá láti yẹra fún ọ̀nà ìgbàránṣọ tí ó jẹ́ àṣejù, tí yóò mú àwọn ẹlòmíràn kọsẹ̀, tí yóò sì tàbùkù sí ìfùsì wa àti ti ìjọ Kristẹni. Dípò pípe àfiyèsí sí ìrísí wọn nípasẹ̀ ìṣaralọ́ṣọ̀ọ́, àwọn tí wọ́n ní àwọn bọ̀wọ̀ fún Ọlọ́run gbọ́dọ̀ fi ìyèkooro èrò inú hàn, kí wọ́n sì fún “ẹni ìkọ̀kọ̀ ti ọkàn-àyà nínú aṣọ ọ̀ṣọ́ tí kò lè díbàjẹ́ ti ẹ̀mí ìṣejẹ́ẹ́jẹ́ẹ́ àti ti ìwà tútù” láfiyèsí. Pétérù parí ọ̀rọ̀ rẹ̀ pé, èyí “níye lórí gidigidi lójú Ọlọ́run.”—1 Pétérù 3:4.
Àwọn Kristẹni jẹ́ “ìran àpéwò ní gbọ̀ngàn ìwòran fún ayé.” Ó yẹ kí wọ́n máa ronú nípa èrò tí wọ́n ń gbìn sọ́kàn àwọn ẹlòmíràn, pàápàá bí wọ́n bá ro ti àṣẹ tí a pa fún wọn láti máa wàásù ìhìn rere náà. (1 Kọ́ríńtì 4:9; Mátíù 24:14) Nítorí náà, wọn kò ní fẹ́ láti jẹ́ kí ohunkóhun, títí kan ìrísí wọn, yí àwọn ẹlòmíràn lọ́kàn padà láti má ṣe tẹ́tí sí ìhìn iṣẹ́ pàtàkì yẹn.—2 Kọ́ríńtì 4:2.
Bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé ọ̀nà ìgbàránṣọ kò rí bákan náà níbi gbogbo, Bíbélì fún olúkúlùkù ní ìtọ́sọ́nà bíbọ́gbọ́nmu, tí ó ṣe kedere, tí ń jẹ́ kí wọ́n lè ṣe yíyàn tí ó dára. Ní fàlàlà àti pẹ̀lú ìfẹ́ ni Ọlọ́run fàyè gba àwọn ènìyàn láti yan ọ̀nà ìwọṣọ àti ìmúra tí wọ́n bá yàn láàyò, kí wọ́n sáà ti tẹ̀ lé àwọn ìlànà wọ̀nyẹn.
[Àlàyé ìsàlẹ̀ ìwé]
a Àwọn ènìyàn gbìyànjú láti ti àwọn ìkàléèwọ̀ yìí lẹ́yìn nípa lílọ́ Ìwé Mímọ́ lọ́rùn. Bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé Bíbélì kò sọ ohun tí ó jọ bẹ́ẹ̀, ajẹgàba ẹlẹ́kọ̀ọ́ ìsìn náà, Tertullian, fi kọ́ni pé, nítorí pé obìnrin ló fa “ẹ̀ṣẹ̀ àkọ́kọ́, àti ìtìjú . . . ìparun ayérayé tí ènìyàn wà nínú rẹ̀,” àwọn obìnrin gbọ́dọ̀ máa rìn “kiri bí Éfà, kí wọ́n máa ṣọ̀fọ̀, kí wọ́n sì máa ronú pìwà dà.” Ní gidi, ó rin kinkin mọ́ ọn pé, obìnrin tí ó bá rẹwà lọ́nà àdánidá gbọ́dọ̀ fi ẹwà rẹ̀ pa mọ́ pàápàá.—Fi wé Róòmù 5:12-14; 1 Tímótì 2:13, 14.